ÀWỌN TÍ BÍBÉLÌ SỌ̀RỌ̀ WỌN
Jẹ́ Onígboyà àti Olóòótọ́ Bíi Ti Bẹnáyà
Jagunjagun tó nígboyà ni Bẹnáyà, ó sì bá Ọba Dáfídì àti Sólómọ́nì ṣiṣẹ́. Àlùfáà ni bàbá Bẹnáyà, àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì kì í lo ohun ìjà ogun tàbí kí wọ́n jagun. Síbẹ̀ Bẹnáyà náà kópa nínú àwọn ogun tí wọ́n jà fún Jèhófà, ìyẹn sì fi hàn pé ó nígboyà gan an. Bí àpẹẹrẹ, ó wọnú kòtò omi ó sì pa kìnnìún kan síbẹ̀, yàtọ̀ síyẹn ó pa ọmọ ogun kan tó tóbi fàkìàfakia. Torí pé Dáfídì fọkàn tán Bẹnáyà, ó fi ṣe olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.—2 Sám. 23:20-23.
Bẹnáyà dúró ti Dáfídì nígbà tí Ábúsálómù àti Ádóníjà dìtẹ̀ mọ́ ọn. (2 Sám. 8:18; 15:18; 1 Ọba 1:8) Nígbà tí Dáfídì sì darúgbó, Bẹnáyà ràn án lọ́wọ́ kó lè fi Sólómọ́nì jọba. (1 Ọba 1:32-40) Bẹnáyà jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àtàwọn tó yàn sípò báwọn míì ò tiẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.
Ó yẹ káwa náà nígboyà ká lè kojú Sátánì ọ̀tá wa àtàwọn tó ń tì í lẹ́yìn. Ó tún yẹ ká pinnu pé ohun tí Jèhófà fẹ́ làá máa ṣe láyé wa. (Éfé. 6:11; 1 Pét. 5:8, 9) Kódà táwọn kan bá tiẹ̀ sọ pé àwọn ò sin Jèhófà mọ́, àwa ò ní fi Jèhófà sílẹ̀ torí ó dá wa lójú pé ó máa san wá lérè.—2 Sám. 22:26.