ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 March ojú ìwé 14-19
  • Ohun Tá A Lè Ṣe Kí Ohunkóhun Má Bàa Pín Ọkàn Wa Níyà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tá A Lè Ṣe Kí Ohunkóhun Má Bàa Pín Ọkàn Wa Níyà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀWỌN NǸKAN TÓ LÈ PÍN ỌKÀN WA NÍYÀ
  • OHUN TÍ JÉSÙ ṢE KÍ OHUNKÓHUN MÁ BÀA PÍN ỌKÀN Ẹ̀ NÍYÀ
  • OHUN TÁ A LÈ ṢE KÍ OHUNKÓHUN MÁ BÀA PÍN ỌKÀN WA NÍYÀ
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Wá Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Yìí
    Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká 2025-2026—Tí Alábòójútó Àyíká Máa Bá Wa Ṣe
  • Wá Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Yìí
    Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká 2025-2026—Tí Aṣojú Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Máa Bá Wa Ṣe
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 March ojú ìwé 14-19

MAY 18-24, 2026

ORIN 35 Máa Ṣe “Àwọn Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù”

Ohun Tá A Lè Ṣe Kí Ohunkóhun Má Bàa Pín Ọkàn Wa Níyà

“Ẹ máa fi òye mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.”—ÉFÉ. 5:17.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Bá a ṣe lè gbájú mọ́ àwọn nǹkan tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà, láìka àwọn nǹkan tó lè pín ọkàn wa níyà sí.

1-2. Báwo lohun tó ṣe pàtàkì ṣe lè pín ọkàn wa níyà?

ṢÉ O rántí ìgbà kan tí ohun kan ṣẹlẹ̀ sí ẹ, tíyẹn ò sì jẹ́ kó o fọkàn sóhun tó ò ń ṣe? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun kan lò ń ṣe lọ́wọ́ tí nǹkan náà fi ṣẹlẹ̀, ìyẹn sì gba pé kó o pinnu èwo nínú méjèèjì ló ṣe pàtàkì jù tó o máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé bó o ṣe ń wakọ̀ lọ́wọ́ lẹnì kan pè ẹ́ lórí fóònù. Ó ṣeé ṣe kí ìpè náà ṣe pàtàkì, àmọ́ o ò ní gbé e torí kò ní jẹ́ kó o pọkàn pọ̀ bó o ṣe ń wakọ̀. Ìdí ni pé lásìkò yẹn, ọkọ̀ tó ò ń wà ló ṣe pàtàkì jù.

2 Ojoojúmọ́ là ń ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé wa. Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé ìjọsìn Jèhófàa ló ṣe pàtàkì jù. (Mát. 6:33) Bíi ti awakọ̀ tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, àwa èèyàn Jèhófà máa ń yẹra fáwọn nǹkan tó lè pín ọkàn wa níyà bá a ṣe ń rìn lójú ọ̀nà ìyè.—Òwe 4:25; Mát. 6:22.

3. Àwọn nǹkan wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, kí sì nìdí?

3 Kì í wù wá kí ohunkóhun pín ọkàn wa níyà bá a ṣe ń sin Jèhófà. Síbẹ̀, oríṣiríṣi nǹkan ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa tó lè pín ọkàn wa níyà. (Lúùkù 21:34-36) Ká lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa (1) àwọn nǹkan tó lè pín ọkàn wa níyà, (2) àwọn nǹkan tí Jésù ṣe kí ohunkóhun má bàa pín ọkàn ẹ̀ níyà, àti (3) ohun tá a lè ṣe kí ohunkóhun má bàa pín ọkàn wa níyà lónìí.

ÀWỌN NǸKAN TÓ LÈ PÍN ỌKÀN WA NÍYÀ

4-6. Àwọn nǹkan wo ló lè pín ọkàn wa níyà?

4 Gbogbo wa la ní ọ̀pọ̀ nǹkan nígbèésí ayé wa tá à ń bójú tó, àwọn nǹkan náà sì ṣe pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, a lè ní àìsàn kan tó ń bá wa fínra, ó sì lè jẹ́ pé àwọn nǹkan kan wà tó yẹ ká ṣe fáwọn mọ̀lẹ́bí wa tàbí fún ara wa. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, àwọn nǹkan yìí ṣe pàtàkì, ó sì yẹ ká bójú tó wọn. Àmọ́ ṣé àwọn nǹkan yìí lè bẹ̀rẹ̀ sí í pín ọkàn wa níyà? Bẹ́ẹ̀ ni, ó lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá jẹ́ kó gbà wá lọ́kàn débi tá ò fi lókun, tá ò sì ráyè fáwọn nǹkan míì.

5 Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ wa là ń gbé láwọn ibi tí nǹkan ò ti rọrùn. Bí àpẹẹrẹ, rògbòdìyàn òṣèlú, àtijẹ-àtimu tó túbọ̀ ń ṣòro, àjàkálẹ̀ àrùn àti ogun tó ń wáyè lọ́tùn-lósì lè máa kó wa lọ́kàn sókè. (2 Tím. 3:1) Àwọn nǹkan yìí kì í jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀, ó sì lè gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ.

6 Ó ṣeé ṣe ká mọ àwọn kan táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣàkóbá fún, táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà sì ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn gan-an. Ó ṣe tán, Jèhófà ò dá àwa èèyàn pé ká máa jìyà tàbí ká máa ní ẹ̀dùn ọkàn. Abájọ táwọn kan fi máa ń rò pé ìgbésí ayé àwọn ò nítumọ̀ torí ohun tójú wọn ti rí. Ìyẹn ti mú káwọn míì máa fi fàájì àti eré ìnàjú pàrònú rẹ́. Kí la lè ṣe táwa náà bá ní ẹ̀dùn ọkàn torí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tá a lè kọ́ lára Jésù tó máa jẹ́ ká lè yẹra fáwọn nǹkan tó lè pín ọkàn wa níyà bá a ṣe ń sin Jèhófà.

OHUN TÍ JÉSÙ ṢE KÍ OHUNKÓHUN MÁ BÀA PÍN ỌKÀN Ẹ̀ NÍYÀ

7. Kí làwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó pín ọkàn Jésù níyà?

7 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè pín ọkàn Jésù níyà, lára ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ òṣèlú àtàwọn nǹkan míì tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ. Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ aláìní, àwọn míì sì ń ṣàìsàn. (Mát. 14:14; Máàkù 14:7) Àwọn ará Róòmù àtàwọn Júù bíi tiwọn máa ń fojú wọn rí màbo. Nígbà táwọn èèyàn rí i pé Jésù lágbára, ó sì lè ṣiṣẹ́ ìyanu, wọ́n fẹ́ kó di ọba wọn. (Jòh. 6:14, 15) Yàtọ̀ síyẹn, Èṣù náà dájú sọ Jésù nígbà tó dán an wò, ó sọ fún un pé ó lè di alákòóso ayé tó bá kàn tẹrí ba fún òun. (Mát. 4:8, 9) Ìgbà kan tún wà tí àpọ́sítélì Pétérù, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ Jésù sọ fún un pé kó tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́, ó ní: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa.”—Mát. 16:21, 22.

8. Kí làwọn nǹkan tí Jésù ṣe kí ohunkóhun má bàa pín ọkàn ẹ̀ níyà?

8 Kí làwọn nǹkan tí Jésù ṣe kí ohunkóhun má bàa pín ọkàn ẹ̀ níyà? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́ta tó ṣe. Àkọ́kọ́ ni pé, Jésù máa ń ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú. (Jòh. 8:28; 14:9) Ìkejì, ìjọsìn Ọlọ́run ló gbájú mọ́. (Mát. 9:35) Ìkẹta ni pé Jésù mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù. (Jòh. 4:34) Bí àpẹẹrẹ, Jésù ò rò ó lẹ́ẹ̀mejì kó tó kọ àwọn ìdẹwò Sátánì, kò sì gbà nígbà tí Pétérù ní kó ṣàánú ara ẹ̀, torí ó mọ̀ pé ohun tí Pétérù sọ yẹn ò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. (Mát. 4:10; 16:23) Jésù ò jẹ́ kí ohun táwọn èèyàn rò, ohun tí wọ́n sọ tàbí ohun tí wọ́n ṣe dí òun lọ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Òótọ́ ni pé ó ṣeé ṣe káwọn nǹkan tó lè pín ọkàn wa níyà yàtọ̀ sí ti Jésù. Àmọ́ tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù, àá lè borí àwọn nǹkan tó lè fẹ́ pín ọkàn tiwa náà níyà.

OHUN TÁ A LÈ ṢE KÍ OHUNKÓHUN MÁ BÀA PÍN ỌKÀN WA NÍYÀ

9. Báwo la ṣe lè “fi òye mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́”? (Éfésù 5:17)

9 Máa ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú. Tó o bá ń ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú, wàá lè “máa fi òye mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.” (Ka Éfésù 5:17.) Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà, ìyẹn á jẹ́ ká lè fi òye mọ ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́. Kódà tí Bíbélì ò bá sọ ohun tó yẹ ká ṣe láwọn ipò kan, a ṣì lè fi òye mọ ohun tí Jèhófà máa fẹ́ ká ṣe. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń gbìyànjú láti mọ bí Jèhófà ṣe ń ronú, tá a sì ń jẹ́ kíyẹn pinnu ohun tá a máa ṣe.

10. Báwo la ṣe lè mọ bí Jèhófà ṣe ń ronú?

10 Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a sì ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ìyẹn á jẹ́ ká lè mọ bí Jèhófà ṣe ń ronú. (Jer. 45:5) Tá a bá ń ka Bíbélì, a lè bi ara wa láwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí lohun tí mo kà yìí kọ́ mi nípa Jèhófà? Àtúnṣe wo ló yẹ kí n ṣe kí n lè máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó?’ Ó dájú pé ìrònú Jèhófà ga ju tiwa lọ. (Àìsá. 55:9) Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká máa bẹ̀ ẹ́ pé kó kọ́ wa láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Sm. 143:10) Bákan náà, ó yẹ ká máa gbàdúrà pé kó kọ́ wa láti mọ bó ṣe ń ronú, kó sì jẹ́ kí ìrònú wa bá tiẹ̀ mu.—1 Jòh. 5:14.

11. Kí ni Jèhófà ò fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ sí wa?

11 Bá a ṣe ń sapá kí ìrònú wa lè bá ti Jèhófà mu, àá rí i pé ó fẹ́ ká yẹra fáwọn nǹkan tó lè pín ọkàn wa níyà ká lè múra sílẹ̀ de òpin ètò àwọn nǹkan yìí. (Mát. 24:44) Kò fẹ́ kí àníyàn gbà wá lọ́kàn. (Mát. 6:31, 32) Tí ọ̀rọ̀ ìlera wa, ọ̀rọ̀ ìdílé, ọ̀rọ̀ iṣẹ́, ọ̀rọ̀ ilé tàbí àwọn nǹkan míì bá gbà wá lọ́kàn, ó dájú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó fún wa ní ọgbọ́n àti okun nígbà ìṣòro, á ṣe bẹ́ẹ̀.—Sm. 55:22; Òwe 3:5-7.

12. Kí la lè ṣe káwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé má bàa gbà wá lọ́kàn? (Mátíù 5:3)

12 Ìjọsìn Ọlọ́run ni kó o gbájú mọ́. Gbogbo wa la máa ń ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan tí kò dáa tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé, kò sì sóhun tá a lè ṣe sáwọn nǹkan yẹn. Torí náà, káwọn nǹkan yìí má bàa gbà wá lọ́kàn, á dáa ká gbájú mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Tá a bá sún mọ́ Ọlọ́run tá a sì ń wá ìtọ́sọ́nà ẹ̀, a máa láyọ̀, torí pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe nìyẹn. (Ka Mátíù 5:3.) A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká lè túbọ̀ mọ Jèhófà, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí tá a bá láǹfààní láti ṣe. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá múnú Jèhófà dùn torí pé à ń lo àkókò wa lọ́nà tó dáa dípò ká máa ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé.—Òwe 23:15.

13. Báwo la ṣe lè “máa lo àkókò [wa] lọ́nà tó dára jù lọ”?

13 Àwa Kristẹni ti pinnu pé àá “máa lo àkókò [wa] lọ́nà tó dára jù lọ.” (Éfé. 5:15, 16; wo àlàyé ọ̀rọ̀ “making the best use of your time” nínú nwtsty-E.) A mọ̀ pé kì í ṣe bá a ṣe ń lo àkókò wa lórí àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tá à ń ṣe lójoojúmọ́ ni ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń rọ̀ wá pé ká fọgbọ́n lo ìwọ̀nba àkókò tó kù kí Jèhófà tó fòpin sí ayé burúkú yìí. Torí náà, báwo la ṣe lè lo àkókò wa lọ́nà tó dára jù? Tó bá jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wa la fi ń tẹ́tí sí àwọn ìròyìn burúkú tó kúnnú ayé yìí, ọkàn wa lè pínyà, ká rẹ̀wẹ̀sì, ká má sì fi bẹ́ẹ̀ nítara lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà mọ́. Ẹ ò rí i pé ó máa dáa gan-an tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ là ń lò láti gbọ́ tàbí ka ìròyìn! Ìyẹn ò ní jẹ́ kí nǹkan tojú sú wa, àá sì lè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, a lè fi kún ohun tá à ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, irú bíi ká túbọ̀ máa ṣe ìpadàbẹ̀wò. Torí náà, ó ṣe pàtàkì ká máa lo gbogbo àǹfààní tá a bá rí láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ‘kí wọ́n lè rígbàlà, kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.’—1 Tím. 2:4.

14. Tá a bá ní ọ̀pọ̀ nǹkan tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run, àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe wá? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 Tá a bá ní ọ̀pọ̀ nǹkan tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run, kò ní jẹ́ káwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò yìí kó wa lọ́kàn sókè. Bí ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu ṣe túbọ̀ ń ṣòro, tí rògbòdìyàn òṣèlú àti àjàkálẹ̀ àrùn sì ń pọ̀ sí i, ẹ̀rù ò bà wá. Torí àwọn nǹkan yìí jẹ́ àmì tó ń jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló ń ṣẹ. Dípò ká jẹ́ káwọn nǹkan yìí kó jìnnìjìnnì bá wa, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa fòpin sáwọn ìṣòro yìí láìpẹ́. Torí náà, a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ìyẹn sì jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara dà á.—Sm. 16:8; 112:1, 6-8.

Tọkọtaya kan gbé àtẹ ìwé dání, wọ́n ń wo ọ̀ọ́kán, ọkàn wọn sì balẹ̀. Fọ́tò: Àwòrán tó jẹ́ ká rí oríṣiríṣi nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. 1. Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń wọ́de tínú sì ń bí. 2. Àtẹ tó ń fi bí ìdìbò ṣe ń lọ hàn. 3. Àwọn sójà tó wà lójú ogun. 4. Àwọn oògùn òyìnbó. 5. Àtẹ tó ń fi bí ọrọ̀ ajé ilé iṣẹ́ kan ṣe ń dẹnu kọlẹ̀ hàn.

Ìjọsìn Ọlọ́run ló yẹ ká gbájú mọ́ láìka àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé yìí sí (Wo ìpínrọ̀ 14)b


15. Tá a bá ń “ronú jinlẹ̀,” kì nìyẹn máa jẹ́ ká ṣe? (1 Pétérù 4:7)

15 Máa fi ohun tó ṣe pàtàkì jù sọ́kàn. Lóde òní, dípò kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ronú nípa bí òpin ṣe ń sún mọ́lé, bí wọ́n ṣe máa gbádùn ara wọn ni wọ́n kà sí pàtàkì. Òótọ́ ni pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn gbádùn ara ẹ̀, síbẹ̀ ó yẹ ká “máa ronú jinlẹ̀” kí ayé yìí má bàa kéèràn ràn wá. (Ka 1 Pétérù 4:7.) Kí nìyẹn gba pé ká ṣe? Lára ẹ̀ ni pé ká máa ronú dáadáa, ìyẹn á jẹ́ ká lè máa ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu, ká má sì ṣàṣejù torí pé a fẹ́ gbafẹ́ tàbí a fẹ́ gbádùn ara wa. Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ ká tó ṣèpinnu, àá fi hàn pé à ń ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú, a sì mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù.—2 Tím. 1:7.

16. Kí ló gba Jésù lọ́kàn bí ikú ẹ̀ ṣe ń sún mọ́lé?

16 Jésù mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ku díẹ̀ kó kù, nǹkan ò rọrùn fún un rárá. Síbẹ̀ bó ṣe máa jẹ́ olóòótọ́, tó sì máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà ló gbà á lọ́kàn pátápátá. Torí náà, ó gbàdúrà taratara. Àmọ́ dípò káwọn ọmọ ẹ̀yìn wà lójúfò bíi ti Jésù, ṣe ni wọ́n sùn lọ fọnfọn. Torí pé “ẹ̀dùn ọkàn ti mú kó rẹ̀ wọ́n gan-an.”—Lúùkù 22:39-46; Jòh. 19:30.

17. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń lo ìkànnì àjọlò, ọ̀fìn wo lèèyàn lè jìn sí tí ò bá ṣọ́ra? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

17 Bíi tàwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ẹ̀dùn ọkàn lè mú kó rẹ àwa náà nígbà míì. Àwọn nǹkan tó sì ń ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn lè mú ká máa ṣàníyàn. Ọ̀pọ̀ lónìí máa ń lo àkókò tó pọ̀ lórí ìkànnì àjọlò kí wọ́n lè gbọ́kàn kúrò lórí ìṣòro wọn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń kàn sáwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí wọn lórí ìkànnì àjọlò, wọ́n sì ń gbé fọ́tò, fídíò àtàwọn ìròyìn míì sórí ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń gbá onírúurú géèmù lórí ẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ fídíò àti fíìmù tí ò lóǹkà ni wọ́n sì lè wò níbẹ̀. Àwọn nǹkan yìí lè wọ̀ wọ́n lára débi pé ọ̀pọ̀ àkókò àti okun wọn ni wọ́n á máa lò kí wọ́n lè máa wo àwọn nǹkan tuntun tó dé síbẹ̀. Káwa náà má bàa jìn sínú ọ̀fìn yìí, a lè bi ara wa pé, ‘Ṣé àwọn nǹkan tí mò ń ṣe lórí ìkànnì àjọlò máa ń jẹ́ kára tù mí, àbí ó ń dí mi lọ́wọ́ láti ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù?’

Arábìnrin kan fẹ́ ka Bíbélì, àmọ́ ìsọfúnni ń wọ orí fóònù ẹ̀ látorí ìkànnì àjọlò, ìkànnì tí wọ́n ti ń wo fí ìmù àti ìkànnì tí wọ́n ti ń rajà, ìyẹn ò sì jẹ́ kó lè pọkàn pọ̀.

Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ tá a sì ń ṣèpinnu tó tọ́, a ò ní jẹ́ kí ìkànnì àjọlò, eré ìnàjú tàbí bá a ṣe fẹ́ lọ gbafẹ́ pín ọkàn wa níyà (Wo ìpínrọ̀ 17)


18. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ tá a bá fẹ́ pinnu ohun tá a fẹ́ fi ṣeré ìnàjú?

18 Ó tún yẹ ká ronú jinlẹ̀, ká sì ṣèpinnu tó dáa tó bá jẹ́ pé a máa ń wo ètò tẹlifíṣọ̀n àtàwọn fíìmù tó máa ń ní apá tó pọ̀ lórí Íńtánẹ̀ẹ̀tì. Ó sì lè jẹ́ àwọn fídíò kéékèèké orí Íńtánẹ̀ẹ̀tì la máa ń wò, tàbí kó jẹ́ pé géèmù la máa ń gbá. Òótọ́ ni pé a máa ń gbádùn àwọn nǹkan yìí, ó sì lè mára tù wá. Àmọ́ a gbọ́dọ̀ kíyè sára tó bá kan irú eré ìnàjú tá a yàn àti àkókò tá à ń lò nídìí ẹ̀. Àwọn ìkànnì yìí sábà máa ń gbé oríṣiríṣi fídíò wá, ìwà ipá àti ìṣekúṣe sì lè wà nínú àwọn fídíò náà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin kan tó ń gbé nílẹ̀ Éṣíà nìyẹn. Àwọn fídíò kéékèèké tí wọ́n fi ṣe àkópọ̀ fíìmù ló máa ń wò lórí ìkànnì. Àmọ́ nígbà tó yá, ìkànnì náà bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn fídíò míì tó ní ìṣekúṣe wá, ó sì ń wò ó. Bó ṣe di pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í wo fíìmù ìṣekúṣe nìyẹn. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn alàgbà àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ tí wọ́n ràn án lọ́wọ́. Ó yọ ìkànnì náà kúrò lórí fóònù ẹ̀, ó sì dín àkókò tó ń lò lórí fóònù kù. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin yìí jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ tá a bá fẹ́ pinnu ohun tá a fẹ́ fi ṣeré ìnàjú.

19. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé bá a ṣe máa gbafẹ́ ló gbà wá lọ́kàn?

19 Ó tún yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ ká lè ṣèpinnu tó tọ tá a bá fẹ́ lọ gbafẹ́, tàbí tá a bá fẹ́ sinmi. Òótọ́ ni pé ó máa ń dáa gan-an tá a bá wáyè ṣeré jáde torí pé ó máa ń jẹ́ kára tù wá kára wa sì jí pépé. Àmọ́ tó bá jẹ́ bá a ṣe máa gbafẹ́ ló gbà wá lọ́kàn, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàṣejù ká má sì ráyè ṣe àwọn nǹkan pàtàkì. (Fílí. 1:10) Òótọ́ ni pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa pinnu ohun tóun fẹ́ ṣe àti àkókò tóun máa fi ṣe é. Àmọ́, ká tó ṣèpinnu yìí ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé àkókò tí mo fẹ́ lọ fi gbafẹ́ yìí ò pọ̀ jù ṣá? Ṣé ìpinnu tí mo fẹ́ ṣe yìí fi hàn pé àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù ni mo fi ṣáájú? Ṣé ó sì fi hàn pé mò ń múra sílẹ̀ de “òpin ohun gbogbo”?’

20. Àǹfààní wo la máa rí tá ò bá jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn wa níyà?

20 Àǹfààní tó pọ̀ la máa rí tá ò bá jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn wa níyà bá a ṣe ń sin Jèhófà. (Àìsá. 48:17) Lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà, àá lè fara da àwọn ìṣòro wa. Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ò ní kó wa lọ́kàn sókè. A ò sì ní jẹ́ kí eré ìnàjú àti bá a ṣe máa gbafẹ́ gbà wá lọ́kàn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú, àá máa ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan nínú ìjọsìn Ọlọ́run, àá sì máa fi ohun tó ṣe pàtàkì jù sọ́kàn. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ohunkóhun ò ní lè pín ọkàn wa níyà, àá sì “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.”—1 Tím. 6:19.

TÁ Ò BÁ FẸ́ KÍ OHUNKÓHUN PÍN ỌKÀN WA NÍYÀ, KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ . . .

  • máa ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú?

  • máa ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan nínú ìjọsìn Ọlọ́run?

  • máa fi ohun tó ṣe pàtàkì jù sọ́kàn?

ORIN 129 A Ó Máa Fara Dà Á Nìṣó

a ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Lára ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà ni pé a máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a máa ń lọ sípàdé, a máa ń ṣe ìjọsìn ìdílé, a sì ń wàásù. A tún ń jọ́sìn Jèhófà tá a bá ń kọ́ àwọn Ilé Ìpàdé wa tá a sì ń bójú tó o, tá à ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá, tá a yọ̀ǹda ara wa láti ṣiṣẹ́ làwọn àpéjọ wa tàbí tá a lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì.

b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Tọkọtaya kan ò jẹ́ kí àwọn nǹkan tó ń lọ nínú ayé pín ọkàn wọn níyà, kàkà bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n gbájú mọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́