ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 131
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Tí Ò Ríran

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Tí Ò Ríran
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí ọ̀rọ̀ àwọn tí ò ríran ṣe rí lára Ọlọ́run
  • Bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́
  • Àwọn nǹkan tá a lè fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wo la ti ṣe fáwọn tí ò ríran dáadáa?
  • Ran Àwọn Afọ́jú Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Mọ Jèhófà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Ìwé Tó Ń Ṣe Àwọn Èèyàn Láǹfààní
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Máa Wàásù fún Àwọn Afọ́jú
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Bí A Ṣe Lè Lo Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Gbohùn Wọn Sílẹ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 131
Ọkùnrin kan tí ò ríran jókòó síta, ó ń gbọ́ àtẹ́tísí kan lórí “JW Library.”

Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Tí Ò Ríran

Kárí ayé, nǹkan bíi mílíọ̀nù métàlélógójì (43) èèyàn ni ò ríran, àwọn mílíọ̀nù márùn-ún dín ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (295) ni ò sì ríran dáadáa.a Ó máa ń dùn wá gan-an tá a bá rí báwọn èèyàn ṣe ń hùwà ìkà, tí wọ́n sì ń rẹ́ àwọn èèyàn yìí jẹ.

Báwo lọ̀rọ̀ àwọn tí ò ríran ṣe rí lára Ọlọ́run? Kí ni Bíbélì sọ nípa wọn? Àwọn nǹkan wo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́ lónìí?

Bí ọ̀rọ̀ àwọn tí ò ríran ṣe rí lára Ọlọ́run

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ àwọn tí ò ríran jẹ Jèhófàb lógún, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn. Kò fẹ́ ká fojú pa wọ́n rẹ́, ó fẹ́ káwọn náà jàǹfààní àwọn ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ wa. Yàtọ̀ síyẹn, ó jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan rere tó máa ṣe fún wọn lọ́jọ́ iwájú.

Bíbélì sọ pé: “Ègún ni fún ẹni tó bá mú kí afọ́jú ṣìnà.”—Diutarónómì 27:18.

Èyí fi hàn pé: Nínú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn èèyàn ẹ̀, kò fẹ́ kí wọ́n máa hùwà àìdáa sáwọn tí kò ríran.

Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.”—Ìṣe 10:34.

Èyí fi hàn pé: Bóyá a ríran tàbí a ò ríran, gbogbo wa pátá ni Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́.

Bíbélì sọ pé: Jésù “mú kí ọ̀pọ̀ afọ́jú pa dà ríran.”—Lúùkù 7:21.

Èyí fi hàn pé: Jésù máa la ojú àwọn tí kò ríran, nínú Ìjọba Ọlọ́run bó ṣe ṣe nígbà tó wà láyé.

Bíbélì sọ pé: “Ojú àwọn afọ́jú máa là.”—Àìsáyà 35:5.

Èyí fi hàn pé: Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, àwọn tí ò ríran máa pa dà ríran bí Jèhófà ṣe ṣèlérí.

Bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́

Kárí ayé làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù àwọn ohun rere tí Ọlọ́run máa ṣe fáwọn tí ò ríran. Kí ló jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe?

  • A ṣe Bíbélì, àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn fídíò lọ́nà tí àwọn tí ò ríran tàbí tí ò ríran dáadáa á fi lè gbádùn wọn. A tún ṣe ìwé táwọn tí ò ríran lè kà, ìwé tí wọ́n kọ lọ́nà tó tóbi dáadáa àtàwọn àtẹ́tísí.

  • A máa ń ṣe àwọn ìpàdé Kristẹni, gbogbo èèyàn la máa ń pè, èyí ò sì yọ àwọn tí ò ríran sílẹ̀.

  • A máa ń kọ́ ẹni tó bá wù lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.c

A kì í gba owó gbogbo àwọn nǹkan tá à ń ṣe yìí. Kí nìdí? Torí àṣẹ tí Jésù pa ni, ó ní: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.”—Mátíù 10:8.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tí ò ríran gan an. A máa ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti jọ́sìn Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tí ò ríran.

Talita Alnashi lórílẹ̀-èdè Sweden: Kò ríran dáadáa látìgbà tí wọ́n ti bí i. Wo ohun táwọn òbí ẹ̀ ṣe kí wọ́n lè kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti báwọn ọ̀rẹ́ wọn ṣe fìfẹ́ hàn sí wọn, tí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́.

James Ryan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà: Adití ni nígbà tí wọ́n bí i, àmọ́ nígbà tó yá, kò ríran mọ́. Wo ohun tó ṣe tó fi ń láyọ̀.

Cynthia Pablo.

Cynthia Pablo lórílẹ̀-èdè Philippines: Adití ni kò tún ríran. Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi tiẹ̀ ṣe ràn án lọ́wọ́ nígbà àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà? Ka àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Ìjọ Ṣèrànwọ́ fún Arábìnrin Kan Tó Jẹ́ Adití àti Afọ́jú Lákòókò Àjàkálẹ̀ Àrùn.”

Àwọn nǹkan tá a lè fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wo la ti ṣe fáwọn tí ò ríran dáadáa?

Ọkùnrin kan tí ò ríran ń lo ẹ̀rọ táwọn tí ò ríran fi ń kàwé.

Àwọn ìwé táwọn tí ò ríran lè kà (braille). A ti ṣe apá kan tàbí odindi Bíbélì lọ́nà táwọn tí ò ríran fi lè kà á, ó sì ti wà ní èdè mélòó kan. (Wo àwọn èdè tá a ti ṣe nínú àpótí tá a pè ní “Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tá A Ṣe Ní Braille.”) A tún máa ń ṣe àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì lọ́nà táwọn tí ò ríran lè kà. A tún ṣe ìwé táwọn tó bá fẹ́ kọ́ braille lè lò, àkòrí ẹ̀ ni Learn to Read Braille. Ìwé yìí máa jẹ́ kí ẹni tí ò ríran lè ka braille, àmọ́ ẹni tó ríran ló máa ràn án lọ́wọ́.

  • Tó o bá fẹ́ ní ẹ̀dà ìwé braille, sọ fún ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí kó o ní ká wá ẹ wá.

  • Lórí ìkànnì jw.org, wa àwọn ìwé tó o lè lò lórí ẹ̀rọ táwọn afọ́jú fi ń kàwé jáde.d

Àwọn ìwé àtàwọn nǹkan míì tá a ṣe lọ́nà tó tóbi dáadáa. A ṣe àwọn ìwé tí ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ tóbi dáadaa fún àwọn tí kò ríran dáadáa. A ṣe ìkànnì jw.org lọ́nà tó jẹ́ pé, tá a bá tiẹ̀ fẹ̀ ẹ́ lójú, àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ á ṣì ṣeé kà. A tún ṣe JW Library lọ́nà tó jẹ́ pé a lè mú kí àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ tóbi kó lè ṣeé kà dáadáa.

  • Tó o bá fẹ́ ní ìwé tá a kọ lọ́nà tó tóbi, sọ fún ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí kó o ní ká wá ẹ wá.

  • Lórí ìkànnì jw.org, wa àwọn ìwé tá a kọ lọ́nà tó tóbi jáde.

Àwọn àtẹ́tísí. Àtẹ́tísí Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti wà ní èdè tó ju ọgọ́rùn-ún méjì (200) lọ. Ọ̀pọ̀ àwọn ìwé míì tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì la tún gbohùn ẹ̀ sílẹ̀, títí kan àwọn àwòrán tó wà nínú wọn, a sì tún máa ń ka àlàyé àwòrán náà jáde.

  • O lè gbọ́ àtẹ́tísí látorí jw.org àti JW Library, o sì lè wà á jáde.

  • Lọ sórí jw.org, kó o lè wa àwọn ohun táwọn tí ò ríran lè fi kàwé irú bíi screen reader àti digital talking book player jáde.e

Àwòrán ẹnì kan tó ń sọ̀rọ̀ sókè.

Àwọn fídíò tó ní àlàyé.f Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe fídíò tó ní àlàyé jáde ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún (100). Àwọn fídíò yìí máa ń jẹ́ káwọn èèyàn lóye ohun tí Bíbélì sọ, kí wọ́n sì fi ìmọ̀ràn ẹ̀ sílò.

Wo ọ̀wọ́ àwọn fídíò tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o lè rí àwọn fídíò tó ní àlàyé:

  • Tọkọtaya Aláyọ̀

  • Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

  • Àwọn Eré Ojú Pátákó

Àwọn ìpàdé àti àpéjọ. A ní àwọn ìjọ kárí ayé tá a ti ń pàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ká lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run ká sì jọ́sìn ẹ̀. A tún máa ń pàdé láwọn ibòmíì tó tóbi lọ́dọọdún ká lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láwọn ìgbà tá a bá ń wo fídíò láwọn ìpàdé yìí, a máa ń fi àtẹ́tísí tó ń ṣàlàyé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú fídíò yẹn kún un fáwọn tí ò lè ríran. Nígbà míì tó bá ṣeé ṣe, a máa ń ṣètò àwon tó máa túmọ̀ ohun tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ fún àwọn adití tí kò ríran. Gbogbo èèyàn la pè wá sáwọn ìpàdé wa, a kì í ṣe ojúsàájú ẹnikẹ́ni.

  • Wá ibi tá a ti ń ṣèpàdé.

  • Mọ̀ sí i nípa àwọn àpéjọ tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún.

  • Lọ sí ìpàdé tó ṣe pàtàkì jù tá a máa ń ṣe lọ́dún, ìyẹn Ìrántí Ikú Kristi.

Orílẹ̀-èdè Mexico ni José Luis Ayala ń gbé. Adití ni nígbà tí wọ́n bí i, nígbà tó sì di ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29), kò ríran mọ́. Wo àǹfààní ńlá tí àwọn ìpàdé wa ṣe é àti ohun tó ràn án lọ́wọ́ tó fi di ẹni tó ń kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa.

Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tá A Ṣe Ní Braille

Ní May 1, 2025, Bíbélì tó rọrùn kà yìí ti wà ní ẹ̀dà tó ṣeé kà fáwọn afọ́jú láwọn èdè tá a tò sísàlẹ̀ yìí.

Chichewa

Dutch

Gẹ̀ẹ́sì

French

Georgian

German

Greek

Hungarian

Italian

Japanese

Korean

Portuguese (Brazil)

Russian

Spanish

Ukranian

a Tí ẹnì kan kò bá ríran dáadáa, ìṣòro ojú tí kì í lọ ni, kò sì ní rọrùn fún ẹni náà láti ṣe àwọn nǹkan tó máa ń ṣe lójoojúmọ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, tá a bá sọ pé ẹnì kan ò ríran, ó lè jẹ́ pé kò ríran rárá tàbí pé kò ríran dáadáa.

b Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”

c O lè ní kí ẹnì kan wá fi bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn ẹ́ lọ́fẹ̀ẹ́.

d Ẹ̀rọ táwọn afọ́jú fi ń kàwé, tí wọ́n ń pè ní notetaker máa ń ṣàfihàn ìwé lọ́nà tí wọ́n á fi lè fi ìka wọn kà á, ó sì tún máa ń ka ohun tó wà nínú ìwé náà sókè. Àwọn àmì róbótó tó wà lójú ẹ̀rọ náà ló máa ń gbé ọ̀rọ̀ inú ìwé jáde lọ́nà táwọn afọ́jú á fi lè kà á. Téèyàn bá ti ní ẹ̀rọ yìí, kò nílò àtimáa gba ìwé tí wọ́n tẹ̀ sórí bébà fáwọn tí ò ríran mọ́.

e Àwọn ẹ̀rọ tá à ń pè ní screen reader àti digital talking book player máa ń ka ọ̀rọ̀ inú ìwé sókè. Ó lè jẹ́ kọ̀ǹpútà lá máa ka ọ̀rọ̀ náà jáde fúnra ẹ̀ tàbí kó jẹ́ ohùn tá a ti gbà sílẹ̀. Àwọn ẹ̀rọ yìí máa ń jẹ́ kéèyàn lè lọ síbi pàtó tó fẹ́ kà nínú ìwé kan.

f Àlàyé tá a máa ń fi sínú àwọn fídíò yìí máa ń dá lórí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ìran kọ̀ọ̀kan nínú fídíò kan.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́