OHUN TÓ O LÈ KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍPA Ẹ̀
Jẹ́ Kó Túbọ̀ Dá Ẹ Lójú Pé Jèhófà Máa Gbà Ẹ́ Là
Ka Nọ́ńbà 13:25–14:4 kó o lè rí ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe tó fi hàn pé wọn ò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.
Bi ara ẹ láwọn ìbéèrè kan nípa ohun tó ò ń kà. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa gba àwọn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì? (Sm. 78:12-16, 43-53) Kí ló fà á tí wọn ò fi gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà mọ́? (Diu. 1:26-28) Kí ni Jóṣúà àti Kélẹ́bù ṣe tó fi hàn pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?—Nọ́ń. 14:6-9.
Kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀. Kí ló yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe tó máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? (Sm. 9:10; 22:4; 78:11) Tá a bá ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé e?—Nọ́ń. 14:11.
Wá àwọn ẹ̀kọ́ inú ẹ̀. Bi ara ẹ pé:
‘Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ táá fi hàn bóyá mo gbẹ́kẹ́ lé Jèhófà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́?’
‘Àwọn nǹkan wo ni mo lè máa ṣe táá fi hàn pé mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà báyìí àti lọ́jọ́ iwájú?’
‘Kí nìdí tí ò fi yẹ kí n bẹ̀rù tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀?’—Lúùkù 21:25-28.