KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA JÉSÙ
Máa Wáyè Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọlọ́run
Ayé ẹ máa dáa sí i tó o bá ń wáyè láti túbọ̀ mọ Ọlọ́run. Ìyẹn ló máa fi hàn pé o fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Jésù ní ká ṣe tá a bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run.
Ohun tí Jésù sọ
“Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.”—Mátíù 5:3.
Gbogbo wa la fẹ́ mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bíi: Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá wa? Kí nìdí tí ìyà fi pọ̀ gan-an láyé? Kí ló ń ṣelẹ̀ sáwọn tó ti kú? Tá a bá mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí, a máa láyọ̀.
“Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè, àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu Jèhófàa jáde ni èèyàn fi ń wà láàyè.”—Mátíù 4:4.
Bí oúnjẹ ṣe máa ń jẹ́ kéèyàn wà láàyè, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe ohun táá jẹ́ ká sún mọ́ Ọlọ́run. Jésù sọ pé gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa wojú Ọlọ́run fún ìtọ́sọ́nà.
“Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.”—Jòhánù 17:17.
Jésù jẹ́ ká mọ nǹkan tí Ọlọ́run ń lò láti tọ́ wa sọ́nà, ìyẹn ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀.
A rọ̀ ẹ́ pé kó o ṣe ohun tó máa jẹ́ kó o láyọ̀ títí láé. Bó o ṣe lè ṣe é ni pé kó o máa wáyè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, kó o sì máa ṣe ohun tó máa jẹ́ kó o sún mọ́ ọn. Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ rèé:
Ka Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́.
Ní kí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́.
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Ta Ni Jèhófà?”