ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 March ojú ìwé 2-7
  • Bá A Ṣe Lè Di Olùkọ́ Tó Já Fáfá Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Di Olùkọ́ Tó Já Fáfá Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ WỌN JẸ Ẹ́ LÓGÚN
  • MÁA LO BÍBÉLÌ TÓ O BÁ Ń KỌ́ WỌN
  • RÀN WỌ́N LỌ́WỌ́ KÍ WỌ́N LÈ MỌ JÈHÓFÀ
  • MÁA ṢE OHUN TÁÁ MÚ KÓ O TÚBỌ̀ JÁ FÁFÁ BÓ O ṢE Ń KỌ́NI
  • Ran Ẹni Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Lọ́wọ́ Kó Lè Sin Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Mọ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Tètè Ran Àwọn Tó Fẹ́ Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 March ojú ìwé 2-7

MAY 4-10, 2026

ORIN 53 À Ń Múra Láti Lọ Wàásù

Bá A Ṣe Lè Di Olùkọ́ Tó Já Fáfá Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù

“Wàásù ọ̀rọ̀ náà . . . pẹ̀lú ọ̀pọ̀ sùúrù àti ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó dáa.”—2 TÍM. 4:2.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Ohun mẹ́ta tá a lè ṣe ká lè túbọ̀ já fáfá tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

1. Kí ló yẹ kí gbogbo wa kọ́, kí sì nìdí? (2 Tímótì 4:2) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

JÉSÙ sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn . . . , ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mát. 28:19, 20) Ohun tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká rí i pé gbogbo àwa Kristẹni ló yẹ ká máa kọ́ni. Òótọ́ ni pé Jèhófà ló ń fa “àwọn olóòótọ́ ọkàn” wá sọ́dọ̀ ara ẹ̀, àwọn áńgẹ́lì náà sì ń darí wa sọ́dọ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. (Ìṣe 13:48; Jòh. 6:44; Ìfi. 14:6) Síbẹ̀, àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiwa. A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Pọ́ọ̀lù àti Bánábà tí wọ́n jẹ́ àpọ́sítélì. Bíbélì sọ pé nígbà tí wọ́n ń wàásù nínú sínágọ́gù tó wà ní Íkóníónì, wọ́n “sọ̀rọ̀ lọ́nà tó mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù àti Gíríìkì di onígbàgbọ́.” (Ìṣe 14:1) Kò sí àní-àní pé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ti kọ́ bá a ṣe ń lo “ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó dáa.” (Ka 2 Tímótì 4:2.) Torí náà, á dáa kí gbogbo àwa Kristẹni náà kọ́ bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀.

Pọ́ọ̀lù ń fi ìdánilójú sọ̀rọ̀ nínú sínágọ́gù, àwọn èèyàn sì ń tẹ́tí sí i. Inú Bánábà ń dùn bó ṣe ń wo Pọ́ọ̀lù.

Tá a bá fẹ́ túbọ̀ já fáfá nínú bá a ṣe ń kọ́ni, á dáa ká kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù àtàwọn míì bíi Pọ́ọ̀lù àti Bánábà tí wọ́n jẹ́ àpọ́sítélì (Wo ìpínrọ̀ 1)


2. Kí ló lè mú káwọn Kristẹni kan rò pé àwọn ò lè mọ̀ọ̀yàn kọ́?

2 Àwọn kan lè máa rò pé àwọn ò lè mọ̀ọ̀yàn kọ́ torí pé àwọn ò fi bẹ́ẹ̀ kàwé tàbí pé àwọn ò lẹ́bùn kíkọ́ni. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọkùnrin kan tó ronú pé àwọn ò mọ ọ̀rọ̀ sọ. (Ẹ́kís. 4:10; Jer. 1:6) Àwọn míì ronú pé àwọn ò mọ̀ọ̀yàn kọ́ torí pé wọn ò lẹ́ni tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọn ò sì láwọn ìrírí amóríyá bíi tàwọn míì. Ohun kan ni pé kì í ṣe gbogbo àwọn tá a bá wàásù fún ló máa gbọ́rọ̀ wa. Àṣeyọrí èyíkéyìí tá a bá sì ṣe kì í ṣe mímọ̀ọ́ṣe wa. Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, Jèhófà àtàwọn áńgẹ́lì ló ń jẹ́ ká rí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Síbẹ̀, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà táá mú kó wù wọ́n láti kẹ́kọ̀ọ́. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun mẹ́ta táá jẹ́ ká túbọ̀ já fáfá tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ WỌN JẸ Ẹ́ LÓGÚN

3. Kí ló mú kí ọ̀rọ̀ Jésù wọ àwọn èèyàn lọ́kàn?

3 Bíbélì sọ pé Jésù “mọ ohun tó wà nínú èèyàn.” (Jòh. 2:25) Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé Jésù mọ báwọn èèyàn ṣe máa ń ronú àtohun tó wà lọ́kàn wọn. Ọ̀rọ̀ Jésù máa ń wọ àwọn èèyàn lọ́kàn torí ó mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro wọn. Ó mọ̀ pé dípò káwọn aṣáájú ẹ̀sìn kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ṣe ni wọ́n fi àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àtàwọn òfin máṣu-mátọ̀ di ẹrù pa wọ́n. (Mát. 9:36; 23:4) Àwọn nǹkan yìí sì wà lára ohun tí Jésù sọ nínú Ìwàásù Orí Òkè. Abájọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ Jésù torí pé àwọn nǹkan tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn ló bá wọn sọ.

4. Báwo la ṣe lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ wá lógún? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

4 A lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn tá a fẹ́ wàásù fún jẹ wá lógún tá a bá gbìyànjú láti mọ ìṣòro tí wọ́n ń bá yí. Nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí, gbogbo èèyàn ló níṣòro tó ń bá fínra, títí kan àwọn tá à ń wàásù fún. Tá a bá ń rántí ọ̀rọ̀ yìí, àá lè máa fi ọ̀rọ̀ wọn ro ara wa wò. Bí àpẹẹrẹ, ohun kan lè ṣẹlẹ̀ lágbègbè wa tó ń kó àwọn èèyàn lọ́kàn sókè. Ọkàn àwọn òbí lè má balẹ̀ torí wọ́n ń ronú nípa nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ wọn nílé ìwé. Ó sì lè jẹ́ ìṣòro àìníṣẹ́ lọ́wọ́ làwọn èèyàn ń bá fínra. Wá ronú nípa bí nǹkan ṣe rí fáwọn èèyàn pàápàá ní ‘àkókò tí nǹkan le gan-an’ yìí, tí wọn ò sì tún mọ̀ nípa àwọn nǹkan rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.—2 Tím. 3:1; Àìsá. 65:13, 14.

Fọ́tò: Arábìnrin kan ń múra láti lọ sóde ìwàásù, ó sì ń ronú nípa bí nǹkan ṣe rí fáwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. 1. Ìyá kan gbé ọmọ ẹ̀ mọ́ra bí ọkùnrin kan tí inú ń bí ṣe ń halẹ̀ mọ́ wọn. 2. Ọ̀dọ́bìnrin kan ń mu sìgá. 3. Dókítà ń sọ fún màmá àgbàlagbà kan pé ìlera wọn ń burú sí i.

Ronú nípa ohun tó ṣeé ṣe káwọn tó ò ń wàásù fún máa bá yí, kó o sì jẹ́ kọ́rọ̀ wọn jẹ ẹ́ lógún (Wo ìpínrọ̀ 4)


5. Tó bá di pé ká kọ́ni, báwo ni Jésù ṣe yàtọ̀ sáwọn Farisí? (Mátíù 11:28-30)

5 Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, àwọn èèyàn náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀ torí bó ṣe máa ń ṣe sí wọn. Àmọ́, ọwọ́ táwọn Farisí fi mú àwọn èèyàn yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Ṣe ni wọ́n máa ń bẹnu àtẹ́ lù wọ́n, wọ́n sì máa ń wò wọ́n bíi pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan. (Mát. 23:13; Jòh. 7:49) Ní ti Jésù, ó máa ń pọ́n àwọn èèyàn lé, ó sì máa ń ṣoore fún wọn. Bíbélì sọ pé “oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn” ni Jésù, ìyẹn sì wà lára ohun tó mú kó di olùkọ́ tó já fáfá. (Ka Mátíù 11:28-30.) Bíi ti Jésù, ó yẹ káwa náà máa pọ́n àwọn èèyàn lé, ká sì máa ṣoore fún wọn.

6. Kí la lè ṣe táwọn èèyàn ò bá fẹ́ gbọ́rọ̀ wa tàbí tí wọ́n tiẹ̀ kanra mọ́ wa?

6 Àwọn kan lè má fẹ́ gbọ́rọ̀ wa tàbí kí wọ́n tiẹ̀ kanra mọ́ wa. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló yẹ ká ṣe? Ohun tó dáa jù ni pé ká má ṣe bínú. Àmọ́ Jésù sọ pé ká má fi mọ síbẹ̀. Ó ní ká ‘máa ṣe rere sí àwọn tó kórìíra wa, ká máa súre fún àwọn tó ń gégùn-ún fún wa,’ kódà ó ní ká ‘máa gbàdúrà fún àwọn tó ń fi ìwọ̀sí lọ̀ wá.’ (Lúùkù 6:27, 28) Ó máa rọrùn fún wa láti ṣe ohun tí Jésù sọ tá a bá rántí pé nǹkan kan ló fà á tí wọn ò fi fẹ́ gbọ́ wa. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, àwọn kan wà tó dìídì kórìíra wa. Àmọ́, àwọn míì ò kórìíra wa, ìṣòro ìdílé tàbí àníyàn ìgbésí ayé ni ò kàn jẹ́ kí wọ́n ráyè tiwa. Ó sì lè jẹ́ pé ìgbà tí ara ń kan ẹnì kan tàbí tára ẹ̀ ò yá la wá sọ́dọ̀ ẹ̀. Èyí ò wù ó jẹ́, ó yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín máa jẹ́ ọ̀rọ̀ onínúure, tí iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bó ṣe yẹ kí ẹ dá ẹnì kọ̀ọ̀kan lóhùn.” (Kól. 4:6) Tá a bá ń fọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ro ara wa wò, tá a sì gbìyànjú láti mọ ohun tó ṣeé ṣe kí wọ́n máa bá yí, ìyẹn ò ní jẹ́ ká bínú sí wọn, àá sì jẹ́ olùkọ́ tó já fáfá.

MÁA LO BÍBÉLÌ TÓ O BÁ Ń KỌ́ WỌN

7. Kí ni Jésù ṣe tó fi hàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló gbára lé tó bá ń kọ́ àwọn èèyàn? (Jòhánù 7:14-16)

7 Tí Jésù bá ń kọ́ àwọn èèyàn kì í gbára lé òye tiẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló fi ń kọ́ wọn, ó sì máa ń rí i pé ọ̀rọ̀ òun ò lójú pọ̀ kó lè yé wọn dáadáa, kí wọ́n sì lè máa rántí. Bíbélì sọ pé tí Jésù bá ń kọ́ àwọn èèyàn, ó máa ń “kọ́ wọn bí ẹni tó ní àṣẹ, kò kọ́ wọn bí àwọn akọ̀wé òfin.” Ìyẹn sì máa ń “yà wọ́n lẹ́nu” gan-an. (Máàkù 1:22; wo àlàyé ọ̀rọ̀ “not as the scribes” nínú nwtsty-E) Nígbà ayé Jésù, táwọn akọ̀wé òfin bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, ọ̀rọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó gbajúmọ̀ ni wọ́n máa ń tọ́ka sí. Àmọ́ Jésù ò ṣe bíi tiwọn, inú Ìwé Mímọ́ ló ti máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù tó sì jẹ́ pé ọ̀run ló ń gbé tẹ́lẹ̀, kò bẹ̀rẹ̀ sí í sọ gbogbo ohun tó ti mọ̀ fáwọn èèyàn kó lè máa fi ṣe fọ́rífọ́rí, kí wọ́n sì lè máa kan sárá sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló fi kọ́ wọn lóhun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe. (Ka Jòhánù 7:14-16.) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù fi lélẹ̀ fáwa ọmọlẹ́yìn ẹ̀!

8. Báwo ni àpọ́sítélì Pétérù ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

8 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run náà ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù máa ń lò tí wọ́n bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Pétérù bá àwọn èèyàn sọ lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì 33 S.K. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pétérù ò kàwé rẹpẹtẹ, ó fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà sọ ṣe ṣẹ sí Jésù lára. (Ìṣe 2:14-37) Kí ni àbájáde ohun tó ṣe yìí? Bíbélì sọ pé: “Àwọn tó fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe ìrìbọmi, ní ọjọ́ yẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn ló dara pọ̀ mọ́ wọn.”—Ìṣe 2:41.

9. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn?

9 Kò sí nǹkan míì tá a lè lò láti dọ́kàn àwọn èèyàn bíi Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Héb. 4:12) Torí náà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló yẹ kí ọ̀rọ̀ wa dá lé tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn. Ká má gbàgbé pé “ọ̀rọ̀ náà,” ìyẹn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la fẹ́ wàásù fáwọn èèyàn kì í ṣe èrò wa. (2 Tím. 4:2) Òwe 2:6 sọ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń fúnni ní ọgbọ́n; ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.” Torí náà, tá a bá ń fi Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn, ṣe ló dà bí ìgbà tá à ń jẹ́ kí Jèhófà bá wọn sọ̀rọ̀. (Mál. 2:7) A fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé, ìmọ̀ràn inú Bíbélì dáa ju ọgbọ́n èèyàn lọ fíìfíì. Ọlọ́run ló fi ẹ̀mí ẹ̀ darí àwọn tó kọ ọ́, ó sì jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe ká lè múnú Ọlọ́run dùn, káyé wa sì ládùn kó lóyin.—2 Tím. 3:16, 17.

10. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ wa mọ̀ pé inú Bíbélì lohun tó ń kọ ti wá?

10 Tó o bá ń múra láti lọ kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́, ronú nípa àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o lè lò táá jẹ́ kí ẹni náà lóye ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ mọ̀ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwòrán àti fídíò máa jẹ́ kí ẹ̀kọ́ kan túbọ̀ yé e, inú Bíbélì gan-an la ti fa àwọn ẹ̀kọ́ náà yọ. Torí náà, ẹ ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó gbé ẹ̀kọ́ náà yọ ní tààràtà, kó o sì ràn án lọ́wọ́ kó lè ronú jinlẹ̀ nípa wọn. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò àwòrán tàbí fídíò kan, rí i dájú pé akẹ́kọ̀ọ́ ẹ mọ ìlànà Bíbélì tí àwòrán tàbí fídíò yẹn ń kọ́ wa. Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé kó o ka ẹsẹ Bíbélì tó pọ̀ tàbí kó o ṣàlàyé rẹpẹtẹ kó o tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ní sùúrù fún un kí ẹsẹ Bíbélì tẹ́ ẹ kà lè yé e dáadáa, kódà tó bá gba pé kẹ́ ẹ tún un kà, kò sóhun tó burú níbẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la fi kọ́ ẹni yẹn kì í ṣe ọ̀rọ̀ inú ìwé, àwòrán tàbí fídíò.—1 Kọ́r. 2:13.

11-12. (a) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní sùúrù fáwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́? (Ìṣe 17:1-4) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.) (b) Báwo la ṣe lè ran àwọn tí ò mọ̀ nípa Bíbélì lọ́wọ́?

11 Tó bá ṣòro fún ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ láti lóye tàbí fara mọ́ ohun tó ń kọ́, rántí pé ṣe ló yẹ ká “wàásù ọ̀rọ̀ náà . . . pẹ̀lú ọ̀pọ̀ sùúrù.” Ohun kan ni pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ máa ń tètè yé àwọn kan ju àwọn míì lọ. Bí àpẹẹrẹ, ó lè gba àkókò díẹ̀ fáwọn kan tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tí ò ṣòro fáwa láti lóye. Àwọn Júù tó wà ní Tẹsalóníkà ò tètè lóye ohun tí Pọ́ọ̀lù ń kọ́ wọn, torí náà léraléra ló pa dà lọ kó lè ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún wọn. Ìgbà yẹn lohun tó ń sọ wá yé àwọn kan lára wọn.—Ka Ìṣe 17:1-4.

12 Ọ̀nà míì tá a lè gbà máa ṣe sùúrù fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa ni pé ká máa bi wọ́n ní ìbéèrè táá jẹ́ kí wọ́n sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, ká sì rí i dájú pé a ò sọ̀rọ̀ jù. Ó yẹ ká fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn kóhun tí wọ́n ń sọ lè yé wa dáadáa. Lẹ́yìn náà, ẹ ka àwọn ẹsẹ Bíbélì táá jẹ́ kí wọ́n mọ èrò Ọlọ́run lórí ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́, kẹ́ ẹ sì jíròrò ẹ̀. Má gbàgbé pé, àwọn kan wà tí wọn ò mọ̀ nípa Bíbélì, tí wọn ò sì mọ ohun tó wà nínú ẹ̀. Ó lè gba pé ká fi Bíbélì tá a tẹ̀ sórí ìwé hàn wọ́n. O lè fi apá “Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” níwájú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun hàn wọ́n, kí wọ́n lè rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó lè ṣe wọ́n láǹfààní ló wà nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, o lè lo ẹsẹ Bíbélì kan tàbí méjì lábẹ́ ìbéèrè 15 kí wọ́n lè rí i pé àwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì lè jẹ́ kọ́kàn èèyàn balẹ̀. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, tó o bá jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹ̀ rí agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní, wàá túbọ̀ di olùkọ́ tó já fáfá.

Arábìnrin tó wà nínú àwòrán lẹ́ẹ̀kan ń kọ́ ọ̀dọ́bìnrin tá a rí tó ń mu sìgá lẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n jókòó síta, arábìnrin náà sì ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí ọ̀dọ́bìnrin náà bó ṣe ń sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀.

Olùkọ́ tó já fáfá máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn èèyàn, kì í sì í sọ̀rọ̀ jù (Wo ìpínrọ̀ 11-12)


RÀN WỌ́N LỌ́WỌ́ KÍ WỌ́N LÈ MỌ JÈHÓFÀ

13. Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, ta ló yẹ ká darí wọn sí? Ṣàpèjúwe.

13 Ohun tá a fẹ́ ni pé káwọn tá à ń wàásù fún mọ Jèhófà kí wọ́n sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Jém. 4:8) Torí náà, a lè fi bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn wé ẹnì kan tó tan iná fún ẹlòmíì tó ń kàwé nínú òkùnkùn. Ìwé tẹ́ni náà ń kà ló máa tanná sí, kì í ṣe ara ẹ̀. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́, Jèhófà la fẹ́ darí ẹ̀ sí kì í ṣe ara wa.

14. Báwo lo ṣe lè ran ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè mọ Jèhófà?

14 Tó o bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́, ràn án lọ́wọ́ kó lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kó sì máa wù ú láti múnú ẹ̀ dùn. (Òwe 27:11) Kì í ṣe pé o kàn fẹ́ kó jáwọ́ nínú àwọn ìwà kan torí kó lè di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe lo fẹ́ ràn án lọ́wọ́ kó lè ṣe àyípadà torí pé ó fẹ́ múnú Jèhófà dùn. Bí àpẹẹrẹ, tí ò bá rọrùn fún un láti jáwọ́ nínú ìwà kan tí ò dáa, o lè bi í láwọn ìbéèrè bíi: “Kí nìdí tí Jèhófà fi kórìíra ìwà yìí? Kí nìdí tí Jèhófà ṣe fẹ́ kó o jáwọ́ nínú ohun kan tó o fẹ́ràn láti máa ṣe? Báwo lohun tí Jèhófà sọ nípa ìwà yìí ṣe fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ?” Bó o bá ṣe ń ran akẹ́kọ̀ọ́ ẹ lọ́wọ́ kó lè máa ronú nípa Jèhófà, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ rí i pé Baba onífẹ̀ẹ́ ni. Ìyẹn á sì jẹ́ kó wù ú láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́.

MÁA ṢE OHUN TÁÁ MÚ KÓ O TÚBỌ̀ JÁ FÁFÁ BÓ O ṢE Ń KỌ́NI

15. Kí lo lè ṣe kó o lè túbọ̀ já fáfá bó o ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́?

15 Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tó o máa ṣe kó o lè túbọ̀ já fáfá bó o ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn nípa ẹ̀. (1 Jòh. 5:14) O lè ṣe ohun táá mú kí Jèhófà dáhùn àdúrà ẹ, tó o bá ń fiyè sáwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá à ń gbà láwọn ìpàdé ìjọ tó o sì ń fi wọ́n sílò. Yàtọ̀ síyẹn, o lè mú àwọn tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa lọ sọ́dọ̀ ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kó o wá ní kí ẹni náà sọ àwọn apá ibi tó o ti lè ṣe dáadáa sí i. Má sì gbàgbé pé, akẹ́kọ̀ọ́ ẹ ò mọ ìwé tẹ́ ẹ fi ń kẹ́kọ̀ọ́ náà dáadáa tó bí ìwọ ṣe mọ̀ ọ́n. Torí náà, gbìyànjú láti mọ bí ohun tẹ́ ẹ fẹ́ kọ́ ṣe máa rí lára ẹ̀. Kó o sì jẹ́ kó mọ̀ pé ìròyìn ayọ̀ lohun tó ń kọ́ nínú Bíbélì. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn lè mú kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ sún mọ́ Jèhófà, kó sì máa láyọ̀.—Sm. 1:1-3.

16. Kí nìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ já fáfá nínú bá a ṣe ń kọ́ni?

16 Ọ̀kan lára ohun tó máa ń múnú wa dùn jù ni pé ká kọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n lè wá mọ Jèhófà. Tá a bá tún wá dé inú ayé tuntun, ọ̀pọ̀ èèyàn la máa kọ́, ìyẹn sì máa múnú wa dùn gan-an. Torí náà, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn tó ò ń wàásù fún jẹ ẹ́ lógún, máa lo Bíbélì tó o bá ń kọ́ wọn, kó o sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ já fáfá bó o ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lọ́rọ̀ Ọlọ́run.

BÁWO LA ṢE LÈ . . .

  • fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn tá à ń wàásù fún jẹ wá lógún?

  • lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a bá ń kọ́ni?

  • ran àwọn tá à ń kọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà?

ORIN 65 Ẹ Tẹ̀ Síwájú!

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́