ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 138
  • “Ẹ Máa Gbọ́ Nípa Àwọn Ogun”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Máa Gbọ́ Nípa Àwọn Ogun”
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Jésù sọ
  • Ohun tí Jésù máa ṣe
  • Ìgbà Wo Ni Gbogbo Ogun Yìí Máa Dópin?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ayé Kan Láìsí Ogun Yóò Dé Láìpẹ́
    Jí!—1996
  • Bí A Ṣe Lè Mọ̀ Pé Amágẹ́dọ́nì Ti Sún Mọ́lé
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Lóde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 138
Fọ́tò: Jésù ń bá àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ohun táá máa ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí. Àwọn àwòrán róbótó nípa ogun tó ń jà lóde òní: àdúgbò kan tí ogun runlérùnnà ti jà, iná yọ níbi tí bọ́ńbù ti bú gbàù, àtàwọn ọmọ ogun tó ń rìn lọ rìn bọ̀, tí àwọn ọkọ̀ arọ̀jò-ọta sì ń tẹ̀ lé wọn.

KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA JÉSÙ

“Ẹ Máa Gbọ́ Nípa Àwọn Ogun”

John Simpson, tó jẹ́ oníròyìn àgbà nípa ohun tó ń lọ lágbàáyé fún iléeṣẹ́ BBC sọ pé: “Láti nǹkan bí ọgọ́ta (60) ọdún tí mo ti ń ṣiṣẹ́ oníròyìn, àwọn ogun tí mo ti sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú ìròyìn ti lé ní ogójì (40). Ojú mi báyìí ló ṣe ní gbogbo ìgbà tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ìjọba Soviet Union fi ń gbé e gbóná fúnra wọn àti ìgbà tí ìjà ọ̀hún ṣàdédé rọlẹ̀. Àmọ́ kò tíì sí èyí tó bà mí lẹ́rù tó ti ọdún 2025. Ìdí ni pé iye àwọn orílẹ̀-èdè olókìkí tó ń bára wọn jà kì í ṣe kékeré. Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣeé ṣe kí ọ̀kan nínú àwọn ogun tó ń jà yìí ṣàkóbá tó lágbára fún ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tó wà láyé.”

Àwọn ogun tó ń jà káàkiri ayé ń dẹ́rù ba àwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń rò ó pé tó bá yá, àfàìmọ̀ kí nǹkan má tiẹ̀ burú ju bó ṣe wà yìí. Kí ni Jésù sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí?

Ohun tí Jésù sọ

Jésù ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí máa ṣẹlẹ̀. Ó kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Ẹ máa gbọ́ nípa àwọn ogun, ẹ sì máa gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ogun.”—Mátíù 24:6.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ogun àti rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní máa ń dẹ́rù bà wá, ohun kan wà tó yẹ kó fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé nǹkan ṣì máa dáa. Kí ni nǹkan ọ̀hún? Jésù kọ́ wa pé àwọn ogun tó ń jà yìí àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míì, títí kan àwọn ìwà táwọn èèyàn á máa hù, máa para pọ̀ jẹ́ “àmì” tá a fi máa mọ̀ pé a ti wà ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 24:3; Lúùkù 21:7) Èyí jẹ́ ká rí i pé ìgbà kan ń bọ̀ tí Jésù máa fòpin sí ogun, tó sì máa di nǹkan àtijọ́. Lọ́nà wo?

Ohun tí Jésù máa ṣe

Láìpẹ́, Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run máa “fòpin sí ogun kárí ayé.”—Sáàmù 46:9.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí àlàáfíà ṣe máa jọba láyé àti bí ayé ṣe máa rí nígbà tí kò bá sí ogun mọ́, ka àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Bí Ogun àti Rògbòdìyàn Ṣe Máa Dópin.”

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́