ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 132
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ogun Tí Wọ́n Ń Jà ní Middle East?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ogun Tí Wọ́n Ń Jà ní Middle East?
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé àwọn ìjọba máa fòpin sí ogun tí wọ́n ń jà ní Middle East?
  • Ṣé ogun tí wọ́n ń jà ní Middle East ń jẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ ni?
  • Ṣé Middle East ni Amágẹ́dọ́nì ti máa bẹ̀rẹ̀?
  • Kí ló máa jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ lásìkò ogun?
  • Ìgbà Wo Ni Gbogbo Ogun Yìí Máa Dópin?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ṣé Orílẹ̀-Èdè Israel Ni Amágẹ́dọ́nì Ti Máa Bẹ̀rẹ̀?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Amágẹ́dọ́nì Yóò Ṣínà Ayọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Lóde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 132
Èéfín ń rú túú ní ìlú kan tí wọ́n ju bọ́ǹbù sí ní Middle East.

Photo by Stringer/Getty Images

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ogun Tí Wọ́n Ń Jà ní Middle East?

Kárí ayé lọkàn àwọn èèyàn ò ti balẹ̀ torí ogun tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Ísírẹ́lì àti Iran ń bá ara wọn jà. Ṣé ogun náà máa le débi pé ó máa kan àwọn orílẹ̀-èdè míì? Ṣé àwọn ìjọba lè fòpin sí wàhálà náà kí wọ́n sì jẹ́ kí àlàáfíà jọba kárí ayé?

Àwọn tó mọ̀ nípa Bíbélì lè máa rò pé ṣé ogun tí wọ́n ń jà ní Middle East ló máa bẹ̀rẹ̀ ogun Amágẹ́dọ́nì tí ìwé Ìfihàn sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.

Kí ni Bíbélì sọ nípa ẹ̀?

Ṣé àwọn ìjọba máa fòpin sí ogun tí wọ́n ń jà ní Middle East?

Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé àwọn olórítàbí lé ọmọ èèyàn, tí kò lè gbani là.”—Sáàmù 146:3.

A ò mọ̀ bóyá àwọn ìjọba máa lè ṣe nǹkan táá jẹ́ kí àlàáfíà wà ní Middle East déwọ̀n àyè kan. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé kò sí olóṣèlú kankan, ìjọba èèyàn tàbí àwùjọ èyíkéyìí tó lè fòpin sí ogun, kí wọ́n sì jẹ́ kí àlàáfíà wà kárí ayé. Ọlọ́run nìkan ló lè “fòpin sí ogun kárí ayé.”—Sáàmù 46:9.

  • Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka Ilé Ìṣọ́ tó ní àkòrí náà “Ṣé Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Kò Ní Sí Ogun Mọ́?”

Ṣé ogun tí wọ́n ń jà ní Middle East ń jẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ ni?

Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa gbọ́ nípa àwọn ogun, ẹ sì máa gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ogun. . . . Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.”—Mátíù 24:6, 7.

Ogun tí wọ́n ń jà ní Middle East jẹ́ ká mọ̀ pé a ti wà ní “ìparí ètò àwọn nǹkan” àti pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí. (Mátíù 24:3; 2 Tímótì 3:1) Ogun tí wọ́n ń jà kárí ayé fi hàn pé Ọlọ́run máa tó fòpin sí gbogbo ogun àtàwọn wàhálà míì tó ń pọ́n aráyé lójú.

  • Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Àmì Wo Ló Fi Hàn Pé A Ti Wà Ní “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn,” Tàbí ‘Òpin Ayé’?”

Ṣé Middle East ni Amágẹ́dọ́nì ti máa bẹ̀rẹ̀?

Bíbélì sọ pé: “Wọ́n sì kó wọn jọ sí ibi tí wọ́n ń pè ní Amágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.”—Ìfihàn 16:16.

Ogun Amágẹ́dọ́nì kì í ṣe ogun tó máa bẹ̀rẹ̀ láàárín ìjọba èèyàn ní Middle East. Ogun náà máa jẹ́ láàárín gbogbo ìjọba ayé pátá àti Ọlọ́run.

  • Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì?”

Kí ló máa jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ lásìkò ogun?

Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, àmọ́ nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run.”—Fílípì 4:6.

Jèhófàa Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbàdúrà sí òun. Ó máa gbọ́ àdúrà wa, ó sì máa jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ nígbà ìṣòro torí ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ń bójú tó wa. (1 Pétérù 5:7) Ọ̀kan lára ọ̀nà tó ń gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa ni pé ó jẹ́ ká mọ ìdí táwọn èèyàn fi ń bára wọn jagun àti pé òun máa fòpin sí ogun, òun sì máa mú gbogbo ẹ̀dùn ọkàn àti ìrora tí ogun ti fà kúrò.—Ìfihàn 21:3, 4.

  • Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Ọlọ́run ṣe ń ràn wá lọ́wọ́, ka àpilẹ̀kọ tó ní àkòrí náà “Ṣé Mo Lè Rí Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Máa Tù Mí Nínú Nínú Bíbélì?”

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́