ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Friday, October 16

Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ lọ sí àwọn ọ̀nà rẹ̀. Má rìn gbéregbère wọ àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.—Òwe 7:25.

Ohun tí Sólómọ́nì sọ jẹ́ ká mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí ìránṣẹ́ Jèhófà kan. Ó lè dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kó sì rò pé ‘òjijì’ ló ṣẹlẹ̀. Ó sì lè sọ pé ó kàn ṣàdédé ṣẹlẹ̀ ni. Síbẹ̀, tó bá ronú jinlẹ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, á rí i pé òun ti ṣe àwọn ìpinnu kan tí ò mọ́gbọ́n dání tó jẹ́ kóun dá ẹ̀ṣẹ̀ náà. Ó lè máa kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́, kó máa wo eré ìnàjú tí ò dáa tàbí kó máa ṣe é, ó sì lè máa lọ síbi tí ò yẹ kó lọ láàárín ìlú tàbí kó máa lọ síbi tí ò dáa lórí ìkànnì. Ó ṣeé ṣe kó má gbàdúrà mọ́, kó má ka Bíbélì mọ́, kó má lọ sípàdé mọ́, kó má sì wàásù mọ́. Bíi ti ọ̀dọ́kùnrin tí ìwé Òwe sọ, kì í ṣe ‘òjijì’ ló dẹ́ṣẹ̀. Kí la rí kọ́? Ó yẹ ká sá fún ẹ̀ṣẹ̀ àti ohun tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀. Ohun tí Sólómọ́nì sọ nìyẹn nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀dọ́kùnrin àti obìnrin oníṣekúṣe yẹn.—Mát. 5:​29, 30. w24.07 16 ¶10-11

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2026

Saturday, October 17

A ní ìṣúra yìí nínú àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe.—2 Kọ́r. 4:7.

Kí ni ìṣúra tí Pọ́ọ̀lù ń sọ? Iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni, iṣẹ́ náà sì ń gbẹ̀mí àwọn èèyàn là. (2 Kọ́r. 4:1) Kí wá làwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe? Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ń wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn ni. Nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, àwọn oníṣòwò máa ń fi ìkòkò amọ̀ gbé àwọn ohun tó ṣe pàtàkì bí oúnjẹ, wáìnì àti owó. Lọ́nà kan náà, Jèhófà gbé iṣẹ́ tó ṣeyebíye lé àwa náà lọ́wọ́ pé ká wàásù ìhìn rere. Ó dájú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́, á sì fún wa lókun ká lè ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí. Nígbà míì, a lè máa bẹ̀rù pé àwọn èèyàn lè ta kò wá tàbí pé wọ́n lè má gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa bẹ̀rù? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àdúrà táwọn àpọ́sítélì gbà nígbà táwọn aláṣẹ sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́. Dípò tí wọ́n á fi máa bẹ̀rù, wọ́n bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ káwọn lè máa fi ìgboyà sọ̀rọ̀. Ojú ẹsẹ̀ sì ni Jèhófà dáhùn àdúrà wọn. (Ìṣe 4:​18, 29, 31) Torí náà, tẹ́rù bá ń bà ẹ́ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, kó o lè wàásù ìhìn rere fún wọn láìbẹ̀rù. w24.04 16 ¶8-9

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2026

Sunday, October 18

Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́.—Mát. 6:9.

Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó máa ń wù wá láti sọ orúkọ ẹ̀ di mímọ́. Irọ́ ńlá ni Sátánì pa mọ́ Jèhófà, a sì fẹ́ wà lára àwọn tó máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òpùrọ́ ni Sátánì. (Jẹ́n. 3:​1-5; Jóòbù 2:4; Jòh. 8:44) Tá a bá ń wàásù, ó máa ń wù wá gan-an láti jẹ́ kí gbogbo àwọn tó bá ń tẹ́tí sí wa mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ àtohun tó fẹ́ ká ṣe. A fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé ìfẹ́ ló gbawájú lára àwọn ànímọ́ Jèhófà, onídàájọ́ òdodo ni àti pé ọ̀nà tó dáa jù ló ń gbà ṣàkóso. Yàtọ̀ síyẹn, Ìjọba ẹ̀ máa tó mú gbogbo ìyà kúrò, ó sì máa mú ayọ̀ àti àlàáfíà wá fún gbogbo èèyàn. (Sm. 37:​10, 11, 29; 1 Jòh. 4:8) Tá a bá ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ àwọn nǹkan yìí nípa Jèhófà, ṣe là ń sọ orúkọ ẹ̀ di mímọ́. Inú wa tún ń dùn pé ohun tó ní káwa Ẹlẹ́rìí ẹ̀ máa ṣe là ń ṣe. w24.05 18 ¶12

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2026
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́