Courtesy Jamie Christiani/Bulletin of the Atomic Scientists
Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Aago Doomsday Ti Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọ̀gànjọ́ Òru
Ní January 27, 2026, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì túbọ̀ sún ọwọ́ aago tí wọ́n ń pè ní Doomsdaya mọ́ aago méjìlá (12) òru. Wọ́n sọ pé tí ọwọ́ aago yẹn bá wọ aago méjìlá pẹ́nrẹ́n, ṣe ni àjálù máa bá gbogbo èèyàn tó wà láyé.
“Ìgbìmọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ìwé Bulletin of the Atomic Scientists sọ pé lónìí, àwọn ti sún aago Doomsday sí aago méjìlá ku ìṣẹ́jú àáyá márùnlélọ́gọ́rin (85). Aago yìí ò tíì sún mọ́ ọ̀gànjọ́ òru tó báyìí rí.”—Bulletin of the Atomic Scientists.
“Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì máa ń lo aago Doomsday láti jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe bà jẹ́ tó láyé. Ńṣe layé túbọ̀ ń dibi eléwu sí i, àwọn èèyàn ò fọwọ́ sọwọ́ pọ̀ mọ́, ṣe ni nǹkan ń burú sí i. Àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ ṣàtúnṣe, ó sì ṣeé ṣe. Àmọ́ àwọn èèyàn kárí ayé gbọ́dọ̀ fi dandan mú àwọn olórí wọn láti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ.”—Alexandra Bell, tó jẹ́ ààrẹ àti ọ̀gá ilé iṣẹ́ Bulletin of the Atomic Scientists.
Ṣé òótọ́ ni pé gbogbo èèyàn máa tó kú, ilẹ̀ ayé náà sì máa pa run pátápátá? Ṣé ó yẹ ká máa bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀? Kí ni Bíbélì sọ?
Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la
Bíbélì sọ pé “ayé wà títí láé” àti pé àwọn èèyàn “máa gbé inú rẹ̀ títí láé.” (Oníwàásù 1:4; Sáàmù 37:29) Torí náà, àwọn èèyàn ò lè pa ayé rẹ́ tàbí sọ ayé di ibi tá ò ní lè gbé mọ́.
Àmọ́, Bíbélì sọ pé ohun kan wà tó máa dópin. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé “ayé ń kọjá lọ.”—1 Jòhánù 2:17.
Tó o bá fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì ń sọ nígbà tó sọ pé ayé máa dópin, ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Ayé Ò Ní Pẹ́ Pa Run? Kí Ni Àpókálíìsì?”
Tó o bá fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìgbà táwọn nǹkan máa sẹlẹ̀ láyé, ka àpilẹ̀kọ náà “Ìgbà Wo Ni Òpin Ayé Máa Dé?”
Gbà pé nǹkan máa dáa
Ohun tó wà nínú Bíbélì lè jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ láìka àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí. Lọ́nà wo?
Àwọn ìmọ̀ràn tó máa ràn wá lọ́wọ́ wà nínú Bíbélì. (2 Tímótì 3:16, 17) Bí àpẹẹrẹ, ka àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Bó O Ṣe Lè Borí Àníyàn” kó o lè rí bí Bíbélì ṣe lè jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ láìka àwọn ìṣòro tó ò ń kojú sí.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ohun rere máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Róòmù 15:4) Ó jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ báyìí àtàwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ò dẹ́rù bà wá.
Kó o lè túbọ̀ jàǹfààní látinú àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ, a rọ̀ ẹ́ pé kó o jẹ́ kẹ́nì kan kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́.
a “Wọ́n máa ń fi aago Doomsday ṣàpèjúwe bí ayé yìí ṣe sún mọ́ àjálù tó. Wọ́n máa ń fi jẹ́ káwọn èèyàn mọ bí àwọn èèyàn ṣe ń fi àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tó léwu ba ayé jẹ́. Àfiwé ni, ó sì máa ń jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tó yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ káyé pa run.”—Bulletin of the Atomic Scientists.