ÀPILẸ̀KỌ 51
ORIN 132 A Ti Di Ọ̀kan Ṣoṣo
Ohun Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Bọlá fún Jèhófà Lọ́jọ́ Ìgbéyàwó Ẹ
“Ẹ jẹ́ kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó bójú mu àti létòlétò.”—1 KỌ́R. 14:40.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Bí tọkọtaya ṣe lè bọlá fún Jèhófà kí wọ́n sì ṣohun táá múnú ẹ̀ dùn lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn.
1-2. Báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ kọ́jọ́ ìgbéyàwó ẹ rí?
ṢÉ Ẹ ti mú ọjọ́ ìgbéyàwó yín? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a bá yín yọ̀ o, ẹ kú ìpalẹ̀mọ́! Ó ṣeé ṣe kó o ti máa ṣètò bí nǹkan ṣe máa lọ lọ́jọ́ ìgbéyàwó ẹ. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Jèhófà náà fẹ́ kọ́jọ́ ìgbéyàwóa ẹ dùn, kẹ́yin méjèèjì sì bára yín kalẹ́?—Òwe 5:18; Orin Sól. 3:11.
2 Ó ṣe pàtàkì ká bọlá fún Jèhófà lọ́jọ́ ìgbéyàwó wa. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Kí la sì lè ṣe táá fi hàn pé a bọlá fún Jèhófà lọ́jọ́ náà? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn méjì tó ń múra ìgbéyàwó la darí àpilẹ̀kọ yìí sí, àwọn ìlànà tá a máa jíròrò lè ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti bọlá fún Jèhófà, bóyá wọ́n pè wá síbi ìgbéyàwó náà tàbí wọ́n ní ká gba àwọn nímọ̀ràn nípa ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe níbẹ̀.
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÓ O BỌLÁ FÚN JÈHÓFÀ LỌ́JỌ́ ÌGBÉYÀWÓ Ẹ?
3. Kí ló yẹ káwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó fi sọ́kàn bí wọ́n ṣe ń múra ìgbéyàwó wọn, kí sì nìdí?
3 Ó ṣe pàtàkì káwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà tó wà nínú Bíbélì bí wọ́n ṣe ń múra ìgbéyàwó wọn. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀. Òun ló ṣètò ìgbéyàwó àkọ́kọ́, èyí tó fi so Ádámù àti Éfà pọ̀ di tọkọtaya. (Jẹ́n. 1:28; 2:24) Torí náà, ó yẹ káwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó rí i pé ohun tó máa múnú Jèhófà dùn làwọn máa ṣe lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn.
4. Kí nìdí míì tó fi yẹ káwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó bọlá fún Jèhófà lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn?
4 Ìdí míì tó ṣe pàtàkì tó fi yẹ kó o bọlá fún Jèhófà kó o sì múnú ẹ̀ dùn lọ́jọ́ ìgbéyàwó ẹ ni pé, Jèhófà ni Bàbá rẹ ọ̀run, òun náà sì ni Ọ̀rẹ́ tó dáa jù tó o ní. (Héb. 12:9) Ó dájú pé o ò ní fẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Torí náà, o ò ní fẹ́ kí ohunkóhun ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ìgbéyàwó ẹ tàbí lọ́jọ́ míì táá múnú bí Ọ̀rẹ́ rẹ ọ̀wọ́n yìí. (Sm. 25:14) Tó o bá ronú nípa gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ àtohun tó ṣì máa ṣe fún ẹ, ó dájú pé wàá fẹ́ bọlá fún un, wàá sì fẹ́ múnú ẹ̀ dùn lọ́jọ́ ìgbéyàwó ẹ.—Sm. 116:12.
BÓ O ṢE LÈ BỌLÁ FÚN JÈHÓFÀ
5. Báwo ni ìlànà Bíbélì ṣe lè ran àwọn tó ń ṣètò ìgbéyàwó wọn lọ́wọ́?
5 Bíbélì ò fún wa láwọn òfin jànràn-janran nípa ohun tó yẹ ká ṣe níbi ètò ìgbéyàwó tàbí níbi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu tá a máa ṣe lẹ́yìn ètò náà. Àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó ló máa pinnu bí ìgbéyàwó wọn ṣe máa rí, ìpinnu náà lè dá lórí àṣà ìbílẹ̀ wọn, bí nǹkan ṣe rí fún wọn àtohun tó wù wọ́n. Àwa Kristẹni tún máa ń tẹ̀ lé òfin tí ìjọba bá gbé kalẹ̀. (Mát. 22:21) Síbẹ̀, tá a bá fi ìlànà Bíbélì sílò nígbà tá à ń ṣètò ìgbéyàwó wa, a máa bọlá fún Jèhófà, a sì máa múnú ẹ̀ dùn. Torí náà, àwọn ìlànà Bíbélì wo ló yẹ kí wọ́n máa rántí?
6. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì káwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó tẹ̀ lé òfin tí ìjọba gbé kalẹ̀?
6 Tẹ̀ lé òfin ìjọba. (Róòmù 13:1, 2) Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ìjọba ti ṣe àwọn òfin kan táwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé. Torí náà, ó yẹ káwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó mọ òfin tí ìjọba gbé kalẹ̀ yìí. Tó o bá ní ìbéèrè èyíkéyìí lórí ohun tí ìjọba fẹ́ kó o ṣe, o lè béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà.b
7. Kí lo lè ṣe láti buyì kún ètò ìgbéyàwó rẹ?
7 Ohun tó bójú mu, tó sì buyì kún ètò náà ni kẹ́ ẹ ṣe. (1 Kọ́r. 10:31, 32) Jẹ́ kó hàn níbi ìgbéyàwó ẹ pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń darí ẹ dípò kẹ́ ẹ máa ṣe àwọn nǹkan tó ń gbé ẹ̀mí ayé lárugẹ. (Gál. 5:19-26) Bí Bíbélì ṣe sọ, ọkọ ni orí aya. Torí náà, ọwọ́ ọkọ ìyàwó ló wà láti rí i dájú pé àwọn nǹkan tó bójú mu ni wọ́n ṣe níbi ètò ìgbéyàwó náà. Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe é? Kí ẹni tó fẹ́ sọ àsọyé ìgbéyàwó tó dá lórí Bíbélì sọ ọ́ lọ́nà tó tuni lára, kó má sì sọ̀rọ̀ tàbí dápàárá tó ń kọni lóminú, ìyẹn á jẹ́ káwọn tó ń gbọ́ túbọ̀ mọyì ètò ìgbéyàwó tí Ọlọ́run ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó wá síbi ìgbéyàwó náà á kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n á sì rí i pé ìgbéyàwó kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré. Torí náà, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó fẹ́ ṣègbéyàwó máa ń fẹ́ kí wọ́n sọ àsọyé náà nínú Ilé Ìpàdé wa tó bá ṣeé ṣe. Tó o bá fẹ́ lo Ilé Ìpàdé, á dáa kó o tètè kọ̀wé sí ìgbìmọ̀ alàgbà ọ̀kan lára ìjọ tó ń lo Ilé Ìpàdé náà nígbà tí ọjọ́ ìgbéyàwó náà ṣì jìn.
8. Kí ni ò ní jẹ́ kẹ́ ẹ ṣàṣejù níbi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu ìgbéyàwó yín? (Róòmù 13:13)
8 Ka Róòmù 13:13. Tó o bá fẹ́ ṣe àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu níbi ìgbéyàwó rẹ, kí lo lè ṣe tí ò fi ní dà bíi tàwọn èèyàn ayé? Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “àríyá aláriwo” ń tọ́ka sí àwọn àríyá tí wọ́n ti ń mutí àmujù, tí wọ́n sì ń kọrin títí dòru. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ “wild parties” tó wà ní Róòmù 13:13 nínú nwtsty-E.) Tẹ́ ẹ bá máa fún àwọn èèyàn ní ọtí, ẹ rí i dájú pé ẹ ṣe àwọn ètò tí ò ní jẹ́ káwọn èèyàn mu àmujù.c Tí orin bá máa wà níbẹ̀, ẹ rí i dájú pé ohùn ẹ̀ ò lọ sókè lala, kí àwọn tó wá lè máa bára wọn sọ̀rọ̀ láìjẹ́ pé ariwo orin náà máa dí wọn lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ fara balẹ̀ yan àwọn orin tẹ́ ẹ máa gbọ́ níbẹ̀, kẹ́ ẹ sì rí i dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọsẹ̀.
9. Kí ló yẹ káwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó fi sọ́kàn nípa àwọn tó máa sọ̀rọ̀ ṣókí àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n fẹ́ fi dá àwọn èèyàn lára yá?
9 Ṣé àwọn kan máa sọ̀rọ̀ ṣókí, àbí ẹ máa fi fọ́tò, fídíò tàbí àwọn nǹkan míì dá àwọn èèyàn lára yá níbi ayẹyẹ náà? Àwọn nǹkan yìí wà lára ohun tó lè mú kí ọjọ́ náà ṣàrà ọ̀tọ̀. Àmọ́, ẹ rí i dájú pé ohun tó máa gbé àwọn èèyàn ró lẹ ṣe níbẹ̀. (Fílí. 4:8) Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé ohun tá a fẹ́ ṣe yìí máa fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn? Ṣé ó máa buyì kún ètò ìgbéyàwó náà?’ Ohun tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ kó o bi ara ẹ ni pé: ‘Ṣé ó máa bọlá fún Jèhófà?’ Òótọ́ ni pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn ṣàwàdà, àmọ́ a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé a ò ṣe àwọn àwàdà táá mú káwọn èèyàn máa ronú nípa ìbálòpọ̀. (Éfé. 5:3) Bákan náà, jẹ́ kí àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n fẹ́ sọ̀rọ̀ ṣókí mọ ohun tó o fẹ́ àtohun tí o ò fẹ́.
10. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó mọ̀wọ̀n ara wọn? (1 Jòhánù 2:15-17)
10 Mọ̀wọ̀n ara ẹ. (Ka 1 Jòhánù 2:15-17.) Inú Jèhófà máa ń dùn táwa ìránṣẹ́ ẹ̀ bá fògo fún un dípò ká máa wá ògo fún ara wa. Torí náà, àwọn Kristẹni tó mọ̀wọ̀n ara wọn ò ní náwó rẹpẹtẹ torí wọ́n fẹ́ ṣe “àṣehàn” tàbí ṣekárími. Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ṣe-bó-o-ti-mọ, tí o ò sì ṣe ìgbéyàwó náà ní aláriwo? Ó ṣeé ṣe kọ́rọ̀ ẹ dà bíi ti Arákùnrin Mike tó ń gbé ní Norway. Ó sọ pé: “A ò jẹ gbèsè rárá, ìyẹn sì jẹ́ ká lè máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà lọ. A ò ṣe ìgbéyàwó wa ní aláriwo, síbẹ̀ a gbádùn ẹ̀ gan-an, inú wa sì máa ń dùn tá a bá ń rántí ọjọ́ náà.” Arábìnrin Tabitha tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Íńdíà sọ pé: “Torí pé a ò ṣe ìgbéyàwó wa ní aláriwo, ìwọ̀nba ni nǹkan tá a ṣètò. Torí náà, kò sóhun tá a fẹ́ máa bára wa fà, ìyẹn ò sì jẹ́ ká kó nǹkan tó pọ̀ sọ́kàn.”
Ibi yòówù ká máa gbé, àwa Kristẹni lè ṣe ìgbéyàwó tí kò lariwo lọ, ká gbádùn ẹ̀ dáadáa, ká sì máa rántí ọjọ́ náà sí rere (Wo ìpínrọ̀ 10-11)
11. Irú aṣọ wo ló yẹ káwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó wọ̀ lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
11 Ṣé ẹ ti mọ aṣọ tẹ́ ẹ fẹ́ wọ̀ lọ́jọ́ ìgbéyàwó yín? Kò sí àní-àní pé aṣọ tó dùn-ún wò, tó sì máa gbé ẹwà yín yọ lẹ máa fẹ́ wọ̀. Kódà láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó kì í fọ̀rọ̀ ìrísí wọn ṣeré. (Àìsá. 61:10) Òótọ́ ni pé aṣọ tó o máa wọ̀ lọ́jọ́ ìgbéyàwó ẹ lè yàtọ̀ sí èyí tó o sábà máa ń wọ̀ lọ sáwọn òde míì, síbẹ̀ ó yẹ kó bójú mu. (1 Tím. 2:9) Kò yẹ kó jẹ́ aṣọ tó o wọ̀ tàbí àwọn nǹkan tara míì ló máa gbàfiyèsí jù lọ́jọ́ ìgbéyàwó ẹ.—1 Pét. 3:3, 4.
12. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó yẹra fún àwọn àṣà tí kò bá ìlànà Bíbélì mu táwọn èèyàn ń lọ́wọ́ sí ládùúgbò wọn?
12 Yẹra fáwọn àṣà tí ò bá ìlànà Bíbélì mu. (Ìfi. 18:4) Ọ̀pọ̀ àwọn àṣà tí ò bá ìlànà Bíbélì mu, àwọn ẹ̀kọ́ èké àti ìbẹ́mìílò làwọn èèyàn ń gbé lárugẹ níbi ìgbéyàwó wọn, Sátánì ló sì wà nídìí ẹ̀. Jèhófà kìlọ̀ fún wa pé ká sá fún irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. (2 Kọ́r. 6:14-17) Tí àwọn èèyàn bá ń lọ́wọ́ sí àwọn àṣà kan tó ń kọni lóminú níbi tó ò ń gbé, fara balẹ̀ ṣèwádìí nípa ibi tí àṣà náà ti wá àtàwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o tó pinnu bóyá wàá ṣe é nígbà ìgbéyàwó ẹ.
13. Báwo làwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó ṣe lè fìwà jọ Jèhófà tó bá dọ̀rọ̀ ẹ̀bùn táwọn èèyàn mú wá?
13 Ṣé àwọn tó wá síbi ìgbéyàwó sábà máa ń fún tọkọtaya lẹ́bùn níbi tó ò ń gbé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, báwọn èèyàn bá ṣe lówó tó máa ń pinnu irú ẹ̀bùn tí wọ́n máa fún tọkọtìyàwó. Bíbélì gba àwa Kristẹni níyànjú pé ká máa fúnni, inú wa sì máa ń dùn tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀. (Òwe 11:25; Ìṣe 20:35) Àmọ́, kò yẹ ká ṣe ohun tó lè mú káwọn tó fẹ́ wá síbi ìgbéyàwó náà rò pé dandan ni káwọn mú ẹ̀bùn wá. Yàtọ̀ síyẹn, kò yẹ ká ṣe ohun tó lè mú kí ojú ti àwọn tí kò mú ẹ̀bùn tó jọjú wá fún wa. Ó yẹ ká fìwà jọ Jèhófà, ká mọyì ẹ̀bùn èyíkéyìí táwọn èèyàn bá fún wa, ká sì jẹ́ káwọn èèyàn fún wa ní ohun tágbára wọn bá ká, tó sì tinú wọn wá.—2 Kọ́r. 9:7.
OHUN TẸ́ Ẹ LÈ ṢE TÍ ÌṢÒRO BÁ YỌJÚ
14. Ìṣòro wo làwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó máa ń ní?
14 Àwọn ìṣòro kan lè yọjú bó o ṣe ń gbìyànjú láti ṣètò ìgbéyàwó ẹ kó lè bọlá fún Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ó lè má rọrùn fún ẹ láti ṣe ìgbéyàwó tí kò la ariwo lọ. Ẹ gbọ́ ohun tí Charlie tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Solomon Islands sọ, ó ní: “Nínú àṣà ìbílẹ̀ wa, wọ́n retí pé gbogbo ọ̀rẹ́ ẹ ló yẹ kó o pè tó o bá fẹ́ ṣe ìnáwó, ọ̀rẹ́ tá a ní sì pọ̀ gan-an. Torí náà, kò rọrùn láti pinnu àwọn tá a máa pè àtàwọn tá ò ní pè síbi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu ìgbéyàwó wa.” Tabitha tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Lágbègbè wa, táwọn èèyàn bá ń ṣe ayẹyẹ, wọ́n máa ń fẹ́ káyé gbọ́, kí ọ̀run mọ̀. Torí náà, kò rọrùn rárá fáwọn òbí wa láti fara mọ́ ìpinnu wa pé nǹkan bí ọgọ́rùn-ún (100) èèyàn péré la máa pè.” Sarah tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Íńdíà sọ pé: “Àwọn èèyàn kì í fẹ́ káwọn míì fojú yẹpẹrẹ wò wọ́n. Nígbà táwọn mọ̀lẹ́bí mi kan ṣègbéyàwó, wọ́n filé pọntí fọ̀nà rokà. Torí náà, nígbà témi náà fẹ́ ṣègbéyàwó, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í fúngun mọ́ wa pé ká ṣe é kó ju tiwọn lọ.” Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí lágbègbè ẹ nìyẹn, kí lo lè ṣe láti borí ìṣòro yìí àtàwọn ìṣòro míì tó lè yọjú?
15. Kí nìdí tó fi yẹ kó o bẹ Jèhófà kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó o ṣe ń múra ìgbéyàwó ẹ sílẹ̀?
15 Bẹ Jèhófà kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó o ṣe ń múra sílẹ̀. O lè sọ ìṣòro èyíkéyìí tó o bá ní àti bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ fún Jèhófà. (Fílí. 4:6, 7 àti àlàyé ọ̀rọ̀ “in everything” nínú nwtsty-E.) O lè bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́ tàbí kó jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ tó o bá ń ṣàníyàn. O sì lè sọ fún un pé kó fún ẹ nígboyà láti dúró lórí ìpinnu tó o bá ṣe. (1 Pét. 5:7) Bó o ṣe ń rí bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà ẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ máa lágbára. Tabitha tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ọkàn èmi àti àfẹ́sọ́nà mi ò balẹ̀ torí pé a ò fẹ́ kọ́rọ̀ ìgbéyàwó wa fa wàhálà láàárín wa tàbí láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí wa. Ohun tá a wá ṣe ni pé, nígbàkigbà tá a bá fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ètò ìgbéyàwó wa, a máa ń kọ́kọ́ gbàdúrà. Torí náà, a rọ́wọ́ Jèhófà, gbogbo ètò náà sì lọ láìsí wàhálà kankan.”
16-17. Tẹ́ ẹ bá ń bára yín sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, báwo nìyẹn ṣe máa ràn yín lọ́wọ́ bẹ́ ẹ ṣe ń múra ìgbéyàwó yín?
16 Ẹ bá ara yín sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. (Òwe 15:22) Ọ̀pọ̀ ìpinnu lẹ máa ní láti ṣe nípa ìgbéyàwó yín. Bí àpẹẹrẹ, ẹ máa mú ọjọ́, ẹ máa pinnu iye tẹ́ ẹ máa ná, àwọn tẹ́ ẹ máa pè àtàwọn nǹkan míì. Àmọ́ kẹ́ ẹ tó ṣèpinnu, ẹ gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò dáadáa, kẹ́ ẹ wo àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn yín lọ́wọ́, kẹ́ ẹ sì ronú nípa ìmọ̀ràn táwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn fún yín. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí yín, ẹ fi ohùn jẹ́jẹ́ sọ̀rọ̀, kẹ́ ẹ sì gba tiwọn rò. Táwọn òbí yín tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí bá fẹ́ kẹ́ ẹ ṣe àwọn nǹkan kan, táwọn nǹkan ọ̀hún ò sì burú, á dáa kẹ́ ẹ gba tiwọn rò. Ẹ má gbàgbé pé bọ́jọ́ náà ṣe jẹ́ ọjọ́ ayọ̀ yín, ọjọ́ ayọ̀ ló jẹ́ fáwọn náà. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ẹ ò ní lè ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, ẹ fara balẹ̀ ṣàlàyé fún wọn. (Kól. 4:6) Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ohun tó jẹ yín lógún ni bí ọjọ́ náà ṣe máa dùn, táá sì bọlá fún Jèhófà.
17 Ó lè ṣòro láti ṣàlàyé ohun tẹ́ ẹ fẹ́ fáwọn òbí yín, pàápàá tó bá jẹ́ pé wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, fọkàn balẹ̀, o lè ṣàṣeyọrí. Arákùnrin Santhosh tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Íńdíà sọ pé: “Àwọn mọ̀lẹ́bí wa fẹ́ ká ṣe àwọn ààtò kan táwọn ẹlẹ́sìn Hindu máa ń ṣe níbi ìgbéyàwó. Kò rọrùn rárá fún wa láti ṣàlàyé pé a ò ní lè ṣe é, kódà ó pẹ́ gan-an kí wọ́n tó gbà pẹ̀lú wa. Ohun tá a wá ṣe ni pé a gbà láti ṣe àwọn nǹkan míì tí wọ́n fẹ́ àmọ́ tí ò ta ko ìlànà Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, a yí oúnjẹ tá a fẹ́ fún àwọn èèyàn pa dà sí èyí tí wọ́n fẹ́. A sì yọ orin àti ijó kúrò nínú ètò náà torí pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣàjèjì sí wọn.”
18. Kí ló máa jẹ́ kí gbogbo nǹkan lọ bó ṣe yẹ lọ́jọ́ ìgbéyàwó yín? (1 Kọ́ríńtì 14:40) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
18 Fara balẹ̀ ṣètò bí nǹkan ṣe máa lọ. Tó o bá ṣètò gbogbo nǹkan bó ṣe yẹ, ìyẹn á dín wàhálà ẹ kù lọ́jọ́ ìgbéyàwó ẹ. (Ka 1 Kọ́ríńtì 14:40.) Wayne tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Taiwan sọ pé: “Nígbà tó kù díẹ̀ kọ́jọ́ ìgbéyàwó wa pé, a ṣèpàdé ráńpẹ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn tó fẹ́ bá wa ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ náà. A sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ṣe máa rí lọ́jọ́ ìgbéyàwó náà, a sì fi dánra wò ká lè rí i dájú pé gbogbo nǹkan lọ bó ṣe yẹ.” Kẹ́ ẹ lè fi hàn pé ẹ bọ̀wọ̀ fáwọn tẹ́ ẹ pè wá síbi ayẹyẹ náà, ẹ ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe kí ètò náà lè bẹ̀rẹ̀ kó sì parí lásìkò.
Tẹ́ ẹ bá fara balẹ̀ ṣe àwọn ètò tó yẹ ṣáájú ọjọ́ ìgbéyàwó yín, ìyẹn á jẹ́ kí gbogbo nǹkan lọ bó ṣe yẹ (Wo ìpínrọ̀ 18)
19. Kí lo tún lè ṣe kó má bàa sí àṣejù níbi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu ìgbéyàwó rẹ?
19 Tó o bá ronú àwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kó o mọ ohun tó o lè ṣe táwọn ìṣòro kan bá yọjú. (Òwe 22:3) Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ń gbé níbi táwọn èèyàn ti máa ń lọ síbi ayẹyẹ tí wọn ò pè wọ́n sí, á dáa kó o ronú ohun tó o lè ṣe kíyẹn má bàa ṣẹlẹ̀ níbi ìgbéyàwó ẹ. Jẹ́ kí àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ bí ètò ìgbéyàwó náà ṣe máa lọ, àwọn nǹkan tẹ́ ẹ máa ṣe àtàwọn nǹkan tẹ́ ò ní ṣe. O lè fi àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Ìgbéyàwó Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Máa Ń Rí?” lórí jw.org ránṣẹ́ sí wọn. Kí gbogbo nǹkan lè lọ bó ṣe yẹ, á dáa kó o fi arákùnrin kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ ṣe “alága” àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu náà. (Jòh. 2:8) Tó o bá fara balẹ̀ ṣàlàyé ohun tó o fẹ́ fún arákùnrin náà dáadáa, á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dárí ètò náà lọ́nà táwọn èèyàn ò fi ní ṣàṣejù, kí gbogbo nǹkan sì lọ létòlétò bó o ṣe fẹ́.
20. Kí ló yẹ kí àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó máa rántí bí wọ́n ṣe ń múra ìgbéyàwó wọn sílẹ̀?
20 Tó o bá ronú nípa gbogbo ètò tó o máa ṣe láti múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó ẹ, ó lè kà ẹ́ láyà. Àmọ́, má gbàgbé pé ayẹyẹ ìgbéyàwó ẹ ò kọjá ọjọ́ kan ṣoṣo. Ọjọ́ náà sì lẹ̀yin méjèèjì á bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà pa pọ̀ torí pé ẹ ti di tọkọtaya báyìí. Ohun kan ni pé, kò dìgbà tó o bá filé pọntí fọ̀nà rokà níbi ìgbéyàwó ẹ kí ọjọ́ náà tó lè dùn, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí ayẹyẹ náà bọlá fún Jèhófà. Torí náà, fi ohun gbogbo lé Jèhófà lọ́wọ́. Tó o bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ẹ̀, ọjọ́ ìgbéyàwó ẹ̀ á dùn, á lóyin, wàá sì máa rántí ọjọ́ náà sí rere.—Sm. 37:3, 4.
ORIN 107 Ìfẹ́ Ọlọ́run Jẹ́ Àpẹẹrẹ fún Wa
a ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Lọ́pọ̀ ibi láyé, ohun tí wọ́n máa ń ṣe lọ́jọ́ ìgbéyàwó ni pé tọkọtaya á jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú Ọlọ́run pé àwọn ò ní fira wọn sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, àwọn kan máa ń ṣe àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu. Láwọn ibì kan, wọn kì í ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó tàbí àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu, síbẹ̀ tọkọtaya ṣì máa jàǹfààní tí wọ́n bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn.
b Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ojú táwa Kristẹni fi ń wo òfin ìjọba lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó, wo àpilẹ̀kọ náà “Ìgbéyàwó Tó Ní Ọlá Lójú Ọlọ́run àti Èèyàn” nínú Ilé Ìṣọ́ October 15, 2006.
c Wo fídíò náà Ṣó Yẹ Kí N Fún Àwọn Èèyàn Ní Ọtí Níbi Ìgbéyàwó Mi? lórí jw.org.