MAY 25-31, 2026
ORIN 135 Jèhófà Fìfẹ́ Rọ̀ Ọ́ Pé: “Ọmọ Mi, Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n”
Wàá “Ṣàṣeyọrí” Tó O Bá Ní Ìjìnlẹ̀ Òye
“Ẹni tó ń lo ìjìnlẹ̀ òye nínú ọ̀ràn yóò ṣàṣeyọrí.”—ÒWE 16:20.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Tá a bá ń ní sùúrù tá a sì ń ronú jinlẹ̀, ìyẹn ò ní jẹ́ ká ṣìwà hù tá a bá kojú ipò tó le.
1-2. Kí ni ìjìnlẹ̀ òye, àǹfààní wo ló sì lè ṣe wá?
ṢÉ ÌGBÀ kan wà tẹ́nì kan ti yájú sí ẹ rí? Ṣé ẹnì kan ti fẹ̀sùn kàn ẹ́ rí tó sì jẹ́ pé ìwọ kọ́ lo ṣe nǹkan náà? Tàbí ṣé nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ tó bà ẹ́ lẹ́rù gan-an? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ náà á gbà pé kò rọrùn kéèyàn ní sùúrù kó má sì ṣìwà hù táwọn nǹkan tí kò bára dé bá ṣẹlẹ̀. A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà fún wa ní Bíbélì tó jẹ́ ká mọ ànímọ́ tó lè ràn wá lọ́wọ́ táwọn nǹkan tá a mẹ́nu bà yìí tàbí àwọn nǹkan míì bá ṣẹlẹ̀. Ànímọ́ náà ni ìjìnlẹ̀ òye.
2 Ohun tí ìjìnlẹ̀ òye túmọ̀ sí ni pé kéèyàn fara balẹ̀ ronú nípa nǹkan tó ṣẹlẹ̀, wọ́n ṣáà máa ń sọ pé tójú bá fara balẹ̀ dáadáa á rímú. Ìjìnlẹ̀ òye máa ń jẹ́ ká mọ ìdí tí ohun kan fi ṣẹlẹ̀ tàbí tẹ́nì kan fi ṣe nǹkan tó ṣe. Ànímọ́ yìí kì í jẹ́ ká ṣìwà hù. Bí àpẹẹrẹ, ó máa jẹ́ ká ‘ṣọ́ ẹnu wa’ ká sì mọ̀gbà tó yẹ ká “dákẹ́ jẹ́ẹ́.” (Òwe 10:19; Sm. 4:4) Yàtọ̀ síyẹn, kò ní jẹ́ ká bínú jù táwọn èèyàn bá ṣe ohun tó dùn wá, á sì jẹ́ ká gbójú fo àṣìṣe àwọn míì. Ó tún máa jẹ́ ká gba ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún wa, ká sì ṣàtúnṣe. (Òwe 19:20) Tá a bá ní ìjìnlẹ̀ òye, àwọn nǹkan tá a bá ń ṣe á múnú Jèhófà dùn, á jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀, ọ̀rọ̀ wa sì máa tu àwọn míì lára. Táwọn èèyàn bá kàn wá lábùkù tàbí ṣe ohun tó dùn wá, ànímọ́ yìí ò ní jẹ́ ká gbaná jẹ tàbí ká ṣìwà hù. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àpẹẹrẹ mẹ́ta nínú Bíbélì tó jẹ́ ká rí i pé tá a bá ní ìjìnlẹ̀ òye, ìyẹn máa jẹ́ ká nírẹ̀lẹ̀, ká ní sùúrù, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá.
NÍRẸ̀LẸ̀ MÁ ṢE GBÉRA GA
3. Ta ni Náámánì?
3 Tá a bá fẹ́ máa ṣe ohun tó tọ́, ó ṣe pàtàkì ká nírẹ̀lẹ̀. (1 Pét. 5:5) Tá a bá ń fara balẹ̀ ronú ká tó ṣe nǹkan, ìyẹn ò ní jẹ́ ká máa gbéra ga. Kí nìdí? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa Náámánì. Ìlú Síríà tó wà ní àríwá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ló ń gbé. Èèyàn pàtàkì ni, òun sì ni olórí ọmọ ogun Síríà. Àmọ́, adẹ́tẹ̀ ni.—2 Ọba 5:1.
4. Báwo ni Náámánì ṣe fi hàn pé òun láròjinlẹ̀?
4 Ọmọbìnrin Ísírẹ́lì kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ ìyàwó Náámánì sọ fún ọ̀gá ẹ̀ pé, wòlíì kan wà ní Ísírẹ́lì tó lè wo ọkọ ẹ̀ sàn. (2 Ọba 5:2, 3) Náámánì lè ronú pé, ‘Kí ni ọmọ kékeré tó jẹ́ ẹrú, táwọn èèyàn ẹ̀ sì jẹ́ ọ̀tá wa lè sọ táá ṣe mí láǹfààní?’ Àmọ́ Náámánì ò ronú bẹ́ẹ̀, ó láròjinlẹ̀. Dípò kó jẹ́ kí ìgbéraga wọ òun lẹ́wù kó sì kó ọ̀rọ̀ ọmọ náà dànù, ṣe ló fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀, ó sì ṣe ohun tọ́mọ náà sọ. Ó gbàyè lọ́dọ̀ ọba Síríà, ó sì lọ sórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kó lè lọ gba ìwòsàn.—2 Ọba 5:4, 5.
5. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Náámánì nígbà tó dé Ísírẹ́lì?
5 Náámánì gbéra, ó lọ sí ààfin Ọba Jèhórámù ní Ísírẹ́lì kó lè wo ẹ̀tẹ̀ ẹ̀ sàn. Àmọ́ bí Jèhórámù ṣe rí i, ó ronú pé ṣe ni ọba Síríà fẹ́ bá òun fa wàhálà. Nígbà tí wòlíì Èlíṣà gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní kí Jèhórámù sọ fún Náámánì pé kó máa bọ̀ lọ́dọ̀ òun. (2 Ọba 5:6-9) Àmọ́ ohun tí Náámánì rò kọ́ ló ṣẹlẹ̀ nígbà tó débẹ̀. Èlíṣà ò tiẹ̀ yọjú sí Náámánì tàbí kó bá a sọ̀rọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni Èlíṣà rán ìránṣẹ́ ẹ̀ sí Náámánì pé kó sọ ohun tó máa ṣe fún un kó lè rí ìwòsàn.—2 Ọba 5:10.
6. (a) Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí Náámánì fi bínú nígbà tí ìránṣẹ́ Èlíṣà jíṣẹ́ fún un? (b) Báwo làwọn ìránṣẹ́ Náámánì ṣe lo ìjìnlẹ̀ òye, kí sì ni àbájáde ẹ̀? (2 Ọba 5:13, 14)
6 Náámánì kọ́kọ́ fara ya nígbà tí ìránṣẹ́ Èlíṣà jíṣẹ́ fún un. Ó ‘yíjú pa dà, ó sì bínú lọ.’ (2 Ọba 5:11, 12) Ìdí tó fi bínú tó bẹ́ẹ̀ ni pé, ó ṣeé ṣe kó ronú pé ó yẹ kí Èlíṣà pọ́n òun lé ju ìyẹn lọ, ó ṣe tán olórí ọmọ ogun lòun. Bákan náà, ó tún lè rò pé ohun tí Èlíṣà ní kóun ṣe fi hàn pé kò bọ̀wọ̀ fún Síríà orílẹ̀-èdè òun. Èyí ó wù ó jẹ́, Náámánì pinnu pé òun máa pa dà sílé bóun ò tiẹ̀ rí ìwòsàn. Àmọ́ àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ fara balẹ̀ ro ọ̀rọ̀ náà dáadáa, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣe ohun tí Èlíṣà sọ. Náámánì rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀, ó lọ ṣe ohun tí Èlíṣà sọ, ìyẹn ló sì jẹ́ kó rí ìwòsàn!—Ka 2 Àwọn Ọba 5:13, 14.
7. Kí la kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Náámánì? (Òwe 22:4) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
7 Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí? Tá a bá ní ìjìnlẹ̀ òye, a ò ní yára ṣèpinnu torí ohun tá a rí tàbí tá a rò nìkan. Bákan náà, tá a bá láròjinlẹ̀, a ò kàn ní máa ṣe nǹkan torí bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìjìnlẹ̀ òye tá a bá ní máa jẹ́ ká nírẹ̀lẹ̀, ká sì gbà pé kì í ṣe gbogbo nǹkan la mọ̀. Ànímọ́ yìí máa jẹ́ ká gbà káwọn míì ràn wá lọ́wọ́, ká sì máa wojú Jèhófà ká tó ṣe ohunkóhun. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Náámánì kò tíì máa sin Jèhófà, ìjìnlẹ̀ òye tó ní mú kó tẹ́tí sí ọmọbìnrin kékeré kan láti Ísírẹ́lì tó jẹ́ ìránṣẹ́ ìyàwó ẹ̀, ó fetí sáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀, ó sì ṣe ohun tí Èlíṣà aṣojú Jèhófà ní kó ṣe. Náámánì rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀, ìyẹn ló jẹ́ kó ṣèpinnu tó tọ́, ó sì bọ́ lọ́wọ́ àìsàn tó ń ṣe é. Torí náà, ó máa dáa káwa náà máa fara balẹ̀ ro ọ̀rọ̀ síwá sẹ́yìn ká tó ṣe ìpinnu. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ẹnì kan gbà wá nímọ̀ràn látinú Bíbélì, àmọ́ tí ohun tó sọ ò bá wa lára mu, tàbí kó jẹ́ pé ohun tí ètò Ọlọ́run sọ ò fi bẹ́ẹ̀ yé wa. Ohun tá a bá sọ tàbí ṣe máa fi hàn bóyá agbéraga tàbí onírẹ̀lẹ̀ ni wá.—Ka Òwe 22:4.
Bí Náámánì ṣe fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀ tó sì tẹ́tí sáwọn míì, ó yẹ káwa náà máa tẹ́tí sílẹ̀ táwọn míì bá ń fún wa nímọ̀ràn, tí wọ́n bá ń sọ èrò wọn fún wa àti nígbà tí ètò Ọlọ́run bá ní ká ṣe ohun kan (Wo ìpínrọ̀ 7)
ṢE SÙÚRÙ MÁ ṢE BÍNÚ SÓDÌ
8. Àwọn nǹkan wo ló lè mú kó ṣòro fún wa láti ní sùúrù?
8 Ìjìnlẹ̀ òye tá a ní máa jẹ́ ká ṣe sùúrù tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó múnú bí wa gan-an. Ká sòótọ́, ó máa ń dùn wá tẹ́nì kan bá fẹ̀sùn kàn wá tá ò sì ṣe nǹkan náà, tàbí tó sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí wa. (Éfé. 4:26 àti àlàyé ọ̀rọ̀ “Be wrathful” nínú nwtsty-E) Ẹ jẹ́ ká wo bí Dáfídì àti Ábígẹ́lì ṣe fi hàn pé wọ́n láròjinlẹ̀ nígbà tí wọ́n kojú ipò kan tó le gan-an.
9. Báwo ni Nábálì ṣe hùwà sí Dáfídì?
9 Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Dáfídì àtàwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ ń sá fún Sọ́ọ̀lù, tí wọ́n sì ń gbé ní aginjù Páránì. (1 Sám. 25:1) Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, wọ́n dáàbò bo àwọn olùṣọ́ àgùntàn àtàwọn àgùntàn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Nábálì. (1 Sám. 25:15, 16) Lásìkò táwọn ìránṣẹ́ Nábálì ń rẹ́ irun àgùntàn, Dáfídì rán àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ sí Nábálì. Ó ní kí wọn kì i dáadáa kí wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé kó fún àwọn ní ìwọ̀nba oúnjẹ tágbára ẹ̀ bá gbé. (1 Sám. 25:6-8) Àmọ́, Nábálì fárígá kò sì mọyì gbogbo ohun tí Dáfídì àtàwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ ṣe fún un. Ṣe ló kan Dáfídì àtàwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lábùkù, tó sì sọ̀rọ̀ burúkú sí wọn.—1 Sám. 25:10, 11.
10. Kí ni Ábígẹ́lì àti Dáfídì ṣe tó fi hàn pé wọ́n ní ìjìnlẹ̀ òye? (1 Sámúẹ́lì 25:32, 33) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
10 Ká sọ pé ìwọ lóhun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì yẹn ṣẹlẹ̀ sí, kí lo máa ṣe? Ó ṣeé ṣe kínú bí ẹ torí ohun tí Nábálì ṣe yẹn ò dáa rárá. O lè wá rídìí tí Dáfídì fi bínú tó bẹ́ẹ̀ débi pé ó fẹ́ pa Nábálì! (1 Sám. 25:13, 21, 22) Ojú ọ̀nà ibi tó ti fẹ́ lọ pa Nábálì ló wà nígbà tó pàdé Ábígẹ́lì ìyàwó Nábálì, obìnrin ọlọ́gbọ́n yìí sì dá a dúró. Báwo ni Ábígẹ́lì ṣe fi hàn pé òun ní ìjìnlẹ̀ òye? Ó mọ̀ pé èèyàn dáadáa ni Dáfídì àti pé ohun tí ọkọ òun ṣe fún un ló jẹ́ kínú bí i tó bẹ́ẹ̀. Ìyẹn ló jẹ́ kó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kára Dáfídì lè balẹ̀ kó má sì ṣìwà hù. Torí náà, ó gbé ẹ̀bùn wá fún un, ó sì fìrẹ̀lẹ̀ gbà á nímọ̀ràn tó mọ́gbọ́n dání. (1 Sám. 25:18, 23-31) Dáfídì náà fi hàn pé òun láròjinlẹ̀, ó fara balẹ̀ gbọ́ ohun ti Ábígẹ́lì sọ, ó sì rí i pé ohun tóbìnrin náà sọ bá èrò Jèhófà mu. Ohun tí Ábígẹ́lì ṣe yìí ló jẹ́ kí Dáfídì ṣe sùúrù, tí kò sì ṣohun tó máa pa dà kábàámọ̀.—Ka 1 Sámúẹ́lì 25:32, 33.
Nígbà tí Dáfídì àti Ábígẹ́lì kojú ipò kan tó le gan-an, àwọn méjèèjì fi hàn pé àwọn ní ìjìnlẹ̀ òye, ìyẹn ni ò sì jẹ́ kí ẹ̀mí àwọn èèyàn bọ́ (Wo ìpínrọ̀ 10)
11. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ìjìnlẹ̀ òye tẹ́nì kan bá múnú bí wa? (Òwe 19:11)
11 Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí? Tá a bá ní ìjìnlẹ̀ òye nípa ohun tó ṣẹlẹ̀, á jẹ́ ká ṣe sùúrù ká má sì ṣìwà hù, kódà tóhun tẹ́nì náà ṣe bá tiẹ̀ bí wa nínú. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa jẹ́ ká ronú nípa ohun tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ yọ tá a bá bínú sódì. (Ka Òwe 19:11.) Nígbà tí Ábígẹ́lì sọ fún Dáfídì pé ohun tó fẹ́ ṣe yẹn máa dun Jèhófà, Dáfídì tún èrò ẹ̀ pa, ìyẹn ni ò sì jẹ́ kó ṣìṣe. Tẹ́nì kan bá múnú bí ẹ tàbí ṣe ohun tó dùn ẹ́ gan-an, má ṣe jẹ́ kí ìbínú mú kó o ṣìwà hù. (Jém. 1:19) Gbàdúrà sí Jèhófà, kó o sì wáyè ronú nípa ohun tó fẹ́ kó o ṣe sọ́rọ̀ náà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn lè jẹ́ kára tù ẹ́.
12. Báwo làwọn míì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa ronú jinlẹ̀ ká sì máa ṣe sùúrù?
12 Bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí Ábígẹ́lì ran Dáfídì lọ́wọ́ kó lè ronú jinlẹ̀, Jèhófà lè lo àwọn ará wa náà ká lè mọ èrò ẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ kan. Torí náà, tí ohun kan bá ṣẹlẹ̀ tó lè mú kó o bínú sódì, á dáa kó o kọ́kọ́ fọ̀rọ̀ náà lọ Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ tó máa jẹ́ kó o mọ èrò Jèhófà nípa ọ̀rọ̀ náà. (Òwe 12:15; 20:18) Ṣéwọ náà lè ṣe bí Ábígẹ́lì tí ọ̀rẹ́ ẹ kan bá ń bínú torí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i? Ṣé o lè jẹ́ kí ọ̀rẹ́ ẹ mọ èrò Jèhófà nípa ohun tó ṣẹlẹ̀? Ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn sí ẹ tó o bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ṣe sùúrù kí wọ́n sì ronú jinlẹ̀ tóhun tó lè múnú bí wọn bá ṣẹlẹ̀.
GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ MÁ ṢE BẸ̀RÙ
13. Tá a bá ń ronú jinlẹ̀, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká borí ìbẹ̀rù?
13 Nígbà míì, àwọn nǹkan kan máa ń ṣẹlẹ̀ tó lè mú kẹ́rù bà wá gan-an. Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe lágbára tó, ìyẹn máa jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá tí ẹnikẹ́ni bá ń dẹ́rù bà wá tàbí tí ohunkóhun ń bà wá lẹ́rù. (Sm. 27:1) Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ kódà tó bá dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wòlíì Jónà nìyẹn. Ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àmọ́ ẹ̀rù bà á nígbà tí Jèhófà gbéṣẹ́ kan tí ò rọrùn fún un. Torí náà ó yẹ kó ronú jinlẹ̀ nípa iṣẹ́ náà kó lè ṣàṣeyọrí.
14. Kí nìdí tí Jónà ò ṣe fẹ́ jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an?
14 Jèhófà gbéṣẹ́ kan tí ò rọrùn fún Jónà, ó ní kó lọ kéde ìdájọ́ fáwọn ará ìlú Nínéfè. (Jónà 1:1, 2) Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Jèhófà rán, báwo ló ṣe máa rí lára ẹ? Ẹsẹ̀ ni Jónà fi máa rìn láti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lọ sí Nínéfè tó jẹ́ olú ìlú Ásíríà, ìrìn àjò yìí máa tán an lókun ó sì máa gbà á tó oṣù kan gbáko. Àwọn ará Asíríà tí Jónà fẹ́ lọ jíṣẹ́ fún yìí rorò gan-an, wọ́n sì máa ń hùwà ìkà. Kódà Bíbélì pe ìlú Nínéfè ní “Ìlú tó ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.” (Náh. 3:1, 7) Dípò kí Jónà lọ jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an, ṣe ló fẹsẹ̀ fẹ.—Jónà 1:3.
15. Kí ló mú kí Jónà túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? (Jónà 2:6-9)
15 Nígbà tí Jónà ń sá lọ kó má bàa jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an, ohun kan ṣẹlẹ̀ sí i, Jèhófà sì gbà á sílẹ̀ lọ́nà ìyanu. Ìyẹn ló jẹ́ kó rántí bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó. (Jónà 1:15, 17) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kọ́ Jónà lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. Ó rí i pé kò yẹ kóun bẹ̀rù ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀ tóun bá lọ jíṣẹ́ tí Jèhófà rán òun, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló yẹ kóun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa dáàbò bo òun. (Ka Jónà 2:6-9.) Torí náà, nígbà tí Jèhófà fún Jónà láǹfààní láti pa dà lọ ṣe iṣẹ́ náà, kò jáfara, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló lọ. Àwọn ará Nínéfè yí pa dà, Jèhófà ò sì pa wọ́n run.—Jónà 3:5.
16. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ń bẹ̀rù? (Òwe 29:25) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí? Kò yẹ ká jẹ́ kí ohunkóhun mú ká pa ìjọsìn Jèhófà tì, kódà táwọn èèyàn bá tiẹ̀ dẹ́rù bà wá. (Ka Òwe 29:25.) Torí pé Jónà ronú jinlẹ̀, ìyẹn ló jẹ́ kó lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á ran òun lọ́wọ́ dípò kó máa ronú nípa bí iṣẹ́ tí Jèhófà rán an ṣe le tó. Lọ́nà kan náà, dípò ká máa ronú ṣáá nípa ohun tó ń bà wá lẹ́rù, ṣe ló yẹ ká máa ronú nípa àwọn ìgbà tí Jèhófà ti ràn wá lọ́wọ́ tó sì dáàbò bò wá. Bákan náà, a lè ronú jinlẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn ará wa lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n kojú àwọn ipò tó lè mú kí wọ́n bẹ̀rù tàbí bó ṣe jẹ́ kí wọ́n ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ tó gbé fún wọn torí pé wọ́n gbára lé e.a (Héb. 13:6) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa ronú jinlẹ̀ dáadáa, ìyẹn máa fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá àá sì lè jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa fáwọn míì.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jónà kọ́ wa pé tá a bá ní ìjìnlẹ̀ òye, àá lè ṣe ohunkóhun tí Jèhófà bá ní ká ṣe, á sì dá wa lójú pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ kódà tá a bá bára wa ní ipò tí ò rọrùn (Wo ìpínrọ̀ 16)
MÁA WÁ BÓ O ṢE LÈ TÚBỌ̀ NÍ ÌJÌNLẸ̀ ÒYE
17. Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye?
17 Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, tá a bá ní ìjìnlẹ̀ òye, kò ní jẹ́ ká ṣìwà hù tá a bá kojú ipò tó le. Báwo la ṣe lè ní ànímọ́ yìí? Jèhófà ló lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní in. Ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Neh. 9:20; Sm. 32:8) Jèhófà ń fún wa làwọn ìmọ̀ràn táá jẹ́ ká lè ṣèpinnu tó tọ́, ká má sì ṣìwà hù tí ohun kan bá bí wa nínú. (Sm. 119:97-101) Bákan náà, a máa ní ìjìnlẹ̀ òye tá a bá fara balẹ̀ ronú nípa ohun tí Bíbélì sọ, tá a sì bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀. Ànímọ́ yìí lá jẹ́ ká ronú nípa ohun tó mú kẹ́nì kan ṣe ohun tó ṣe, á sì jẹ́ ká ṣe sùúrù kí ohun tá a bá ṣe tàbí sọ lè bá èrò Jèhófà mu.—Òwe 21:11, àlàyé ìsàlẹ̀.
18. Kí lo pinnu pé wàá ṣe?
18 Ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ìjìnlẹ̀ òye, ká sì máa lo ànímọ́ yìí nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. (Sm. 14:2) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀ a ò ní “fi ọ̀nà ìjìnlẹ̀ òye sílẹ̀” láé. (Òwe 21:16) Bákan náà, àá túbọ̀ láròjinlẹ̀, ìyẹn sì máa jẹ́ ká “ṣàṣeyọrí.”
ORIN 42 Àdúrà Ìránṣẹ́ Ọlọ́run
a Bí àpẹẹrẹ, ka ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Georgiy Porchulyan nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Ìtàn Ìgbésí Ayé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà” lórí ìkànnì jw.org àti lórí JW Library®.