ÀPILẸ̀KỌ 41
ORIN 108 Ìfẹ́ Ọlọ́run Tí Kì Í Yẹ̀
Ìfẹ́ Tí Ọlọ́run Ní sí Wa Ń Jẹ́ Ká Lè Fara Da Ìṣòro
“ Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ó jẹ́ ẹni rere; ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.”—SM. 136:1.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa jíròrò ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa bí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da ìṣòro wa.
1-2. Tá a bá níṣòro, báwo ni nǹkan ṣe máa ń rí lára wa?
FOJÚ inú wo ọkọ̀ ojú omi kan tó wà lójú agbami, tí ìjì tó lágbára ń bì síbí bì sọ́hùn-ún. Ibi tí ìjì bá darí ọkọ̀ náà sí ló máa ń lọ. Àmọ́ tí awakọ̀ náà bá fẹ́ kí ọkọ̀ náà dúró, àfi kó lo ìdákọ̀ró. Ìdákọ̀ró yẹn ò ní jẹ́ kí ọkọ̀ náà bì síbí bì sọ́hùn-ún mọ́, kò sì ní jẹ́ kó rì.
2 Tó o bá ń fara da ìṣòro tó le gan-an, ọ̀rọ̀ ẹ lè dà bí ọkọ̀ tá a sọ yìí. Inú ẹ lè dùn lónìí, kó má sì dùn lọ́la. Àwọn ìgbà kan lè wà tí wàá gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, ó sì ń ràn ẹ́ lọ́wọ́, àmọ́ láwọn ìgbà míì ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé bóyá ni Jèhófà mọ ohun tó ò ń bá yí. (Sm. 10:1; 13:1) Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rẹ́ ẹ kan sọ̀rọ̀ tó tù ẹ́ nínú, kíyẹn sì jẹ́ kára tù ẹ́ fúngbà díẹ̀. (Òwe 17:17; 25:11) Àmọ́ kò pẹ́ sígbà yẹn, o tún lè bẹ̀rẹ̀ sí í rò pé bóyá ni Jèhófà rí tìẹ rò. Kódà, o tiẹ̀ lè máa rò pé ọ̀rọ̀ ẹ ti sú Jèhófà. Bí ìdákọ̀ró ṣe máa ń jẹ́ kí ọkọ̀ dúró sójú kan tí ìjì bá ń jà, kí nìwọ náà lè ṣe nígbà ìṣòro tí ò ní jẹ́ kó o máa ṣiyèméjì bóyá Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ àbí kò nífẹ̀ẹ́ ẹ? Ìyẹn ni pé, báwo lo ṣe lè jẹ́ kó dá ẹ lójú hán-ún hán-ún pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́?
3. Bí Sáàmù 31:7 àti 136:1 ṣe sọ, kí ni “ìfẹ́ tí kì í yẹ̀,” kí sì nìdí tá a fi sọ pé Jèhófà ló máa ń fi ìfẹ́ yìí hàn jù? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
3 Ọ̀kan lára ohun tó máa jẹ́ kó dá ẹ lójú hán-ún hán-ún pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ ni tó o bá ń rántí pé Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀. (Ka Sáàmù 31:7; 136:1.) Ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́ tí kì í yẹ̀” ni ìfẹ́ alọ́májàá tẹ́nì kan ní sí ẹlòmíì, tó sì máa wà títí láé. Jèhófà ni àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ tó bá dọ̀rọ̀ ká fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn. Kódà, Bíbélì sọ pé ‘ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ pọ̀ gidigidi.’ (Ẹ́kís. 34:6, 7) Bíbélì tún sọ nípa Jèhófà pé: “Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí gbogbo àwọn tó ń ké pè ọ́ pọ̀ gidigidi.” (Sm. 86:5) Ronú nípa ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ. Ohun tó ń sọ ni pé Jèhófà ò ní fi àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ sílẹ̀ láé! Torí náà, tó o bá ń rántí pé Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀, á jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú hán-ún pé ó máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹ nígbà ìṣòro.—Sm. 23:4.
Ìdákọ̀ró máa ń jẹ́ kí ọkọ̀ dúró digbí tí ìjì bá ń jà. Lọ́nà kan náà, tó bá dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, a ò ní máa ṣiyèméjì nígbà ìṣòro (Wo ìpínrọ̀ 3)
RÁNTÍ PÉ ÌFẸ́ TÍ JÈHÓFÀ Ń FI HÀN SÍ WA WÀ LÁRA Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ TÁ A KỌ́KỌ́ MỌ̀
4. Sọ àpẹẹrẹ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́kọ́ mọ̀, kó o sì ṣàlàyé ìdí tí ẹnikẹ́ni ò fi lè yí wa lérò pa dà.
4 Nǹkan míì táá jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ nígbà ìṣòro ni pé kó o máa rántí pé ìfẹ́ tí Jèhófà ń fi hàn sí wa wà lára àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́kọ́ mọ̀, tó sì jẹ́ kígbàgbọ́ wa lágbára. Tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́kọ́ mọ̀,” kí lo máa rò? Ó ṣeé ṣe kó o ronú nípa àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó o ti kọ́ nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, o ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, pé Jésù ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí Ọlọ́run ní, pé àwọn òkú ò mọ nǹkan kan rárá àti pé ayé máa di Párádísè, àwọn èèyàn á sì máa gbé ibẹ̀ títí láé. (Sm. 83:18; Oníw. 9:5; Jòh. 3:16; Ìfi. 21:3, 4) Látìgbà tó o ti gba àwọn ẹ̀kọ́ yẹn gbọ́, o ò jẹ́ kẹ́nikẹ́ni yí ẹ lérò pa dà. Kí nìdí? Ìdí ni pé o gbà pé òótọ́ làwọn ẹ̀kọ́ yẹn torí inú Bíbélì lo ti kọ́ wọn. Torí náà, tó o bá ń rántí pé ìfẹ́ tí Jèhófà ń fi hàn sí wa wà lára àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́kọ́ mọ̀ tó jẹ́ kígbàgbọ́ wa lágbára, o ò ní ṣiyèméjì pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ tàbí kó o máa rò pé kò mọ ohun tó ò ń bá yí. Jẹ́ ká wo bó o ṣe lè ṣe é.
5. Ṣàlàyé bí ẹnì kan ṣe lè fi ẹ̀kọ́ èké sílẹ̀.
5 Nígbà tó ò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí ni ò jẹ́ kó o gba àwọn ẹ̀kọ́ èké gbọ́ mọ́? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé o fi ohun tí wọ́n ń kọ́ ẹ nínú ìsìn tó ò ń lọ tẹ́lẹ̀ wé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan: Ká sọ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, o gbà pé Jésù ni Ọlọ́run Olódùmarè. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣeé ṣe kó o bi ara ẹ pé, ‘Ṣé òótọ́ lohun tí wọ́n fi ń kọ́ mi?’ Lẹ́yìn tó o mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí, o gbà pé Jésù kọ́ ni Ọlọ́run Olódùmarè. O wá fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ yìí rọ́pò ẹ̀kọ́ èké tó o mọ̀ tẹ́lẹ̀. Ẹ̀kọ́ òtítọ́ náà ni pé Jésù ni “àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá,” òun sì ni “Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run.” (Kól. 1:15; Jòh. 3:18) Ká sòótọ́, ẹ̀kọ́ èké dà bí àwọn nǹkan tó ti “fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in,” tó sì ṣòro láti borí. (2 Kọ́r. 10:4, 5) Àmọ́ lẹ́yìn tó o kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó o sì gbà á gbọ́, o ò tún pa dà sídìí ẹ̀kọ́ èké mọ́.—Fílí. 3:13.
6. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́ [Jèhófà] tí kì í yẹ̀ wà títí láé” fi fara hàn léraléra nínú Sáàmù 136?
6 Ní báyìí, ohun kan náà ló yẹ kíwọ náà ṣe kó o lè gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́ nípa bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wa. Tó o bá ń bá ìṣòro kan yí, tó o wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì bóyá Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ tàbí kò nífẹ̀ẹ́ ẹ, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé ohun tí mò ń rò tọ̀nà?’ Tó o bá ń rò pé bóyá ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, ronú nípa ohun tí Sáàmù 136:1 tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé sọ nípa ìfẹ́ Jèhófà. Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé ìfẹ́ òun “kì í yẹ̀”? Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé” fi fara hàn ní ìgbà mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) nínú Sáàmù 136? Bá a ṣe sọ, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà ń fi hàn sáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ wà lára àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́kọ́ mọ̀, a sì gba àwọn ẹ̀kọ́ yẹn gbọ́ torí inú Bíbélì la ti kọ́ wọn. Torí náà, tó o bá ń rò pé o ò já mọ́ nǹkan kan lójú Jèhófà tàbí kò nífẹ̀ẹ́ ẹ, máa rántí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ lóòótọ́. Pinnu pé o ò ní gba èrò yẹn láyè, bó o ṣe pinnu pé o ò ní gba ẹ̀kọ́ èké èyíkéyìí gbọ́!
7. Sọ díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tó jẹ́ ká gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa.
7 Ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì míì wà tó jẹ́ ká gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Ẹ níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” (Mát. 10:31) Jèhófà náà sọ fáwọn èèyàn ẹ̀ pé: “Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́, ní tòótọ́, màá fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin.” (Àìsá. 41:10) Kí nìdí táwọn ọ̀rọ̀ yìí fi dá wa lójú? Kíyè sí pé Jésù ò sọ pé ‘O lè níye lórí gan-an,’ Jèhófà ò sì sọ pé ‘Mo lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n sọ ni pé: “Ẹ níye lórí gan-an” àti “Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.” Torí náà, tó o bá ń bá ìṣòro kan yí, tó sì ń ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ ẹ, kì í ṣe pé àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ nìkan ni, wọ́n á tún jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ gan-an. Ìdí tó sì fi yẹ kó dá ẹ lójú ni pé Bíbélì ló sọ bẹ́ẹ̀. Tó o bá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kó o lè borí iyèméjì, tó o sì ronú nípa àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, ìwọ náà á lè sọ ohun tó wà nínú 1 Jòhánù 4:16 pé: “A ti wá mọ̀, a sì gbà gbọ́ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa.”a
8. Kí lo lè ṣe tó bá ń ṣe ẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bíi pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ ẹ?
8 Tó bá ń ṣe ẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bíi pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ ẹ, kí lo lè ṣe? Fi ohun tó ò ń rò wé ohun tó o mọ̀ nípa Jèhófà. Ohun téèyàn ń rò nígbà míì lè má jóòótọ́, àmọ́ òótọ́ pọ́ńbélé lohun tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́ tí Jèhófà ń fi hàn sí wa. Tá a bá ń ṣiyèméjì pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ṣe ló máa fi hàn pé a ò mọyì ànímọ́ Jèhófà tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn ìfẹ́.—1 Jòh. 4:8.
MÁA RÁNTÍ PÉ JÈHÓFÀ NÍ ‘ÌFẸ́ TÓ JINLẸ̀ FÚN Ẹ’
9-10. Ní Jòhánù 16:26, 27, kí ni Jésù ń sọ nígbà tó sọ pé “Baba fúnra rẹ̀ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún yín?” (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
9 Tá a bá ronú nípa ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀, á tún jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Ó sọ pé: “Baba fúnra rẹ̀ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún yín.” (Ka Jòhánù 16:26, 27.) Jésù ò kàn sọ̀rọ̀ yìí fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ kínú wọn lè dùn. Kódà, ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣáájú àtàwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé e sọ fi hàn pé kì í ṣe bí nǹkan ṣe rí lára wọn ni Jésù ń sọ lásìkò yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ àdúrà ló ń bá wọn sọ.
10 Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ bá àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ sọ̀rọ̀ tán pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí Jèhófà nípasẹ̀ òun, kì í ṣe sóun. (Jòh. 16:23, 24) Ó sì ṣe pàtàkì kí wọ́n mọ̀ bẹ́ẹ̀ torí lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó ṣeé ṣe káwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ fẹ́ máa gbàdúrà sí i. Ó ṣe tán, ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ làwọn àti Jésù. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n rò pé torí ó nífẹ̀ẹ́ àwọn gan-an, táwọn bá gbàdúrà sí i, ó máa gbọ́ àwọn, á sì báwọn sọ ohun táwọn fẹ́ fún Bàbá ẹ̀. Àmọ́, Jésù sọ fún wọn pé kò yẹ kí wọ́n ronú bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé: “Baba fúnra rẹ̀ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún [wọn].” Ohun tí Jésù sọ yìí wà lára àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́kọ́ mọ̀ nípa àdúrà. Ronú nípa bọ́rọ̀ yìí ṣe kàn ẹ́: Ohun tó o kọ́ nínú Bíbélì ti jẹ́ kó o mọ Jésù, kó o sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. (Jòh. 14:21) Àmọ́ bíi tàwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé tó o bá gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó máa gbọ́ ẹ torí òun “fúnra rẹ̀ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún [ẹ].” Torí náà, gbogbo ìgbà tó o bá ń gbàdúrà sí Jèhófà tó o sì mọ̀ pé á gbọ́ ẹ, ńṣe lò ń fi hàn pé o gba ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí gbọ́.—1 Jòh. 5:14.
Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé tó o bá gbàdúrà sí Jèhófà, ó máa gbọ́ ẹ torí òun “fúnra rẹ̀ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún [ẹ]” (Wo ìpínrọ̀ 9-10)b
MỌ OHUN TÓ LÈ MÚ KÓ O MÁA RÒ PÉ JÈHÓFÀ Ò NÍFẸ̀Ẹ́ Ẹ
11. Inú ta lo rò pé ó máa dùn tá a bá ń rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa, kí sì nìdí?
11 Ta ló ń jẹ́ kó o máa rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ ẹ? Ó ṣeé ṣe kó o sọ pé Sátánì ló fà á, ìyẹn sì lè jóòótọ́. Èṣù ‘ń wá bó ṣe máa pa wá jẹ,’ torí náà inú ẹ̀ máa dùn tá a bá ń rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa. (1 Pét. 5:8) Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ló ṣe fi Ọmọ ẹ̀ rà wá pa dà, àmọ́ Sátánì fẹ́ ká máa rò pé ẹ̀ṣẹ̀ wa pọ̀ gan-an débi pé ìràpadà tí Jèhófà pèsè ò tọ́ sí wa. (Héb. 2:9) Tó o bá ń rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ ẹ, inú ta lo rò pé ó máa dùn? Inú Sátánì ló máa dùn. Inú ta lo rò pé ó máa dùn tó o bá fi Jèhófà sílẹ̀ nígbà ìṣòro? Inú Sátánì náà ló máa dùn. Sátánì fẹ́ ká máa rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa, àmọ́ irọ́ ló ń pa. Òun gan-an ni Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́. Ọ̀kan lára “àwọn àrékérekè” tàbí ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tó máa ń lò láti mú wa ni pé ó fẹ́ ká rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ti pa wá tì. (Éfé. 6:11) Tá a bá mọ̀ pé ṣe ni Sátánì ọ̀tá wa fẹ́ tàn wá jẹ, a máa túbọ̀ pinnu pé àá “dojú ìjà kọ Èṣù.”—Jém. 4:7.
12-13. Báwo ni ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún ṣe ṣàkóbá fún wa?
12 Nǹkan míì wà tó lè mú ká máa rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa. Ǹjẹ́ o mọ nǹkan náà? Ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún ni. (Sm. 51:5; Róòmù 5:12) Ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún yìí ti ba àjọṣe àwa àti Ẹlẹ́dàá wa jẹ́. Bákan náà, ẹ̀ṣẹ̀ yìí kì í jẹ́ ká ronú bó ṣe tọ́, ó sì ti ṣàkóbá fún ìmọ̀lára àti ìlera wa.
13 Ẹ̀ṣẹ̀ ti ṣàkóbá fún ìmọ̀lára wa torí pé ó máa ń jẹ́ ká dára wa lẹ́bi, ó ń jẹ́ ká ṣàníyàn, kì í jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀, ó sì máa ń jẹ́ kójú tì wá. Àwọn nǹkan tá a sọ yìí máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá dẹ́ṣẹ̀. Ó tún máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa torí a jẹ́ aláìpé, àmọ́ kì í ṣe bí Ọlọ́run ṣe dá wa nìyẹn. (Róòmù 8:20, 21) Tí táyà mọ́tò kan bá jò, kò ní lè sáré dáadáa. Lọ́nà kan náà, torí a jẹ́ aláìpé, a kì í lè ṣe nǹkan lọ́nà tó pé bí Ọlọ́run ṣe dá wa ní pípé níbẹ̀rẹ̀. Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé nígbà míì ó máa ń ṣe wá bíi pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa. Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ ẹ, máa rántí pé Jèhófà ni ‘Ọlọ́run tí ó tóbi, tó yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù, tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.’—Neh. 1:5.
14. Tá a bá ń rántí pé Jèhófà fi Ọmọ ẹ̀ rà wá pa dà, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an? (Róòmù 5:8) (Wo àpótí náà “Má Gba ‘Agbára Ìtannijẹ Ẹ̀ṣẹ̀’ Láyè.”)
14 Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè máa ṣe wá bíi pé a ò yẹ lẹ́ni tó yẹ kí Jèhófà nífẹ̀ẹ́. Ká sòótọ́, ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ṣàrà ọ̀tọ̀ torí pé a ò lẹ́tòọ́ sí i. Kì í ṣe pé a ṣe ohun ńlá kan fún Jèhófà tó mú kó pọn dandan pé kó nífẹ̀ẹ́ wa. Síbẹ̀ Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ìdí nìyẹn tó ṣe fi Ọmọ ẹ̀ rà wá pa dà ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (1 Jòh. 4:10) Yàtọ̀ síyẹn, rántí pé torí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni Jésù ṣe wá sáyé, kì í ṣe torí àwọn èèyàn pípé. (Ka Róòmù 5:8.) Kò sẹ́nì kankan nínú wa tó lè ṣe nǹkan lọ́nà tó pé, Jèhófà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Tá a bá ń rántí pé ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún lè mú ká rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa, àá túbọ̀ pinnu pé a ò ní jẹ́ kí àìpé mú ká máa ronú lọ́nà tí kò tọ́.—Róòmù 7:24, 25.
PINNU PÉ O Ò NÍ FI JÈHÓFÀ SÍLẸ̀
15-16. Tá ò bá fi Jèhófà sílẹ̀, kí ni Jèhófà máa ṣe fún wa, kí sì nìdí? (2 Sámúẹ́lì 22:26)
15 Jèhófà fẹ́ ká ṣe ìpinnu tó tọ́, ìyẹn ni pé ká ‘rọ̀ mọ́ òun.’ (Diu. 30:19, 20) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé kò ní fi wá sílẹ̀. (Ka 2 Sámúẹ́lì 22:26.) Tá ò bá ṣáà ti fi Jèhófà sílẹ̀, ìṣòro yòówù kó dé bá wa, ó dájú pé ó máa ràn wá lọ́wọ́.
16 Àwọn nǹkan tá a ti kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí ti jẹ́ ká rí i pé kò yẹ ká máa ṣiyèméjì pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa àti pé kò ní fi wá sílẹ̀ nígbà ìṣòro. Torí náà, ó dá wa lójú pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì máa ràn wá lọ́wọ́. Ohun tí Bíbélì fi kọ́ wa nìyẹn. Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ ẹ, máa rántí àwọn nǹkan tó o mọ̀ nípa Jèhófà tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ, dípò kó o máa ronú nípa ìṣòro tó ò ń bá yí lọ́wọ́lọ́wọ́. Torí náà bí Bíbélì ṣe sọ, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé títí láé ni Jèhófà á máa fìfẹ́ hàn sí wa.
ORIN 159 Jèhófà Ni Ìyìn àti Ògo Yẹ!
a Ara àwọn ẹsẹ Bíbélì míì tó fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ni Diutarónómì 31:8, Sáàmù 94:14 àti Àìsáyà 49:15.
b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kóun lè tọ́jú ìyàwó òun tára ẹ̀ ò yá, kóun lè fọgbọ́n ná owó tó ń wọlé, kóun sì lè kọ́ ọmọ òun láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.