ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 July ojú ìwé 20-25
  • Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Mọ Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Mọ Jèhófà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • RÀN ÁN LỌ́WỌ́ KÓ LÈ MỌ JÈHÓFÀ DÁADÁA
  • KỌ́ Ọ KÓ LÈ MỌ ẸNI TÍ JÈHÓFÀ JẸ́
  • RÀN ÁN LỌ́WỌ́ KÍ OHUN TÓ TI MỌ̀ NÍPA JÈHÓFÀ LÈ ṢE É LÁǸFÀÀNÍ
  • ÌBÙKÚN TÁWỌN TÓ MỌ JÈHÓFÀ MÁA GBÁDÙN
  • Ran Ẹni Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Lọ́wọ́ Kó Lè Sin Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kejì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kìíní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 July ojú ìwé 20-25

SEPTEMBER 28–OCTOBER 4, 2026

ORIN 79 Kọ́ Wọn Kí Wọ́n Lè Dúró Gbọn-in

Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Mọ Jèhófà

“Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo.”—JÒH. 17:3.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Bó o ṣe lè ran ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kó lè mọ Jèhófà, kó mọ àwọn ànímọ́ ẹ̀, ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí àtohun tí ò nífẹ̀ẹ́ sí.

1. Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tẹ́ni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ń tẹ̀ síwájú?

BÁWO ló ṣe máa ń rí lára ẹ tẹ́ni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá wá sípàdé fúngbà àkọ́kọ́? Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í dáhùn, ó ń sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn èèyàn, nígbà tó sì yá ó pinnu láti ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ó dájú pé tí wọ́n bá gẹṣin nínú wa kò ní kọsẹ̀! Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, Jèhófà ló ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú. Torí náà, òun lọpẹ́ yẹ.—1 Kọ́r. 3:5-9; 3 Jòh. 3, 4.

2. Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe? (1 Tímótì 2:3, 4)

2 Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé “ká gba onírúurú èèyàn là, kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.” (Ka 1 Tímótì 2:3, 4.) Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn mọ òun àtàwọn nǹkan tóun fẹ́ ṣe. (Jer. 9:24) Ìyẹn sì máa gba pé káwọn èèyàn ní ìmọ̀ tó péye. Nígbà tí ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan ń ṣàlàyé ohun tí ọ̀rọ̀ náà “ìmọ̀ tó péye” túmọ̀ sí, ó sọ pé kéèyàn kó ìmọ̀ jọ nìkan ò tó, àmọ́ ó tún yẹ kí ohun téèyàn mọ̀ máa “hàn nínú ìgbésí ayé ẹ̀.” Torí náà, tí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá mọ Jèhófà, ìyẹn máa hàn nínú bó ṣe ń gbé ìgbésí ayé ẹ̀. Á sì tún jẹ́ kó nírètí láti wà láàyè títí láé.—Jòh. 17:3.

3. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Jèhófà ti fún wa láǹfààní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá mọ òun. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ Jèhófà dáadáa? Báwo la ṣe lè kọ́ wọn kí wọ́n lè mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́? Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí ohun tí wọ́n ti mọ̀ nípa Jèhófà lè ṣe wọ́n láǹfààní?

RÀN ÁN LỌ́WỌ́ KÓ LÈ MỌ JÈHÓFÀ DÁADÁA

4. Bí Máàkù 12:30 ṣe sọ, kí ló yẹ kó jẹ wá lógún tá a bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

4 Jésù sọ pé àṣẹ tó tóbi jù ni kéèyàn fi gbogbo ọkàn ẹ̀, ara ẹ̀, èrò ẹ̀ àti okun ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. (Ka Máàkù 12:30.) Kí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ mọ̀ ọ́n dáadáa. Kì í ṣe torí pé ẹni náà fẹ́ràn wa, ó fẹ́ràn àwọn ará, tàbí pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan ló fi yẹ kó ya ara ẹ̀ sí mímọ́. Ìdí tó fi yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Torí náà, ohun tó yẹ kó jẹ wá lógún tá a bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ ni bá a ṣe máa ràn án lọ́wọ́ kó lè mọ Jèhófà kó sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.

5. Tí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí nìyẹn máa jẹ́ kó ṣe?

5 Tá a bá nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan, ó máa yá wa lára láti ṣe ohun tẹ́ni yẹn bá sọ. Torí náà, tí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá mọ Jèhófà dáadáa tó sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, á máa wù ú láti pa àwọn àṣẹ ẹ̀ mọ́. Jésù sọ pé: “Torí kí ayé lè mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ Baba, ohun tí Baba pa láṣẹ fún mi pé kí n ṣe gẹ́lẹ́ ni mò ń ṣe.” (Jòh. 14:31) Lọ́nà kan náà, tẹ́ni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ju ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun míì lọ, ìyẹn á mú kó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà kó sì máa pa àwọn àṣẹ ẹ̀ mọ́.—1 Jòh. 5:3.

6. Tí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá mọ Jèhófà dáadáa, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kó ṣèpinnu tó tọ́? Ṣàpèjúwe.

6 Tí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá mọ Jèhófà dáadáa, ìyẹn á jẹ́ kó lè ṣèpinnu tó tọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí: Ti pé ẹnì kan ń kà nípa bí wọ́n ṣe ń wa mọ́tò tàbí tó ń wo àwọn tó ń wà á kò túmọ̀ sí pé ó ti mọ mọ́tò wà. Ó gbọ́dọ̀ kọ́ bí wọ́n ṣe ń wà á, lẹ́yìn náà á máa wà á látìgbàdégbà. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, á mọ ohun téèyàn lè ṣe tó bá bára ẹ̀ láwọn ipò kan. Bí àpẹẹrẹ, tí súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ bá wà tàbí tí ọ̀nà ò dáa, á mọ ohun tó yẹ kóun ṣe. Á sì tún mọ̀ pé àwọn nǹkan tóun bá ṣe lè mú kí mọ́tò náà lálòpẹ́. Lọ́nà kan náà, kì í ṣe ohun tẹ́nì kan ń kọ́ nínú Bíbélì nìkan lá jẹ́ kó mọ Jèhófà. Tó bá tún rí i pé bóun ṣe ń ṣe àwọn ìpinnu tó bá ìlànà Bíbélì mu layé òun dáa sí i, ìyẹn á jẹ́ kó túbọ̀ mọ Jèhófà dáadáa. Torí náà, bó ṣe ń mọ Jèhófà sí i, tó sì ń rí bí Jèhófà ṣe ń ran òun lọ́wọ́, á jẹ́ kó lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó dáa nígbèésí ayé ẹ̀.

7. Torí pé Jósẹ́fù mọ Jèhófà dáadáa, báwo nìyẹn ṣe jẹ́ kó ṣe ìpinnu tó dáa?

7 Torí pé Jósẹ́fù mọ Jèhófà dáadáa, ó kọ̀ jálẹ̀ nígbà tí ìyàwó Pọ́tífárì ní kó bá òun sùn. Kò sí àní-àní pé àtikékeré ni Jósẹ́fù ti gbọ́ ìtàn Ádámù àti Éfà, ó sì tún mọ ìtàn Ábúráhámù àti Sérà. (Jẹ́n. 2:24; 20:3, 6) Àwọn ìtàn yẹn ti jẹ́ kí Jósẹ́fù mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo ìgbéyàwó, ó sì jẹ́ kó rí i pé àárín tọkọtaya nìkan ni ìbálòpọ̀ gbọ́dọ̀ mọ. Jósẹ́fù ti mọ Jèhófà débi pé ó kọ̀ láti bá ìyàwó Pọ́tífárì sùn. Ó sọ fún obìnrin náà pé: “Ṣé ó wá yẹ kí n hùwà burúkú tó tó báyìí, kí n sì ṣẹ Ọlọ́run?” (Jẹ́n. 39:7-9) Jósẹ́fù ti mọ ohun tó dáa àtohun tí ò dáa lójú Jèhófà, ó sì mọ ohun tó máa ba Ọlọ́run nínú jẹ́. Ohun tí Jósẹ́fù mọ̀ yìí ló jẹ́ kó ṣèpinnu tó dáa. Torí náà, tá a bá ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà, kí wọ́n sì mọ ẹni tó jẹ́ dáadáa, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè máa ṣe àwọn ìpinnu táá múnú Ọlọ́run dùn.

KỌ́ Ọ KÓ LÈ MỌ ẸNI TÍ JÈHÓFÀ JẸ́

8. Báwo lo ṣe lè fi ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! ran ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kó lè mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́?

8 Báwo lo ṣe lè ran ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kó lè mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́? Kí Jóòbù lè mọ Jèhófà dáadáa, Jèhófà bi í ní ìbéèrè tó ju àádọ́ta (50) lọ! (Jóòbù 38:1–41:34) Táwa náà bá fẹ́ kẹ́ni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ mọ Jèhófà dáadáa, á dáa ká máa béèrè ìbéèrè. A dìídì ṣe àwọn ìbéèrè tó wà nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! kó lè ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an. (Wo àpótí náà “Àwọn Ìbéèrè Tá A Lè Fi Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́.”) Torí náà, lo àwọn ìbéèrè yìí láti mú kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ túbọ̀ mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an.

Arábìnrin kan ń fetí sí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ bó ṣe ń dáhùn ìbéèrè kan ní ẹ̀kọ́ 17 nínú ìwé “Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!”

Àwọn Ìbéèrè Tá A Lè Fi Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́

Ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó lè jẹ́ káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ túbọ̀ mọ Jèhófà ló wà nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára wọn:

  • “Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó ń wàásù ìhìn rere?” (ẹ̀kọ́ 21)

  • “Báwo ni ohun tó o mọ̀ nípa Jèhófà àti Jésù ṣe mú kó dá ẹ lójú pé wọ́n máa ṣe ohun tó tọ́ àtohun tó yẹ fún gbogbo èèyàn [ní Amágẹ́dọ́nì]?” (ẹ̀kọ́ 33)

  • “Báwo ló ṣe máa rí lára Jèhófà tó o bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó o sì ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?” (ẹ̀kọ́ 34)

  • “Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Jèhófà tí Kristẹni kan bá fẹ́ ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?” (ẹ̀kọ́ 42)

  • “Báwo ni ọwọ́ tí Jèhófà fi ń mú àwọn tó bá dẹ́ṣẹ̀ ṣe fi hàn pé ó ń fòye báni lò, ó jẹ́ aláàánú, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa?” (ẹ̀kọ́ 57)

9-10. (a) Kí ló máa ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ronú jinlẹ̀ tí wọ́n bá ń ka Bíbélì láyè ara wọn? (Jémíìsì 5:11) (b) Báwo ni ìtàn Bíbélì kan ṣe lè jẹ́ ká mọ ohun tó lè múnú Jèhófà dùn àtohun tó lè bà á nínú jẹ́? Sọ àpẹẹrẹ kan.

9 Àtìgbà tá a bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ la ti máa ń gbà á níyànjú pé kó máa ka Bíbélì lójoojúmọ́.a Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ronú jinlẹ̀ tí wọ́n bá ń ka Bíbélì láyè ara wọn? A lè gbà wọ́n níyànjú pé nígbàkigbà tí wọ́n bá ka ẹsẹ Bíbélì kan, kí wọ́n ronú nípa ìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí ẹsẹ náà wà nínú Ọ̀rọ̀ ẹ̀ àti ohun tí ẹsẹ náà kọ́ wa nípa Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jémíìsì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń sọ ohun tó kọ́ nínú ìtàn Jóòbù, kì í ṣe ìfaradà Jóòbù nìkan ló mẹ́nu kàn, ó tún mẹ́nu kan àwọn ànímọ́ Jèhófà bí ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti àánú.—Ka Jémíìsì 5:11.

10 A lè ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè fòye mọ ohun tí ìtàn kan nínú Bíbélì kọ́ wa nípa ohun tó lè múnú Jèhófà dùn àtohun tó lè bà á nínú jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lo àtẹ náà “Máa Ka Bíbélì Lójoojúmọ́” nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! ó wá sọ fún wa pé òun fẹ́ ka ìtàn Dáníẹ́lì nínú ihò kìnnìún. A lè gbà á níyànjú pé kó ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí nìdí tí Jèhófà fi gba Dáníẹ́lì sílẹ̀? Báwo ni ìtàn yìí ṣe lè jẹ́ kí n mọ ohun tí máa ṣe táá múnú Jèhófà dùn?’ (Dán. 6:10, 22) Ó tún lè bi ara ẹ̀ pé: ‘Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn ọkùnrin tó fẹ̀sùn kan Dáníẹ́lì? Kí lèyí jẹ́ kí n mọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà kórìíra?’ (Dán. 6:4, 5, 24) Paríparí ẹ̀, a lè sọ fún un pé kó ronú nípa àwọn nǹkan míì tí ìtàn yẹn kọ́ ọ nípa Jèhófà.—Dán. 6:26, 27.

11. Báwo la ṣe lè jẹ́ kẹ́ni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ pé Jèhófà gan-an lẹni tó ń kọ́ ọ?

11 Inú wa máa ń dùn gan-an tí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá mọyì bí ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe ń tún ayé òun ṣe. Àmọ́, ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ pé Jèhófà Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá ló ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. (Àìsá. 30:20, 21) Ẹni náà lè fẹ́ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ wa nítorí ohun tó ń kọ́ tàbí kó tiẹ̀ máa yìn wá pé a mọ̀ọ̀yàn kọ́. Òótọ́ ni pé kò sóhun tó burú tó bá dúpẹ́ lọ́wọ́ wa, àmọ́ a gbọ́dọ̀ jẹ́ kó mọ̀ pé Jèhófà gan-an ni ìyìn, ògo àti ọpẹ́ tọ́ sí.

RÀN ÁN LỌ́WỌ́ KÍ OHUN TÓ TI MỌ̀ NÍPA JÈHÓFÀ LÈ ṢE É LÁǸFÀÀNÍ

12-13. Báwo ni ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ kan ti mọ̀ nípa Jèhófà ṣe lè ràn án lọ́wọ́ tí ìtàn Bíbélì kan ò bá yé e? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

12 Kí ohun tẹ́nì kan ń kọ́ tó lè ṣe é láǹfààní, ó gbọ́dọ̀ máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ti mọ̀ nípa Jèhófà. Báwo la ṣe lè ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, kọ́ ọ pé kó máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ti mọ̀ nípa Jèhófà tó bá ń ka ìtàn Bíbélì kan tí ò yé e. Bí àpẹẹrẹ, tó bá ń ka ìtàn kan níbi tí Jèhófà ti dá àwọn kan lẹ́jọ́, ó lè má mọ ìdí tí Jèhófà fi pa àwọn kan, tó sì dá àwọn míì sí. Báwo lo ṣe lè ràn án lọ́wọ́?

13 O lè gbà á níyànjú pé kó ronú lórí ohun tó ti mọ̀ nípa Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, báwo ni ẹ̀mí èèyàn ṣe ṣeyebíye tó lójú Jèhófà? (2 Pét. 3:9) Kí ló ná Jèhófà láti gbà wá là bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá? (Éfé. 2:4, 5) Ṣé Jèhófà máa ń fìyà jẹ àwọn tí ò mọwọ́ mẹsẹ̀? Lọ́wọ́ kejì, ṣé ó máa ń jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ láìjìyà? (Ẹ́kís. 34:6, 7) Nígbà míì, ìtàn Bíbélì kan lè má ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ìdí tí Jèhófà fi ṣe ohun tó ṣe. Àmọ́, kò pọn dandan ká mọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ yìí torí pé a mọ Ọlọ́run wa. Ó sì dá wa lójú pé gbogbo ìgbà ló máa ń ṣe ohun tó tọ́.

Fọ́tò: Arábìnrin náà àti akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ ń ṣe àtúnyẹ̀wò ohun tí wọ́n kọ́. 1. Jèhófà wà lórí ìtẹ́ ẹ̀ lọ́run. 2. Ádámù àti Éfà ń wò ó bóyá káwọn jẹ èso tí Ọlọ́run ní kí wọ́n má jẹ. 3. Ẹsẹ̀ kan tẹ orí ejò kan fọ́. 4. Ọkọ̀ Nóà léfòó nígbà àkúnya omi. 5. Mósè pín Òkun Pupa sí méjì. 6. Ilé Ráhábù ò wó nígbà tí odi Jẹ́ríkò wó. 7. Ebedi-mélékì fa Jeremáyà jáde nínú kòtò omi. 8. Wọ́n kan Jésù mọ́gi.

Ran akẹ́kọ̀ọ́ ẹ lọ́wọ́ kó lè ronú lórí ohun tó ti mọ̀ nípa Jèhófà tí ẹ̀kọ́ Bíbélì kan ò bá yé e (Wo ìpínrọ̀ 12-13)


14. Báwo lo ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ ẹ lọ́wọ́ tí àárín òun àtẹnì kan nínú ìjọ ò bá gún?

14 Ẹ jẹ́ ká wo ìdí kejì tó fi yẹ kí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ti mọ̀ nípa Jèhófà. Ká sọ pé ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ti ń wá sípàdé, àmọ́ àárín òun àti akéde kan nínú ìjọ ò gún. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé akéde náà ṣe ohun tó dùn ún. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, o lè gba akẹ́kọ̀ọ́ ẹ níyànjú pé kó ronú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Bí àpẹẹrẹ, ó lè bi ara ẹ̀ pé: ‘Kí ló ná Jèhófà kó lè fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn?’ (Jòh. 3:16) ‘Báwo ni ìṣọ̀kan àárín wa ṣe jẹ Jèhófà lógún tó?’ (Sm. 133:1) ‘Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ̀ tó bá rí i pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí ìṣọ̀kan lè túbọ̀ wà láàárín wa?’ (2 Kọ́r. 13:11) Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ mọ̀ pé inú Jèhófà máa ń dùn tó bá jẹ́ pé ibi táwọn ará wa dáa sí là ń wò, dípò ibi tí wọ́n kù sí.

15-16. (a) Tí akẹ́kọ̀ọ́ wa bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì kan, báwo ló ṣe lè fìwà jọ Jésù? (Jòhánù 8:29) (b) Báwo ni Marianne ṣe ran akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Paríparí ẹ̀, ran akẹ́kọ̀ọ́ ẹ lọ́wọ́ kó lè fi ohun tó ti mọ̀ nípa Jèhófà ṣe ìpinnu tó tọ́. O lè ní kó lọ ka ẹ̀kọ́ 35 nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! tí àkòrí ẹ̀ jẹ́, “Bá A Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Dáa.” Àmọ́, ká sọ pé akẹ́kọ̀ọ́ ẹ ti gbàdúrà, ó sì ti ṣèwádìí, síbẹ̀ ó ṣì ṣòro fún un láti ṣe ìpinnu kan, bóyá torí pé àwọn ìlànà Bíbélì tó rí pọ̀, kò sì mọ èyí tó bá ipò ẹ̀ mu. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe? O lè sọ fún un pé kó ronú lórí àpẹẹrẹ Jésù. Kí ni Jésù máa ń rò kó tó ṣèpinnu? Jésù sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń ṣe ohun tó wu Bàbá mi.” (Ka Jòhánù 8:29.) Torí náà, gba akẹ́kọ̀ọ́ ẹ níyànjú pé kó bi ara ẹ̀ pé, ‘Tí mo bá ronú lórí ìwádìí tí mo ṣe àtohun tí mo ti mọ̀ nípa Jèhófà, ìpinnu wo ni màá ṣe táá múnú ẹ̀ dùn?’ Tí ìpinnu tá a bá ṣe bá múnú Jèhófà dùn, á jẹ́ pé ìpinnu tó dáa ni.

16 Ìgbà kan wà tí obìnrin kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórílẹ̀-èdè Chile fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì kan. Àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ ń fúngun mọ́ ọn pé kó gba iṣẹ́ kan táá máa mówó gidi wọlé, àmọ́ iṣẹ́ náà ò ní jẹ́ kó ráyè máa wá sípàdé déédéé. Arábìnrin Marianne tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ sọ pé: “Mo gbà á níyànjú pé kó ronú nípa bí ìpinnu tó bá ṣe ṣe máa rí lára Jèhófà. Ṣé ó máa múnú ẹ̀ dùn àbí ó máa bà á nínú jẹ́? Mo tún gbà á níyànjú pé kó dìídì fọ̀rọ̀ náà sádùúrà, kó sì kíyè sí ọ̀nà tí Jèhófà máa gbà dáhùn àdúrà ẹ̀. Ó kọ̀ láti gba iṣẹ́ náà, kò sì pẹ́ tó fi ríṣẹ́ míì táá jẹ́ kó máa wá sípàdé déédéé.” Ṣé ẹ kíyè sí i pé kàkà kí Marianne sọ ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ máa ṣe, ṣe ló ràn án lọ́wọ́ kó lè ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ti mọ̀ nípa Jèhófà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn mú kí akẹ́kọ̀ọ́ náà túbọ̀ sún mọ́ Marianne, ìyẹn nìkan kọ́ o, ó tún mú kí àárín òun àti Jèhófà túbọ̀ gún régé. Marianne sọ pé: “Akẹ́kọ̀ọ́ mi ti wá rí i pé téèyàn bá fi ìjọsìn Jèhófà ṣáájú láyé ẹ̀, Jèhófà máa bójú tó ẹni náà.”

Ọ̀gá akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan fẹ́ fún un ní fọ́ọ̀mù iṣẹ́ tuntun àti báírò, àmọ́ ó sọ fún ọ̀gá náà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé òun ò ní lè ṣe iṣẹ́ náà.

Ran akẹ́kọ̀ọ́ ẹ lọ́wọ́ kó lè mọ bó ṣe lè máa ṣèpinnu táá múnú Jèhófà dùn (Wo ìpínrọ̀ 15-16)b


ÌBÙKÚN TÁWỌN TÓ MỌ JÈHÓFÀ MÁA GBÁDÙN

17. Yàtọ̀ sáwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì, kí ló tún ṣe pàtàkì káwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa mọ̀?

17 Ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣe pàtàkì làwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa máa ń mọ̀ tá a bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, wọn á mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ibi táwọn òkú wà, ìdí tí Jésù fi kú àtohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á tún mọ bá a ṣe ṣètò ìjọ Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n á mọ bá a ṣe máa ń ṣe àwọn ìpàdé wa, iṣẹ́ àwọn alàgbà, títí kan ojúṣe Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Àmọ́, kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ yìí nìkan la fẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa mọ̀. Ó tún ṣe pàtàkì ká jẹ́ kí wọ́n mọ Jèhófà dáadáa.

18. Àwọn nǹkan wo làwọn tó bá mọ Jèhófà máa gbádùn?

18 A mọyì àǹfààní tá a ní láti máa kọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n lè mọ Jèhófà. Ní báyìí, àwọn tó mọ Jèhófà, tí wọ́n sì ń jọ́sìn ẹ̀ ń gbádùn ìgbésí ayé wọn. (Sm. 25:12-15) Tó bá sì dọjọ́ iwájú, gbogbo àwọn tó “mọ [Jèhófà] ẹni tòótọ́ náà” máa gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun. (1 Jòh. 5:20) Àmọ́ kò tán síbẹ̀ o, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “Ọlọ́run mọ” gbogbo àwọn tó ń sapá kí wọ́n lè mọ̀ ọ́n, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. (1 Kọ́r. 8:3) Inú wa mà dùn o pé Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè mọ̀ wá, ó sì kà wá sí ọ̀rẹ́ ẹ̀! Ẹ ò rí i pé tá a bá mọ Ọlọ́run tòótọ́, àwọn ìbùkún tá a máa rí ò láfiwé!

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí nìdí tó fi yẹ kí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ Jèhófà dáadáa?

  • Báwo la ṣe lè kọ́ ọ kó lè mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́?

  • Báwo la ṣe lè ràn án lọ́wọ́ kí ohun tó ti mọ̀ nípa Jèhófà lè ṣe é láǹfààní?

ORIN 84 Wá Wọn Lọ

a Apá ohun tó yẹ kó o ṣe ní ẹ̀kọ́ 05 nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! sọ pé: “Bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì déédéé, kó o lo àtẹ náà ‘Máa Ka Bíbélì Lójoojúmọ́.’”

b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Àwòrán tó jẹ́ ká rí bí ẹni tí Marianne ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe kọ̀ láti gba iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ fún un.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́