ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 February ojú ìwé 30-ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 7
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Oju-iwoye Bibeli Nipa Alaafia ati Ailewu
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Wíwò Rekọja “Alaafia ati Ailewu” Atọwọda Eniyan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Ẹ̀sìn?—Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 February ojú ìwé 30-ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 7
Àwọn alákòóso ayé dúró nítòsí ọ́fí ìsì Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé, wọ́n sì ń kéde “àlàáfíà àti ààbò” níwájú ọ̀pọ̀ èèyàn tí inú wọn ń dùn.

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìgbà wo làwọn orílẹ̀-èdè máa kéde “àlàáfíà àti ààbò”?

Bá a ṣe sọ nínú “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́a lẹ́nu àìpẹ́ yìí, kò ní pẹ́ mọ́ tí Jèhófà máa fi sí ọkàn “ìwo mẹ́wàá” náà (ìyẹn gbogbo ìjọba ayé) láti ṣe “ohun tí òun fẹ́.” Ìyẹn ni pé àwọn orílẹ̀-èdè máa fún “ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” tó ṣàpẹẹrẹ Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé ní agbára àti àṣẹ wọn. Ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yìí ni Bíbélì tún pè ní “ère ẹranko náà.” (Ìfi. 13:14, 15; 17:3, 16, 17) Lẹ́yìn ìyẹn, “ìwo mẹ́wàá” àti ẹranko tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gba agbára yìí máa pa ìsìn èké run kárí ayé. Ìbéèrè náà ni pé, ṣé ṣáájú ìparun ìsìn èké làwọn orílẹ̀-èdè máa kéde “àlàáfíà àti ààbò”b àbí lẹ́yìn tí ìsìn èké bá pa run?—1 Tẹs. 5:3.

Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, a ò mọ ìgbà tí wọ́n máa kéde “àlàáfíà àti ààbò.” Ká sọ pé a mọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe máa jẹ́, a lè má múra sílẹ̀ ká sì wà lójúfò. Àmọ́, léraléra ni Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n “máa ṣọ́nà.” (Mát. 24:42; 25:13; 26:41) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ tí ẹ̀mí Ọlọ́run darí Pọ́ọ̀lù láti kọ sínú lẹ́tà tó fi ránṣẹ́ sáwọn ará Tẹsalóníkà.

Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nígbàkigbà tí wọ́n bá ń sọ pé, ‘Àlàáfíà àti ààbò!’ ìgbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn.” (1 Tẹs. 5:2, 3) Àlàyé tá a ti ṣe nípa ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yìí nínú àwọn ìwé wa ni pé: Wọ́n máa kéde “àlàáfíà àti ààbò” ṣáájú kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀. Ìparun Bábílónì Ńlá, ìyẹn àpapọ̀ ìsìn èké àgbáyé ló sì máa bẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá. Bákan náà, a sọ pé ìkéde yìí ló máa jẹ́ àmì pé ìpọ́njú ńlá ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀.

Àmọ́, lẹ́yìn tá a tún gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò, a rí i pé ó tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn ìparun ìsìn èké ni wọ́n máa kéde “àlàáfíà àti ààbò.” Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká dáhùn àwọn ìbéèrè yìí ná.

Kí ni ìsìn èké máa ń ṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè bá ń jagun? Bíbélì sọ pé: “Inú rẹ̀ [ìyẹn “aṣẹ́wó ńlá” náà, tá a tún mọ̀ sí Bábílónì Ńlá] ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ . . . gbogbo àwọn tí wọ́n pa ní ayé.” (Ìfi. 17:1, 5; 18:24) Ọjọ́ pẹ́ tí aṣẹ́wó ńlá náà ti ń ṣètìlẹyìn fáwọn orílẹ̀-èdè tó ń bára wọn jagun àtàwọn tó ń pa àwọn èèyàn nípakúpa. Torí náà, ogun àti rògbòdìyàn ni ìsìn èké ń gbé lárugẹ kì í ṣe àlááfíà àti ààbò. Ìyẹn lè mú ká béèrè pé: Ṣé lẹ́yìn tí àwọn orílẹ̀-èdè bá pa Bábílónì Ńlá run ni wọ́n máa tó kéde “àlàáfíà àti ààbò”? Ó ṣeé ṣe kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ kò dá wa lójú.

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìkéde “àlàáfíà àti ààbò”? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìgbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn.” (1 Tẹs. 5:3) Àlàyé ọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ Bíbélì yìí lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nínú ẹsẹ yìí ni pé, ó lè jẹ́ ojú ẹsẹ̀ tàbí kó má pẹ́ rárá sígbà táwọn orílẹ̀-èdè bá kéde ‘àlàáfíà àti ààbò’ ni ìparun òjijì náà máa wá sórí wọn. Òjijì ló máa jẹ́, wọn ò sì ní yè bọ́.” Tí àwọn alákòóso ayé bá kéde “àlàáfíà àti ààbò” lẹ́yìn ìparun ìsìn èké, á jẹ́ pé ìparun tiwọn náà máa tẹ̀ lé e lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Kí ló máa dá àwa èèyàn Jèhófà lójú táwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀yin ará, ẹ ò sí nínú òkùnkùn, tí ọjọ́ yẹn á fi dé bá yín lójijì bí ìgbà tí ilẹ̀ mọ́ bá olè.” (1 Tẹs. 5:4) Rò ó wò ná: Tó bá jẹ́ pé lẹ́yìn tí wọ́n pa ìsìn èké run ni wọ́n kéde “àlàáfíà àti ààbò,” àwa èèyàn Jèhófà máa mọ̀ pé ìparun àwọn orílẹ̀-èdè kò ní pẹ́ mọ́ nìyẹn. Àmọ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè, ṣe ni ìparun wọn máa dé lójijì láìròtẹ́lẹ̀ bí ìgbà tí ilẹ̀ mọ́ bá olè.

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́? Láìpẹ́, “ìwo mẹ́wàá” àti ẹranko tó ti gba agbára máa pa ìsìn èké run. Ìparun yìí ló sì máa bẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá. A tún mọ̀ pé àwọn orílẹ̀-èdè máa kéde “àlàáfíà àti ààbò.” Ìgbà wo nìyẹn máa ṣẹlẹ̀? Àkọ́kọ́: Bá a ṣe jíròrò, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣáájú kí ìsìn èké tó pa run ni ìkéde náà máa wáyé. Ìkejì: Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìkéde náà máa wáyé lẹ́yìn táwọn alákòóso ayé yìí bá pa ìsìn èké run pátápátá. Èyí ó wù ó jẹ́, ó máa gba pé ká dúró dìgbà yẹn ká lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, tí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì bá ń ṣẹ lọ́wọ́ tàbí lẹ́yìn tó ti ṣẹ ló máa ń yé wa dáadáa.—Fi wé Jòhánù 12:16.

Bá a ṣe ń retí ìgbà tí wọ́n máa kéde “àlàáfíà àti ààbò,” ẹ má jẹ́ ká gbàgbé pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Torí náà, ẹ jẹ́ “kí a wà lójúfò, kí a sì máa ronú bó ṣe tọ́,” ká lè gbára dì fún ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.—1 Tẹs. 5:6.

a Ka “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ November 2025.

b Ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lò jẹ́ ká rí i pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan ni wọ́n máa kéde àlàáfíà àti ààbò tàbí kí wọ́n kéde ẹ̀ nígbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́