CAROL APPLEBY | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Jèhófà Ràn Mí Lọ́wọ́ Kí N Lè Tọ́ Àwọn Ọmọ Mi Márààrún
Ìpínlẹ̀ North Yorkshire, lórílẹ̀-èdè England, nítòsí ìlú Malton ni mo gbé dàgbà. Òkè pọ̀ níbẹ̀, pápá lọ salalu, àwọn igi lóríṣiríṣi wà níbẹ̀, àwọn ọ̀nà tó ṣe kọ́lọkọ̀lọ, àwọn ilé tí wọ́n fi òkúta kọ́ àtàwọn abúlé tó rẹwà pọ̀ níbẹ̀. Torí náà, ó dáa gan-an pé ibẹ̀ ni mo ti tọ́ àwọn ọmọ mi márààrún dàgbà. Àmọ́ àwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ kó nira fún mi, ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé fún yín.
Mo ní ẹ̀gbọ́n méjì àti àbúrò méjì, inú oko kan ni gbogbo wa sì ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí wa. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn nǹkan tá a nílò la máa ń ní lóko wa. A ní adìyẹ, ẹlẹ́dẹ̀ àti màlúù. A máa ń ṣiṣẹ́ kára torí pé oko là ń gbé, àmọ́ a láyọ̀.
Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni mí níbí, mo wà nínú oko wa
Ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì là ń lọ. Bàbá mi mọrin kọ, torí náà wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ akọrin ṣọ́ọ̀ṣì wa, wọ́n tún máa ń lọ sáwọn ṣọ́ọ̀ṣì míì tó wà ládùúgbò láti kọrin, mo sì sábà máa ń tẹ̀ lé wọn. Òkúta ni wọ́n fi kọ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì náà, ó sì máa ń tutù gan-an nígbà òtútù. Bàbá mi máa ń dúró síwájú, wọ́n á sì máa kọrin. Àwọn èèyàn ńláńlá ló máa ń jókòó sáwọn ìjókòó tó wà níwájú, torí náà ẹ̀yìn ni mo máa ń jókòó sí. Síbẹ̀, ìyẹn ò ṣe mí ní nǹkan kan torí mo máa ń gbádùn ẹ̀ tí wọ́n bá ń kọrin.
Màmá àgbà ni mo máa ń pe màmá bàbá mi, gbogbo ọjọ́ Sunday ni wọ́n sì máa ń wá kí wa. Ó bà mí nínú jẹ́ pé wọ́n kú nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16). Mo fẹ́ mọ ibi tí wọ́n wà, mo sì fẹ́ mọ̀ bóyá màá pa dà rí wọn. Torí náà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo lọ sọ́dọ̀ ẹni tó ń woṣẹ́. Ilé ẹ̀ tutù, ó dúdú, ẹ̀rù sì máa ń bà mí tí mo bá lọ síbẹ̀. Mo ṣáà fẹ́ mọ ibi tí màmá àgbà wà, àmọ́ wọn ò lè sọ fún mi.
Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, mọ̀lẹ́bí bàbá mi kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní kí n wá sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo pinnu láti lọ bó tiẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi nǹkan ni mo ti gbọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nípàdé yẹn, obìnrin onínúure kan bí mi bóyá màá fẹ́ kóun máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í mọ Jèhófà nìyẹn o. Bíbélì King James Version ni mo kọ́kọ́ ń lò torí mo gba ohun tí mọ́mì mi sọ fún mi gbọ́ pé Bíbélì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò péye. Àmọ́ kò pẹ́ rárá tí mo fi rí i pé kò rí bẹ́ẹ̀.
Àwọn nǹkan tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì múnú mi dùn gan-an ní pàtàkì nígbà tí mo kọ́ pé màmá àgbà ń “sùn” nínú ibojì àti pé màá tún pa dà rí wọn nígbà àjíǹde!a Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, mo rí i pé mi ò mọ nǹkan kan nípa Ọlọ́run àti Bíbélì. Kódà, bàbá mi tó ti ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì fún ọ̀pọ̀ ọdún náà ò mọ nǹkan kan nípa Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ ìgbà la ti kọ orin “Fi Ìṣọ́ Rẹ Ṣọ́ Mi Ìwọ Jèhófà Títóbi,” àmọ́ a ò mọ nǹkan kan nípa ẹni tá à ń kọrin sí.
Mo Ṣègbéyàwó Àmọ́ Ọkọ Mi Ò Jẹ́ Kó Rọrùn Fún Mi Láti Sin Jèhófà
Ọ̀rẹ́kùnrin mi tó ń jẹ́ Ian nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun tó ń kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn débi pé kò mu sìgá mọ́. Nígbà tó sì di September 1971, a ṣègbéyàwó. Àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni ìyá ọkọ mi kú, àwọn nǹkan tó sì ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn dán ìgbàgbọ́ wa wò. Àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ wa fẹ́ ká dara pọ̀ mọ́ ètò àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu tí wọ́n ṣe fún ìsìnkú náà. Láwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣètò yìí, wọ́n máa ń mu sìgá, wọ́n sì máa ń mutí lámujù. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í wu Ian pé kóun náà lọ́wọ́ sáwọn nǹkan yẹn.
Ó dùn mí pé Ian pa dà sí ẹsẹ̀ àárọ̀ ẹ̀, kò sì fi nǹkan tó ń kọ́ sílò mọ́. Kò ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ déédéé mọ́, ó sì ń pa ìpàdé jẹ. Àmọ́ ní tèmi, mò ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ mi lọ, mo sì ń lọ sípàdé àti òde ìwàásù déédéé. Nígbà tó di March 9, 1972, mo ṣèrìbọmi, Ian tẹ̀ lé mi lọ lọ́jọ́ yẹn. Àmọ́ nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ kó nira fún mi láti jọ́sìn Jèhófà. Ibi tó ti bẹ̀rẹ̀ ni pé kò fẹ́ rí àwọn ìwé wa sójú. Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé mi ò gbọdọ̀ lọ sóde ìwàásù mọ́. Nígbà tó yá, ó ní kí n máa tẹ̀ lé òun lọ síbi tí wọ́n ti ń mutí lọ́jọ́ Kérésìmesì àti láwọn ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ojọ́ ìbí. Torí pé òun ni olórí ìdílé, mo sì fẹ́ bọ̀wọ̀ fún un, mo máa ń tẹ̀ lé e nígbà míì, àmọ́ mo pinnu pé mi ò ní ṣe ohunkóhun tínú Jèhófà ò dùn sí.b Mo máa ń lọ sílé ìgbọ̀nsẹ̀, màá sì gbàdúrà léraléra sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n má bàa ṣe ohunkóhun tó máa ba ìgbàgbọ́ mi jẹ́ tàbí tó máa da ẹ̀rí ọkàn mi láàmú. Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ràn mí lọ́wọ́.
Èmi àti Ian ní ọmọkùnrin mẹ́ta: Philip, Nigel àti Andrew. Ọkọ mi kì í sí nílé ní ọ̀pọ̀ ìgbà láàárín ọ̀sẹ̀ torí pé ó máa ń wa àwọn ọkọ̀ ńláńlá lọ sáwọn ìlú tó jìnnà. Mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti jẹ́ ìyàwó tó dáa, kí n sì tún fi gbogbo ọkàn mi sin Jèhófà. Mo máa ń lọ sóde ìwàásù tí ò bá sí nílé, mo sì máa ń dúró sílé láwọn òpin ọ̀sẹ̀ ká lè jọ wà pa pọ̀. Mo tún pinnu pé mi ò ní máa sọ̀rọ̀ ẹ̀ láìdáa níṣojú àwọn ọmọ wa.
Mo láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà nínú ìjọ, mo sì máa ń mú wọn dání tí mo bá lọ kí màmá mi àti bàbá mi. Nígbà tó yá, àwọn òbí mi bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ wọn. Nígbà tí arákùnrin kan níjọ wa kú, màmá mi lọ síbi ètò ìsìnkú tí wọ́n ṣe fún un ní Ilé Ìpàdé wa. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, màmá mi, bàbá mi, ẹ̀gbọ́n mi àtìyàwó ẹ̀ tó ń jẹ́ Averil bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ṣèrìbọmi.
Ẹ̀gbọ́n mi Stanley àtìyàwó ẹ̀ ní ọmọbìnrin àti ọmọkùnrin kan. Inú èmi àti ìyàwó ẹ̀gbọ́n mi máa ń dùn láti lọ sóde ìwàásù pẹ̀lú àwọn ọmọ wa. Èmi àti Averil ò ní mọ́tò, torí náà ṣe la máa ń gbé àwọn ọmọ wa sínú kẹ̀kẹ́ tí wọ́n fi ń ti àwọn ọmodé tá a bá fẹ́ lọ wàásù níbi tó jìn, inú wa sì máa ń dùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Andrew la máa ń gbé sínú kẹ̀kẹ́, Nigel máa jókòó sórí ẹ̀, Philip máa ń rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ wa, á wá di kẹ̀kẹ́ náà mú.
Èmi, Philip, Nigel àti bàbá mi rèé níbi tá a dé sí nígbà tá a lọ fún àpéjọ agbègbè kan
Mo Kọ́ Àwọn Ọmọ Mi Nípa Jèhófà
Nígbà tó yá mo tún bímọ méjì: Caroline àti Debbie. Mo ti pinnu pé màá kọ́ àwọn ọmọ mi nípa Jèhófà kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, kí wọ́n sì jọ́sìn ẹ̀. Mo fẹ́ ṣe gbogbo ohun tí Bíbélì sọ pé káwọn òbí máa ṣe. Mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, mo sì fẹ́ káwọn ọmọ mi mọ̀ pé mi ò ní yẹ àdéhùn tí mo bá Jèhófà ṣe yẹn, torí náà gbogbo ìgbà ni mo máa ń sapá láti ṣe nǹkan lọ́nà tí Jèhófà fẹ́.
Ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tí mo kọ́kọ́ há sórí ni 1 Kọ́ríńtì 15:33, tó sọ pé: “Ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà rere jẹ́.” Ní àpéjọ kan tá a lọ, arábìnrin kan sọ pé òun gba àwọn ọmọ òun níyànjú pé kí wọ́n má bá àwọn ọmọ ilé ìwé wọn ṣeré lẹ́yìn ilé ìwé. Èmi náà gbìyànjú ẹ̀, àmọ́ kò rọrùn! Nígbà míì, àwọn ọmọkùnrin mi máa ń yọ́ lọ gbá bọ́ọ̀lù pẹ̀lú àwọn ọmọ àdúgbò. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ilé ìwé wọn ló níwà tó dáa, àmọ́ wọn ò sin Jèhófà. Ìyẹn sì máa ń hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn.
Ìgbà kan wà tí mo sọ fáwọn ọmọ mi pé tí wọ́n bá fẹ́ gbá bọ́ọ̀lù lẹ́yìn ilé ìwé, a jọ máa gbá a. Àmọ́ mi ò rí i ṣe torí mi ò mọ bọ́ọ̀lù gbá. Síbẹ̀, mò ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti jẹ́ káwọn ọmọ mi rí i pé àwọn tó ń sin Jèhófà ló yẹ kí wọ́n mú lọ́rẹ̀ẹ́. Nígbà tó sì yá, wọ́n rí àwọn eré ìnàjú tí wọ́n lè máa ṣe láìjẹ́ pé wọ́n bá àwọn tí ò sin Jèhófà kẹ́gbẹ́.
Ẹsẹ Bíbélì míì tó tún sábà máa ń wá sí mi lọ́kàn ni 1 Jòhánù 2:17 tó sọ pé: “Ayé ń kọjá lọ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló máa wà títí láé.” Mo mọ̀ pé ayé Sátánì máa kọjá lọ, mo sì fẹ́ káwọn ọmọ mi láwọn àfojúsùn tó máa jẹ́ kí wọ́n sún mọ́ Jèhófà dáadáa, kí wọ́n sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ títí láé. Tí mo bá níṣòro, mo máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́, mo sì máa ń rí ìmọ̀ràn tó máa ṣe mí láǹfààní nínú Bíbélì. Tí mo bá fi ohun tí Bíbélì sọ hàn wọ́n, wọ́n máa ń rí i pé kì í ṣe èmi ni mò ń bá wọn sọ̀rọ̀, Jèhófà ni. Kì í ṣe ohun tí mò ń sọ fún wọn nìkan ni mo fi ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n tún máa ń rí i nínú ìwà mi, àwọn náà sì ń ṣe dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, àtikékeré ni gbogbo wọn ti ní ìpadàbẹ̀wò, ìyẹn máa ń fún wọn láyọ̀, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n fẹ́ lọ sóde ìwàásù.
Mo mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa lọ sípàdé. Ìgbà kan wà tí mo kíyè sí i pé láwọn ọjọ́ tá à ń ṣèpàdé àárín ọ̀sẹ̀, táwọn ọmọ mi bá máa fi dé ìpàdé, ó ti máa ń rẹ̀ wọ́n gan-an. Torí náà tí mo bá lọ mú wọn nílé ìwé láwọn ọjọ́ ìpàdé, màá fún wọn ní oúnjẹ díẹ̀, àá sì sùn díẹ̀ ká tó lọ sípàdé. Lọ̀rọ̀ bá yanjú! A kì í pa ìpàdé jẹ àfi tí ara ọ̀kan nínú wa ò bá yá. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a máa jọ kẹ́kọ̀ọ́ àwọn nǹkan tá a máa kọ́ nípàdé lọ́jọ́ yẹn. Tá a bá parí la máa tó tan tẹlifíṣọ̀n. Àmọ́ nígbà míì, ọkọ mi á kàn ṣàdédé wálé. Àá wá sáré lọ tọ́jú àwọn ìwé wa, àá sì tan tẹlifíṣọ̀n.
A máa ń rí i pé a ṣe ìjọsìn ìdílé wa déedée. A tún máa ń sọ̀rọ̀ nípa Bẹ́tẹ́lì àti ẹ̀ka tó wù wọ́n pé kí wọ́n ti ṣiṣẹ́.
Láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Àwọn ọmọ mi—Philip, Caroline, Debbie, Andrew àti Nigel
A Pinnu Láti Ṣiṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà
Nígbà tí Philip ọmọ mi àgbà pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16), àwọn kan ní kó wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mẹkáníìkì lọ́dọ̀ wọn. Àwọn míì tún ní kó máa bá àwọn fọ wíńdò láwọn ọjọ́ kan láàárín ọ̀sẹ̀. Àmọ́ kò wù ú pé kó fọ wíńdò, iṣẹ́ mẹkáníìkì yẹn ló wù ú torí ó ní ìyẹn máa jẹ́ kóun lè máa gbọ́ lára bùkátà ilé. Mo ṣàlàyé fún un pé ojúṣe bàbá ẹ̀ ni láti gbọ́ bùkátà ìdílé, kì í ṣe tiẹ̀. Mo jẹ́ kó mọ̀ pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń pèsè nǹkan tá a nílò. Mo tún jẹ́ kó mọ̀ pé tó bá gba iṣẹ́ wíńdò yẹn, ó máa ṣeé ṣe fún un láti bẹ̀rẹ̀ aṣáájú-ọ̀nà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Philip bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé lẹ́yìn tó parí ilé ẹ̀kọ́, èmi náà sì bẹ̀rẹ̀ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Nígbà tí Nigel ọmọ wa kejì náà parí ilé ìwé, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, bí èmi náà ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ asáájú-ọ̀nà déédéé nìyẹn. Mo ronú pé tí mo bá ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún kan, á rọrùn fún mi láti máa lọ sóde ìwàásù pẹ̀lú àwọn ọmọ mi, màá sì tún lè lọ sílé ẹ̀kọ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó yá, mo láǹfààní láti lọ sílé ẹ̀kọ́ aṣáájú-ọ̀nà pẹ̀lú Nigel.
Àtìbẹ̀rẹ̀ ni mo ti nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, mo sì mọ̀ pé tí mo bá ṣe é, ó máa ran àwọn ọmọ mi lọ́wọ́ gan-an. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé mo ti ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún márùndínlógójì (35) báyìí. Ká sọ pé ọkọ mi mọ̀gbà tí mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ni, kò ní gbà mí láyè. Àmọ́ àárín ọ̀sẹ̀ tí kì í sí nílé ni mo máa ń lọ sóde ìwàásù, màá sì dúró tì í nílé lópin ọ̀sẹ̀.
Nígbà tó yá, Nigel ọmọ mi gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì, wọ́n sì pè é. Ó láwọn ọ̀rẹ́ gidi níbẹ̀, ó sì gba ọ̀pọ̀ ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ kó di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ dáadáa. Philip àti Andrew lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́.c Lójú mi ọmọdé ni wọ́n nígbà tí wọ́n lọ, àmọ́ nígbà tí wọ́n máa pa dà, wọ́n ti di géńdé ọkùnrin. (1 Pétérù 5:10) Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni Jèhófà ń gbà dá àwọn èèyàn ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Mo dúpẹ́, mo tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà àti ètò ẹ̀ fún gbogbo ìdálẹ́kọ̀ọ́ táwọn ọmọ mi rí gbà.
Ó ń lọ sóde ìwàásù
Mo Kojú Àwọn Ìṣòro Tó Le
Àwọn ìṣòro kan tó le wà tí mo kojú. Ọ̀kan lára ẹ̀ ni bí ọkọ mi ṣe di aláìṣòótọ́. Lẹ́yìn ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) tá a ti ṣègbéyàwó, ó fi mí sílẹ̀, ó sì lọ ń gbé pẹ̀lú ẹlòmíì. Ìṣòro míì ni bí mo ṣe ń rí báwọn òbí mi ṣe ń dàgbà. Ó dùn mí gan-an pé bàbá mi kú ní March 1997. Torí náà, màmá mi máa ń dá wà, wọn ò sì lè wa mọ́tò. Wọ́n máa ń ṣàárò ọkọ wọn gan-an, torí náà, mo máa ń pè wọ́n, màá sì sọ fún wọn pé, “Ṣé kí n gbé yín jáde, ká lọ wo àwọn ìpadàbẹ̀wò mi kan?” Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn náà di aṣáájú-ọ̀nà. Iṣẹ́ yìí múnú wọn dùn gan-an, ó sì jẹ́ kí wọ́n gbà pé àwọn ṣì wúlò. Ọdún mẹ́wàá ni wọ́n fi ṣiṣẹ́ náà kí wọ́n tó kú.
Lóòótọ́, kò rọrùn láti tọ́ àwọn ọmọ márùn-ún, kí gbogbo wọn sì jọ́sìn Jèhófà. Mo mọ̀ pé mi ò lè fipá mú àwọn ọmọ mi pé kí wọ́n sin Jèhófà, mi ò sì lè pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe fún wọn. Àmọ́ mo lè pinnu ohun tí èmi fúnra mi máa ṣe. Torí náà, mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, mo sì máa ń fi ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Inú mi dùn gan-an pé àwọn ọmọ mi sin Jèhófà.d Mo dúpẹ́ pé Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ láti tọ́ wọn dàgbà.
Carol àtàwọn ọmọ ẹ̀ ní báyìí
a Wo fídíò tá a pè ní Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Tó Ti Kú?
b Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 5 “Àwọn Ayẹyẹ Tí Inú Ọlọ́run Ò Dùn Sí” nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!
c A ti fi Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run rọ́pò ilé ẹ̀kọ́ yìí.
d Ní báyìí, Philip wà lára àwọn olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run lórílẹ̀-èdè Ireland. Nigel ń bójú tó Gbọ̀ngàn Àpéjọ wa kan ní England. Alàgbà ni Andrew, ó sì ti ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ọgbọ̀n (30) ọdún báyìí. Caroline ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún márùn-ún, Debbie wà nílé, ó ń ti màmá wọn lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.