Ǹjẹ́ O Rántí?
Nígbà tó o ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lọ́dún yìí, ṣó o gbádùn ẹ̀? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa yin Jèhófà lógo?
Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún un, a sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ tọkàntọkàn. Bákan náà, tá a bá ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́, à ń yìn ín lógo nìyẹn.—w25.01, ojú ìwé 3.
Tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn wá, kí ló máa jẹ́ kó túbọ̀ yá wa lára láti dárí ji ẹni náà?
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà ti kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ, á dá a kó o wá nǹkan ṣe sí i. Yàtọ̀ síyẹn, tá ò bá di àwọn tó ṣẹ̀ wá sínú, kò ní jẹ́ ká foró yaró.—w25.02, ojú ìwé 15-16.
Báwo ni Máàkù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa fáwọn ọ̀dọ́kùnrin?
Máàkù múra tán láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n gbé fún un. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe dun Máàkù, kò sọ pé òun ò ní ran àwọn ará lọ́wọ́ mọ́. Nígbà tó yá, Máàkù àti Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú àwọn Kristẹni míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn pa dà di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, wọ́n sì jọ ń ṣiṣẹ́ Ọlọ́run.—w25.04, ojú ìwé 27.
Kí ni Jésù ń sọ nígbà tó gbàdúrà pé: “Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ?” (Jòhánù 17:26)
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti mọ̀ pé Jèhófà lorúkọ Ọlọ́run. Àmọ́ Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, àwọn nǹkan tó ti ṣe àtàwọn ànímọ́ ẹ̀ títí kan ohun tó fẹ́ ṣe fáráyé.—w25.05, ojú ìwé 20-21.
Tá a bá nírẹ̀lẹ̀, àǹfààní wo la máa rí?
Á jẹ́ ká gbà pé kì í ṣe gbogbo nǹkan la mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, a ò mọ ìgbà tí òpin máa dé, a ò sì mọ bí Jèhófà ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà yẹn. Bákan náà, a ò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́la. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà mọ̀ wá ju bá a ṣe mọ ara wa lọ.—w25.06, ojú ìwé 15-18.
Báwo la ṣe lè jàǹfààní àwọn àpilẹ̀kọ ètò Ọlọ́run àtàwọn àsọye tá a máa ń gbọ́?
O lè bi ara ẹ pé: ‘Àwọn nǹkan wo ló wà níbẹ̀ tó máa jẹ́ káwọn èèyàn gbà pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ làwọn gbọ́? Ṣé àpèjúwe kan wà tí mo lè lò tí mo bá fẹ́ kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́? Ta ló máa fẹ́ mọ ẹ̀kọ́ náà?’—w25.07, ojú ìwé 19.
Kí la kọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe ń dárí jini nínú ìtàn Dáfídì?
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì dẹ́ṣẹ̀ ńlá, nígbà tó ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà dárí jì í. (1 Ọba 9:4, 5) Tí Jèhófà bá dárí jì wá, kò tún ní fìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà jẹ wá mọ́, kò sì ní fi dá wa lẹ́jọ́ tó bá yá.—w25.08, ojú ìwé 17.
Tó o bá rí i pé ohun kan ò yé ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí ló yẹ kó o ṣe?
Tó o bá rí i pé nǹkan kan ò yé ẹni náà lẹ́yìn tó o ti fi Bíbélì ṣàlàyé fún un dáadáa, ẹ fi apá ibẹ̀ sílẹ̀, kẹ́ ẹ wá ṣètò bẹ́ ẹ ṣe máa pa dà sórí ẹ̀ tó bá yá.—w25.09, ojú ìwé 24.
Kí ni Bíbélì ń sọ nígbà tó ní ‘ẹ̀ṣẹ̀ lágbára láti tàn wá jẹ’? (Héb. 3:13)
Àìpé tá a jogún lè mú ká dẹ́ṣẹ̀ ńlá. Bákan náà, ó lè mú ká máa ronú léraléra pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa.—w25.10, ojú ìwé 16.
Àwọn nǹkan mẹ́ta wo la lè ṣe táá jẹ́ ká máa gbàdúrà látọkàn wá?
(1) Máa ronú nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà. (2) Ronú nípa ìṣòro tó ò ń bá yí, kó o sì sọ ọ́ fún Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá rí i pé ó yẹ kó o dárí ji ẹnì kan, o lè gbàdúrà nípa ẹ̀. (3) Má ṣe kánjú gbàdúrà. Tá a bá jẹ́ kí àdúrà wa gùn, àá lè sọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa fún Jèhófà.—w25.10, ojú ìwé 19-20.
Báwo la ṣe lè ran àwọn arúgbó lọ́wọ́?
A lè lọ kí wọn nílé tàbí ká pè wọ́n lórí fóònù. Yàtọ̀ síyẹn, tí wọ́n bá fẹ́ lọ rí dókítà, a lè tẹ̀ lé wọn lọ. O tún lè ṣètò bẹ́ ẹ ṣe jọ máa wàásù lónírúurú ọ̀nà.—w25.11, ojú ìwé 6-7.
Àwọn nǹkan wo ló yẹ kí Kristẹni kan ṣe kó lè bọlá fún Jèhófà lọ́jọ́ ìgbéyàwó ẹ̀?
Tẹ̀ lé òfin ìjọba lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó. Ohun tó bójú mu tó sì buyì kún ètò náà ni kẹ́ ẹ ṣe, kó lè hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń darí yín. Aṣọ tó bójú mu ni kẹ́ ẹ wọ̀, kẹ́ ẹ sì rí i dájú pé ẹ yẹra fún àwọn àṣà tí ò bá ìlànà Bíbélì mu. Bákan náà, tẹ́ ẹ bá ń múra ìgbéyàwó yín sílẹ̀, ẹ jọ sọ̀rọ̀ dáadáa nípa bí ètò náà ṣe máa lọ.—w25.12, ojú ìwé 21-24.