ÀPILẸ̀KỌ 43
ORIN 41 Jọ̀ọ́, Gbọ́ Àdúrà Mi
Máa Rántí Gbàdúrà Fáwọn Ará
‘ Ẹ máa gbàdúrà fún ara yín. Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo lágbára gan-an.’—JÉM. 5:16.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa gbàdúrà fáwọn ará àti bá a ṣe lè ṣe é.
1. Báwo la ṣe mọ̀ pé àdúrà wa ṣe pàtàkì lójú Jèhófà?
NǸKAN ńlá ni Jèhófà ṣe fún wa bó ṣe jẹ́ ká lè gbàdúrà sóun. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ti gbé àwọn iṣẹ́ kan fáwọn áńgẹ́lì. (Sm. 91:11) Bákan náà, ó gbé àwọn iṣẹ́ pàtàkì kan fún Jésù Ọmọ ẹ̀. (Mát. 28:18) Àmọ́ ta ni Jèhófà sọ pé kó máa gbọ́ àdúrà? Jèhófà ò gbéṣẹ́ yẹn fún ẹnì kankan. Jèhófà tó jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà” fúnra ẹ̀ ló ń gbọ́ àdúrà wa.—Sm. 65:2.
2. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń ṣe, kí la sì rí kọ́ lára ẹ̀?
2 Òótọ́ ni pé a lè bá Jèhófà sọ gbogbo ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn, síbẹ̀ ó yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn míì. Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó kọ̀wé sáwọn ará tó wà níjọ Éfésù, ó sọ pé: ‘Mò ń gbàdúrà fún yín.’ (Éfé. 1:16) Kì í ṣèyẹn nìkan o, Pọ́ọ̀lù tún máa ń gbàdúrà fáwọn ará lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fún Tímótì pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, . . . mi ò sì yéé rántí rẹ nínú àwọn ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi tọ̀sántòru.” (2 Tím. 1:3) Pọ́ọ̀lù náà láwọn ìṣòro tiẹ̀ tó ń gbàdúrà nípa ẹ̀. (2 Kọ́r. 11:23; 12:7, 8) Síbẹ̀, ó ṣì wáyè gbàdúrà fáwọn ará.
3. Kí ló lè mú ká gbàgbé láti gbàdúrà fáwọn míì?
3 Ìgbà míì máa ń wà tá a máa ń gbàgbé láti gbàdúrà fáwọn míì. Kí nìdí? Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sabrinaa sọ ọ̀kan lára ohun tó lè fà á. Ó ní: “Ìṣòro pọ̀ gan-an láyé. Tá ò bá ṣọ́ra, ìṣòro wa lè gbà wá lọ́kàn débi pé ọ̀rọ̀ ara wa nìkan làá máa sọ fún Jèhófà.” Ṣé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan tá a máa sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. (1) Ó máa ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa gbàdúrà fáwọn ará, (2) ó sì máa sọ bá a ṣe lè ṣe é.
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA GBÀDÚRÀ FÁWỌN ARÁ?
4-5. Kí nìdí tí àdúrà tá à ń gbà fáwọn ará fi “lágbára gan-an”? (Jémíìsì 5:16)
4 Àdúrà tá à ń gbà fáwọn ará “lágbára gan-an.” (Ka Jémíìsì 5:16.) Ṣé àdúrà tá a bá gbà fáwọn míì lè mú kí ìṣòro wọn yanjú? Bẹ́ẹ̀ ni. Jésù mọ̀ pé àpọ́sítélì Pétérù máa tó da òun, torí náà ó sọ pé: “Mo ti bá yín bẹ̀bẹ̀, kí ìgbàgbọ́ yín má bàa yẹ̀.” (Lúùkù 22:32) Pọ́ọ̀lù náà mọ̀ pé Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà táwọn èèyàn bá gbà torí àwọn ẹlòmíì. Nígbà tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nílùú Róòmù, ó kọ̀wé sí Fílémónì pé: “Mo ní ìrètí pé wọ́n á jẹ́ kí n pa dà sọ́dọ̀ yín, lọ́lá àdúrà tí ẹ̀ ń gbà fún mi.” (Fílém. 22; wo àlàyé ọ̀rọ̀ “for I am hoping that through your prayers” nínú nwtsty-E.) Lóòótọ́, kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n dá Pọ́ọ̀lù sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù.
5 Àmọ́, ìyẹn ò sọ pé tá a bá ń gbàdúrà, ká wá máa fúngun mọ́ Jèhófà pé kó ṣe ohun tá a fẹ́. Ó mọ ohun tá a torí ẹ̀ ń gbàdúrà sóun, nígbà míì á sì ṣe ohun tá a fẹ́. Ohun tá a mọ̀ yìí máa ń jẹ́ ká gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn, ká sì gbà pé tó bá tó àsìkò lójú ẹ̀, ó máa dáhùn àdúrà wa.—Sm. 37:5; wo 2 Kọ́ríńtì 1:11 àti àlàyé ọ̀rọ̀ ẹsẹ yìí nínú nwtsty-E.
6. Tá a bá ń gbàdúrà fáwọn míì, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká ṣàánú wọn? (1 Pétérù 3:8)
6 Àdúrà tá à ń gbà fáwọn míì máa ń jẹ́ ká “lójú àánú.” (Ka 1 Pétérù 3:8.) Àánú máa ń jẹ́ ká kíyè sí nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn, ká sì múra tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Máàkù 1:40, 41) Alàgbà kan tó ń jẹ́ Michael sọ pé: “Tí mo bá gbàdúrà pé kí Jèhófà pèsè àwọn nǹkan táwọn míì nílò, ó máa ń jẹ́ kí n túbọ̀ mọ nǹkan tí wọ́n ń bá yí, ó sì máa ń jẹ́ kí n nífẹ̀ẹ́ wọn sí i. Bákan náà, ó jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ wọn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè má mọ bọ́rọ̀ wọn ṣe jẹ mí lógún tó.” Alàgbà kan tó ń jẹ́ Richard sọ àǹfààní míì tá a máa rí. Ó ní: “Tá a bá ń gbàdúrà fáwọn míì, ó máa jẹ́ kó wù wá láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Tá a bá ṣe nǹkan pàtó láti ran ẹni tá a gbàdúrà fún lọ́wọ́, ṣe là ń jẹ́ kí Jèhófà lò wá láti dáhùn àdúrà tá a gbà fún ẹni náà.”
7. Tá a bá ń gbàdúrà fáwọn míì, báwo ni ò ṣe ní jẹ́ ká máa ronú ṣáá nípa ìṣòro wa? (Fílípì 2:3, 4) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
7 Àdúrà tá à ń gbà fáwọn míì ò ní jẹ́ ká máa ronú ṣáá nípa ìṣòro wa. (Ka Fílípì 2:3, 4.) Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló níṣòro tó ń bá yí torí pé inú ayé tí Sátánì ń darí là ń gbé. (1 Jòh. 5:19; Ìfi. 12:12) Àmọ́ tá a bá jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa gbàdúrà fáwọn míì, á máa rán wa létí pé “irú ìyà kan náà ló ń jẹ gbogbo àwọn ará.” (1 Pét. 5:9) Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Katherine sọ pé: “Bí mo ṣe ń gbàdúrà fáwọn míì máa ń jẹ́ kí n rántí pé bí mo ṣe níṣòro làwọn náà níṣòro. Tí mo bá ti rántí ọ̀rọ̀ yìí, kì í jẹ́ kí n máa ronú ṣáá nípa ìṣòro mi.”
Tá a bá ń gbàdúrà fáwọn míì, a ò ní máa ronú ṣáá nípa ìṣòro wa (Wo ìpínrọ̀ 7)d
Ó YẸ KÁ MÁA GBÀDÚRÀ FÁWỌN ARÁ
8. Àwọn wo ló yẹ ká máa gbàdúrà fún?
8 Àwọn wo ló yẹ ká máa gbàdúrà fún? A lè gbàdúrà fún onírúurú èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, a lè gbàdúrà fáwọn tí ara wọn ò yá, àwọn ọmọ tí wọ́n fi ń ṣe yẹ̀yẹ́ nílé ìwé tàbí àwọn ọmọ táwọn ojúgbà wọn fẹ́ kí wọ́n ṣohun tí ò dáa, a sì tún lè gbàdúrà fáwọn tó ti dàgbà. Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa làwọn ará ilé wọn tàbí àwọn aláṣẹ ń ṣe inúnibíni sí. (Mát. 10:18, 36; Ìṣe 12:5) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará kan ti sá kúrò nílé torí rògbòdìyàn ọ̀rọ̀ òṣèlú. Àwọn kan sì ń jìyà torí àjálù tó ṣẹlẹ̀ sí wọn. A lè má mọ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, àmọ́ tá a bá ń gbàdúrà fún wọn, ìyẹn máa fi hàn pé à ń pa àṣẹ Jésù mọ́ tó ní ká “nífẹ̀ẹ́ ara” wa.—Jòh. 13:34.
9. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn tó ń bójú tó wa nínú ètò Ọlọ́run àtàwọn ìyàwó wọn?
9 Ó tún yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn tó ń bójú tó wa nínú ètò Ọlọ́run. Lára wọn ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àtàwọn tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́, àwọn arákùnrin tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka kárí ayé, àwọn alábòójútó ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn alábòójútó àyíká, àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ọ̀pọ̀ lára àwọn arákùnrin yìí náà láwọn ìṣòro tiwọn, síbẹ̀ wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́. (2 Kọ́r. 12:15) Bí àpẹẹrẹ, alábòójútó àyíká kan tó ń jẹ́ Mark sọ pé: “Ọ̀kan lára ohun tó máa ń dùn mí jù ni bí mo ṣe jìnnà sáwọn òbí mi, bẹ́ẹ̀ sì rèé, wọ́n ti dàgbà, ara àwọn méjèèjì ò sì le rárá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀gbọ́n mi obìnrin àti ọkọ ẹ̀ ń tọ́jú wọn dáadáa, ó ṣì máa ń dùn mí gan-an pé mi ò sí níbẹ̀ kémi náà lè tọ́jú wọn.” Bóyá a mọ ìṣòro táwọn arákùnrin yìí ń bá yí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó ṣì yẹ ká máa gbàdúrà fún wọn. (1 Tẹs. 5:12, 13) Ó tún yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn ìyàwó àwọn arákùnrin yìí torí bí wọ́n ṣe ń ti ọkọ wọn lẹ́yìn tọkàntọkàn kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run lọ.
10-11. Ṣé Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà tá a gbà fáwọn ará lápapọ̀? Ṣàlàyé.
10 Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń gbàdúrà fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lápapọ̀. Bí àpẹẹrẹ, láì dárúkọ ẹnì kan pàtó, a lè bẹ Jèhófà pé kó wà pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n, kó sì tu àwọn tí èèyàn wọn kú nínú. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Donald sọ pé, “Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló níṣòro tó le gan-an. Torí náà nígbà míì, a máa ń gbàdúrà fún gbogbo wọn lápapọ̀ pé kí Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́.”
11 Ṣé Jèhófà máa ń gbọ́ irú àdúrà bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, ó máa ń gbọ́! Àmọ́ kì í ṣe gbogbo nǹkan táwọn ará wa nílò la mọ̀. Torí náà, á dáa ká máa gbàdúrà fún gbogbo wọn lápapọ̀. Bí àpẹẹrẹ, a lè sọ pé kí Jèhófà dúró ti àwọn tó wà lẹ́wọ̀n, kó ran àwọn tó ń ṣàìsàn àtàwọn tí àjálù dé bá lọ́wọ́, kó sì tu àwọn tí èèyàn wọn kú nínú. (Jòh. 17:20; Éfé. 6:18) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á fi hàn pé òótọ́ la “nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará.”—1 Pét. 2:17.
OHUN TÓ O LÈ ṢE TÓ O BÁ Ń GBÀDÚRÀ FÁWỌN ARÁ LẸ́NÌ KỌ̀Ọ̀KAN
12. Tá a bá ń kíyè sí àwọn ará, kí nìyẹn máa jẹ́ ká ṣe tá a bá ń gbàdúrà?
12 Máa kíyè sí àwọn ará. Yàtọ̀ sí àdúrà tá à ń gbà fáwọn ará lápapọ̀, ó tún yẹ ká máa gbàdúrà fún wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ká sì máa dárúkọ wọn. Ṣé ẹnì kan wà nínú ìjọ yín tó ń ṣàìsàn tó le gan-an? Ṣé ọ̀dọ́ kan wà tó rẹ̀wẹ̀sì torí pé wọ́n ń fúngun mọ́ ọn pé kó ṣe nǹkan tí ò dáa nílé ìwé? Àbí o mọ òbí kan tó ń dá tọ́mọ, tó sì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó lè fi “ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà” kọ́ ọmọ ẹ̀? (Éfé. 6:4) Tó o bá ń kíyè sí àwọn ará, wàá túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sí wọn, ìyẹn á sì jẹ́ kó o máa gbàdúrà fún wọn ní gbogbo ìgbà.b—Róòmù 12:15.
13. Báwo la ṣe lè gbàdúrà fáwọn tá ò mọ̀ rí?
13 Máa dárúkọ àwọn tó ò mọ̀ tó o bá ń gbàdúrà. Tá a bá ń gbàdúrà, a lè dárúkọ àwọn tá ò tiẹ̀ mọ̀ rí rárá. Bí àpẹẹrẹ, ẹ ronú nípa àwọn ará wa tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n ní Crimea, Eritrea, Rọ́ṣíà àti Singapore. Tó o bá lọ sórí ìkànnì jw.org, wàá rí orúkọ àwọn ará wa tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n níbẹ̀.c Alábòójútó àyíká kan tó ń jẹ́ Brian sọ pé: “Bí mo ṣe máa ń kọ orúkọ àwọn ará tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n sílẹ̀, tí mo sì máa ń pe orúkọ wọn sókè máa ń jẹ́ kí n rántí láti dárúkọ wọn tí mo bá ń dá gbàdúrà.”
14-15. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí àdúrà wa ṣe pàtó?
14 Sọ nǹkan pàtó tó o fẹ́ kí Jèhófà ṣe fún wọn. Arákùnrin Michael tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Tí mo bá ń kà nípa àwọn ará tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n lórí ìkànnì jw.org, mo máa ń wo bó ṣe máa rí lára mi ká sọ pé èmi ni wọ́n fi sẹ́wọ̀n. Mo mọ̀ pé màá máa ṣàníyàn nípa ìyàwó mi, màá sì fẹ́ kí wọ́n bójú tó o dáadáa. Bí mo ṣe ń ronú yìí máa ń jẹ́ kí n mọ nǹkan tí mo máa sọ pé kí Jèhófà ṣe fáwọn arákùnrin tó ti ṣègbéyàwó tó wà lẹ́wọ̀n.”—Héb. 13:3, àlàyé ìsàlẹ̀.
15 Tá a bá ń ronú nípa nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ará tó wà lẹ́wọ̀n, ó ṣeé ṣe ká mọ nǹkan pàtó tá a lè bẹ Jèhófà pé kó ṣe fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, a lè gbàdúrà pé káwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n máa finúure hàn sí wọn, káwọn aláṣẹ sì gbà wọ́n láyè láti máa jọ́sìn Jèhófà bó ṣe wù wọ́n. (1 Tím. 2:1, 2) A tún lè gbàdúrà pé kí àpẹẹrẹ àwọn arákùnrin olóòótọ́ yìí fún àwọn ará ìjọ níṣìírí tàbí pé káwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà kíyè sí ìwà rere táwọn ará tó wà lẹ́wọ̀n yìí ń hù, kí wọ́n sì tẹ́tí sí ìhìn rere. (1 Pét. 2:12) A lè ṣe ohun kan náà tá a bá ń gbàdúrà fáwọn ará tí wọ́n ní onírúurú ìṣòro. Torí náà, tá a bá ń kíyè sí àwọn ará, tá à ń dárúkọ wọn nínú àdúrà, tá a sì ń bẹ Jèhófà pé kó ṣe nǹkan pàtó fún wọn, àá fi hàn pé ‘a pọ̀ gidigidi nínú ìfẹ́ sí ara wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.’—1 Tẹs. 3:12.
MÁA RÁNTÍ GBÀDÚRÀ FÁWỌN MÍÌ
16. Kí ló yẹ ká máa rántí tá a bá ń gbàdúrà? (Mátíù 6:8)
16 Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, tá a bá ń gbàdúrà fáwọn míì, Jèhófà lè gbọ́ kó sì yanjú ìṣòro wọn. Síbẹ̀, kò yẹ ká rò pé gbogbo nǹkan tá a bá sọ fún Jèhófà pé kó ṣe fún wa ló máa ṣe. Tá a bá ń gbàdúrà, ó yẹ ká máa rántí pé Jèhófà ti mọ ìṣòro yẹn ká tiẹ̀ tó sọ fún un, àwa kọ́ la sì máa sọ bó ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà. Jèhófà mọ nǹkan táwa ìránṣẹ́ ẹ̀ nílò kódà káwa fúnra wa tó mọ̀ pé a nílò ẹ̀. (Ka Mátíù 6:8.) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn míì? Yàtọ̀ sáwọn nǹkan tá a ti sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, ohun táwọn tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn máa ń ṣe nìyẹn. Ìfẹ́ tá a ní sáwọn ará ló ń mú ká gbàdúrà fún wọn. Inú Jèhófà sì máa ń dùn tó bá ń rí i pé a fìwà jọ òun, a sì ń fìfẹ́ hàn síra wa.
17-18. Kí la lè fi ṣàpèjúwe àdúrà tá à ń gbà fáwọn ará?
17 Tí nǹkan ò bá tiẹ̀ yí pa dà lẹ́yìn tá a gbàdúrà fáwọn ará, àdúrà tá a gbà ṣì máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, Jèhófà sì mọyì ẹ̀ gan-an. Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná. Ká sọ pé bàbá kan àti ìyàwó ẹ̀ bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin kan. Nígbà tó yá, ọmọkùnrin náà ṣàìsàn. Ọmọbìnrin náà wá bẹ bàbá wọn pé: “Dádì, ẹ jọ̀ọ́, ẹ ran ẹ̀gbọ́n mi lọ́wọ́, àìsàn tó ń ṣe é yìí le gan-an!” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé bàbá náà á ti máa wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà torí ó nífẹ̀ẹ́ ọmọ ẹ̀, ó sì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti tọ́jú ẹ̀. Àmọ́, ó dájú pé inú bàbá yẹn máa dùn gan-an bó ṣe rí i pé ọmọbìnrin ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀gbọ́n ẹ̀ débi tó fi ń bẹ̀ ẹ́ pé kó tọ́jú ẹ̀.
18 Ohun tí Jèhófà fẹ́ káwa náà máa ṣe nìyẹn. Ó fẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ ara wa, ká sì máa gbàdúrà fún ara wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á fi hàn pé a ò mọ tara wa nìkan, pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, inú Jèhófà sì máa dùn sí wa. (2 Tẹs. 1:3; Héb. 6:10) Bákan náà, bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, àdúrà tá a gbà fáwọn ará lè mú kí nǹkan yí pa dà fún wọn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa rántí gbàdúrà fáwọn ará.
ORIN 101 À Ń Ṣiṣẹ́ Níṣọ̀kan
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
b Wo fídíò Arákùnrin Takeshi Shimizu: Jèhófà Ni “Olùgbọ́ Àdúrà” lórí jw.org.
c Tó o bá fẹ́ rí orúkọ àwọn ará tó wà lẹ́wọ̀n, lọ sí jw.org, kó o wo àkòrí náà “Wọ́n Fi Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́—Ibì Kọ̀ọ̀kan.”
d ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin táwọn náà níṣòro ń gbàdúrà fáwọn míì.