Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Kí Ni Bíbélì Sọ Pé Ó Máa Ṣẹlẹ̀ sí Ìwà Ìkà Táwọn Èèyàn Ń Hù Torí Ẹ̀tanú?
Ó bani nínú jẹ́ pé ìwà ìkà táwọn èèyàn ń hù torí ìkórìíra tàbí ẹ̀tanú tí wọ́n ní sí àwọn ẹlòmíì ti wá pọ̀ gan-an ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ohun tó sì ń fa ẹ̀tanú yìí ò ju àwọn nǹkan bí ẹ̀sìn téèyàn ń ṣe, ẹ̀yà tàbí orílẹ̀-èdè téèyàn ti wá, bóyá ẹni náà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, àtàwọn nǹkan míì. Ìwà yìí ń dẹ́rù ba ọ̀pọ̀ èèyàn gan-an. Àwọn tó ń hùwà ìkà yìí ti ṣe àwọn kan léṣe, wọ́n sì ti dọ́gbẹ́ sáwọn míì lọ́kàn, kódà ràbọ̀ràbọ̀ ẹ̀ ò tíì kúrò lára wọn. Níbi tọ́rọ̀ ọ̀hún le dé, wọ́n ti dẹ́mìí àwọn míì légbodò.
Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé lásìkò wa yìí, àwọn èèyàn máa jẹ́ “ẹni tó burú gan-an, ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ ohun rere,” àti “ẹni tí kò ní ìfẹ́ àdámọ́ni.” (2 Tímótì 3:1-5) Àmọ́ ṣé ìgbà kan ń bọ̀ táwọn èèyàn ò ní hùwà ìkà mọ́? Kí ni Bíbélì sọ?
Bí ìwà ìkà táwọn èèyàn ń hù torí ẹ̀tanú ṣe máa dópin
Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run lágbára láti fòpin sí ìwà ìkà, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀.
“A ó mú àwọn ẹni ibi kúrò . . . Àmọ́ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé, inú wọn yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.” (Sáàmù 37:9-11) Ọlọ́run ò ní máa wò ó káwọn ìkà máa ṣe àwọn èèyàn léṣe títí lọ.
“[Ọlọ́run] máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìfihàn 21:4) Ọlọ́run máa wo àwọn tó fara pa torí ìwà ìkà tí wọ́n hù sí wọn sàn, ó máa wo ọgbẹ́ ọkàn wọn sàn, á sì mára tù wọ́n.
“Àjíǹde . . . yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Ọlọ́run máa jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tó ti kú dìde, títí kan àwọn tí wọ́n dẹ́mìí wọn légbodò torí ẹ̀tanú.
Ohun tá a lè ṣe báyìí
Lóòótọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìwà ìkà máa tó dópin, àmọ́ ó tún sọ ohun tá a lè ṣe ká lè borí ìkórìíra tó wọ́pọ̀ lóde òní. A rọ̀ ẹ́ pé kó o wo ohun tí Bíbélì sọ tó dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì yìí:
Kí la lè máa ṣe báyìí ká lè borí ìkórìíra tàbí ẹ̀tanú? Wo ẹ̀kọ́ Bíbélì tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ tí àkòrí ẹ̀ sọ pé “Bá A Ṣe Lè Borí Ìkórìíra.”
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi gbà pé ká máa jìyà tó báyìí? Wo fídíò tí àkòrí ẹ̀ sọ pé Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà? kó o lè lóye ohun tí Bíbélì sọ.