KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA JÉSÙ
Ìjà Ò Lè Yanjú Ìṣòro
Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló gbà pé tí wàhálà bá ṣẹlẹ̀, ó yẹ káwọn jà, káwọn sì gbẹ̀san. Wọ́n tiẹ̀ máa ń sọ pé wèrè la fi ń wo wèrè. Àmọ́ èrò yìí ò tọ̀nà torí ó yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Jésù ṣe àtohun tó kọ́ wa. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ohun tí Jésù sọ àtohun tó ṣe.
Ohun tí Jésù sọ
Nínú Ìwàásù orí Òkè, Jésù kọ́ wa pé tá a bá níṣòro pẹ̀lú àwọn èèyàn, ìbínú àti ìjà kọ́ ló máa yanjú ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀.
“Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí wọn.” (Mátíù 7:12; Lúùkù 6:31) Òfin yìí ni wọ́n máa ń pè ní Òfin Oníwúrà.a Ó sì dáa gan-an torí ó jẹ́ ká rí i pé ìwà tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn hù sí wa ló yẹ ká máa hù sí wọn. Ó dájú pé kò sẹ́ni táá fẹ́ kẹ́nì kan máa bá òun jà tàbí kó máa ni òun lára kódà tọ́rọ̀ wọn ò bá wọ̀. Torí náà, ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún gbogbo èèyàn, ká sì máa ṣe dáadáa sí wọn.
“Ẹnikẹ́ni tó bá gbá yín ní etí ọ̀tún, ẹ yí èkejì sí i.” (Mátíù 5:38, 39; Lúùkù 6:29) Jésù ò sọ pé ká wá tẹ́ ara wa bí ẹní, káwọn èèyàn lè máa gun orí wa kọjá o. Dípò bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé kò yẹ káwọn èèyàn máa gbẹ̀san, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan ló ń kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó ń sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ni pé tẹ́nì kan bá múnú bí wọn, wọn ò gbọdọ̀ gbẹ̀san. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kí wọ́n ṣe sùúrù, kí wọ́n má sì bá ẹni náà fa wàhálà.b
“Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín.” (Mátíù 5:43, 44; Lúùkù 6:27) Jésù sọ pé ká máa ṣoore fáwọn tó kórìíra wa tàbí tó hùwà àìdáa sí wa, àmọ́ kò sọ pé ká fara mọ́ ìwà burúkú wọn.c Tá a bá ń ṣoore fáwọn tó kórìíra wa, ọkàn wọn lè rọ̀ káwọn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà tó dáa sí wa.
Ohun tí Jésù ti ṣe àtohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú
Jésù kọ́ wa pé ìjà àti wàhálà kọ́ ló máa yanjú ìṣòro, ohun tó kọ́ àwọn èèyàn lòun náà sì ṣe. Bí àpẹẹrẹ, lálẹ́ ọjọ́ táwọn ọ̀tá Jésù wá mú un, ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bá wọn jà, àmọ́ Jésù sọ pé: “Dá idà rẹ pa dà sí àyè rẹ̀, torí gbogbo àwọn tó bá yọ idà máa ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:52) Jésù fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá tó hùwà àìdáa sóun torí ó dárí jì wọ́n, kódà ó gbàdúrà fún wọn!—Lúùkù 23:33, 34; 1 Pétérù 2:23.
Bíbélì ṣèlérí pé Jésù tó jẹ́ Ọmọ Aládé Àlàáfíà máa tó fòpin sí gbogbo wàhálà. (Àìsáyà 9:6, 7) Kó o lè mọ̀ sí i nípa àwọn nǹkan rere tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ka àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Bí Ogun àti Rògbòdìyàn Ṣe Máa Dópin.”
a Kó o lè mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Kí Ni Òfin Oníwúrà?”
b Kó o lè mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Kí Ni Ìtumọ̀ ‘Ojú fún Ojú’?”
c Kó o lè mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti ‘Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ọ̀tá Wa’?”