“Àwọn Ọmọ Jẹ́ Ogún Láti Ọ̀dọ̀ Jèhófà”
KÍ LÓ máa wá sí ẹ lọ́kàn tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “ogún”? Ọkàn ẹ lè lọ sí owó, ilé, ilẹ̀, aṣọ tàbí àwọn nǹkan míì tí mọ̀lẹ́bí kan tó nífẹ̀ẹ́ ẹ fi sílẹ̀ fún ẹ. Ohun yòówù kó jẹ́, kò sí àní-àní pé nǹkan tó ṣeyebíye ni ogún jẹ́, ó sì dájú pé wàá fẹ́ tọ́jú ẹ̀ dáadáa.
Bíbélì sọ pé, “àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” (Sm. 127:3) Ìdí nìyẹn tí àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni fi gbà pé àwọn ọmọ jẹ́ ẹ̀bùn tó ṣeyebíye látọ̀dọ̀ Baba wọn ọ̀run, wọ́n sì máa ń fẹ́ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti bójú tó wọn. Wọ́n máa ń pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò fún wọn, wọ́n máa ń ṣìkẹ́ wọn, wọ́n sì máa ń kọ́ wọn lohun táá jẹ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.
Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé, àwọn òbí kan ò gbà pé Ọlọ́run ló fi àwọn ọmọ náà ta àwọn lọ́rẹ. (Àìsá. 49:15; 2 Tím. 3:1-3) Ní tàwọn míì, ó wù wọ́n kí wọ́n bójú tó àwọn ọmọ wọn, àmọ́ kò rọrùn fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó mú kó ṣòro fáwọn òbí láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dáadáa? Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn òbí ṣe fáwọn ọmọ wọn? Kí làwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni lè ṣe kí wọ́n lè tọ́ àwọn ọmọ wọn yanjú?
ÀWỌN ÌṢÒRO
Àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn míì máa ń fúngun mọ́ wọn. Láwọn ibì kan, ojú pàtàkì làwọn ará àdúgbò fi máa ń wo àwọn tó bá bímọ rẹpẹtẹ. Torí náà, àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ará àdúgbò máa ń fúngun mọ́ àwọn tọkọtaya pé kí wọ́n bímọ rẹpẹtẹ. Kódà, àwọn ọmọ náà lè pọ̀ ju ohun tágbára tọkọtaya náà ká lọ.
Wọ́n máa ń ṣàníyàn nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí wọ́n bá darúgbó. Láwọn ibì kan, àwọn ọmọdé máa ń kú gan-an torí wọn ò rí oúnjẹ tó dáa jẹ, wọ́n máa ń ṣàìsàn, ilé ìwòsàn tí wọ́n ti lè gba ìtọ́jú ò sì pọ̀. Ìdí nìyẹn táwọn tọkọtaya kan fi máa ń bímọ tó pọ̀ gan-an, torí wọ́n gbà pé táwọn kan bá kú, àwọn kan á yè. Àwọn tọkọtaya míì sì máa ń bímọ rẹpẹtẹ torí wọ́n gbà pé ìyẹn á jẹ́ káwọn rọ́mọ tọ́jú àwọn táwọn bá darúgbó. Irú nǹkan yìí sábà máa ń ṣẹlẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè tí ìjọba ò ti ní ètò láti ran àwọn arúgbó lọ́wọ́.
Fífi ètò sọ́mọ bíbí. Láwọn ibì kan, àwọn tọkọtaya ò ní oríṣiríṣi nǹkan tí wọ́n lè lò tí kò ní jẹ́ kéèyàn lóyún. Ní tàwọn míì, àwọn oògùn tí kì í jẹ́ kéèyàn lóyún tó jẹ́ gbàrọgùdù ló wà ládùúgbò wọn, wọ́n sì ń bẹ̀rù pé táwọn bá lò ó, ó lè ṣàkóbá fáwọn. Ohun tó jẹ́ ìṣòro àwọn míì ni pé wọn ò lówó láti ra àwọn oògùn tí kì í jẹ́ kéèyàn lóyún torí ó wọ́n gan-an lágbègbè wọn.a
KÍ NI JÈHÓFÀ FẸ́ KÁWỌN ÒBÍ ṢE FÁWỌN ỌMỌ WỌN?
Ẹ máa wáyè fún ọmọ kọ̀ọ̀kan
Máa pèsè àwọn nǹkan tí ọmọ rẹ nílò. Jèhófà ti gbé iṣẹ́ pàtàkì kan lé àwọn òbí lọ́wọ́, ó ní kí wọ́n máa pèsè ohun táwọn ọmọ wọn nílò. Ó fẹ́ káwọn òbí máa ṣiṣẹ́ kára, kí wọ́n lè pèsè oúnjẹ, aṣọ àti ibi táwọn ọmọ wọn máa gbé títí wọ́n á fi dàgbà. Jèhófà tún fẹ́ káwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Torí náà, tó bá dọ̀rọ̀ rírán ọmọ níléèwé, àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni kì í jẹ́ káwọn ọmọ wọn gbé ní àwọn ilé ìwé tó ní ibùgbé. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń rí i pé àwọn ọmọ wọn gbé lọ́dọ̀ wọn títí wọ́n á fi dàgbà, kí wọ́n lè kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ táá jẹ́ kí wọ́n lè gbọ́ bùkátà ara wọn nígbà tí wọ́n bá dàgbà. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún máa ń wáyè láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kọ́kàn àwọn ọmọ náà balẹ̀ kí wọ́n sì mọ̀ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn. Síbẹ̀, Jèhófà ò retí pé káwọn òbí ṣe ju agbára wọn lọ. Kò retí pé kí wọ́n lówó rẹpẹtẹ kí wọ́n tó lè tọ́ àwọn ọmọ wọn. Kódà, àwọn òbí tí ò lówó lọ́wọ́ àmọ́ tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ kára ni Jèhófà lò láti tọ́ Jésù Ọmọ ẹ̀ ọ̀wọ́n.—Mát. 13:55, 56; Lúùkù 2:24.
Ìlànà Bíbélì: “Ó dájú pé tí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, pàápàá fún ìdílé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.”—1 Tím. 5:8.
Jèhófà mọ̀ pé ó ṣeé ṣe káwọn òbí fẹ́ káwọn ọmọ wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n bá darúgbó. Kódà, ọ̀kan lára ohun táwọn ọmọ lè ṣe láti bọlá fáwọn òbí wọn ni pé kí wọ́n bójú tó wọn tọ́jọ́ ogbó bá dé. (Ẹ́kís. 20:12; 1 Tím. 5:4) Àmọ́ ṣá o, inú Jèhófà máa ń dùn táwọn òbí bá fọwọ́ pàtàkì mú bí wọ́n ṣe máa bójú tó àwọn ọmọ wọn dípò kí wọ́n máa ronú báwọn ọmọ ṣe máa bójú tó àwọn.—2 Kọ́r. 12:14.
Kọ́ wọn kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ojúṣe míì tí Jèhófà fún àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ni pé kí wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ òun, kí wọ́n sì máa sin òun. Ìyẹn sì jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó ṣe pàtàkì jù tí Jèhófà retí pé káwọn òbí ṣe fáwọn ọmọ wọn.—Diu. 6:6, 7.
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa tọ́ [àwọn ọmọ yín] dàgbà nínú ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà.”—Éfé. 6:4.
JÈHÓFÀ FẸ́ KÓ O TỌ́ ÀWỌN ỌMỌ Ẹ YANJÚ
Ẹ jọ sọ iye ọmọ tẹ́ ẹ máa bí
Ẹ pinnu iye ọmọ tẹ́ ẹ máa bí. Tó bá wù ẹ́ láti bímọ, ó yẹ kó o rò ó dáadáa bóyá agbára ẹ máa gbé e láti tọ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá bímọ tó pọ̀, ṣé wàá lè bọ́ wọn, kó o raṣọ fún wọn, kó o sì kọ́ wọn? Tó o bá rí i pé agbára ẹ ò lè gbé e, á dáa kí ìwọ àti ọkọ tàbí aya ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa iye ọmọ tẹ́ ẹ máa lè tọ́, kẹ́ ẹ lè pèsè ohun tí ọmọ kọ̀ọ̀kan nílò, kẹ́ ẹ sì ṣe ojúṣe tí Jèhófà fún yín dáadáa. Ká sòótọ́, Jèhófà mọ̀ pé àwọn nǹkan tá ò rò tẹ́lẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ nígbà míì. (Oníw. 9:11) Àmọ́ tẹ́ ẹ bá ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe, Jèhófà máa ràn yín lọ́wọ́ kẹ́ ẹ lè tọ́ àwọn ọmọ yín yanjú.
Ìlànà Bíbélì: “Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere, àmọ́ ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá ń kánjú yóò di aláìní.”—Òwe 21:5.
“Èwo nínú yín ló máa fẹ́ kọ́ ilé gogoro, tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kó ṣírò ohun tó máa ná an, kó lè mọ̀ bóyá àwọn ohun tó ní máa tó parí ilé náà?”—Lúùkù 14:28.
Ìjọsìn Jèhófà ni kẹ́ ẹ kà sí pàtàkì jù nínú ìdílé yín. Rí i dájú pé ìjọsìn Jèhófà lẹ kà sí pàtàkì jù nínú ìdílé rẹ. Tó o bá ti bímọ, pinnu pé wàá kọ́ ọmọ kọ̀ọ̀kan kó lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè máa fetí sílẹ̀ dáadáa àti bí wọ́n ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ láwọn ìpàdé ìjọ. Rí i pé ẹ̀ ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé yín déédéé. Kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè máa wàásù. Má ṣe retí pé àwọn ọmọ ẹ tó ti dàgbà, àwọn mọ̀lẹ́bí tàbí ẹlòmíì lá bá ẹ tọ́ àwọn ọmọ ẹ. Ojúṣe rẹ ni! Òótọ́ ni pé, ó máa ń gba àkókò àti iṣẹ́ àṣekára ká tó lè tọ́ àwọn ọmọ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àmọ́ tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní kábàámọ̀ ẹ̀ láé!
Ìlànà Bíbélì: “Kò sí ohun tó ń mú inú mi dùn bíi kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń rìn nínú òtítọ́.”—3 Jòh. 4.b
Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Tó o bá ti bímọ tàbí tó o ṣì ń ronú láti bímọ, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé àwọn ìlànà Jèhófà ló ṣe pàtàkì jù, kì í ṣe àṣà ìbílẹ̀ tàbí ohun táwọn èèyàn ń ṣe lágbègbè yín.
Ó máa ń gba àkókò àti iṣẹ́ àṣekára káwọn òbí tó lè kọ́ àwọn ọmọ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
Tó o bá pinnu láti dín iye ọmọ tó o fẹ́ bí kù, fọkàn tán Jèhófà pé ó máa bójú tó ẹ tó o bá darúgbó. Má ṣe jẹ́ kóun táwọn èèyàn ń sọ tàbí tí wọ́n ń rò mú kó o bímọ rẹpẹtẹ, kó o wá máa ronú pé àwọn ọmọ yìí ló máa bá ẹ tán ìṣẹ́ tó o bá dàgbà. Kò yẹ kó o bẹ̀rù pé Jèhófà máa pa ẹ́ tì. Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa bójú tó ẹ, gbogbo ìgbà ló sì máa ń mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ.—Jóṣ. 23:14.
Ìlànà Bíbélì: “Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Máa kíyè sí i ní gbogbo ọ̀nà rẹ, á sì mú kí àwọn ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:5, 6.
“Mo ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, àmọ́ ní báyìí mo ti darúgbó, síbẹ̀, mi ò tíì rí i kí a pa olódodo tì, tàbí kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.”—Sm. 37:25.
“Torí náà, ẹ máa wá Ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn yìí la sì máa fi kún un fún yín.”—Mát. 6:33.
Àwọn ọmọ jẹ́ ẹ̀bùn tó ṣeyebíye tí Jèhófà fún àwọn òbí, ó sì fẹ́ kí wọ́n bójú tó wọn. Ẹ ò rí i pé inú Jèhófà máa dùn gan-an tí àwọn òbí bá ń bójú tó àwọn ọmọ náà bó ṣe fẹ́! Torí náà, ẹ máa pèsè àwọn nǹkan táwọn ọmọ yín nílò fún wọn, ẹ máa ṣìkẹ́ wọn, kẹ́ ẹ sì máa kọ́ wọn lohun táá jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Bákan náà, ó yẹ kí tọkọtaya jọ sọ̀rọ̀ nípa iye ọmọ tí wọ́n máa lè tọ́. Paríparí ẹ̀, kí wọ́n máa rántí pé àwọn ìlànà Jèhófà ló ṣe pàtàkì jù, kì í ṣe àṣà ìbílẹ̀ tàbí ohun táwọn èèyàn ń ṣe lágbègbè wọn. Tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe lẹ̀ ń fi hàn pé àwọn ọmọ yín jẹ́ ẹ̀bùn tó ṣeyebíye, wọ́n sì jẹ́ “ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.”
a Tọkọtaya ló máa pinnu iye ọmọ tí wọ́n máa bí, ìgbà tí wọ́n máa bímọ àti bóyá wọ́n á lo àwọn oògùn tí kì í jẹ́ kéèyàn lóyún, àmọ́ tí ò ní ba oyún jẹ́. Ẹnì kankan ò sì gbọ́dọ̀ dá wọn lẹ́bi. (Róòmù 14:4, 10-13) Bákan náà, àwọn Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó tún gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 7:3-5 sílò.
b Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni tó ti di ọmọ ẹ̀yìn ni Jòhánù ń sọ nínú ẹsẹ yìí, àwọn òbí náà lè sọ ọ̀rọ̀ yìí nípa àwọn ọmọ wọn tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn.