AUGUST 3-9, 2026
ORIN 113 Àlàáfíà Tó Wà Láàárín Wa
Má Ṣe Máa Dá Àwọn Míì Lẹ́bi Tí Wọ́n Bá Ṣèpinnu Tó Wù Wọ́n
“Ẹ má ṣe dá a lẹ́jọ́ nítorí èrò rẹ̀.”—RÓÒMÙ 14:1.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Bá ò ṣe ní máa dá àwọn ará wa lẹ́bi tí wọ́n bá ṣèpinnu tí ò bá wa lára mu.
1-2. Kí nìdí tá a fi máa ń ṣèpinnu tó yàtọ̀ sí tàwọn ará wa?
ṢÉ ẸNÌ kan ti sọ ohun tí ò dáa nípa ẹ rí torí ìpinnu tó o ṣe? Ṣé ìgbà kan wà tíwọ náà ti sọ ohun tí ò dáa nípa arákùnrin tàbí arábìnrin kan torí ìpinnu tó ṣe? Ó ṣeé ṣe kí gbogbo wa dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè yẹn.
2 Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé láwọn ìgbà míì ìpinnu wa máa ń yàtọ̀ sí tàwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. Kí nìdí? Ìdí ni pé gbogbo wa ò rí bákan náà. Bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa máa ń yàtọ̀ síra. Yàtọ̀ síyẹn, àṣà ìbílẹ̀ wa, ilé tí wọ́n ti tọ́ wa dàgbà àtàwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa ló sábà máa ń pinnu bá a ṣe máa ń ronú. Àmọ́ o, kò yẹ ká jẹ́ kí èrò wa tó yàtọ̀ síra bá àjọṣe tó wà láàárín wa jẹ́, a ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kó dá ìyapa sílẹ̀ nínú ìjọ.—Éfé. 4:3.
3. Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣe ìpinnu kan tí ò bá wa lára mu, kí la lè fẹ́ ṣe?
3 Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣe ìpinnu kan tí ò bá wa lára mu, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká yí i lérò pa dà, ká sì rọ̀ ọ́ pé kó tún ìpinnu náà ṣe. Nígbà míì sì rèé, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára wa fáwọn míì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èrò tó dáa ló wà lọ́kàn wa la ṣe fẹ́ gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ká sòótọ́, a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ wá lógún. (Òwe 17:17) Torí náà, a ò fẹ́ kí wọ́n ṣèpinnu tí wọ́n máa pa dà kábàámọ̀ tàbí táá mú kí wọ́n jìnnà sí Jèhófà.
4-5. Kí ló yẹ ká ṣe tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣèpinnu tó yàtọ̀ sóhun táwa máa ṣe?
4 Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣèpinnu kan, tí ìpinnu náà sì rí bákan lára wa, ṣé ó yẹ ká sọ fún un? Ìpinnu tẹ́ni náà ṣe ló máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ó yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá rí i pé ohun tó fẹ́ ṣe yẹn ta ko ohun tí Bíbélì sọ, ó yẹ ká ràn án lọ́wọ́ kó lè tún èrò ẹ̀ ṣe torí pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. (Òwe 27:5, 6) Àmọ́, kí ló yẹ ká ṣe tó bá jẹ́ pé ohun tó fẹ́ ṣe yẹn ò ta ko òfin Ọlọ́run àmọ́ tó kàn jẹ́ pé ó yàtọ̀ sí ohun táwa máa ṣe? Ẹsẹ Bíbélì tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé sọ ohun tó yẹ ká ṣe, ó ní: “Ẹ má ṣe dá a lẹ́jọ́ nítorí èrò rẹ̀.”—Róòmù 14:1.
5 Nígbà míì, ó máa ń ṣòro fún wa láti fara mọ́ ìpinnu táwọn míì bá ṣe. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí kò fi yẹ ká dá àwọn ará wa lẹ́bi tí wọ́n bá ṣèpinnu tí ò bá wa lára mu àtohun tí ò ní jẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa onírúuru ìpinnu táwọn ará lè ṣe tó jẹ́ pé tá ò bá ṣọ́ra a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí wọn.
OHUN TÓ LÈ MÚ KÁ MÁA ṢÀRÍWÍSÍ ÌPINNU TÁWỌN MÍÌ ṢE
6-7. Kí ló lè mú ká ronú pé ìpinnu táwọn ará wa ṣe ò dáa tó? Sọ àpẹẹrẹ kan.
6 Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, torí ibi tí wọ́n ti tọ́ wa dàgbà àtàwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa, a lè máa ronú pé báwa ṣe ń ṣe nǹkan ló yẹ kí gbogbo èèyàn máa ṣe é. Ó lè máa ṣe wá bíi pé bọ́rọ̀ kan ṣe rí lára wa náà ló ṣe yẹ kó rí lára àwọn míì. Àmọ́ kì í fìgbà gbogbo rí bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn àpẹẹrẹ kan. Àpẹẹrẹ àkọ́kọ́: Nígbà tí arákùnrin kan wà ní kékeré, bàbá ẹ̀ máa ń mutí para. Lẹ́yìn tí arákùnrin náà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó lọ síbi àpèjẹ kan, ó sì rí àwọn ará tó ń mu ọtí níbẹ̀. Ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn bí i nínú, ó sì sọ fún wọn pé kò yẹ kí wọ́n máa mutí. Àpẹẹrẹ kejì: Arábìnrin kan ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ nínú àìsàn kan tó le gan-an. Nígbà tó yá, ó gbọ́ pé irú àìsàn náà ń ṣe arábìnrin míì. Torí pé ó fẹ́ ran arábìnrin náà lọ́wọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ ọ́ pé kó gba irú ìtọ́jú tóun gbà. Ó sọ fún un pé kó máa jẹ irú àwọn oúnjẹ kan tàbí kó máa lo oògùn tàbí àwọn àgbo kan. Àpẹẹrẹ kẹta: Ṣọ́ọ̀ṣì ni arákùnrin kan máa ń lọ tẹ́lẹ̀ kó tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Torí ohun tójú ẹ̀ ti rí níbẹ̀, ó pinnu pé òun ò ní ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì mọ́. Àmọ́ inú bí i gan-an nígbà tó gbọ́ pé arákùnrin kan lọ síbi ìsìnkú kan tí wọ́n ṣe nínú ṣọ́ọ̀ṣì.a
7 Ẹ jẹ́ ká tún wo àwọn àpẹẹrẹ míì. Àpẹẹrẹ kẹrin: Lásìkò tí arákùnrin kan kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé kò bójú mu kí ọkùnrin máa dá irùngbọ̀n sí, kí obìnrin sì máa wọ ṣòkòtò lọ sáwọn òde pàtàkì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé arákùnrin yìí mọ àtúnṣe tí ètò Ọlọ́run ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó ṣì máa ń tẹnu mọ́ ọn fáwọn ará pé kò yẹ káwọn arákùnrin máa dá irùngbọ̀n sí tàbí káwọn arábìnrin máa wọ ṣòkòtò tí wọ́n bá ń bọ̀ nípàdé. Àpẹẹrẹ karùn-ún: Alàgbà kan mọ arákùnrin kan tó lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga, tó sì fi Jèhófà sílẹ̀ nígbà tó yá. Nínú ìjọ tí alàgbà yẹn wà, ọ̀dọ́kùnrin kan pinnu pé òun fẹ́ lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga. Ọkàn alàgbà yẹn ò balẹ̀, ó sì gbìyànjú láti yí ọmọ náà àtàwọn òbí ẹ̀ lérò pa dà.
8. (a) Kí ló lè mú kí òbí kan máa ronú pé àwọn òbí míì ò tọ́ ọmọ wọn dáadáa? (b) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ń fojú burúkú wo àwọn ará torí pé a ò fara mọ́ ìpinnu tí wọ́n ṣe?
8 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sáwọn òbí. Àpẹẹrẹ kẹfà: Ká sọ pé o ti ṣiṣẹ́ kára láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ “nínú ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Àmọ́ àwọn òbí kan máa ń gba àwọn ọmọ wọn láyè láti ṣe àwọn ohun kan tíwọ ò fàyè gbà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè gbà káwọn ọmọ wọn ṣeré jáde, kí wọ́n gbá àwọn géèmù tí kò níwà ipá, tàbí kí wọ́n máa lo fóònù nígbà tí wọ́n ṣì kéré. Ìyẹn lè mú kó máa ṣe àwọn ọmọ ẹ bíi pé o ti le koko jù. Wọ́n lè sọ pé: “Kí ló dé tá ò lè ṣe ohun táwọn ọ̀rẹ́ wa ń ṣe?” Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé àwọn òbí náà gbàgbàkugbà fáwọn ọmọ wọn, wọn ò sì tọ́ wọn dáadáa. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, tí Kristẹni kan bá ṣèpinnu kan tó yàtọ̀ sí tiwa, a lè má fara mọ́ ohun tó ṣe tàbí ká máa bínú sí i. Bí àpẹẹrẹ, a lè ronú pé Kristẹni kan ò mowó ná, tàbí pé ó ti máa ń múra jù, tàbí ká má fara mọ́ eré ìnàjú tó ń ṣe. Àmọ́ o, kò yẹ ká máa fojú burúkú wo àwọn ará torí pé a ò fara mọ́ ìpinnu tí wọ́n ṣe. Ìdí ni pé ìyẹn lè dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ.
9. Kí ló yẹ ká máa rántí? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
9 Òótọ́ ni pé ìpinnu tí Kristẹni kọ̀ọ̀kan máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ kan lè yàtọ̀ síra, àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ìpinnu kan dáa ju òmíì lọ. (Róòmù 14:5) Bíbélì gba àwa Kristẹni níyànjú pé tó bá kan àwọn ìlànà Jèhófà, ó yẹ ká “máa ronú níṣọ̀kan,” síbẹ̀ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ìpinnu kan náà làá máa ṣe ní gbogbo ìgbà. (2 Kọ́r. 13:11) Ọ̀rọ̀ yìí dà bí ìgbà táwọn mélòó kan bá fẹ́ rìnrìn àjò lọ síbì kan náà. Lọ́pọ̀ ìgbà, onírúurú ọ̀nà ni wọ́n lè gbà débi tí wọ́n ń lọ, ó ṣe tán, ọ̀nà kan ò wọjà. Ibi tó bá rọ kálukú lọ́rùn ló máa gbà. Lọ́nà kan náà, àwa Kristẹni lè ṣe ìpinnu tó yàtọ̀ síra lórí ọ̀rọ̀ kan, àmọ́ ohun kan náà ló ṣe pàtàkì sí gbogbo wa, ìyẹn ni pé a fẹ́ múnú Jèhófà dùn. Torí náà, a kì í dá àwọn míì lẹ́jọ́ torí ìpinnu tí wọ́n bá ṣe.—Mát. 7:1; 1 Tẹs. 4:11.
Bó ṣe jẹ́ pé àwọn tó fẹ́ rìnrìn àjò lè gba ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ dé ibi tí wọ́n ń lọ, lọ́nà kan náà ìpinnu tàwa Kristẹni máa ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ ara ẹni máa ń yàtọ̀ síra (Wo ìpínrọ̀ 9)
ÌDÍ TÍ KÒ FI YẸ KÁ DÁ ÀWỌN MÍÌ LẸ́BI TÍ WỌ́N BÁ ṢÈPINNU TÓ WÙ WỌ́N
10. Bí Jémíìsì 4:12 ṣe sọ, kí la ò láṣẹ láti ṣe, kí sì nìdí?
10 Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí tí kò fi yẹ ká dá àwọn míì lẹ́bi nígbà tí wọ́n bá ṣe àwọn ìpinnu kan. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára wọn. A ò láṣẹ láti dá àwọn míì lẹ́jọ́ lórí ìpinnu tí wọ́n bá ṣe nípa àwọn ọ̀rọ̀ ara ẹni. (Ka Jémíìsì 4:12.) Jèhófà ni Afúnnilófin àti Onídàájọ́ wa. Òun nìkan ló láṣẹ láti sọ ohun tó yẹ ká ṣe àtohun tí kò yẹ ká ṣe. Ká má gbàgbé pé Jèhófà làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa máa jíhìn fún, kì í ṣe àwa. (Róòmù 14:10) Torí náà, a ò lẹ́tọ̀ọ́ láti dá àwọn míì lẹ́jọ́ tàbí ṣàríwísí ìpinnu tí wọ́n bá ṣe torí pé kò bá wa lára mu.b
11. Kí la lè ṣe kí ìṣọ̀kan lè túbọ̀ wà nínú ìjọ? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
11 Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí gbogbo àwọn èèyàn ẹ̀ wà níṣọ̀kan, kì í ṣe ká rí bákan náà. Jèhófà dá àwọn nǹkan lónírúurú, ìyẹn sì fi hàn pé kò fẹ́ kí gbogbo nǹkan rí bákan náà. Bí àpẹẹrẹ, kò sí ewé méjì tó jọra délẹ̀délẹ̀. Tá a bá sì wo àwa èèyàn, a máa rí i pé kò sí bí ẹni méjì ṣe lè jọra tó, ìyàtọ̀ díẹ̀ ṣì máa wà láàárín wọn, ìwà wọn sì máa yàtọ̀ síra. Jèhófà ò dá wa ká rí bákan náà, kò sì retí pé ká máa ṣe nǹkan lọ́nà kan náà. Àmọ́, ó fẹ́ ká wà níṣọ̀kan. Torí náà, a kì í jẹ́ kí ìyàtọ̀ tó wà láàárín wa dá wàhálà sílẹ̀, dípò bẹ́ẹ̀ a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí àlàáfíà lè wà. Bí ìṣọ̀kan ṣe máa wà nínú ìjọ ló ṣe pàtàkì jù sí wa, kì í ṣe èrò wa àti bí nǹkan ṣe rí lára wa.—Róòmù 14:19.
Jèhófà ò dá wa ká rí bákan náà, àmọ́ ó fẹ́ ká wà níṣọ̀kan (Wo ìpínrọ̀ 11)
OHUN TÓ YẸ KÁ ṢE KÁ MÁ BÀA DÁ ÀWỌN MÍÌ LẸ́BI TÍ WỌ́N BÁ ṢÈPINNU TÓ WÙ WỌ́N
12-13. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rò pé ẹnì kan ti “ṣi ẹsẹ̀ gbé”? (Gálátíà 6:1; tún wo àpótí náà “Tó O Bá Rò Pé Ìpinnu Tẹ́nì Kan Ṣe Ò Dáa.”)
12 Táwọn míì bá ṣe ìpinnu kan lórí ọ̀rọ̀ ara ẹni. Bi ara ẹ pé, ‘Ṣe ẹni náà “ṣi ẹsẹ̀ gbé” ni àbí ohun tó ṣe kàn yàtọ̀ sóhun témi máa ṣe?’ Tó bá sì jẹ́ pé ó ṣi ẹsẹ̀ gbé ni, ìyẹn ni pé ohun tó ṣe ta ko ìlànà Bíbélì, bi ara ẹ pé, ‘Ṣé èmi ló yẹ kí n tọ́ ọ sọ́nà, àbí ẹlòmíì wà tó kúnjú ìwọ̀n jù mí lọ?’ Tó bá jẹ́ pé ìwọ ló yẹ kó o tọ́ ọ sọ́nà, ṣe ló yẹ kó o fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. (Ka Gálátíà 6:1.) Àmọ́, tó o bá ro ọ̀rọ̀ yẹn dáadáa, o lè rí i pé kò ṣi ẹsẹ̀ gbé, ìpinnu ẹ̀ kàn yàtọ̀ sóhun tíwọ máa ṣe ni. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe máa fi ìbéèrè lọ́ ọ nífun, tàbí kó o máa sọ̀rọ̀ bíi pé ìpinnu tó ṣe ò dáa. Gbà pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó bá fẹ́ ṣe, má sì dá a lẹ́jọ́.—Róòmù 14:2-4.
13 Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná: Tíwọ àti ọ̀rẹ́ ẹ kan bá jọ lọ sílé oúnjẹ, ṣé wàá sọ pé dandan ni kó ra irú oúnjẹ tó o rà? Rárá o. Ṣe lo máa gbà kó ra oúnjẹ tó bá wù ú. Ó ṣe tán ohun yòówù kó rà, òun ló máa jẹ ẹ́ kì í ṣe ìwọ. Ó sì dájú pé ohun tíwọ náà máa fẹ́ kọ́rẹ̀ẹ́ ẹ ṣe fún ẹ nìyẹn, o ò ní fẹ́ kó fi agídí mú ẹ láti ra oúnjẹ tí kò wù ẹ́. Lọ́nà kan náà, tá ò bá fi dandan mú àwọn míì pé kí wọ́n ṣe ohun tá a fẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ara ẹni, ìyẹn á fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún wọn.
14. Tó o bá fẹ́ ṣe ìpinnu ara ẹni, kí lo lè ṣe kí àlàáfíà lè wà nínú ìjọ? (1 Kọ́ríńtì 8:12, 13)
14 Tó o bá fẹ́ ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ ara ẹni. Àlàáfíà máa wà nínú ìjọ tó o bá ń sapá kó o má bàa ṣe ohun táá kọ àwọn míì lóminú. (Ka 1 Kọ́ríńtì 8:12, 13.) Nígbà míì, ìpinnu tó o fẹ́ ṣe lè “bófin mu,” ìyẹn ni pé kò sóhun tó burú níbẹ̀. Àmọ́ tí ìpinnu yẹn bá máa kọ àwọn ará lóminú, ṣé a lè sọ pé ó “ṣàǹfààní”?c (1 Kọ́r. 10:23, 24) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, dípò kó o rin kinkin mọ́ ohun tó wù ẹ́ láti ṣe, ṣé o lè gba tàwọn míì rò? (Róòmù 15:1) Àmọ́, ṣebí a ti sọ pé kò yẹ káwọn míì dá wa lẹ́bi tá a bá ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ ara ẹni? Òótọ́ ni. Ó yẹ kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún wa tá a bá ṣèpinnu, ohun tó sì yẹ káwa náà ṣe nìyẹn. Síbẹ̀, ó yẹ ká fi ìmọ̀ràn tó wà ní Róòmù 12:18 sọ́kàn, tó sọ pé: “Nígbà tó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ló wà, ẹ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn.” Torí náà, a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí àlàáfíà lè wà láàárín àwa àtàwọn ará, á sì máa ń sapá ká má bàa ṣe ohun táá kọ wọ́n lóminú.
15. Kí làwọn alàgbà lè ṣe kí ìṣọ̀kan lè túbọ̀ wà nínú ìjọ? (1 Kọ́ríńtì 4:6)
15 Àwọn alàgbà kì í dá àwọn míì lẹ́bi tí wọ́n bá ṣèpinnu. Táwọn alàgbà ò bá gbé òfin kalẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ara ẹni, tí wọ́n ò sì “ṣe kọjá àwọn ohun tó wà lákọsílẹ̀” nínú Bíbélì, ìyẹn á jẹ́ kí àlàáfíà túbọ̀ wà nínú ìjọ. (Ka 1 Kọ́ríńtì 4:6.) Bákan náà, kó yẹ kí wọ́n ní káwọn ará máa ṣe àwọn nǹkan tí ètò Ọlọ́run ò sọ nínú àwọn ìwé wa. Yàtọ̀ síyẹn, táwọn ará bá ní kí wọ́n ran àwọn lọ́wọ́, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má lọ jẹ́ pé ìrírí wọn ni wọ́n á fi gba àwọn ará nímọ̀ràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló yẹ kí wọ́n máa gbé ìmọ̀ràn wọn kà.—Àìsá. 48:17, 18.
16. Báwo ni alàgbà kan ṣe lè fi hàn pé òun fara mọ́ ìpinnu tí ìgbìmọ̀ alàgbà ṣe?
16 Ó yẹ kí alàgbà kan fara mọ́ ìpinnu èyíkéyìí tí ìgbìmọ̀ alàgbà bá ṣe. Lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ alàgbà bá gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́, tí wọ́n wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lórí ọ̀rọ̀ kan, tí wọ́n wá ṣèpinnu, ó yẹ kí gbogbo àwọn alàgbà fara mọ́ ìpinnu náà, kódà tí ọ̀kan nínú wọn bá ṣì ní èrò tó yàtọ̀ sí tàwọn tó kù. (Éfé. 5:17) Bákan náà, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí wọ́n má ṣe máa fi ìtumọ̀ míì sáwọn ìtọ́ni ètò Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, alàgbà kan ò ní mú gbólóhùn kan nínú àwọn ìwé wa láìwo ohun tí wọ́n ń bá bọ̀ nínú ìwé náà, kó wá fún un ní ìtumọ̀ míì kó lè bá èrò ẹ̀ mu.
17. Àǹfààní wo la máa rí tá ò bá dá àwọn míì lẹ́bi torí ìpinnu tí wọ́n ṣe?
17 Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, gbogbo wa ò rí bákan náà. Kálukú wa ló ní ohun tó wù ú, àti bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára ẹ̀. Kò sì sóhun tó burú níbẹ̀. Torí pé ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la ti wá, tí ìwà wa sì yàtọ̀ síra èyí máa ń jẹ́ kára tù wá láwọn ìpàdé wa. Torí náà, dípò ká jẹ́ kì ìyàtọ̀ tó wà láàárín wa dá wàhálà sílẹ̀, ṣe ló yẹ ká wà níṣọ̀kan. Ó tún yẹ ká máa kíyè sára, ká má lọ ṣe ohun táá bí àwọn míì nínú. Yàtọ̀ síyẹn, kò yẹ ká máa dá àwọn míì lẹ́bi tí wọ́n bá ṣe ìpinnu tó wù wọ́n lórí ọ̀rọ̀ ara ẹni. Tá a bá fi àwọn nǹkan yìí sọ́kàn, Jèhófà máa bù kún wa, gbogbo wa á wà níṣọ̀kan, àá sì máa láyọ̀.—Sm. 133:1; Mát. 5:9.
ORIN 89 Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O sì Gba Ìbùkún
a Ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ kí Kristẹni kan ronú lé, kó tó pinnu bóyá òun máa lọ síbi ìsìnkú tàbí ìgbéyàwó tí wọ́n ṣe ní ṣọ́ọ̀ṣì. Ka àpilẹ̀kọ náà “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 2002.
b Nígbà míì, àwọn alàgbà lè ṣèdájọ́ ẹnì kan tó rú òfin Ọlọ́run. Àmọ́, ó yẹ kí wọ́n fi sọ́kàn pé ìlànà Jèhófà ni wọ́n fẹ́ gbé ìdájọ́ náà kà, kì í ṣe èrò wọn tàbí bí nǹkan ṣe rí lára wọn.—Fi wé 2 Kíróníkà 19:6.
c Bí àpẹẹrẹ, ka ẹ̀kọ́ 35 kókó 5 nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!