ÀPILẸ̀KỌ 42
ORIN 44 Àdúrà Ẹni Tó Ní Ẹ̀dùn Ọkàn
Bó O Ṣe Lè Gbàdúrà sí Jèhófà Látọkàn Wá
“ Gbogbo ọkàn mi ni mo fi pè ọ́. Dá mi lóhùn, Jèhófà.”—SM. 119:145.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Tá a bá ń ronú nípa àwọn àdúrà tó wà nínú Bíbélì, á jẹ́ ká lè máa gbàdúrà sí Jèhófà látọkàn wá.
1-2. (a) Tá a bá ń gbàdúrà, kí ni kì í jẹ́ ká sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa fún Jèhófà? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa ń fetí sí àdúrà wa?
ṢÉ Ó máa ń ṣe ẹ́ nígbà míì bíi pé ohun kan náà lo máa ń sọ tó o bá ń gbàdúrà tàbí pé o kì í sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ tó o bá ń gbàdúrà? Tó bá ń ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀, mọ̀ pé ìwọ nìkan kọ́ nirú ẹ̀ ń ṣe. Kòókòó jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé lè má jẹ́ kí àdúrà wa gùn tó bá a ṣe fẹ́. Ẹ̀rù sì lè máa bà wá láti sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa fún Jèhófà torí a rò pé a ò yẹ lẹ́ni tó ń bá a sọ̀rọ̀.
2 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà kì í wo bí àdúrà wa ṣe dùn mọ̀ràn-ìn mọran-in tó, ohun tó ń wò ni bóyá a gbàdúrà látọkàn wá. Bíbélì sọ pé Jèhófà máa ń “gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́.” (Sm. 10:17) Torí náà, ó máa ń fetí sí gbogbo ohun tá à ń sọ torí ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.—Sm. 139:1-3.
3. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 A lè bi ara wa pé: Báwo la ṣe lè sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa fún Jèhófà tá a bá ń gbàdúrà? Báwo la ṣe lè gbàdúrà sí Jèhófà látọkàn wá? Báwo làwọn àdúrà àtọkànwá tó wà nínú Bíbélì ṣe lè mú kí àdúrà wa dára sí i? Kí la lè ṣe tá ò bá mọ ohun tá a máa sọ fún Jèhófà? Ẹ jẹ́ ká dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
SỌ BÍ NǸKAN ṢE RÍ LÁRA Ẹ FÚN JÈHÓFÀ
4. Kí ló máa jẹ́ ká sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa fún Jèhófà? (Sáàmù 119:145)
4 Torí a mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ ọ̀rẹ́ tó ń dúró tini nígbà ìṣòro, àá sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa fún un tá a bá ń gbàdúrà. Ẹni tó kọ Sáàmù 119 gbà pé irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà. Onísáàmù yẹn náà níṣòro. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹlẹ́tàn parọ́ burúkú mọ́ ọn. (Sm. 119:23, 69, 78) Ó tún máa ń ṣàṣìṣe torí aláìpé ni. (Sm. 119:5) Láìka gbogbo ìyẹn sí, ó sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ fún Jèhófà.—Ka Sáàmù 119:145.
5. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká jẹ́ kí ohunkóhun mú ká rò pé a ò lè gbàdúrà sí Jèhófà? Sọ àpèjúwe kan.
5 Jèhófà fẹ́ kí gbogbo wa títí kan àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì máa gbàdúrà sóun. (Àìsá. 55:6, 7) Torí náà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun mú ká rò pé a ò lè gbàdúrà sí Jèhófà. Wo àpèjúwe yìí. Tí ẹnì kan bá sọ nù sínú igbó tí ò sì mọ̀nà mọ́, á pariwo kí àwọn tó wà lágbègbè náà lè ràn án lọ́wọ́. Àmọ́ ṣé ẹni náà ò ní wá ìrànlọ́wọ́ torí pé ojú ń tì í póun ti sọ nù sínú igbó? Rárá o! Lọ́nà kan náà, tá a bá ti dẹ́ṣẹ̀ tàbí tá ò mọ ohun tá a máa ṣe nípa ọ̀rọ̀ kan, ó yẹ ká sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa fún Jèhófà.—Sm. 119:25, 176.
BÁ A ṢE LÈ GBÀDÚRÀ SÍ JÈHÓFÀ LÁTỌKÀN WÁ
6-7. Kí ló máa jẹ́ ká sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa fún Jèhófà? Sọ àpẹẹrẹ kan. (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
6 Tá a bá sọ ohun tá à ń rò àti bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa fún Jèhófà, á jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Torí náà, kí lá jẹ́ ká máa gbàdúrà látọkàn wá?
7 Máa ronú nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà.a Tá a bá ń ronú nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà, á jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún wa láti sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa tá a bá ń gbàdúrà. (Sm. 145:8, 9, 18) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Kristine tí bàbá ẹ̀ jẹ́ oníwà ipá. Ó sọ pé: “Kò rọrùn fún mi láti gbà pé Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ mi ni Jèhófà, kí n sì máa bá a sọ̀rọ̀. Mo rò pé kò lè nífẹ̀ẹ́ mi mọ́ nítorí àwọn àṣìṣe mi.” Kí ló mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lọ́nà tó tọ́? Ó sọ pé: “Nígbà tí mo ronú nípa ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà ń fi hàn sáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀, mo rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ mi. Mo mọ̀ pé kò ní fi mí sílẹ̀ láé. Tí mo bá tiẹ̀ ṣàṣìṣe, ó ṣì máa nífẹ̀ẹ́ mi, á sì ràn mí lọ́wọ́. Ìyẹn ti jẹ́ kó rọrùn fún mi láti bá a sọ ohun tó ń múnú mi dùn àtohun tó ń bà mí nínú jẹ́.”
8-9. Àwọn àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ronú nípa ohun tó o fẹ́ sọ kó o tó gbàdúrà? Sọ àpẹẹrẹ kan.
8 Ronú nípa ohun tó o fẹ́ sọ. Kó o tó gbàdúrà, o lè bi ara ẹ láwọn ìbéèrè kan. Bí àpẹẹrẹ, ‘Ìṣòro wo ni mò ń bá yí lọ́wọ́lọ́wọ́? Ṣé ẹnì kan wà tó yẹ kí n dárí jì? Ṣé àwọn nǹkan kan wà tí mò ń bá yì lọ́wọ́lọ́wọ́ tí mo fẹ́ kí Jèhófà bá mi yanjú?’ (2 Ọba 19:15-19) Àwa náà lè fara wé Jésù tá a bá ń gbàdúrà. Ó yẹ ká máa ronú ohun tá a fẹ́ sọ nípa orúkọ Jèhófà, Ìjọba ẹ̀ àtohun tó fẹ́ ṣe fáráyé.—Mát. 6:9, 10.
9 Nígbà tí Arábìnrin Aliska mọ̀ pé ọkọ òun ò ní pẹ́ kú torí àrùn jẹjẹrẹ inú ọpọlọ, kò rọrùn fún un láti gbàdúrà. Ó sọ pé: “Ìdààmú bá mi débi pé tí mo bá fẹ́ gbàdúrà, mi kì í mọ ohun tí mo lè sọ.” Kí ló ràn án lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Kí n tó gbàdúrà, mo máa ń ro ohun tí màá sọ fún Jèhófà kó má jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ara mi àti ti ọkọ mi nìkan ni màá sọ. Ìyẹn máa ń jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀ kára sì tù mí tí mo bá ń gbàdúrà.”
10. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká máa kánjú gbàdúrà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
10 Má ṣe kánjú gbàdúrà. A lè gbàdúrà tí ò gùn ká sì sọ ohun tá a fẹ́ fún Jèhófà, àmọ́ tá a bá jẹ́ kí àdúrà wa gùn, àá lè sọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa fún Jèhófà.b Arákùnrin Elijah tó jẹ́ ọkọ Aliska gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, ó sọ pé: “Mo máa ń sapá láti gbàdúrà lọ́pọ̀ ìgbà jálẹ̀ ọjọ́ kan. Mo máa ń jẹ́ kí àdúrà mi gùn, ìyẹn sì ti jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Jèhófà máa ń ní sùúrù fún mi kí n parí àdúrà mi, torí náà mo máa ń fara balẹ̀ tí mo bá ń gbàdúrà, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí n sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi.” Á dáa kó o máa wáyè gbàdúrà níbi tó dákẹ́ rọ́rọ́ láìsí ohun tó máa dí ẹ lọ́wọ́, kódà o lè gbà á sókè, kó o sì jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa gbàdúrà tó gùn.
Wáyè gbàdúrà níbi tó dákẹ́ rọ́rọ́ láìsí ohun tó máa dí ẹ lọ́wọ́ (Wo ìpínrọ̀ 10)
RONÚ NÍPA ÀWỌN ÀDÚRÀ ÀTỌKÀNWÁ TÓ WÀ NÍNÚ BÍBÉLÌ
11. Báwo la ṣe lè jàǹfààní tá a bá ń ronú nípa àwọn àdúrà àtọkànwá tó wà nínú Bíbélì? (Wo àpótí náà, “Ṣé Ọ̀rọ̀ Tìẹ Jọ Tiwọn?”)
11 Wàá jàǹfààní tó o bá ronú nípa àwọn àdúrà àtọkànwá, àwọn orin ẹ̀mí tàbí àwọn orin sáàmù tó wà nínú Bíbélì. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa báwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn fún Jèhófà, ìwọ náà á lè máa gbàdúrà sí Jèhófà látọkàn wá. O tún lè rí àwọn ọ̀rọ̀ míì nínú àdúrà wọn tó o lè máa fi yin Ọlọ́run tó o bá ń gbàdúrà. O sì lè rí ohun tí wọ́n sọ tàbí béèrè nígbà tí wọ́n ń gbàdúrà tó jọ ohun tíwọ náà fẹ́ sọ tàbí tó o fẹ́ béèrè.
12. Àwọn ìbéèrè wo la lè bi ara wa bá a ṣe ń ronú nípa àdúrà tẹ́nì kan gbà nínú Bíbélì?
12 Tó o bá ń ronú nípa àdúrà tẹ́nì kan gbà nínú Bíbélì, bi ara ẹ pé: ‘Ta ló gba àdúrà yìí? Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sẹ́ni náà? Ṣé ohun tó ń ṣe mí ló ṣe é? Kí ni mo lè kọ́ nínú àdúrà náà?’ Á dáa kó o ṣèwádìí sí i kó o lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan lo máa rí kọ́. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àdúrà mẹ́rin kan tó wà nínú Bíbélì.
13. Kí la kọ́ nínú àdúrà tí Hánà gbà? (1 Sámúẹ́lì 1:10, 11) (Tún wo àwòrán.)
13 Ka 1 Sámúẹ́lì 1:10, 11. Nígbà tí Hánà gbàdúrà yìí, ìṣòro ńlá méjì ló ní. Kò rọ́mọ bí, orogún ẹ̀ tún fayé ni ín lára. (1 Sám. 1:4-7) Tó o bá ní ìṣòro kan tó ń bá ẹ fínra, kí lo lè kọ́ nínú àdúrà Hánà? Ó fara balẹ̀ sọ gbogbo ohun tó ń dà á láàmú fún Jèhófà, lẹ́yìn náà ara tù ú. (1 Sám. 1:12, 18) Ara máa tu àwa náà tá a bá “ju ẹrù [wa] sọ́dọ̀ Jèhófà,” tá a sì sọ gbogbo ìṣòro wa àti bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára wa fún un.—Sm. 55:22.
Hánà ò rọ́mọ bí, orogún ẹ̀ tún ń fayé ni ín lára, ló bá sọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ fún Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 13)
14. (a) Nǹkan míì wo la kọ́ lára Hánà? (b) Tá a bá ń ka Bíbélì tá a sì ń ṣàṣàrò, báwo ló ṣe máa jẹ́ ká mọ ohun tá a máa sọ tá a bá ń gbàdúrà? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
14 Ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí Hánà bí Sámúẹ́lì, ó mú un wá fún Àlùfáà Àgbà Élì. (1 Sám. 1:24-28) Nígbà tó gbàdúrà, ohun tó sọ fi hàn pé ó mọ̀ pé Jèhófà máa ń dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀, ó sì máa ń pèsè ohun tí wọ́n nílò.c (1 Sám. 2:1, 8, 9) Kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà yanjú ìṣòro ẹ̀, àmọ́ ó ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń ran òun lọ́wọ́. Kí la kọ́? Ohun tá a kọ́ ni pé tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́, àá lè fara da ìṣòro tó ń bá wa fínra.
15. Báwo ni àdúrà Jeremáyà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ táwọn èèyàn bá hùwà ìkà sí wa? (Jeremáyà 12:1)
15 Ka Jeremáyà 12:1. Ìgbà kan wà tínú wòlíì Jeremáyà ò dùn bó ṣe rí i táwọn èèyàn burúkú ń ṣàṣeyọrí. Ìwà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń hù sí i tún bà á nínú jẹ́. (Jer. 20:7, 8) Ọ̀rọ̀ tiwa náà jọ ti Jeremáyà torí ó máa ń dùn wá táwọn èèyàn bá fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, tá a sì ń rí báwọn tó ń hùwà burúkú ṣe ń rọ́wọ́ mú. Jeremáyà jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn dun òun, àmọ́ kò sọ pé Jèhófà ò ṣe ohun tó tọ́. Nígbà tó rí bí Jèhófà ṣe fìyà jẹ àwọn èèyàn ẹ̀ tó ya ọlọ̀tẹ̀, ó túbọ̀ fọkàn tán Jèhófà pé onídàájọ́ òdodo ni. (Jer. 32:19) Àwa náà lè sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa fún Jèhófà táwọn èèyàn bá hùwà ìkà sí wa, ká sì fọkàn tán an pé á mú gbogbo ìrẹ́jẹ kúrò lásìkò tó yẹ.
16. Tá a bá wà níbi tá ò ti lè jáde, kí la lè kọ́ nínú àdúrà ọmọ Léfì kan tó wà nígbèkùn? (Sáàmù 42:1-4) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Ka Sáàmù 42:1-4. Ọmọ Léfì kan tó wà nígbèkùn ló kọ sáàmù yìí nígbà tí ò lè bá àwọn èèyàn Ọlọ́run jọ́sìn ní tẹ́ńpìlì. Sáàmù tó kọ yìí jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀. Ọ̀rọ̀ tiwa náà lè dà bíi tiẹ̀ tí àìsàn bá sé wa mọ́lé tàbí tí wọ́n fi wá sẹ́wọ̀n torí ohun tá a gbà gbọ́. Nígbà míì, inú wa lè dùn, ìgbà míì sì rèé inú wa lè bà jẹ́, àmọ́ á dáa ká sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa fún Jèhófà. Ìyẹn á jẹ́ kára tù wá, á sì jẹ́ ká ní èrò tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ Léfì náà mọ̀ pé òun ṣì máa láǹfààní láti yin Jèhófà. (Sm. 42:5) Ó tún rántí bí Jèhófà ṣe ń bójú tó òun. (Sm. 42:8) Tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà látọkàn wá, àá túbọ̀ mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa, ọkàn wa á balẹ̀, á sì jẹ́ ká lè fara dà á.
Ọmọ Léfì tó kọ Sáàmù 42 sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ fún Ọlọ́run. Táwa náà bá sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa fún Jèhófà, a máa ní èrò tó tọ́ (Wo ìpínrọ̀ 16)
17. (a) Kí la kọ́ nínú àdúrà tí wòlíì Jónà gbà? (Jónà 2:1, 2) (b) Báwo làwọn ẹsẹ Bíbélì kan ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá níṣòro? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
17 Ka Jónà 2:1, 2. Ìgbà tí wòlíì Jónà wà nínú ẹja ńlá kan ló gbàdúrà yìí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jónà ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ó dá a lójú pé ó máa gbọ́ àdúrà òun. Ọ̀pọ̀ lára ọ̀rọ̀ tí Jónà lò nígbà tó ń gbàdúrà wà nínú ìwé Sáàmù.d Ó ṣeé ṣe kí Jónà ti mọ àwọn sáàmù náà dáadáa. Nígbà tó ronú nípa wọn, ó dá a lójú pé Jèhófà máa ran òun lọ́wọ́. Lọ́nà kan náà, tá a bá mọ àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sórí, àá rántí láti lò wọ́n tá a bá ń gbàdúrà nígbà ìṣòro, á sì jẹ́ kára tù wá.
MÁA GBÀDÚRÀ LÁTỌKÀN WÁ KÓ O LÈ TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ JÈHÓFÀ
18-19. Tá ò bá mọ ohun tá a máa sọ tá a bá ń gbàdúrà, báwo lohun tó wà ní Róòmù 8:26, 27 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́? Sọ àpẹẹrẹ kan.
18 Ka Róòmù 8:26, 27. Nígbà míì, ọ̀rọ̀ lè tojú sú wa débi pé a lè má mọ ohun tá a máa sọ tá a bá ń gbàdúrà. Àmọ́, ọ̀nà àbáyọ ṣì wà. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ máa ń bá wa “bẹ̀bẹ̀.” Báwo lẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ṣe é? Jèhófà fẹ̀mí ẹ̀ darí àwọn tó kọ Bíbélì láti kọ àwọn àdúrà kan sílẹ̀. Tá ò bá mọ ohun tá a máa sọ tá a bá ń gbàdúrà, àmọ́ tá a sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó wà nínú àdúrà inú Bíbélì, Jèhófà lè dáhùn àdúrà wa.
19 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Yelena nílẹ̀ Rọ́ṣíà nìyẹn. Ìjọba mú un torí pé ó ń gbàdúrà, ó sì ń ka Bíbélì. Ìdààmú bá Yelena débi pé kò mọ ohun tó fẹ́ gbàdúrà nípa ẹ̀. Ó sọ pé: “Nígbà tí nǹkan tojú sú mi tí mi ò sì mohun tí mo fẹ́ bá Jèhófà sọ, mo máa ń gba àwọn àdúrà táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà gbà nínú Bíbélì, ó sì máa ń gbọ́ mi. Ìyẹn sì máa ń tù mí nínú gan-an nígbà ìṣòro.”
20. Kí ló lè mú kó rọrùn fún wa láti gbàdúrà tí nǹkan bá tojú sú wa?
20 Tí nǹkan bá tojú sú wa, ọkàn wa lè pínyà tá a bá ń gbàdúrà. Kí ọkàn wa má bàa pínyà, a lè gbọ́ àwọn Sáàmù tá a gbohùn ẹ̀ sílẹ̀. A tún lè kọ ohun tó wà lọ́kàn wa sílẹ̀ bí Ọba Dáfídì ti ṣe. (Sm. 18, 34, 142; àkọlé.) Àmọ́, kò sófin kankan nípa bó ṣe yẹ ká múra àdúrà wa sílẹ̀. (Sm. 141:2) Ohun tó bá rọ̀ ẹ́ lọ́rùn ni kó o ṣe.
21. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbàdúrà látọkàn wá?
21 Ó tù wá nínú gan-an pé Jèhófà mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa ká tiẹ̀ tó sọ ọ́. (Sm. 139:4) Síbẹ̀, Jèhófà fẹ́ ká sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa, ká sì fọkàn tán òun. Torí náà, jẹ́ kó yá ẹ lára láti gbàdúrà sí Bàbá ẹ ọ̀run. Máa lo àwọn ọ̀rọ̀ àdúrà tó wà nínú Bíbélì. Máa gbàdúrà látọkàn wá. Sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ fún Jèhófà nígbà tínú ẹ dùn àti nígbà tínú ẹ ò dùn. Rántí pé ọ̀rẹ́ ẹ ni Jèhófà, ó nífẹ̀ẹ́ ẹ, gbogbo ìgbà lá sì máa bójú tó ẹ!
ORIN 45 Àṣàrò Ọkàn Mi
a Lọ wo ìwé náà Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́. Wo àkòrí náà “Jèhófà,” wàá rí ìsọ̀rí náà “Díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ Jèhófà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.”
b Àdúrà tá a máa ń gbà táwọn ará ìjọ bá péjọ kì í sábà gùn.
c Nígbà tí Hánà ń gbàdúrà, ó lo àwọn ọ̀rọ̀ tó jọ ọ̀rọ̀ tí Mósè kọ. Ìyẹn fi hàn pé ó wáyè láti ronú dáadáa nípa ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́. (Diu. 4:35; 8:18; 32:4, 39; 1 Sám. 2:2, 6, 7) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí Màríà ìyá Jésù ń yin Ọlọ́run, ó lo ọ̀rọ̀ tó jọ èyí tí Hánà sọ.—Lúùkù 1:46-55.
d Bí àpẹẹrẹ, fi Jónà 2:3-9 wé Sáàmù 69:1; 16:10; 30:3; 142:2, 3; 143:4, 5; 18:6; àti 3:8. Wàá rí i pé ọ̀rọ̀ tó wà nínú àwọn Sáàmù náà bá àdúrà tí Jónà gbà mu.