KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA JÉSÙ
Àlàáfíà Máa Wà Kárí Ayé
Gbogbo èèyàn ló fẹ́ gbé ayé tí àlàáfíà máa wà. Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn alákòóso kárí ayé ti ń gbìyànjú láti dá àlàáfíà pa dà síbi tí ogun bá ti jà. Nígbà míì, ohun tí wọ́n bá ṣe máa ń mú kí àlàáfíà wà fúngbà díẹ̀, torí pé kì í pẹ́ tí ogun á tún fi bẹ̀rẹ̀. Àmọ́ ṣé àlàáfíà lè wà kárí ayé? Bẹ́ẹ̀ ni! Àwọn nǹkan tí Jésù máa ṣe àtàwọn ohun tó sọ jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀.
Ohun tí Jésù máa ṣe
Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tí Jésù máa ṣe kí àlàáfíà lè wà kárí ayé.
“Orúkọ [Jésù] á máa jẹ́ . . . Ọmọ Aládé Àlàáfíà. Àkóso rẹ̀ á máa gbilẹ̀ títí lọ, àlàáfíà kò sì ní lópin.” (Àìsáyà 9:6, 7) Torí Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó máa mú kí àlàáfíà tí kò lópin wà kárí ayé.
“Yóò gba àwọn aláìní tó ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀ . . . àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.” (Sáàmù 72:12-14) Jésù máa mú kí ìdájọ́ òdodo wà, ó máa fòpin sí gbogbo ogun, ìwà ọ̀daràn àti ìyà.
“Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́, wọn ò sì ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” (Àìsáyà 2:4) Nígbà tí Jésù bá ń ṣàkóso, gbogbo èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn dípò kí wọ́n máa bá ara wọn jà.
Kó o lè mọ bí Jésù ṣe máa ṣe àwọn nǹkan yìí àtohun tó yẹ kíwọ náà ṣe, wo fídíò tá a pe àkòrí ẹ̀ ní Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
Ohun tí Jésù sọ
Títí dòní, àwọn ẹ̀kọ́ Jésù ṣì ń ran ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wà ní àlàáfíà. Nínú Ìwàásù orí Òkè, Jésù kọ́ àwọn èèyàn lóhun tó máa jẹ́ kí wọ́n máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀.
“Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá àlàáfíà.” (Mátíù 5:9) Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé yàtọ̀ sí pé kí wọ́n má bá àwọn èèyàn jà, ó tún yẹ kí wọ́n máa wá àlàáfíà.
“Kọ́kọ́ wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ, lẹ́yìn náà, kí o pa dà wá fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.” (Mátíù 5:23, 24) Jésù gba àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n tètè máa yanjú aáwọ̀. Ó sọ pé tá a bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run, ó ṣe pàtàkì pé ká wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn.
“Ẹ yéé dáni lẹ́jọ́, kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.” (Mátíù 7:1) Jésù sọ pé ká má dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́, ká má ṣàríwísí wọn tàbí ká máa retí pé kí wọ́n ṣe ohun táwa fúnra wa ò lè ṣe. Dípò bẹ́ẹ̀, ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n “máa dárí” ji àwọn tó ṣẹ̀ wọ́n.—Lúùkù 6:37.
Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló ń ṣe ohun tí Jésù sọ yìí. Kódà láwọn ibi tí wàhálà wà tàbí táwọn èèyàn ti ń bára wọn jagun, wọ́n ń yanjú aáwọ̀ láìbá ara wọn jà, wọ́n ń dárí ji ara wọn, wọ́n sì ń fìfẹ́ hàn síra wọn kódà nígbà táwọn míì hùwà tí ò dáa sí wọn.
Kó o lè rí bí ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe jẹ́ kí ọkàn àwọn kan balẹ̀, ka àpilẹ̀kọ náà “Ọkàn Ẹ Lè Balẹ̀ Láìka Ohun Tí Ogun àti Rògbòdìyàn Ti Fojú Ẹ Rí.”