ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 February ojú ìwé 32
  • Ọbadáyà Bẹ̀rù Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọbadáyà Bẹ̀rù Ọlọ́run
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbàgbọ́ Àti Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Fún Wọn Ní Ìgboyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Bẹ̀rù Jèhófà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ọbadáyà, Ìwé Jónà, àti Ìwé Míkà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Kíkọ́ Láti Rí Ìgbádùn Nínú Ìbẹ̀rù Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 February ojú ìwé 32

ÀWỌN TÍ BÍBÉLÌ SỌ̀RỌ̀ WỌN

Ọbadáyà Bẹ̀rù Ọlọ́run

Ọbadáyà ló ń bójú tó agboolé Ọba Áhábù. Áhábù burú gan-an, ó sì gbà káwọn èèyàn máa jọ́sìn Báálì nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Àmọ́, Ọbadáyà bẹ̀rù Jèhófà “láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.” (1 Ọba 18:1-13) Torí náà nígbà tí Ayaba Jésíbẹ́lì pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo wòlíì Jèhófà, Ọbadáyà mọ̀ pé òun gbọ́dọ̀ nígboyà kóun lè dáàbò bò wọ́n. Nígbà yẹn, téèyàn bá fi wòlíì kan péré pa mọ́ wàhálà ni, àmọ́ Ọbadáyà kó ọgọ́rùn-ún wòlíì pa mọ́, ó sì ń fún wọn lóúnjẹ lásìkò tí ìyàn mú! Fojú inú wo bó ṣe máa nira tó láti fi àwọn wòlíì yẹn pa mọ́, kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wòlíì èké tó ń bá ọba àti ayaba ṣiṣẹ́ má sì mọ̀.—1 Ọba 18:19.

Kí la lè kọ́ lára ọkùnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run yìí? Òótọ́ ni pé Ọbadáyà bẹ̀rù Áhábù, àmọ́ ó bẹ̀rù Ọlọ́run ju Áhábù lọ. Ìyẹn ló jẹ́ kó nígboyà, kó sì fẹ̀mí ẹ̀ wewu kó lè dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run. Táwọn aláṣẹ bá fòfin de iṣẹ́ wa níbi tá à ń gbé, ìbẹ̀rù Ọlọ́run máa ran àwa náà lọ́wọ́. Tá a bá bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ̀rù ò ní bà wá láti dúró ti àwọn ará wa tó níṣòro, àá sì lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́