Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Sí Ẹ̀sìn?—Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ṣé àwọn nǹkan kan wà táwọn ẹlẹ́sìn ń ṣe, tó o gbà pé kò yẹ ká bá lọ́wọ́ wọn rárá tíyẹn sì mú kó o kórìíra ẹ̀sìn? Òótọ́ ni pé àwọn ẹlẹ́sìn ti ṣe àwọn nǹkan kan tó ṣàǹfààní fáwọn èèyàn, àmọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n tún ń ṣe tó ń ṣàkóbá tó pọ̀ fáwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopedia of Religion and War sọ pé: “Wàhálà táwọn ẹlẹ́sìn ń bára wọn fà torí pé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ yàtọ̀ síra ló fa àwọn kan lára ogun tó burú jù lọ tọ́mọ aráyé ò lè gbàgbé.” Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn olórí ẹ̀sìn máa ń fi ẹ̀sìn gbé ọ̀rọ̀ òṣèlú lárugẹ, dípò kí wọ́n fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run. Kódà, àwọn olórí ẹ̀sìn kan máa ń mọ̀ sí ìṣekúṣe tó burú jáì tàbí ìwà jìbìtì tó wáyé nínú ìjọ wọn, àmọ́ wọ́n á dọwọ́ bò ó mọ́lẹ̀.
Tó bá jẹ́ pé ohun táwọn ẹlẹ́sìn ń ṣe ti mú kí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn sú ẹ, o lè máa rò ó pé, ‘Ṣé Ọlọ́run fọwọ́ sí àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe yìí?’ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ò tẹ́wọ́ gba ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn tó wà lónìí torí ohun tí wọ́n ń ṣe. Bíbélì tún sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa ohun tí Ọlọ́run máa ṣe sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Ó sọ àpèjúwe àwọn nǹkan tí ò tíì ṣẹlẹ̀ rí tí Ọlọ́run máa ṣe láìpẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kárí ayé.
Kí ni Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀sìn?
Àsọtẹ́lẹ̀: Ìwé Ìfihàn sọ̀rọ̀ nípa obìnrin aṣẹ́wó kan tó pe orúkọ ẹ̀ ní Bábílónì Ńlá. Aṣẹ́wó yìí jókòó sórí ẹranko kan tó ní àwọ̀ rírẹ̀dòdò. Àmọ́ nígbà tó yá, ẹranko yẹn gbéjà ko aṣẹ́wó náà, ó sì pa á.—Ìfihàn 17:3, 5, 16.
Ohun tó túmọ̀ sí: Aṣẹ́wó tí Bíbélì pè ní Bábílónì Ńlá yẹn ń tọ́ka sí gbogbo ẹ̀sìn èké, ìyẹn àwọn ẹ̀sìn tí Ọlọ́run ò fọwọ́ sí.a Ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yẹn ṣàpẹẹrẹ Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé (ìyẹn UN).b Nígbà tí Bíbélì sọ pé aṣẹ́wó yìí jókòó sórí ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé ẹ̀sìn èké ń gbìyànjú láti darí àjọ UN kí àjọ yìí lè máa ṣe ohun tó fẹ́. Àmọ́ nígbà tí Bíbélì sọ pé ẹranko náà pa aṣẹ́wó náà, ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé àjọ UN àtàwọn ìjọba orílẹ̀-èdè tó ń tì í lẹ́yìn máa gbéjà ko gbogbo ẹ̀sìn èké tó wà láyé yìí, wọ́n á sì pa wọ́n run. Ó dájú pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí máa mi ayé jìgìjìgì.
Báwo ni ẹ̀sìn èké ṣe máa pa run?
Àsọtẹ́lẹ̀: “Ìwo mẹ́wàá tí o rí àti ẹranko náà, máa kórìíra aṣẹ́wó náà, wọ́n máa sọ ọ́ di ahoro, . . . wọ́n sì máa fi iná sun ún pátápátá. Torí Ọlọ́run ti fi sí ọkàn wọn [ìyẹn ọkàn àwọn aláṣẹ ìjọba àgbáyé] láti ṣe ohun tí òun fẹ́, àní láti ṣe ohun kan ṣoṣo tí wọ́n ń rò láti fún ẹranko náà ní ìjọba wọn . . . Àwọn ìyọnu rẹ̀ . . . máa dé ní ọjọ́ kan ṣoṣo, ikú àti ọ̀fọ̀ àti ìyàn, a sì máa fi iná sun ún pátápátá, torí pé Jèhófàc Ọlọ́run, ẹni tó ṣèdájọ́ rẹ̀, jẹ́ alágbára.”—Ìfihàn 17:16, 17; 18:8.
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run máa fi ‘ohun tó fẹ́’ sí ọkàn àwọn ìjọba tó ń ṣàkóso kárí ayé. Ó máa mú kí wọ́n fún àjọ UN ní “ìjọba wọn” tàbí agbára tí wọ́n fi ń ṣàkóso. Lẹ́yìn náà, àjọ UN táwọn ìjọba ayé ti ró lágbára yìí máa wá gbéjà ko ẹ̀sìn èké kárí ayé, wọ́n á sì pa gbogbo wọn run. Ohun àgbàyanu yìí máa ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, ó máa bá ọ̀pọ̀ èèyàn lójijì, ó sì máa dà bíi pé “ọjọ́ kan ṣoṣo” ló fi ṣẹlẹ̀ torí pé kò ní pẹ́ rárá tí wọ́n á fi pa gbogbo ẹ̀sìn èké run.—Ìfihàn 18:21.
Kí nìdí tí ẹ̀sìn èké fi máa pa run?
Àsọtẹ́lẹ̀: “Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti ga dé ọ̀run, Ọlọ́run sì ti rántí àwọn ìwà àìṣòdodo tó hù.”—Ìfihàn 18:5.
Ohun tó túmọ̀ sí: Àìmọye nǹkan burúkú ni ẹ̀sìn èké ti ṣe láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Wo díẹ̀ lára “àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀” tó máa mú kí Ọlọ́run pa á run:
Ó ń lọ́wọ́ sí òṣèlú. Jésù Kristi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n má lọ́wọ́ sí òṣèlú, àmọ́ kí wọ́n máa retí Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ìjọba tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ lọ́run tó máa rọ́pò ìjọba èèyàn.d (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10; Jòhánù 6:15; 18:36) Ìdàkejì ohun tí Jésù sọ yìí ni ẹ̀sìn èké ń ṣe. Dípò kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, ṣe ni wọ́n tara bọ òṣèlú. Ìdí nìyẹn tí ìwé Ìfihàn fi sọ pé Bábílónì Ńlá ń ṣe “ìṣekúṣe,” abájọ tí Bíbélì fi pè é ní “aṣẹ́wó ńlá.”—Ìfihàn 17:1, 2; Jémíìsì 4:4.
Ó ń lọ́wọ́ sí ìwà ipá. Bíbélì sọ pé ẹ̀sìn èké ló lẹ̀bi ikú “gbogbo àwọn tí wọ́n pa ní ayé.” (Ìfihàn 18:24) Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ni ò kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn pé kí wọ́n máa wá àlàáfíà, yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ń kọ́wọ́ ti àwọn afẹ̀míṣòfò, wọ́n sì ń mú káwọn èèyàn máa bára wọn jagun.
Ó ń kó ọrọ̀ jọ. Ẹ̀sìn èké ń gbé “ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ láìnítìjú.” (Ìfihàn 17:4; 18:7) Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ń lo agbára tí wọ́n ní àti ipò tí wọ́n wà láti kó ọrọ̀ jọ. Ọlọ́run ò sì nífẹ̀ẹ́ irú ìwà bẹ́ẹ̀.—Títù 1:7.
Ó ń parọ́. Ohun tí ò sí nínú Bíbélì àti ìwà tí ò bá Bíbélì mu ni ẹ̀sìn èké ń kọ́ àwọn èèyàn.e Torí pé ẹ̀sìn èké ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà bí wọ́n ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ àti ìwà tó ń mú kí wọ́n máa ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́, Bíbélì pè é ní “ìyá . . . àwọn ohun ìríra ayé.”—Ìfihàn 17:5; 18:23.
Ṣé gbogbo ẹ̀sìn ló máa pa run?
Rárá o. Ìwé Ìfihàn sọ̀rọ̀ nípa àwùjọ àwọn èèyàn kan tó wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láyé, ó pè wọ́n ní “ogunlọ́gọ̀ èèyàn.” (Ìfihàn 7:9) Ó sọ pé àwọn èèyàn yìí “wọ aṣọ funfun,” tó túmọ̀ sí pé wọ́n ń fi òótọ́ inú sin Ọlọ́run lọ́nà tó fẹ́. Àwọn èèyàn yìí ò ní pa run nígbà “ìpọ́njú ńlá,” ìyẹn àsìkò tí Bíbélì sọ pé ẹ̀sìn èké àti gbogbo àwọn tó ń ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́ máa pa run. (Ìfihàn 7:13, 14; 19:11, 19-21) Ẹ̀sìn tòótọ́ ni àwọn èèyàn tó wọ aṣọ funfun yìí ń ṣe, ẹ̀sìn yìí ò sì ní pa run títí láé.f
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó fẹ́ máa là á já, ẹ̀sìn èké sì máa pa run
Kí ló yẹ kó o ṣe ní báyìí tó o ti mọ̀ pé ẹ̀sìn èké máa pa run?
Ǹjẹ́ ọkàn ẹ ò balẹ̀ ní báyìí tó o ti mọ̀ pé Ọlọ́run ò fọwọ́ sí àwọn nǹkan burúkú táwọn ẹlẹ́sìn ń ṣe? Ó dájú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, torí o ti mọ̀ báyìí pé gbogbo ẹ̀sìn tó ń ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́, tó sì ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà máa tó pa run.
Ohun míì tún ni pé àwa èèyàn lè sin Ọlọ́run lọ́nà tó fẹ́. Bíbélì sọ pé “àwọn olùjọsìn tòótọ́ á máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́, torí ní tòótọ́, irú àwọn ẹni yìí ni Baba ń wá pé kí wọ́n máa jọ́sìn òun.” (Jòhánù 4:23) Ọlọ́run sọ fún àwọn olùjọsìn tòótọ́ pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ [ìyẹn Bábílónì Ńlá], ẹ̀yin èèyàn mi, tí ẹ kò bá fẹ́ pín nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu rẹ̀.” (Ìfihàn 18:4, 5) Ọlọ́run ń pe àwa èèyàn ká wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa òun ká lè jọ́sìn òun lọ́nà tó fẹ́. (1 Tímótì 2:3, 4) Ó ṣèlérí pé àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ máa wà láàyè títí láé.—1 Jòhánù 2:17.
a Tó o bá fẹ́ mọ ohun mẹ́rin tó o lè fi dá Bábílónì Ńlá mọ̀, ka àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Kí Ni Bábílónì Ńlá?”
b Tó o bá fẹ́ mọ ohun mẹ́fà tó o lè fi dá ẹranko náà mọ̀, ka àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Kí Ni Ẹranko Ẹhànnà Aláwọ̀ Rírẹ̀dòdò Tó Wà Nínú Ìṣípayá Orí Kẹtàdínlógún?”
c Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Ka àpilẹ̀kọ náà, “Ta Ni Jèhófà?”
d Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo fídíò tá a pe àkòrí ẹ̀ ní Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
e Kó o lè rí àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan, wo àpótí tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Ṣé Àwọn Ẹ̀sìn Kan Tó Pera Wọn Ní Kristẹni Náà Wà Lára Bábílónì Ńlá?”
f Tó o bá fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa bó o ṣe lè dá ẹ̀sìn tòótọ́ mọ̀, ka àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mọ Ìsìn Tòótọ́?”