ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 May ojú ìwé 14-19
  • Bó O Ṣe Lè Ṣèpinnu Tó Dáa Lórí Ọ̀rọ̀ Àfikún Ẹ̀kọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bó O Ṣe Lè Ṣèpinnu Tó Dáa Lórí Ọ̀rọ̀ Àfikún Ẹ̀kọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ṢÉ Ó YẸ KÓ O GBA ÀFIKÚN Ẹ̀KỌ́?
  • RONÚ LÓRÍ ÌDÍ TÓ O FI FẸ́ KÀWÉ SÍ I
  • RONÚ NÍPA ÀǸFÀÀNÍ TÓ MÁA ṢE É ÀTOHUN TÓ MÁA NÁ Ẹ
  • Àwọn Nǹkan Tí Ò Ní Jẹ́ Kó O Fi Jèhófà Sílẹ̀ Tó O Bá Ń Gba Àfikún Ẹ̀kọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Bíbélì Ha Ṣàìfún Ẹ̀kọ́ Ìwé Níṣìírí Bí?
    Jí!—1998
  • Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́—Lò Ó Láti Yin Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ẹkọ-iwe Pẹlu Ète Kan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 May ojú ìwé 14-19

JULY 20-26, 2026

ORIN 133 Sin Jèhófà Nígbà Ọ̀dọ́

Bó O Ṣe Lè Ṣèpinnu Tó Dáa Lórí Ọ̀rọ̀ Àfikún Ẹ̀kọ́

“Aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.”—ÒWE 14:15.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àwọn nǹkan tó yẹ kó o gbé yẹ̀ wò àtàwọn ìlànà Bíbélì tó o lè fi pinnu bóyá kó o kàwé sí i tàbí kó o má ṣe bẹ́ẹ̀.

1-2. (a) Ìpinnu wo làwọn ọ̀dọ́ máa ṣe? (b) Tá a bá sọ pé ẹnì kan gba “àfikún ẹ̀kọ́,” kí là ń sọ gan-an? (Wo “Àlàyé Ọ̀rọ̀.”)

“IṢẸ́ wo ló wù ẹ́ kó o ṣe tó o bá dàgbà?” Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, ó ṣeé ṣé kí wọ́n ti bi ẹ́ níbèérè yìí lọ́pọ̀ ìgbà. Ó dájú pé ohun tó dáa jù tó o lè fayé ẹ ṣe ni iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì kó o ṣiṣẹ́ kó o lè gbọ́ bùkátà ara ẹ. (2 Tẹs. 3:10) Kò sí àní-àní pé wàá ti máa ronú nípa iṣẹ́ tó o máa fi gbọ́ bùkátà ara ẹ lọ́jọ́ iwájú.

2 Lẹ́yìn táwọn ọ̀dọ́ àtàwọn òbí wọn bá ti jọ sọ̀rọ̀, àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń pinnu pé táwọn bá ti parí ilé ẹ̀kọ́ girama, àwọn máa kàwé sí i káwọn lè ríṣẹ́ lọ́jọ́ iwájú, tàbí kọ́ṣẹ́ ọwọ́ táwọn máa fi ṣiṣẹ́ ṣe. Torí náà, ó ṣeé ṣe kíwọ náà máa wò ó pé á dáa kó o gba àfikún ẹ̀kọ́.a Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o rò kó o to pinnu èyí tó o máa ṣe? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà Bíbélì tó máa jẹ́ kó o lè ṣe ìpinnu tó dáa tó bá dọ̀rọ̀ àfikún ẹ̀kọ́. Ọ̀rọ̀ yìí gbèrò gan-an, ó sì yẹ kó o rò ó dáadáa, ó ṣe tán wọ́n ní èrò lọbẹ̀ gbẹ̀gìrì. Òótọ́ ni pé àwọn ọ̀dọ́ la dìídì kọ àpilẹ̀kọ yìí fún, síbẹ̀ gbogbo àwọn Kristẹni tó ń ronú àtikàwé sí i tàbí kọ́ṣẹ́ ni àpilẹ̀kọ yìí máa ṣe láǹfààní. Kò tán síbẹ̀ o, àwọn ìlànà tá a máa jíròrò á jẹ́ káwọn òbí mọ bí wọ́n ṣe máa tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà.

ṢÉ Ó YẸ KÓ O GBA ÀFIKÚN Ẹ̀KỌ́?

3. Kí ló lè mú káwọn Kristẹni kan pinnu láti kàwé sí i?

3 Láwọn ibì kan, kò pọn dandan kéèyàn kàwé sí i kó tó lè ríṣẹ́ táá fi gbọ́ bùkátà ara ẹ̀. Àmọ́ láwọn ibòmíì, ó lè gba pé kẹ́nì kan kàwé sí i kó tó lè ríṣẹ́ gidi tàbí iṣẹ́ tí ò ní gba àkókò tó pọ̀ jù. Nírú àwọn agbègbè bẹ́ẹ̀, tí Kristẹni kan bá kàwé sí i, ìyẹn lè jẹ́ kó túbọ̀ ráyè iṣẹ́ ìwàásù tàbí kó láǹfààní àtiṣe ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Síbẹ̀, ẹni tó bá fẹ́ kàwé sí i gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ó máa ná òun lówó, ó sì máa gba okun àti àkókò. Yàtọ̀ síyẹn ó ṣeé ṣe kó láwọn ìṣòro kan.

4. Ta ló máa pinnu bí ẹnì kan ṣe máa kàwé tó? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

4 Bíbélì sọ pé, “kálukú ló máa ru ẹrù ara rẹ̀.” (Gál. 6:5.) Torí náà, Kristẹni kọ̀ọ̀kan tó ti tójú bọ́ ló máa pinnu bóyá kóun kàwé sí i tàbí kóun má ṣe bẹ́ẹ̀.b Tó bá sì jẹ́ pé ọmọ kan ṣì kéré, àwọn òbí ẹ̀ ló máa ṣèpinnu nípa ọ̀rọ̀ ilé ìwé ẹ̀. (Éfé. 6:1) Bí òbí kan bá ṣe tọ́ ọmọ ẹ̀ sọ́nà máa jẹ́ kọ́mọ náà lè ṣèpinnu tó dáa nípa bó ṣe yẹ kó kàwé tó nígbà tó bá dàgbà.—Òwe 22:6.

5. Ìgbà wo ló yẹ kẹ́nì kan pinnu bóyá òun máa kàwé sí i, kí sì nìdí? (Tún wo àwòrán.)

5 Lọ́pọ̀ ìgbà, kí ọ̀dọ́ kan tó parí ilé ìwé girama láá ti pinnu bóyá òun máa kàwé sí i. Ohun tó dáa jù ni pé kóun àtàwọn òbí ẹ̀ jọ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ kó tó pinnu ohun tó máa ṣe. Èyí á fún wọn láyè láti gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò dáadáa, kí wọ́n sì ṣèwádìí nípa irú ẹ̀kọ́ tó máa gbà lọ́jọ́ iwájú. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á lè yan irú ẹ̀kọ́ tó máa gbà nílé ìwé báyìí kó lè bá ẹ̀kọ́ tó fẹ́ gbà lọ́jọ́ iwájú mu, táá sì jẹ́ kó lè ríṣẹ́. Ṣé dandan ni kí wọ́n ṣèpinnu yìí kọ́mọ náà tó parí ilé ìwé girama? Kò pọn dandan kó rí bẹ́ẹ̀. (Òwe 21:5) Àwọn ọ̀dọ́ kan ti pinnu pé àwọn máa parí ilé ìwé, àwọn á wáṣẹ́, àwọn á sì ṣe aṣáájú-ọ̀nà kí wọ́n tó pinnu bóyá àwọn máa kàwé sí i. Kódà, kó sìgbà téèyàn ò lè pinnu bóyá kóun kàwé sí i.

Ọ̀dọ́bìnrin kan àtàwọn òbí ẹ̀ jọ ń sọ̀rọ̀ nípa àfikún ẹ̀kọ́ tó fẹ́ gbà. Wọ́n ń wo onírúurú ilé ẹ̀kọ́ tó lè lọ, wọ́n sì ń ṣèwádìí nínú Bíbélì àti fídíò JW.

Àwọn òbí máa ń ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣèpinnu tó dáa lórí ọ̀rọ̀ àfikún ẹ̀kọ́ (Wo ìpínrọ̀ 5)


6. Kí ló máa jẹ́ kẹ́nì kan ṣèpinnu tó dáa tó bá ń ronú bóyá kóun kàwé sí i?

6 Kí ló máa jẹ́ kó o lè ṣèpinnu tó dáa tó o bá ń ronú bóyá kó o kàwé sí i? Ohun kan tó yẹ kó o ṣe ni pé kó o fọ̀rọ̀ náà sádùúrà. (Jém. 1:5) Lẹ́yìn náà, fara balẹ̀ ronú lórí àwọn nǹkan méjì yìí. Àkọ́kọ́, ó yẹ kó o mọ ìdí tó o fi fẹ́ kàwé sí i. (Sm. 26:2) Ìkejì, fara balẹ̀ ronú lórí àǹfààní tí ẹ̀kọ́ tó o yàn máa ṣe ẹ́ àti ohun tó máa ná ẹ. (Òwe 14:15) Ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa àwọn kókó méjèèjì yìí.

RONÚ LÓRÍ ÌDÍ TÓ O FI FẸ́ KÀWÉ SÍ I

7. Kí ló yẹ kí Kristẹni kan fi sọ́kàn tó bá ń ronú pé kóun kàwé sí i?

7 Tó o bá ń ronú pé o fẹ́ kàwé sí i, ó yẹ kó o bi ara ẹ pé, ‘Kí nìdí tí mo fi fẹ́ kàwé sí i?’ Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fẹ́ kàwé sí i torí ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n rí iṣẹ́ tó tẹ́ wọn lọ́rùn, táá sì máa mówó gidi wọlé. Òótọ́ kan ni pé kò sóhun tó burú nínú àwọn nǹkan yìí. (1 Tím. 5:8) Àmọ́, Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ owó gbà wá lọ́kàn tàbí ká máa ronú pé tá a bá ní ohun ìní tó pọ̀ lọkàn wa máa tó balẹ̀. (Òwe 23:4, 5; 1 Tím. 6:8-10; 1 Jòh. 2:17) Tó bá jẹ́ pé torí kó o lè di olówó tàbí kó o lè gbayì láwùjọ lo ṣe fẹ́ kàwé sí i, ìyẹn ò ní jẹ́ kó o láyọ̀. Èyí tó wá burú jù ni pé ó lè mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í jìnnà sí Jèhófà.

8-9. (a) Ojú wo ló yẹ káwa Kristẹni fi wo gbígba àfikún ẹ̀kọ́? (Mátíù 6:33) (b) Kí lo kọ́ nínú ohun tí Josefina, Morine, àti Iris sọ?

8 Ṣé àfikún ẹ̀kọ́ tá a fẹ́ gbà ló yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí wa? Ohun kan ni pé ìjọsìn Jèhófà ló yẹ kó ṣe pàtàkì jù láyé wa. (Mát. 22:37, 38; Fílí. 3:8) Torí náà, máa wo àfikún ẹ̀kọ́ bí ohun táá jẹ́ kó o lè gbọ́ bùkátà ara ẹ bó o ṣe ń gbájú mọ́ ìjọsìn Jèhófà.—Ka Mátíù 6:33.

9 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ran àwọn Kristẹni kan lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó tọ́ lórí ọ̀rọ̀ gbígba àfikún ẹ̀kọ́. Josefina tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Chile sọ pé: “Mo kàwé sí i kí n lè ríṣẹ́ táá jẹ́ kí n túbọ̀ ráyè fún ìjọsìn Jèhófà. Mo rí i dájú pé ìjọsìn Jèhófà lohun tó ṣe pàtàkì jù kì í ṣe ẹ̀kọ́ tí mò ń gbà.” Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Morine lọ fi ọdún kan kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe irun. Kí nìdí? Ó sọ pé: “Ó wù mí kí n lọ sìn níbi tí àìní wà. Ìdí nìyẹn tí mo fi wá ohun tí mo lè ṣe táá jẹ́ kọ́wọ́ mi tẹ àfojúsùn yẹn. Nígbà tí mo kọ́ṣẹ́ tán, mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn èèyàn ṣerun kí n lè kówó jọ láti lọ síbi tí àìní wà. Lẹ́yìn tí mo kó lọ síbẹ̀, iṣẹ́ tí mo kọ́ jẹ́ kí n lè ríṣẹ́ tí mo fi ń gbọ́ bùkátà ara mi.” Iris tóun fi ọdún mélòó kan kẹ́kọ̀ọ́ níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú eyín sọ pé: “Òótọ́ ni pé àǹfààní wà nínú kéèyàn kàwé sí i, àmọ́ òun kọ́ ló ń jẹ́ kéèyàn ní ayọ̀ tòótọ́, kọ́kàn ẹ̀ sì balẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí ò le rárá: Tó o bá fi ti Jèhófà ṣáájú láyé ẹ, ó dájú pé ọkàn ẹ á balẹ̀, wàá sì ní ayọ̀ tòótọ́.” Torí náà, tó bá jẹ́ pé bá a ṣe máa sún mọ́ Jèhófà lohun tó ṣe pàtàkì jù láyé wa, àá ṣe àwọn ìpinnu táá jẹ́ ká máa láyọ̀.

RONÚ NÍPA ÀǸFÀÀNÍ TÓ MÁA ṢE É ÀTOHUN TÓ MÁA NÁ Ẹ

10. Báwo la ṣe lè lo ìlànà tó wà nínú Diutarónómì 32:29 tá a bá fẹ́ ṣèpinnu nípa àfikún ẹ̀kọ́?

10 Ó ṣeé ṣe kó o ní iṣẹ́ kan lọ́kàn tó wù ẹ́ láti kọ́. Àmọ́, ó máa dáa kó o fara balẹ̀ ronú nípa àwọn iṣẹ́ míì tó o lè kọ́. Iṣẹ́ náà lè jọ èyí tó wà lọ́kàn ẹ tàbí kó tiẹ̀ yàtọ̀ pátápátá. (Fi wé Òwe 18:17.) Onírúurú ọ̀nà lèèyàn lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ lónìí, kò sì rí bẹ́ẹ̀ láwọn ìgbà kan. Bí àpẹẹrẹ, èèyàn lè gba àfikún ẹ̀kọ́ látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Bákan náà, wò ó bóyá o lè gbọ́ bùkátà ara ẹ láìjẹ́ pé o kàwé sí i tàbí kọ́ṣẹ́ míì. Bí àpẹẹrẹ, Johanna tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Finland ò gba àfikún ẹ̀kọ́ rárá. Ó sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo jáde ilé ìwé, mo rí iṣẹ́ kan tí ò gba àkókò mi, mo sì ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Oríṣiríṣi iṣẹ́ ni mo ti ṣe, mo sì ti rí bí Jèhófà ṣe ń mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ pé òun á máa pèsè ohun tá a nílò.” Má gbàgbé pé ìpinnu yòówù kó o ṣe nípa àfikún ẹ̀kọ́ àti irú èyí tó o fẹ́ gbà, ó máa ní ibi tó dáa sí àti ibi tó kù sí. Torí náà bi ara ẹ pé: ‘Ṣé wàhálà tí máa ṣe ò ní pọ̀ ju àǹfààní tí màá rí lọ?’ (Ka Diutarónómì 32:29; 1 Kọ́r. 10:23) Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o lè dáhùn ìbéèrè yìí.

11. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká wò ó bóyá àfikún ẹ̀kọ́ tá a fẹ́ gbà máa jẹ́ ká ráyè fáwọn nǹkan pàtàkì míì? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Ṣé ó máa jẹ́ kó o ráyè ṣe àwọn nǹkan pàtàkì míì? Ronú nípa iye wákàtí tí wàá máa lò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti lọ sí kíláàsì tàbí ibi tó o ti ń kọ́ṣẹ́ àtèyí tí wàá fi máa ṣe iṣẹ́ àmúrelé. Ṣé wàá ṣì ráyè fún ìjọsìn Jèhófà àtàwọn ojúṣe tó o ní nínú ìdílé? (Fílí. 1:10) Ṣé ẹ̀kọ́ náà á máa mú kó rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu débi pé, o ò ní lè múra ìpàdé tàbí dá kẹ́kọ̀ọ́? Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jeroz tó ń gbé ní Íńdíà nìyẹn. Ó sọ pé: “Kò rọrùn fún mi láti pọkàn pọ̀ nípàdé, àtilọ sóde ìwàásù sì nira gan-an. Nígbà míì, mi ò kì í ráyè wá sípàdé rárá. Ní báyìí, tí mo bá ń ronú nípa àfikún ẹ̀kọ́ tí mo yàn, mo rí i pé ohun tó ná mi ti pọ̀ jù.” Àmọ́ o, kì í ṣe gbogbo ẹ̀kọ́ ló máa ń gba àkókò tó pọ̀ tóyẹn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan wà tó jẹ́ pé ọjọ́ díẹ̀ lèèyàn á fi lọ lọ́sẹ̀. Àwọn míì kì í sábà fún àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ ní iṣẹ́ àmúrelé. Rabeca tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì gbádùn àfikún ẹ̀kọ́ tó yàn. Ó sọ pé: “Wákàtí méjì péré ni mo fi ń kẹ́kọ̀ọ́ lójúmọ́, ìyẹn sì jẹ́ kí n lè máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà mi lọ.”

Fọ́tò: Arákùnrin ń ronú bóyá òun ṣì máa ráyè fáwọn nǹkan pàtàkì tóun bá lọ kàwé sí i. 1. Ó ń gbé makirofóònù nípàdé. 2. Ó ń wàásù láti ilé dé ilé. 3. Ó ń ṣiṣẹ́ nílé oúnjẹ kan. 4. Ó wà nílé ìwé.

Tó o bá ń ronú àtikàwé sí i, rí i dájú pé o ṣì máa ráyè fáwọn ojúṣe pàtàkì míì tó o ní (Wo ìpínrọ̀ 11)


12. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kó o bi ara ẹ táá jẹ́ kó o lè lo àkókò ẹ̀ lọ́nà tó dáa jù? (Oníwàásù 12:1)

12 Bó ṣe máa pẹ́ tó. Ronú nípa iye oṣù tàbí ọdún tó o máa fi gba ẹ̀kọ́ náà. Tó o bá lọ gba ẹ̀kọ́ yìí, ṣéyẹn máa fi hàn pé ò ń lo àkókò ẹ lọ́nà tó dáa jù? (Éfé. 5:15-17) Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, ṣé ẹ̀kọ́ tó o fẹ́ gbà máa jẹ́ kó o lè fi ìjọsìn Jèhófà ṣáájú láyé ẹ? Bí àpẹẹrẹ, ṣé á jẹ́ kó o lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà? (Ka Oníwàásù 12:1.) Ṣé ibòmíì wà tó o ti lè gba ẹ̀kọ́ yìí tí kò sì ní gbà ẹ́ lákòókò? Bí àpẹẹrẹ, dípò tí wàá fi lọ sí yunifásítì, ṣé o lè lọ kọ́ṣẹ́ lọ́dọ̀ ẹnì kan tàbí kó o lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ṣẹ́ ọwọ́ tí kò ní gbà ẹ́ lákòókò tàbí ná ẹ lówó tó pọ̀? Mario tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Chile sọ pé: “Ọdún méjì péré ni mo lò nílé ìwè tí wọ́n ti ń kọ́ṣẹ́ ọwọ́, iye tí mo ná sì kéré sí ti yunifásítì. Ọjọ́ mẹ́rin láàárín ọ̀sẹ̀ ni mo fi ń lọ sí kíláàsì, èyí sì fún mi láyè láti máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà.”

13. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tẹ́nì kan bá lọ gba àfikún ẹ̀kọ́ níbi tó jìnnà sílé?

13 Ibi tó o ti máa gba ẹ̀kọ́ náà. Ó ṣeé ṣe kí ibi tó o ti fẹ́ gba ẹ̀kọ́ náà má jìnnà sílé. Àmọ́, ká sọ pé ìlú míì lo ti fẹ́ lọ gba ẹ̀kọ́ náà ńkọ́? Tàbí kó jẹ́ pé ibi tí ilé ìwé ṣètò fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni wàá máa gbé? Máa rántí pé tó o bá jìnnà sáwọn mọ̀lẹ́bí ẹ, ó lè mú kó o má sin Jèhófà mọ́, pàápàá tó bá jẹ́ pé àwọn tí kò sin Jèhófà lò ń bá gbé. (Òwe 22:3; 1 Kọ́r. 15:33) Ọdún kan péré ni Matias tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì fi kàwé sí i, ẹ̀kọ́ náà ò sì fi bẹ́ẹ̀ ná an lówó, síbẹ̀ ó kábàámọ̀ ìpinnu tó ṣe. Kí nìdí? Ó sọ pé: “Inú ilé ìwé ni mo gbé ní gbogbo àkókò tí mo fi gba ẹ̀kọ́ náà. Ojoojúmọ́ ni mo máa ń rí àwọn nǹkan tó máa ń jẹ́ kó wù mí láti ṣe nǹkan tí kò dáa. Ìmọ̀ràn mi ni pé tó o bá fẹ́ gba ẹ̀kọ́, lọ gbà á níbi tí kò jìnnà sílé.” Arábìnrin kan tó ń gbé ní Rọ́ṣíà sọ pé: “Dípò kí n máa gbé inú ilé ìwé, ṣe ni mò ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí mi, èyí ni kò jẹ́ kí n kó sínú wàhálà táá mú kí n ṣohun táá dun Jèhófà.” Ṣé o tiẹ̀ mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kó o rí ẹ̀kọ́ tó o lè gbà látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì?

14. Báwo ni ìlànà tó wà nínú Lúùkù 14:28 ṣe lè jẹ́ kó o ṣèpinnu tó dáa lórí irú ẹ̀kọ́ tó o máa gbà?

14 Iye tó máa ná ẹ. Àwọn ilé ẹ̀kọ́ kan wà tówó tí wọ́n máa ń gbà kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ tàbí kó jẹ́ pé ìjọba ló máa sanwó náà. Tó o bá lọ sí àwọn ilé ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀, kò ní ná ẹ lówó jù, wàá sì lè gba ẹ̀kọ́ táá jẹ́ kó o ríṣẹ́. Àmọ́, àwọn ilé ẹ̀kọ́ míì wà tó máa ń náni lówó gan-an. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ìnáwó kan wà téèyàn lè má fọkàn sí tó bá fẹ́ kàwé sí i. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹ̀kọ́ kan wà tó jẹ́ pé èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe ìdánwò kó tó lè gbà á. Ìyẹn lè gba pé kéèyàn sanwó fún ẹni tó máa kọ́ ọ kó lè yege. Àwọn kan ti tọrùn bọ gbèsè tí wọ́n máa fi ọ̀pọ̀ ọdún san, torí pé ẹ̀kọ́ tí wọ́n gbà wọ́n gan-an. Adilson tó ń gbé ní Mòsáńbíìkì kábàámọ̀ ẹ̀kọ́ tó yàn. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn tó wà nínú ìdílé mi febi panú tí wọ́n sì yááfì àwọn nǹkan míì kí wọ́n lè sanwó ẹ̀kọ́ ọlọ́dún mẹ́rin tí mo gbà.” Bó o ṣe ń ronú nípa irú ẹ̀kọ́ tó o fẹ́ gbà, bi ara ẹ pé: ‘Báwo ni ẹ̀kọ́ náà ṣe wọ́n tó? Ṣé èmi tàbí ìdílé mi máa lè san owó ẹ̀? Ṣé ilé ẹ̀kọ́ míì wà tí kò wọ́n tóyẹn?’ (Ka Lúùkù 14:28.) ‘Tí mo bá lọ yáwó, ọdún mélòó ló máa gbà mí kí n tó san án tán? Tí mo bá tiẹ̀ ríṣẹ́, ṣé owó táá máa wọlé á tó gbọ́ bùkátà mi, kí n sì tún máa san gbèsè náà?’—Òwe 22:7.

15. Kí nìdí tó fi yẹ kó o wo iṣẹ́ tó wọ́pọ̀ lágbègbè ẹ kó o tó pinnu irú ẹ̀kọ́ tó o máa gbà?

15 Ṣé wàá lè fi ẹ̀kọ́ náà ríṣẹ́ lọ́jọ́ iwájú? Ronú nípa àwọn iṣẹ́ tó wọ́pọ̀ lágbègbè ẹ tàbí níbi tó ò ń ronú àtimáa gbé. Ṣé ẹ̀kọ́ tó o fẹ́ gbà máa jẹ́ kó o lè ríṣẹ́? Àwọn ilé ẹ̀kọ́ kan wà tó jẹ́ pé ṣe lèèyán kàn máa kàwé títí táá sì máa kó ìmọ̀ jọ, dípò kí wọ́n fi bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ náà hàn án. (Kól. 2:8) Arábìnrin kan tó ń gbé ní Íńdíà sọ pé: “Àwọn nǹkan tí mo kọ́ ò wúlò fún mi nígbà tí mò ń wáṣẹ́. Ìyẹn ò sì jẹ́ kí n ríṣẹ́ tó bá ẹ̀kọ́ náà mu.” Àwọn ẹ̀kọ́ míì sì wà tó jẹ́ pé iṣẹ́ téèyàn lè fi ṣe ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀. Sublime tó ń gbé ní Central African Republic lọ kọ́ bí wọ́n ṣe ń tún ẹ̀rọ amúlétutù ṣe. Ó sọ pé: “Níbi tí mò ń gbé, àwọn èèyàn máa ń tún àwọn nǹkan tó bà jẹ́ ṣe fúnra wọn, ìyẹn sì jẹ́ kó ṣòro fún mi láti ríṣẹ́.”

16. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ronú nípa iṣẹ́ tó o máa fi ẹ̀kọ́ tó o gbà ṣe?

16 Ronú nípa iṣẹ́ tó ṣeé ṣe kó o rí lẹ́yìn tó o bá gba ẹ̀kọ́ náà. Ṣé wàá gbádùn ẹ̀? (Oníw. 3:12, 13) Ibo ni wàá ti máa ṣiṣẹ́, àwọn wo sì ni wàá máa bá ṣiṣẹ́? Tó o bá tiẹ̀ ríṣẹ́, ṣé iṣẹ́ tó máa léwu ni tàbí èyí térò pọ̀ nídìí ẹ̀ tàbí èyí táá mú kó máa rẹ̀ ẹ́? Èló ni wọ́n máa ń san fáwọn tó ń ṣe irú iṣẹ́ náà? Ṣé owó náà máa tó gbọ́ bùkátà ẹ? Ṣé wàá máa kàwé sí i kíṣẹ́ náà má bàa bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́? Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, ṣé á jẹ́ kó o lè fi Ìjọba Ọlọ́run sákọ̀ọ́kọ́ láyé ẹ? (Oníw. 12:13) Òótọ́ ni pé kò yẹ ká máa fiṣẹ́ ṣakọ pàápàá tí kò bá fi bẹ́ẹ̀ síṣẹ́ nígboro. Àmọ́ ká má gbàgbé pé ẹ̀kọ́ tá a bá yàn lè pinnu irú iṣẹ́ tá a máa rí lọ́jọ́ iwájú. Oṣù mẹ́fà ni Tabitha tó ń gbé ní Íńdíà fi kọ́ṣẹ́ télọ̀. Ó sọ pé: “Mo ronú pé tí mo bá ṣiṣẹ́ télọ̀, ìyẹn á jẹ́ kí n lè máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Mo mọ̀ pé kò sígbà tàwọn èèyàn ò ní máa ránṣọ, àti pé iṣẹ́ yẹn máa jẹ́ kí n ráyè fáwọn nǹkan míì, mi ò sì nílò owó rẹpẹtẹ kí n tó bẹ̀rẹ̀.” Iṣẹ́ tí Tabitha kọ́ yìí ló jẹ́ kó lè gbọ́ bùkátà ara ẹ̀ bó ṣe ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.

17. (a)  Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè rí àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó lè ṣèpinnu tó dáa nípa ẹ̀kọ́ tó fẹ́ gbà? (b) Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló máa jẹ́ kó o lè ṣèpinnu tó tọ́? (Wo àpótí náà “Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́.”)

17 Ọ̀pọ̀ nǹkan tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò tá a bá ń ronú àtigba àfikún ẹ̀kọ́ la ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí. Báwo lo ṣe lè rí àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o lè ṣèpinnu tó dáa? Tó o bá fẹ́ túbọ̀ mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ kan, o lè lọ sílé ẹ̀kọ́ náà láti béèrè tàbí kó o wò ó lórí ìkànnì wọn. Wo àwọn iṣẹ́ tó wọ́pọ̀ lágbègbè ẹ kó o lè mọ̀ bóyá ẹ̀kọ́ náà máa wúlò fún ẹ. O tún lè béèrè lọ́wọ́ àwọn tó ti gba irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ tàbí tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́. (Òwe 13:10) Bi wọ́n pé, “Àǹfààní wo ni ẹ̀kọ́ tàbí iṣẹ́ náà ṣe wọ́n, kí ló sì ń ná wọn?” O tún lè bá àwọn tó ń fayọ̀ sin Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. (Òwe 15:22) O lè bi wọ́n pé, ìmọ̀ràn wo ni wọ́n lè fún ẹ nípa ẹ̀kọ́ tó o lè gbà àti iṣẹ́ tó o lè ṣe? Ó ṣeé ṣe kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ tó ò tiẹ̀ ronú kàn.

Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́

  • Kí nìdí tí mo fi fẹ́ kàwé sí i? (Mát. 6:33; 1 Tím. 6:8-10)

  • Wákàtí mélòó ni màá máa lò nílé ìwé tí máa sì máa fi ṣiṣẹ́ àṣetiléwá lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀? (Fílí. 1:10)

  • Ọdún mélòó ló máa gbà kí n tó parí ẹ̀kọ́ náà? (Éfé. 5:15-17)

  • Ibo ni màá máa gbé? (1 Kọ́r. 15:33)

  • Èló ló máa ná mi? (Lúùkù 14:28)

  • Ṣé ẹ̀kọ́ tí mo fẹ́ gbà yìí á jẹ́ kí n ríṣẹ́ tí màá fi gbọ́ bùkátà ara mi, kọ́wọ́ mi sì tẹ àwọn ohun tí mo fẹ́ ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? (Oníw. 12:13)

18. Kí ló yẹ ká máa rántí?

18 Àwọn nǹkan tá a ti kọ́ jẹ́ ká rí i pé àǹfààní wà nínú kéèyàn gba àfikún ẹ̀kọ́, ó sì tún láwọn ìṣòro tiẹ̀. Torí náà, ohun tó dáa jù ni pé kó o kọ́kọ́ gbàdúrà kó o tó ṣèpinnu. Máa rántí pé tó o bá kàwé sí i, ìyẹn lè jẹ́ kó o ríṣẹ́ táá máa mówó wọlé tí wàá fi máa gbọ́ bùkátà ara ẹ, àmọ́ ohun tó lè fún ẹ láyọ̀ tòótọ́ ni pé kó o sún mọ́ Jèhófà. (Sm. 16:9, 11) Bóyá àwọn èèyàn Jèhófà kàwé tàbí wọn ò kàwé, gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń bójú tó wọn. (Héb. 13:5) Àmọ́, ká wá sọ pé o pinnu láti kàwé sí i ńkọ́? Kí làwọn nǹkan tó o lè máa ṣe táá jẹ́ kó o sún mọ́ Jèhófà bó o ṣe ń gba àfikún ẹ̀kọ́? Ohun tá a máa jíròrò nìyẹn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Bó ṣe wà nínú Gálátíà 6:5, kí ló yẹ kẹ́ni tó ń ronú bóyá kóun kàwé sí i fi sọ́kàn?

  • Ojú wo ló yẹ káwa Kristẹni fi wo àfikún ẹ̀kọ́?

  • Àwọn nǹkan wo ló yẹ kí Kristẹni kan gbé yẹ̀ wò kó tó pinnu bóyá kóun kàwé sí i?

ORIN 45 Àṣàrò Ọkàn Mi

a ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e, tá a bá sọ pé ẹnì kan gba “àfikún ẹ̀kọ́,” ohun tá à ń sọ ni ẹ̀kọ́ èyíkéyìí téèyàn bá gbà lẹ́yìn tó bá parí ilé ẹ̀kọ́ girama. Lára ẹ̀ ni kéèyàn lọ kọ́ṣẹ́ ọwọ́, kó lọ yunifásítì tàbí ilé ẹ̀kọ́ gíga míì. Kò tán síbẹ̀ o, lára ẹ̀ tún ni ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn iṣẹ́ ọwọ́ kan, àwọn ilé ẹ̀kọ́ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tàbí àwọn ẹ̀kọ́ míì tó lè gba àkókò díẹ̀ tàbí àkókò gígùn.

b Láwọn ìgbà kan, a gba àwọn ará níyànjú nínú àwọn ìwé wa pé kí wọ́n má lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga. Bí àpẹẹrẹ, àpilẹ̀kọ náà “Ẹ̀yìn Òbí—Báwo Lẹ Ṣe Fẹ́ Kí Ọjọ́ Ọ̀la Àwọn Ọmọ Yín Rí?” tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ October 1, 2005 sọ̀rọ̀ nípa ewu tó wà níbẹ̀ téèyàn bá lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ewu yìí ṣì wà níbẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá kóun lọ tàbí kóun má lọ. Ó yẹ kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan gbàdúrà, kó ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì àtàwọn nǹkan pàtàkì míì kó tó ṣèpinnu. Tó bá sì jẹ́ pé Kristẹni náà jẹ́ ọmọ tí ò tíì tójú bọ́, olórí ìdílé ló máa ṣèpinnu yìí. Tí Krístẹni kan bá pinnu pé òun máa kàwé sí i tàbí òun ò ní kàwé sí i, ẹnikẹ́ni títí kan àwọn alàgbà kò gbọ́dọ̀ dá a lẹ́jọ́.—Jém. 4:12.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́