ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 March ojú ìwé 26-31
  • Ohun Tó Lè Fún Wa Láyọ̀ Báwọn Èèyàn Tiẹ̀ Kórìíra Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Lè Fún Wa Láyọ̀ Báwọn Èèyàn Tiẹ̀ Kórìíra Wa
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌDÍ TÍ WỌ́N FI KÓRÌÍRA WA
  • OHUN TÓ LÈ MÁA FÚN WA LÁYỌ̀ BÁWỌN ÈÈYÀN TIẸ̀ KÓRÌÍRA WA
  • Ìfẹ́ Ń Jẹ́ Ká Lè Fara Da Ìkórìíra
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Lẹ́tà Tó Máa Mú Ká Jẹ́ Olóòótọ́, Ká sì Fara Dà Á Dópin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Bí Jèhófà Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Fara Da Ìṣòro Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • “Ẹ Fúnra Yín Yan Ẹni Tí Ẹ Fẹ́ Máa Sìn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 March ojú ìwé 26-31

JUNE 1-7, 2026

ORIN 111 Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀

Ohun Tó Lè Fún Wa Láyọ̀ Báwọn Èèyàn Tiẹ̀ Kórìíra Wa

“Aláyọ̀ ni yín nígbàkigbà tí àwọn èèyàn bá kórìíra yín.”—LÚÙKÙ 6:22.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Ìdí tí inú wa fi máa ń dùn táwọn èèyàn bá tiẹ̀ kórìíra wa torí pé à ń sin Jèhófà.

1. Ọ̀rọ̀ tó yani lẹ́nu wo ni Jésù sọ?

NÍGBÀ tí Jésù ń wàásù lórí òkè, ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbàkigbà tí àwọn èèyàn bá kórìíra yín.” (Lúùkù 6:22) Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yẹn máa ya àwọn tó wà níbẹ̀ lẹ́nu. Ó ṣe tán, kò sẹ́ni tó fẹ́ kí wọ́n kórìíra òun. Kí wá nìdí tí Jésù fi sọ̀rọ̀ yìí? Ìbéèrè yìí gba àròjinlẹ̀ torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló kórìíra àwa ọmọ ẹ̀yìn Jésù lónìí. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí táwọn èèyàn fi kórìíra wa àti ìdí tó fi yẹ kínú wa máa dùn tí wọ́n bá tiẹ̀ kórìíra wa.

ÌDÍ TÍ WỌ́N FI KÓRÌÍRA WA

2-3. Kí nìdí tí wọ́n fi máa ń ṣenúnibíni sáwa Kristẹni tòótọ́, èrò wo ló sì yẹ kíyẹn mú ká ní nípa àwọn tó ń ta kò wá? (Jòhánù 16:2, 3)

2 Wọ́n kórìíra wa torí pé à ń sin Jèhófà. Jésù sọ pé àwọn èèyàn máa ṣenúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn òun, kódà wọ́n á pa àwọn kan lára wọn. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó máa hùwà ìkà yìí, ó ní: “Wọn ò tíì wá mọ Baba, wọn ò sì tíì wá mọ̀ mí.” (Ka Jòhánù 16:2, 3.) Àmọ́ ta ló wà nídìí ìwà ìkà tí wọ́n ń hù sáwọn èèyàn Ọlọ́run? Sátánì Èṣù ni. Òun ni “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Kọ́r. 4:3, 4) Sátánì kì í jẹ́ káwọn èèyàn mọ òtítọ́ nípa Jèhófà, ó sì máa ń mú kí wọ́n ta ko àwọn tó ń sin Ọlọ́run. (Jòh. 8:42-44) Èrò wo ló yẹ ká ní nípa àwọn tó ń ta kò wá? Torí a mọ̀ pé Sátánì ló ń ṣì wọ́n lọ́nà, ìyẹn ni ò jẹ́ káwa náà kórìíra wọn.

3 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pavela tó ń gbé lórílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. Àwọn agbófinró mú un torí pé ó ń sin Jèhófà, wọ́n lù ú lálùbolẹ̀, wọ́n sì fi sínú àhámọ́. Pavel sọ pé: “Mo ti wá mọ ìdí táwọn èèyàn fi ń ṣe inúnibíni sí wa, ìdí ni pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ò fẹ́ ká sin Jèhófà. Kì í ṣe pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n kórìíra wa, iṣẹ́ wọn ni wọ́n kàn ń ṣe.” Arákùnrin kan láti orílẹ̀-èdè Croatia táwọn òbí ẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà fojú ẹ̀ rí màbo sọ pé: “Mo mọ̀ pé Sátánì gan-an ló dájú sọ mí, torí ó dá mi lójú pé àwọn òbí mi ò kórìíra mi.”—Éfé. 6:12.

4. Kí la kọ́ nínú ohun tí Jésù àti Sítéfánù ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

4 A ò kórìíra àwọn tó ń ta kò wá, kódà ó yẹ ká máa gbàdúrà fún wọn. (Mát. 5:44) A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù àti Sítéfánù. Nígbà táwọn ọmọ ogun Róòmù kan Jésù mọ́gi, Jésù gbàdúrà pé: “Baba, dárí jì wọ́n.” (Lúùkù 23:34) Ṣe ni Jésù bẹ Jèhófà pé kó dárí ji àwọn ọmọ ogun yẹn torí pé àṣẹ tí wọ́n pa fún wọn ni wọ́n ń tẹ̀ lé. Ó tún ṣeé ṣe kó máa bẹ Jèhófà pé kó dárí ji àwọn èrò tó ń pariwo pé kí wọ́n pa á, torí Jésù mọ̀ pé àwọn aṣáájú ìsìn tó jẹ́ ọ̀tá òun ló wà nídìí ọ̀rọ̀ náà. Ó mọ̀ pé àwọn èèyàn yẹn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe. Bákan náà, Sítéfánù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù bẹ Jèhófà pé kó dárí ji àwọn tó fẹ́ pa á. (Ìṣe 7:58-60) Ṣé Jèhófà dáhùn àdúrà Jésù àti ti Sítéfánù? Bẹ́ẹ̀ ni. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó fọwọ́ sí i pé kí wọ́n pa Jésù ló ronú pìwà dà, wọ́n nígbàgbọ́ nínú ẹ̀, wọ́n sì ṣèrìbọmi. (Ìṣe 2:36-41) Yàtọ̀ síyẹn, a mọ̀ pé ó kéré tán ọ̀kan lára àwọn tó fọwọ́ sí i pé kí wọ́n pa Sítéfánù, ìyẹn Sọ́ọ̀lù ará Tásù di Kristẹni, ó sì kábàámọ̀ gbogbo ìwà burúkú tó ti hù kó tó di Kristẹni.—1 Tím. 1:13.

Arákùnrin kan tí àpá wà lójú ẹ̀ ń gbàdúrà nínú yàrá ẹ̀wọ̀n tó wà, ẹ̀ṣọ́ kan sì dúró nítòsí.

Bíi ti Jésù àti Sítéfánù tí wọ́n gbàdúrà fáwọn tó ń ṣenúnibíni sí wọ́n, àwa náà lè gbàdúrà fáwọn tó ń ṣenúnibíni sí wa (Wo ìpínrọ̀ 4)


5. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí César?

5 Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà táwa náà bá gbà fáwọn tó ń ta kò wá lónìí. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí César tó ń gbé ní Fẹnẹsúélà. Bàbá ẹ̀ kórìíra àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gan-an. César sọ pé: “Ìyá dáadáa ni ìyá mi. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ire Ìjọba Ọlọ́run ló gbawájú láyé wọn, wọn ò pa bàbá mi tì rárá. Wọ́n kọ́ gbogbo wa pé ká máa bọ̀wọ̀ fún bàbá wa. Wọ́n tún kọ́ wa pé a gbọ́dọ̀ máa gbọ́ràn sí bàbá wa lẹ́nu àyàfi tí wọ́n bá sọ pé ká ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́.” Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, bàbá César bẹ̀rẹ̀ sí í yíwà pa dà. César sọ pé: “Lọ́jọ́ kan, mo gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà, mo wá bi Bàbá mi pé ṣé mo lè máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí wọ́n sọ pé mo lè máa kọ́ àwọn, inú mi dùn gan-an, kódà mi ò lè sọ bó ṣe rí lára mi.” Nígbà tó yá, bàbá César ṣèrìbọmi. Òótọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń ta kò wá ló máa ń yíwà pa dà, àmọ́ inú wa máa ń dùn gan-an táwọn kan lára wọn bá ṣe bẹ́ẹ̀ torí wọ́n rí i pé à ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn a sì níwà ọmọlúàbí. Torí náà, à ń fojú sọ́nà sí ìgbà tí Jèhófà, baba aláàánú àti “Onídàájọ́ gbogbo ayé,” máa fa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ wá sọ́dọ̀ ara ẹ̀.—Jẹ́n. 18:25.

6. Kí ni nǹkan míì tí Máàkù 13:13 sọ pé ó mú káwọn èèyàn kórìíra wa?

6 Wọ́n kórìíra wa torí orúkọ Jésù. Jésù sọ pé àwọn èèyàn máa kórìíra àwa Kristẹni tòótọ́ “nítorí orúkọ [òun].” (Ka Máàkù 13:13.) Àmọ́ kí ni “orúkọ” Jésù ṣàpẹẹrẹ? Ó ṣàpẹẹrẹ irú ẹni tó jẹ́ àti àṣẹ tó ní gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn èèyàn tó ń ṣàkóso làwọn tó kórìíra wa gbẹ́kẹ̀ lé dípò Jésù Kristi, ẹni tí Jèhófà ti yàn láti ṣàkóso. Jésù ti di Ọba Ìjọba Ọlọ́run látọdún 1914. Láìpẹ́, ó máa pa gbogbo ìjọba míì run torí wọ́n ń ta ko àṣẹ rẹ̀.

7-8. Kí ló ń mú káwọn èèyàn máa fi wa ṣe yẹ̀yẹ́? (Jòhánù 15:18-20) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

7 Wọ́n kórìíra wa torí a ò fìwà jọ àwọn èèyàn ayé. Jésù sọ pé àwọn èèyàn máa kórìíra àwa ọmọ ẹ̀yìn òun torí pé a “kì í ṣe apá kan ayé.” (Ka Jòhánù 15:18-20.) Bíi tàwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, a kì í ṣe bíi tàwọn èèyàn ayé tí wọ́n máa ń hùwàkiwà tí wọ́n sì máa ń sọ̀sọkúsọ. Ìyẹn sì ti mú kí wọ́n máa fi àwọn ará wa kan ṣe yẹ̀yẹ́ níbiṣẹ́ tàbí níléèwé. (1 Pét. 4:3, 4) Àmọ́, inú wa dùn pé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn kan lára àwọn tó ń ta kò wá máa ń yí èrò wọn pa dà. Wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wa torí ìpinnu tá a ṣe.

8 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ignacio tó ń gbé ní Central America. Nílé ìwé tó lọ, ọ̀pọ̀ ọdún ni olùkọ́ kan fi ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé ó máa ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì. Àmọ́ nígbà tó ku díẹ̀ kí Ignacio jáde nílé ìwé, olùkọ́ yẹn béèrè bó ṣe ń ṣe é tó fi ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwàkiwà làwọn ọmọ tó kù ń hù. Ignacio ṣàlàyé fún un pé àwọn òfin Ọlọ́run máa ń dáàbò bo òun, ìdí nìyẹn tóun fi máa ń pa wọ́n mọ́. Ó wá pe olùkọ́ náà wá sípàdé. Ó ya Ignacio lẹ́nu gan-an pé olùkọ́ náà wá. Ìfẹ́ táwọn ará fi hàn sí olùkọ́ náà wú u lórí débi pé àtìgbà yẹn ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé. Nígbà tó yá, àwọn èèyàn ṣenúnibíni sí olùkọ́ náà torí pé ó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ kò jẹ́ kíyẹn dá òun dúró, ó tẹ̀ síwájú, ó sì ṣèrìbọmi.

Fọ́tò: Àwòrán tó jẹ́ ká rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ignacio nílé ìwé. 1. Ó jókòó jẹ́ẹ́ nínú kíláàsì, olùkọ́ ẹ̀ sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ níwájú àwọn ọmọ ilé ìwé tó kù. 2. Nígbà tó yá, olùkọ́ náà ń tẹ́tí sí Ignacio bó ṣe ń bá a sọ̀rọ̀.

Bóyá ọmọdé ni wá tàbí àgbàlagbà, gbogbo wa lè fìgboyà sọ ohun tá a gbà gbọ́ (Wo ìpínrọ̀ 8)b


9-10. (a) Kí ni nǹkan míì tó mú káwa Kristẹni yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé? (b) Kí la kọ́ nínú ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe?

9 Ohun míì tó tún fi hàn pé a yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé ni pé a kì í dá sọ́rọ̀ òṣèlú àti ogun. (Jòh. 18:36) Bí Róòmù 13:1 ṣe sọ, a máa ń gbìyànjú láti pa òfin ìlú mọ́. Síbẹ̀, àwa Kristẹni kì í lọ́wọ́ sí òṣèlú. Torí náà, a kì í gbégbá ìbò, a kì í sì í dìbò. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀ tí Jésù ń ṣàkóso là ń tì lẹ́yìn. Ọ̀pọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n ti jù sẹ́wọ̀n torí ohun tá a gbà gbọ́. Síbẹ̀, àwọn ará wa tó wà lẹ́wọ̀n yìí ò dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró. Wọ́n fìwà jọ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó ṣì máa ń wàásù bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sé e mọ́lé, wọ́n sì tún fi sẹ́wọ̀n fún ọ̀pọ̀ ọdún. (Ìṣe 24:27; 28:16, 30) Ní gbogbo àsìkò yẹn, gbogbo àwọn tó bá fẹ́ gbọ́ ló máa ń wàásù fún, irú bí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n, àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́, àwọn gómìnà, àwọn ọba títí kan àwọn tó ń bá Olú Ọba Nero ti ìlú Róòmù ṣiṣẹ́.—Ìṣe 9:15.

10 Bákan náà lónìí, àwọn ará wa tó wà lẹ́wọ̀n máa ń wàásù fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ gbọ́, irú bí àwọn adájọ́, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n. Bí àpẹẹrẹ, ohun tó lé lọ́dún mẹ́fà ni arákùnrin kan lò lẹ́wọ̀n torí pé kò dá sọ́rọ̀ òṣèlú. Arákùnrin náà sọ pé òun ò wo àkókò tóun lò lẹ́wọ̀n yìí bíi pé wọ́n fìyà jẹ òun, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe lòun wò ó bíi pé Jèhófà ló rán òun níṣẹ́ láti lọ wá àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ó dájú pé inú wa máa dùn gan-an tí Jèhófà bá lò wá láti ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbọ́ ìhìn rere! (Kól. 4:3) Ẹ jẹ́ ká tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó lè fún wa láyọ̀ báwọn èèyàn tiẹ̀ kórìíra wa torí pé à ń sin Jèhófà.

OHUN TÓ LÈ MÁA FÚN WA LÁYỌ̀ BÁWỌN ÈÈYÀN TIẸ̀ KÓRÌÍRA WA

11. Báwo ni inúnibíni ṣe máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára? Sọ àpẹẹrẹ kan.

11 Báwọn èèyàn ṣe kórìíra wa fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì, Jèhófà sọ pé Sátánì àti ọmọ rẹ̀, ìyẹn àwọn tó ń tẹ̀ lé e máa kórìíra àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tó sì ń sìn ín. (Jẹ́n. 3:15) Nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù sọ ohun tó fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń ṣẹ. (Mát. 10:22; Máàkù 13:9-12; Lúùkù 6:22, 23; Jòh. 15:20) Àwọn míì tó kọ Bíbélì náà sì jẹ́rìí sí i. (2 Tím. 3:12; Jém. 1:2; 1 Pét. 4:12-14; Júùdù 3, 17-19) Torí náà, kì í yà wá lẹ́nu táwọn èèyàn bá kórìíra wá. Kódà, ṣe ni inú wa máa ń dùn pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ. Èyí jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Ọlọ́run tòótọ́ là ń sìn. Arábìnrin kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa sọ pé: “Nígbà tí mo ya ara mi sí mímọ́, mo mọ̀ pé bó pẹ́ bó yá, àwọn èèyàn á ṣenúnibíni sí mi. Torí náà, nígbà tí inúnibíni dé, ẹ̀rù ò bà mí, kò sì yà mí lẹ́nu.” Ọkọ ẹ̀ wà lára àwọn tó ta kò ó. Ó fojú ẹ̀ rí màbo, ó sì dáná sun Bíbélì àtàwọn ìwé tó fi ń kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ dípò kí arábìnrin yìí rẹ̀wẹ̀sì, ṣe ni ìgbàgbọ́ ẹ̀ túbọ̀ lágbára. (Héb. 10:39) Ó sọ pé: “Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣenúnibíni sí wa, torí náà kò bá mi lójijì. Ṣe ló jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé ẹ̀sìn tòótọ́ ni mò ń ṣe.”

12. Kí ló jẹ́ kí arákùnrin kan lè fara da inúnibíni?

12 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a mọ̀ pé wọ́n máa ṣenúnibíni sí wa, kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti fara dà á. Nígbà tí Arákùnrin kan sọ̀rọ̀ nípa àkókò tó lò lẹ́wọ̀n, ó ní: “Nígbà míì, mo máa ń ṣàníyàn, ìrẹ̀wẹ̀sì sì máa ń bá mi débi pé ṣe ni màá bú sẹ́kún.” Kí ló jẹ́ kí arákùnrin yìí lè fara dà á? Ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń gbàdúrà. Tí mo bá jí, àdúrà ni mo máa ń kọ́kọ́ gbà. Tí ohunkóhun bá sì ń kó mi lọ́kàn sókè, màá tún gbàdúrà. Tí inú bá bí mi nítorí ìwà tí ò dáa táwọn èèyàn hù sí mi, ṣe ni màá ti ara mi mọ́ inú balùwẹ̀, màá sì gbàdúrà.” Arákùnrin yìí tún máa ń ronú nípa àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ nígbà àtijọ́ àti lóde òní. Ìyẹn jẹ́ kó lè fara dà á, kó sì ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn tí Jésù ṣèlérí fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀.—Jòh. 14:27; 16:33.

13. Kí lá jẹ́ ká lè fara dà á táwọn èèyàn bá kórìíra wa?

13 Ìfẹ́ máa ń jẹ́ ká lè fara dà á táwọn èèyàn bá kórìíra wa. Jésù fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Bàbá òun tọkàntọkàn títí tó fi kú. Ó tún nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Jòh. 13:1; 15:13) Táwa náà bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn ará wa dénú, àá lè fara dà á táwọn èèyàn bá kórìíra wa. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.

14. Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù jẹ́ olóòótọ́ bó tiẹ̀ mọ̀ pé wọ́n máa pa òun?

14 Kí wọ́n tó pa Pọ́ọ̀lù, ó kọ lẹ́tà sí Tímótì ọ̀rẹ́ ẹ̀, ó sọ fún un pé: “Ọlọ́run kò fún wa ní ẹ̀mí ojo, àmọ́ ó fún wa ní ẹ̀mí agbára àti ti ìfẹ́.” (2 Tím. 1:7) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn? Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé tí Kristẹni kan bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú, ìyẹn á jẹ́ kó lè fara da ìṣòro tó le gan-an. (2 Tím. 1:8) Kò sí àní-àní pé bí Pọ́ọ̀lù ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú ló mú kó nígboyà, kó sì jẹ́ olóòótọ́ bó tiẹ̀ mọ̀ pé wọ́n máa pa òun.—Ìṣe 20:22-24.

15. Báwo làwọn ará wa ṣe ń fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn síra wọn lákòókò yìí? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 A nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa tí wọn ò bọ́hùn lójú àtakò àti inúnibíni. Kódà, bíi ti Ákúílà àti Pírísílà tó fẹ̀mí ara wọn wewu nítorí Pọ́ọ̀lù, àwọn ará wa kan máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè torí ẹ̀ ṣe inúnibíni sáwọn náà. (Róòmù 16:3, 4) Bí àpẹẹrẹ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ọ̀pọ̀ ti lọ sílé ẹjọ́ kí wọ́n lè lọ fún àwọn ará táwọn ọlọ́pàá mú níṣìírí. Nígbà tí arábìnrin kan táwọn ọlọ́pàá mú rí ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n wá dúró tì í nílé ẹjọ́, ẹnu yà á débi pé kò mọ ohun tó fẹ́ sọ. Ìfẹ́ tòótọ́ táwọn ará fi hàn sí i bọ́ sákòókò, ìyẹn sì mú kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ lágbára. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ìfẹ́ táwọn ará wa ń fi hàn máa ń múnú wa dùn gan-an, ó sì ń jẹ́ ká lè fara dà á táwọn èèyàn bá kórìíra wa!

Àwọn ọlọ́pàá ń mú arábìnrin kan lọ sínú mọ́tò, àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin sì ń pàtẹ́wọ́ fún un.

Kódà láwọn ibi tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣì máa ń fìfẹ́ hàn síra wọn (Wo ìpínrọ̀ 15)c


16. Kí nìdí tí àpọ́sítélì Pétérù fi sọ pé a lè láyọ̀ tá a bá fara da àtakò torí pé à ń sin Jèhófà? (1 Peter 4:14)

16 A mọ̀ pé tá a bá fara da ìkórìíra, inú Ọlọ́run máa dùn sí wa. (Ka 1 Pétérù 4:14.) Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé a lè láyọ̀ tá a bá fara da àtakò torí pé à ń sin Jèhófà. Kí nìdí? Ìdí ni pé bí wọ́n ṣe kórìíra wa fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run “ti bà lé [wa].” Pétérù náà ti fara da ọ̀pọ̀ àtakò, ó sì mọ bó ṣe máa ń rí tínú Jèhófà bá dùn sẹ́nì kan. Lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì 33 S.K., àwọn ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì lọ mú Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì tó kù torí pé wọ́n ń wàásù. Àmọ́ Pétérù ò bẹ̀rù, ṣe ló fìgboyà sọ ohun tó gbà gbọ́. (Ìṣe 5:24-29) Kódà lẹ́yìn tí wọ́n nà wọ́n, òun àtàwọn àpọ́sítélì tó kù ò dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni inú wọn ń dùn torí pé “a ti kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ Jésù.” Àwa náà lè máa láyọ̀ bá a tiẹ̀ ń fara da àtakò.—Ìṣe 5:40-42.

17. Kí ni Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lálẹ́ tó ṣáájú ikú ẹ̀?

17 Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ mi, Baba mi máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, èmi náà máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” (Jòh. 14:21) À ń fojú sọ́nà de ìgbà tí kò ní sẹ́ni tó máa kórìíra wa mọ́ torí pé à ń sin Jèhófà! (2 Tẹs. 1:6-8) Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀, ká sì máa rántí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú ká máa yọ̀, kínú wa sì máa dùn báwọn èèyàn tiẹ̀ kórìíra wa.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí nìdí táwọn èèyàn fi kórìíra àwa ọmọ ẹ̀yìn Jésù?

  • Báwo ni ìfẹ́ ṣe máa ń jẹ́ ká fara da ìkórìíra?

  • Kí ló lè máa fún wa láyọ̀ báwọn èèyàn tiẹ̀ kórìíra wa?

ORIN 149 Orin Ìṣẹ́gun

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Àwòrán tó jẹ́ ká rí ibi tí Ignacio ti ń wàásù fún olùkọ́ ẹ̀.

c ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Àwòrán tó jẹ́ ká rí báwọn ará ṣe dúró ti arábìnrin kan tí wọ́n ń mú lọ sẹ́wọ̀n torí ohun tó gbà gbọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́