JULY 27–AUGUST 2, 2026
ORIN 56 Sọ Òtítọ́ Di Tìrẹ
Àwọn Nǹkan Tí Ò Ní Jẹ́ Kó O Fi Jèhófà Sílẹ̀ Tó O Bá Ń Gba Àfikún Ẹ̀kọ́
“Níbi tí a tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò ní ọ̀nà kan náà.”—FÍLÍ. 3:16.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Àwọn ìlànà Bíbélì mẹ́rin tí ò ní jẹ́ kó o jìnnà sí Jèhófà tó o bá pinnu láti kàwé sí i tàbí kọ́ṣẹ́.
1-2. (a) Tó o bá pinnu pe wàá kàwé sí i, kí lo gbọ́dọ̀ máa ṣe nìṣó? (b) Tá a bá ní kéèyàn máa “rìn létòlétò ní ọ̀nà kan náà” kí là ń sọ? (Fílípì 3:16)
ÀWỌN Kristẹni kan ti pinnu pé àwọn á kàwé sí i tàbí gba àfikún ẹ̀kọ́ míì lẹ́yìn tí wọ́n parí ilé ẹ̀kọ́ girama. Wọ́n gbà pé irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ káwọn lè gbọ́ bùkátà ara wọn kí wọ́n sì lè ráyè sin Jèhófà dáadáa. Tó o bá ti pinnu pé wàá kàwé sí i tàbí gba àfikún ẹ̀kọ́ míì, kí lo lè ṣe tó ò fi ní jìnnà sí Jèhófà? (Jém. 4:8a) Kò sí àní-àní pé nígbà tó o wà nílé ẹ̀kọ́ girama, àwọn àdánwò kan wà tó o kojú, síbẹ̀ o borí wọn. Ní báyìí, ó ṣe pàtàkì kó o “máa rìn létòlétò ní ọ̀nà kan náà,” ìyẹn ni pé kó o pinnu láti máa fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà nìṣó bó o ṣe ṣe nígbà yẹn.—Ka Fílípì 3:16.
2 Wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “rìn létòlétò ní ọ̀nà kan náà” fáwọn sójà tí wọ́n jọ ń gbẹ́sẹ̀, tí wọ́n sì ń yan lọ láì bojú wẹ̀yìn. Bíi tàwọn sójà tá a sọ yìí, o gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn ẹ tó o bá pinnu pé wàá kàwé sí i, kò yẹ kó o dúró sójú kan tàbí kó o máa jó rẹ̀yìn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìlànà Bíbélì mẹ́rin tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Àwọn ìlànà yìí ò ṣàjèjì sí ẹ torí o mọ̀ wọ́n tẹ́lẹ̀. O ti fi àwọn ìlànà yìí sílò nígbà tó o wà nílé ẹ̀kọ́ girama. Àmọ́ ó ṣì yẹ kó o máa fi wọ́n sílò báyìí tó o pinnu pé wàá kàwé sí i, kódà àwọn ìlànà yìí á ṣì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ lẹ́yìn tó o bá parí ẹ̀kọ́ ẹ.
MÁA ṢE ÀWỌN NǸKAN TÁÁ JẸ́ KÓ O SÚN MỌ́ JÈHÓFÀ
3. Tó o bá ń gba àfikún ẹ̀kọ́, kí ló lè ṣẹlẹ̀ sáwọn nǹkan tó o máa ń ṣe tẹ́lẹ̀?
3 Ohun tó lè ṣẹlẹ̀. Tó o bá ń gba àfikún ẹ̀kọ́, ọwọ́ ẹ lè dí débi pé o lè má ráyè ṣe àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Torí pé wàá fẹ́ gbájú mọ́ ẹ̀kọ́ ẹ kó o lè yege, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn nǹkan tó ò ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà. Kódà, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í pa ìpàdé jẹ, kó o má wàásù déédéé mọ́, kí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àdúrà ẹ sì di ségesège.—Ìfi. 2:4.
4. Tá a bá sọ pé ká “ní ohun púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa” kí là ń sọ gan-an? (1 Kọ́ríńtì 15:58)
4 Ka 1 Kọ́ríńtì 15:58. Tó o bá fẹ́ kí kẹ̀kẹ́ kan máa lọ síwájú, o gbọ́dọ̀ máa wà á lọ. Lọ́nà kan náà, tó o bá fẹ́ máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Jèhófà, o gbọ́dọ̀ “ní ohun púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.” Kì í ṣe bí àkókò tá a lò nínú ìjọsìn wa ṣe pọ̀ tó ni ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ. Ohun tó ń sọ ni pé ìjọsìn Jèhófà ló yẹ kó gbawájú láyé wa. Má gbàgbé pé ìjọsìn Jèhófà ṣe pàtàkì ju àfikún ẹ̀kọ́ tó ò ń gbà lọ. (Mát. 22:37) Arábìnrin Samantha tó jẹ́ ọ̀dọ́ sọ pé, “Mo ti pinnu pé tí àfikún ẹ̀kọ́ tí mò ń gbà ò bá jẹ́ kí n lè sin Jèhófà dáadáa, màá pa ilé ẹ̀kọ́ náà tì.”
5. Kí ló yẹ kó o ṣe kó o lè fi ìjọsìn Jèhófà ṣáájú láyé ẹ?
5 Ohun tó yẹ kó o ṣe kó o tó bẹ̀rẹ̀ àfikún ẹ̀kọ́. Pinnu pé ìjọsìn Jèhófà lo máa fi ṣáájú láyé ẹ. Bi ara ẹ pé: ‘Kí ni máa ṣe kí n lè máa lọ sípàdé déédéé, kí n máa kópa tó jọjú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kí n sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé?’ (Jóṣ. 1:8; Mát. 28:19, 20; Héb. 10:25) Bákan náà, tún ronú nípa ọwọ́ tó o fi mú àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run nígbà tó o wà nílé ẹ̀kọ́ girama. Tó o bá rí i pé o ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe dáadáa tó nígbà yẹn, àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o ṣe báyìí? Pinnu pé wàá máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà bó o ṣe ń gba àfikún ẹ̀kọ́. Fojú sí ẹ̀kọ́ ẹ, àmọ́ má jẹ́ kó pa ìjọsìn ẹ lára.a—Mát. 6:24.
6. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kó o bi ara ẹ tó o bá ń yẹ ara ẹ wò? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
6 Bó o ṣe ń kàwé sí i tàbí kọ́ṣẹ́, á dáa kó o máa yẹ ara ẹ wò déédéé, o tiẹ̀ lè máa ṣe bẹ́ẹ̀ lóṣooṣù, kó o lè mọ̀ bóyá ìjọsìn Jèhófà lo ṣì kà sí pàtàkì jù láyé ẹ. Bí àpẹẹrẹ, o lè bi ara ẹ pé: Ṣé mo máa ń pa ìpàdé jẹ àbí mo máa ń pẹ́ dé ìpàdé? Tí mo bá sì wà nípàdé ṣe àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n fún mi ni mo máa ń ronú nípa ẹ̀? Ṣé mo fẹ́ràn láti máa ṣèpàdé lórí Zoom dípò kí n lọ lójúkojú? Yàtọ̀ síyẹn, tún bi ara ẹ pé: Ṣé Bíbélì kíkà àti àdúrà mi ti di ségesège? Ṣé mo kàn ń lọ sóde ìwàásù torí kí wọ́n lè rí i pé mo jáde, tó sì máa ń ṣe mi bíi kí n tètè pa dà sílé? Tí ọ̀kan lára àwọn ìdáhùn ẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, á dáa kó o tètè gbé ìgbésẹ̀ láti ṣàtúnṣe. Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀kọ́ tó ò ń gbà mú kó o jìnnà sí Jèhófà.
Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀kọ́ tó ò ń gbà dí ẹ lọ́wọ́ láti fi ìjọsìn Jèhófà ṣáájú láyé ẹ (Wo ìpínrọ̀ 6)
“DÁÀBÒ BO LÀÁKÀYÈ RẸ”
7. Bó o ṣe ń gba àfikún ẹ̀kọ́, èrò tí ò tọ́ wo ni wọ́n lè máa fi kọ́ ẹ?
7 Ohun tó lè ṣẹlẹ̀. Àwọn àfikún ẹ̀kọ́ kan wà tí wọ́n ti lè kọ́ ẹ pé kò sí Ọlọ́run àti pé ṣe ni gbogbo nǹkan tó wà láyé kàn ṣàdédé wà. Bíbélì pe irú àwọn ẹ̀kọ́ yìí ní “ọgbọ́n orí àti ìtànjẹ lásán.” (Kól. 2:8) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún lè kọ́ ẹ pé ọwọ́ ẹ ló wà tó o bá fẹ́ ṣàṣeyọrí, kò yẹ kó o gbára lé ẹnikẹ́ni. Arákùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i, ó sọ pé: “Wọn ò kàn kọ́ wa níwèé nìkan, wọ́n tún kọ́ wa bó ṣe yẹ ká máa ronú. Àwọn ohun tí wọ́n kọ́ wa yìí yàtọ̀ sí bí Jèhófà ṣe fẹ́ ká máa ronú. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n kọ́ wa pé a ò nílò ìrànlọ́wọ́ ẹnikẹ́ni tá a bá fẹ́ káyé wa dáa. Ohun tí wọ́n kọ́ wa yìí ò tíẹ̀ jẹ́ kí n rí ti Jèhófà rò, ìyẹn sì mú kó níra fún mi láti gbára lé e nínú gbogbo ohun tí mò ń ṣe.”
8. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká “dáàbò bo làákàyè [wa]”? (Òwe 5:1, 2)
8 Ka Òwe 5:1, 2. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé ká “dáàbò bo làákàyè [wa].” Ohun tá a bá mọ̀ pé ẹnì kan fẹ́ gbà lọ́wọ́ wa tàbí tá a mọ̀ pé ó lè bà jẹ́ la máa ń dáàbò bò. Ohun tó sì yẹ ká ṣe sí ìrònú wa náà nìyẹn. (1 Pét. 5:8) Àwọn èèyàn ayé ò rí ohun tó burú nínú ìṣekúṣe, wọn ò mọ bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀, kódà àwọn kan nínú wọn ò gbà pé Ọlọ́run wà. Tá ò bá ṣọ́ra a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bíi tiwọn kí ìgbàgbọ́ wa má sì lágbára mọ́. Lójú àwọn tó wà nínú ayé, wọ́n gbà pé èrò àwọn ló tọ̀nà, àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé èrò wọn ò tọ̀nà rárá. Kódà Bíbélì sọ pe irú èrò bẹ́ẹ̀ jẹ́ “òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”—1 Kọ́r. 3:18-20.
9. Tó o bá fẹ́ dáàbò bo làákàyè ẹ, kí ló yẹ kó o ṣe?
9 Ohun tó yẹ kó o ṣe kó o tó bẹ̀rẹ̀ àfikún ẹ̀kọ́. Tó o bá fẹ́ dáàbò bo làákàyè ẹ, ó ṣe pàtàkì kí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni dá ẹ lójú kó o tó bẹ̀rẹ̀ àfikún ẹ̀kọ́ ẹ. Bi ara ẹ pé: ‘Kí ló mú kí n gbà pé Ọlọ́run wà? Kí ló mú kó dá mi lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì? Kí ló mú kí n gbà pé ìmọ̀ràn Bíbélì nípa ìṣekúṣe máa ṣe mí láǹfààní ju ohun táyé ń gbé lárugẹ?’ Tún ronú nípa ìgbà tó o ṣì wà nílé ẹ̀kọ́ girama, kó o wá bi ara ẹ pé: Nígbà tí wọ́n kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, ṣé mi ò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì pé bóyá ni Ọlọ́run wà àti pé òun ló dá ohun gbogbo? Ṣé ó máa ń wù mí kémi náà máa hùwàkiwà bíi táwọn ọmọléèwé mi? Tó o bá rí i pé o ò ṣe dáadáa tó nígbà yẹn, kí lo lè ṣe báyìí táá jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé òótọ́ pọ́ńbélé lohun tí Bíbélì fi kọ́ni? Pinnu pé wàá dáàbò bo làákàyè rẹ bó o ṣe ń gba àfikún ẹ̀kọ́.—2 Tím. 2:16-18.b
10. Kí ló yẹ kó o máa ṣe tí o ò bá fẹ́ máa ronú bí àwọn tí ò mọ Jèhófà?
10 Tó o bá ń gba àfikún ẹ̀kọ́, á dáa kó o máa yẹ ara ẹ wò látìgbàdégbà. Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé ìwàkiwà táwọn tá a jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ ń hù ò ti máa ràn mí? Ṣé màá mọ̀ tó bá jẹ́ pé ọgbọ́n táyé ń gbé lárúgẹ ni wọ́n fi ń kọ́ mi? Ṣé ó dá mi lójú pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa yanjú ìṣòro aráyé?’ Tí o ò bá fẹ́ máa ronú bí àwọn tí ò mọ Jèhófà, ó ṣe pàtàkì kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó o sì ń ṣàṣàrò, á túbọ̀ dá ẹ lójú pé òótọ́ lohun tó o gbà gbọ́.—1 Tím. 4:15.
MÁA LO ÀKÓKÒ Ẹ LỌ́NÀ TÓ DÁA
11. Tó o bá ń gba àfikún ẹ̀kọ́, báwo ni ọ̀nà tó ò ń gbà lo àkókò ẹ ṣe lè di ìṣòro?
11 Ohun tó lè ṣẹlẹ̀. Ó yẹ kó o mọ̀ pé àfikún ẹ̀kọ́ á máa gba àkókò ẹ, pàápàá tó o bá ń múra ìdánwò tàbí tó ò ń ṣiṣẹ́ pàtàkì kan tí wọ́n gbé fún ẹ nílé ẹ̀kọ́. Tí o ò bá lo àkókò ẹ lọ́nà tó dáa, ìyẹn lè jẹ́ kó tètè máa rẹ̀ ẹ́ kí gbogbo nǹkan sì tojú sú ẹ. Torí náà, ó ṣe pàtàkì kó o máa wáyè tọ́jú ara ẹ.
12. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o máa ṣe tó o bá fẹ́ “máa lo àkókò [ẹ] lọ́nà tó dára jù lọ”? (Éfésù 5:15, 16)
12 Ka Éfésù 5:15, 16. Ó lè má rọrùn fún ẹ láti “máa lo àkókò [ẹ] lọ́nà tó dára jù lọ.” Torí náà, ó yẹ kó o fọgbọ́n ṣe é. Bí àpẹẹrẹ, òótọ́ ni pé ó yẹ kó o fojú sí ẹ̀kọ́ ẹ, síbẹ̀ ó ṣe pàtàkì kó o máa wáyè fáwọn mọ̀lẹ́bì ẹ àtàwọn ará ìjọ. (Sm. 133:1; Òwe 18:1) Àmọ́ èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o máa wáyè ṣe ohun táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Mát. 6:33) Yàtọ̀ síyẹn, o lè ní àwọn ojúṣe míì nínú ìdílé tàbí kó o ní iṣẹ́ tó o fi ń gbọ́ bùkátà ara ẹ. Bákan náà, ó yẹ kó o máa wáyè sinmi kó o sì máa ṣeré ìmárale kí ara ẹ lè jí pépé. (Oníw. 4:6; 1 Tím. 4:8) Gbogbo nǹkan yìí gba pé kó o ṣètò àkókò ẹ dáadáa.
13. Kí lo lè ṣe kó o lè máa ráyè ṣe àwọn nǹkan pàtàkì?
13 Ohun tó yẹ kó o ṣe kó o tó bẹ̀rẹ̀ àfikún ẹ̀kọ́. Bíbélì sọ pé téèyàn bá ń múra sílẹ̀, ohun tó bá ṣe máa yọrí sí rere. (Òwe 21:5) Torí náà, ó yẹ kó o ṣètò ara ẹ dáadáa kó o tó bẹ̀rẹ̀ àfikún ẹ̀kọ́ ẹ. Ronú nípa ìgbà tó o ṣì wà nílé ẹ̀kọ́ girama, kó o wá bi ara ẹ pé: Ṣé mo máa ń ráyè ṣe gbogbo ohun tó yẹ kí n ṣe nígbà yẹn? Tó o bá rí i pé o ò ṣe dáadáa tó nígbà yẹn, àwọn àtúnṣe wo lo lè ṣe báyìí? Á dáa kó o ṣètò ara ẹ dáadáa kó o lè ráyè ṣe gbogbo nǹkan pàtàkì tó yẹ kó o ṣe.c
14. Àwọn ìbéèrè wo lo lè fi yẹ ara ẹ wò?
14 Tó o bá ń gba àfikún ẹ̀kọ́, á dáa kó o máa yẹ ara ẹ wò látìgbàdégbà. Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé àfikún ẹ̀kọ́ tí mò ń gbà máa ń jẹ́ kí n ráyè sinmi, kí n sì ṣeré ìmárale? Ṣé mo ṣì máa ń ráyè lọ kí àwọn ará, ká sì jọ ṣeré? Ṣé mo máa ń tètè parí iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n bá fún mi? Tó bá jẹ́ pé mi ò kì í tètè ṣe é, ṣé torí pé iṣẹ́ pọ̀ lọ́wọ́ mi ni àbí torí mo máa ń fi nǹkan falẹ̀? Ṣé àwọn ará ilé mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi ti sọ fún mi pé ó yẹ kí n ṣe àwọn àtúnṣe kan?’ Ó lè jẹ́ pé ó yẹ kó o túbọ̀ ṣètò ara ẹ dáadáa tàbí kó jẹ́ pé ó yẹ kó o túbọ̀ máa fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan. Èyí ó wù kó jẹ́, ó yẹ kó o tètè ṣàtúnṣe. O tún lè bá àwọn míì tí wọ́n mọ béèyàn ṣe ń ṣètò àkókò wọn dáadáa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.—Òwe 11:14.
MÁA BÁ ÀWỌN “ỌLỌ́GBỌ́N RÌN”
15. Kí ni nǹkan míì tó lè ṣẹlẹ̀ bó o ṣe ń gba àfikún ẹ̀kọ́?
15 Ohun tó lè ṣẹlẹ̀. Bó o ṣe ń gba àfikún ẹ̀kọ́, àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹ lè fẹ́ kẹ́ ẹ jọ máa wà pa pọ̀ láwọn ìgbà míì. Ó sì lè bẹ̀rẹ̀ sí í wu ìwọ náà kó o máa lo àkókò pẹ̀lú wọn, ó ṣe tán ọ̀pọ̀ nǹkan ló pa yín pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jọ ń gba ẹ̀kọ́ pa pọ̀ nínú kíláàsì tàbí níbi tó o ti ń kọ́ṣẹ́. Kódà nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ìwọ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ ń gba ẹ̀kọ́ mọwọ́ ara yín ju àwọn ará lọ. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó o ṣọ́ra. Òótọ́ ni pé àwọn nǹkan kan máa ń pa yín pọ̀ nílè ẹ̀kọ́, àmọ́ fi sọ́kàn pé ohun kan náà kọ́ lẹ gbà gbọ́. Má sì gbàgbé pé bó o bá ṣe ń lo àkókò pẹ̀lú wọn tó, bẹ́ẹ̀ ni ìwà wọn á túbọ̀ máa ràn ẹ́ díẹ̀díẹ̀, tí wàá sì máa ronú bíi tiwọn. (1 Kọ́r. 15:33) Michael tó fi ọdún mẹ́rin kọ́ṣẹ́ mànàmáná gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ó sọ pé, “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni mo máa ń wà pẹ̀lú àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé, wọ́n máa ń sọ ìsọkúsọ, wọ́n máa ń gbọ́ orin tí ò dáa, wọ́n sì máa ń fi ojú àbùkù wo àwọn obìnrin. Kò pẹ́ rárá témi náà ò fi rí ohun tó burú nínú àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe yìí.”
16. Kí ni Òwe 13:20 kọ́ wa?
16 Ka Òwe 13:20. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé tá a bá ń kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́ ó lè kó bá wa. Ó tún sọ pé, “ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.” Ohun tá a kọ́ níbẹ̀ ni pé: Ìwà àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ lè ṣe wá láǹfààní, ó sì lè kó bá wa. Torí náà, àwọn tẹ́ ẹ jọ ń sin Jèhófà tọkàntọkàn, tí wọ́n sì fẹ́ káyé ẹ dáa ni kó o mú lọ́rẹ̀ẹ́.—Sm. 101:6, 7; 119:63.
17. Kí lo lè ṣe kó o má bàa kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́?
17 Ohun tó yẹ kó o ṣe kó o tó bẹ̀rẹ̀ àfikún ẹ̀kọ́. Á dáa kó o pinnu bí àjọṣe ìwọ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ ṣe máa rí. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Trenton sọ pé: “Mo máa ń hùwà tó dáa sáwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ mi, àmọ́ gbogbo àkókò tí mo máa ń lò pẹ̀lú wọn ò kọjá ìgbà tá a bá jọ wà nínú kíláàsì. Mo máa ń fi sọ́kàn pé ọmọ kíláàsì mi ni wọ́n, wọn kì í ṣe ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́.” Kí lo máa ṣe kó o lè rí i pé ẹ ò sún mọ́ ara yín ju bó ṣe yẹ lọ? Ronú nípa ìgbà tó o ṣì wà nílé ẹ̀kọ́ girama, kó o wá bi ara ẹ pé: Ṣé wọléwọ̀de èmí àtàwọn ọmọléèwé mi ò pọ̀ jù nígbà yẹn? Tó o bá rí i pé o ò ṣe dáadáa tó nígbà yẹn, àwọn àtúnṣe wo lo lè ṣe báyìí? Pinnu pé ‘àwọn ọlọ́gbọ́n’ ni wàá máa bá rìn, o ò ní bá àwọn tí ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà rìn.d
18. Àwọn ìbéèrè tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní wo ló yẹ kó o bi ara ẹ? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
18 Máa yẹ ara ẹ wò látìgbàdégbà. Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé wọléwọ̀de èmi àtàwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ mi ò ti máa pọ̀ jù? Ṣé mi ò ti máa ronú, kí n máa sọ̀rọ̀, kí n sì máa hùwà bíi tiwọn? Ṣé inú Jèhófà máa dùn tó bá rí bí èmi àtàwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ mi ṣe ń ṣe wọléwọ̀de?’ (Sm. 1:1) Tó o bá rí i pé ó yẹ kó o ṣe àwọn àtúnṣe kan, má fi falẹ̀ rárá. Rí i pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú ni ọ̀rẹ́ ẹ tímọ́tímọ́. Bákan náà, máa wàásù fáwọn tẹ́ ẹ jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ táyè ẹ̀ bá yọ. Torí pé ẹ jọ máa ń lo àkókò tó pọ̀ nílé ẹ̀kọ́ tẹ́ ẹ sì jọ máa ń sọ̀rọ̀, ìyẹn máa fún ẹ láǹfààní láti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà.
Máa lo àǹfààní tó bá yọ láti wàásù fáwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ ń kọ́ṣẹ́ (Wo ìpínrọ̀ 18)e
MÚRA SÍLẸ̀
19. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o ṣe kó o lè múra sílẹ̀ tó o bá fẹ́ gba àfikún ẹ̀kọ́? Ṣàpèjúwe.
19 Wo àpèjúwe yìí ná, ká sọ pé ẹnì kan fẹ́ rìnrìn àjò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè má mọ gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lójú ọ̀nà, ó yẹ kó di ẹ̀rù ẹ̀ dáadáa, kó wọṣọ tó bójú mu, kó sì mọ ibi tóun ń lọ. Lọ́nà kan náà, bó o ṣe ń kàwé sí i tàbí kọ́ṣẹ́, rí i pé o múra sílẹ̀ dáadáa, kí ìgbàgbọ́ ẹ lágbára, kó o sì “gbé gbogbo ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀.” Bákan náà, fi sọ́kàn pé kì í ṣe torí pé o fẹ́ di ọlọ́rọ̀ tàbí gbayì láwùjọ lo ṣe pinnu láti gba àfikún ẹ̀kọ́, má sì gbàgbé pé torí pé o fẹ́ múnú Jèhófà dùn lo ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó ò ń ṣe.—Éfé. 6:11-13; 1 Kọ́r. 9:26, 27; 10:31.
20. Báwo lo ṣe lè máa dán ara ẹ wò bóyá o ṣì “wà nínú ìgbàgbọ́”?
20 Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.” (2 Kọ́r. 13:5) Ìwọ náà lè ṣe ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ bó o ṣe ń gba àfikún ẹ̀kọ́. Máa fi àwọn ohun tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí yẹ ara ẹ wò látìgbàdégbà. Ṣé ò ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o sún mọ́ Jèhófà? Ṣé ò ń dáàbò bo làákàyè ẹ kó o má bàa máa ronú bí àwọn tí ò mọ Jèhófà? Ṣé ò ń lo àkókò ẹ lọ́nà tó dáa? Ṣé o kì í kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́, ṣé àwọn tó sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lo mú lọ́rẹ̀ẹ́? Ó yẹ kó o bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí, ì báà jẹ́ ilé ẹ̀kọ́ lo wà, ibi tó o ti ń kọ́ṣẹ́, ibi tó o ti ń ṣiṣẹ́, tàbí ò ń ṣe àwọn nǹkan míì. Pinnu pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni wàá máa ṣe níbikíbi tó o bá wà. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó o ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kó o lè múnú ẹ̀ dùn.—Òwe 3:5, 6.
ORIN 87 Ẹ Wá Gba Ìtura
a Kó o lè mọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà, ka àpilẹ̀kọ tó wà lórí jw.org àkòrí ẹ̀ ni: “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Lẹ́yìn Tí Mo Bá Ṣèrìbọmi?—Apá 1: Máa Ṣe Àwọn Ohun Táá Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run.”
b Tó o bá fẹ́ mọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe kó o lè dáàbò bo làákàyè rẹ, ka àpilẹ̀kọ náà “Má Ṣe Jẹ́ Kí ‘Ọgbọ́n Ayé Yìí’ Nípa Lórí Rẹ’” nínú Ilé Ìṣọ́ May 2019.
c Tó o bá fẹ́ mọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe kó o lè máa lo àkókò ẹ lọ́nà tó dáa lójoojúmọ́, ka àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Àkókò Lò?” lórí ìkànnì jw.org.
d Tó o bá fẹ́ mọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe kó o lè yan àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa, ka ẹ̀kọ́ 48, nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! àkòrí ẹ̀ ni “Fọgbọ́n Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ.”
e ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan ń fọgbọ́n wàásù fún ẹni tí wọ́n jọ ń kọ́ṣẹ́ irun ṣíṣe.