VIRGILIJUS PUDŽIUVYS | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Gbogbo Ìgbà Ni Jèhófà Máa Ń Ṣọ̀nà Àbáyọ
Lọ́dún 1976, àbúrò màmá mi àtìyàwó wọn wá kí wa, a ò sì ní gbàgbé ìbẹ̀wò yẹn láé. Àbúrò màmá mi sọ fáwọn òbí mi pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́, àwọn sì ti ń kọ́ àwọn nǹkan tuntun nínú Bíbélì. Nǹkan tó wà ní Mátíù orí 23 tí Jésù sọ nípa àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé ẹ̀ ni àbúrò màmá mi kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó tọ́ka sí bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé Jésù ṣe jọ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn òde òní. Kátólíìkì paraku ni màmá mi, àmọ́ ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí Jésù sọ nípa àwọn aṣáájú ẹ̀sìn. Torí náà, wọ́n pinnu pé àwọn máa ka Bíbélì fúnra àwọn káwọn lè rí ohun tí Jésù sọ.
Lithuania là ń gbé, ó sì jẹ́ apá kan ìjọba Soviet Union àtijọ́. Nígbà yẹn, ìjọba ò fàyè gba àwọn èèyàn láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n, torí náà ìwọ̀nba làwọn tó ní Bíbélì. Torí náà, màmá mi lọ yá Bíbélì kan ní ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n kà á, wọ́n sì rí i pé òótọ́ ni Jésù bẹnu àtẹ́ lu àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé ẹ̀ torí ìwà àgàbàgebè wọn. Nǹkan tí wọ́n kà yẹn yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì fẹ́ mọ àwọn nǹkan míì tí Bíbélì tún sọ. Torí náà, wọ́n lọ gba ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ ẹni tó ń kọ́ àbúrò wọn lẹ́kọ̀ọ́.
Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni ìdílé wa bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí pé wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wọn, ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti máa ń ṣèpàdé, kódà inú igbó kan tí ò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí wa ni wọ́n ti máa ń ṣèpàdé nígbà míì. Ọdún 1978 ni màmá mi, èmi àti ìbejì mi tó ń jẹ́ Danguolė ṣèrìbọmi. Àwa ò sì ju ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lọ nígbà yẹn. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn ni bàbá wa ṣèrìbọmi.
Èmi àti ìbejì mi Danguolė nígbà tá a wà lọ́mọdún mẹ́rin
Jèhófà Ṣe Ọ̀nà Àbáyọ fún Mi Nígbà Tí Mo Wà Lọ́dọ̀ọ́
Oṣù kan lẹ́yìn tá a ṣèrìbọmi ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣenúnibíni sí èmi àti Danguolė. Nígbà tí wọ́n ń ṣe ètò kan ní gbọ̀ngàn ilé ìwé wa, àwọn olùkọ́ wa kíyè sí pé èmi àti ìkejì mi ò dìde nígbà tí wọ́n ń kọ orin ẹ̀jẹ́ orílẹ̀-èdè Soviet torí ohun tá a gbà gbọ́. Wọ́n fẹjọ́ wa sun ọ̀gá àgbà ilé ìwé wa. Ọ̀gá àgbà ilé ìwé wa fẹjọ́ wa sun àwọn ọlọ́pàá KGB, àwọn ọlọ́pàá náà sì wá sílé wa láti fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò.
Gbogbo ìgbà làwọn olùkọ́ wa máa ń fúngun mọ́ èmi àti Danguolė ká lè gbà pé kò sí Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16), wọ́n ní káwa ọmọ kíláàsì ṣàlàyé ìdí tá a fi gbà pé “Kò Sí Ọlọ́run.” Torí mi ò fara mọ́ ohun tí wọ́n sọ yẹn, mo kọ “Mo Gbà Pé Ọlọ́run Wà” sínú ìwé àjákọ kan, mo sì fi sórí tábìlì mi. Nígbà tí olùkọ́ mi rí ohun tí mo kọ, inú bí i gan-an, ló bá jágbe mọ́ mi pé “ó yá kọ ìdí tó o fi gbà pé Ọlọ́run wà.” Inú mi dùn pé wọ́n gbà mí láyè láti kọ ohun tí mo gbà gbọ́, ohun tí ìkejì mi náà sì ṣe nìyẹn. Nígbà táwọn ọmọbìnrin méjì kan ní kíláàsì wa rí ohun tá à ń kọ, àwọn náà kọ ìdí tí wọ́n fi gba Ọlọ́run gbọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà máa ń “ṣe ọ̀nà àbáyọ” tá a bá wà nínú ìṣòro, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún mi.—1 Kọ́ríńtì 10:13.
Àwọn arákùnrin tó ń bójú tó iṣẹ́ wa yá wa ní ìwé Lati Paradise T’a Sọnu Si Paradise T’a Jere-Pada táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, oṣù kan ni ìwé náà sì lò lọ́wọ́ wa. Nígbà yẹn, ó jọ pé ìwé yìí ò ju mẹ́rin sí márùn-ún lọ ní gbogbo Lithuania. Èmi àti Danguolė wá sọ fún ara wa pé, “Ì bá mà dáa o, ká ní ìwé yìí lè di tiwa!” Àmọ́ torí a mọ̀ pé ìyẹn ò lè ṣeé ṣe, ṣe la da ìwé náà kọ! Ọwọ́ ro wá lóòótọ́, àmọ́ inú wa dùn gan-an pé a da ìwé náà kọ, ó sì ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun.
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19) ní 1982, wọ́n rán mi lọ sẹ́wọ̀n ọdún méjì torí mo kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Kò rọrùn fún mi torí àárín àwọn ọ̀daràn paraku ni mo wà. Àmọ́ inú mi dùn pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan mo máa ń rí arákùnrin kan tóun náà wà lẹ́wọ̀n bá sọ̀rọ̀. Mo lo ọdún méjì mi pé, àmọ́ nígbà tó yá wọ́n tún jù mí sẹ́wọ̀n.
Mo Fẹ́ Arábìnrin Kan Tó Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
Èmi àti Lidija nígbà tó ku díẹ̀ ká ṣègbéyàwó
Lẹ́yìn tí mo kúrò lẹ́wọ̀n lọ́dún 1984, mo fẹ́ arábìnrin arẹwà kan tó ń jẹ́ Lidija, ó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, orílẹ̀-èdè Ukraine ló sì ń gbé. Lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó Lidija kúrò ní Ukraine, ó sì kó wá bá mi ní Lithuania. Torí ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti wá, wọ́n ṣenúnibíni sóun náà nígbà tó wà nílé ìwé. Ní gbogbo àsìkò yẹn, ìrírí àwọn tó fara da inúnibíni ní àgọ́ Násì tí wọ́n ti ń fìyà jẹ àwọn èèyàn tàbí àwọn tí wọ́n lé kúrò nílùú lọ sórílẹ̀-èdè Siberia ló ràn án lọ́wọ́.
Láwọn ọdún 1980, wọ́n ṣì fòfin de iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè Lithuania. Lọ́pọ̀ ìgbà, táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá fẹ́ ṣe ìgbéyàwó, wọ́n sábà máa ń fi àwọn àpéjọ agbègbè wa sí àsìkò yẹn, torí náà ọjọ́ méjì la máa fi ń ṣe é. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwa náà ṣègbéyàwó nìyẹn. Àwọn èèyàn bá wa yọ̀ fún ti ìgbéyàwó wa, lẹ́sẹ̀ kan náà, ọ̀pọ̀ àsọyé ni wọ́n sọ, a kọ orin tó pọ̀, kódà àwòkẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rin la wò. Mo rántí pé nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ààbọ̀ (450) èèyàn ló wá síbẹ̀ látibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nílẹ̀ Soviet Union títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí wa, kódà àwọn ọlọ́pàá KGB tá ò pè gan-an wá síbẹ̀, àwọn ará kan sì dá wọn mọ̀!
Ìgbà àpéjọ ọlọ́jọ́ méjì la ṣègbéyàwó. Tọkọtaya méjì ló wà lórí pèléle torí mọ̀lẹ́bí mi kan náà ṣègbéyàwó lọ́jọ́ yẹn
Wọ́n Tún Gbé Mi Lọ Sílé Ẹjọ́
Tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ò bá fara mọ́ òfin Soviet lẹ́yìn tó kúrò lẹ́wọ̀n, nígbà míì wọ́n tún máa dá a pa dà sẹ́wọ̀n. Torí náà, kò pé ọdún kan lẹ́yìn ìgbéyàwó wa ni wọ́n tún gbé mi lọ sílé ẹjọ́. Ilé ìwòsàn ni Lidija wà nígbà tí wọ́n gbé mi lọ sílé ẹjọ́, oyún sì wà nínú ẹ̀ lásìkò yẹn. Wọn ò jẹ́ kí n lọ wò ó nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ mi. Àmọ́ lọ́jọ́ kan tí ilé ẹjọ́ lọ fún ìsinmi ráńpẹ́, mo sáré fẹsẹ̀ rìn lọ wò ó nílé ìwòsàn, kódà ojú wíńdò ni mo dúró sí. Ó ṣí wíńdò, a sì jọ sọ̀rọ̀ díẹ̀ láti fi gbé ara wa ró. Ọjọ́ yẹn ni wọ́n rán mi lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta.
Ó ṣeni láàánú pé ọjọ́ méjì lẹ́yìn yẹn loyún bà jẹ́ lára Lidija. Ó sọ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn dun òun gan-an, kódà ṣe ni ìbànújẹ́ dorí òun kodò. Yàtọ̀ síyẹn, nǹkan ò rọrùn fún Lidija torí ara ẹ̀ ò tíì mọlé níbi tó wà báyìí. Ọ̀dọ̀ àwọn òbí mi ló ń gbé, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè Ukraine àti Rọ́ṣíà tó ń sọ. Síbẹ̀ Lidija gbára lé Jèhófà pátápátá, àwọn òbí mi sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti bójú tó o kí wọ́n sì mára tù ú ní gbogbo àsìkò tí nǹkan ò fi rọrùn yẹn.
Jèhófà Ṣọ̀nà Àbáyọ fún Mi
Àwọn nǹkan tí mo kọ́ nígbà tí mo kọ́kọ́ lọ sẹ́wọ̀n ràn mí lọ́wọ́ gan-an nígbà tí mo pa dà síbẹ̀. Ọ̀kan lára ohun tó ràn mí lọ́wọ́ ni pé mo máa ń wàásù fáwọn tá a jọ wà lẹ́wọ̀n. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá ń kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, ṣe ni wọ́n máa ń rọ́ wọn sínú mọ́tò àti ọkọ̀ ojú irin. Nígbà míì, ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sí ogún (20) ni wọ́n máa ń fún pọ̀ síbi tó yẹ kéèyàn márùn-ún sí mẹ́fà wà. Ṣe ni mo máa ń fi àkókò yẹn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù. Mo máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tí mi ò fi wọṣẹ́ ológun, tí mi ò sì dá sọ́rọ̀ òṣèlú àti pé ohun tó sọ mí dèrò ẹ̀wọ̀n nìyẹn. Mo tún máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí mo fi gbà pé Ọlọ́run wà.
Ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà nílùú Marijampolėa ni mo ti ṣẹ̀wọ̀n. Ó jọ pé èmi nìkan ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà láàárín àwọn ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọ̀daràn paraku. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan péré ni àwọn ẹlẹ́wọ̀n nà mí gan-an, àwọn ọ̀daràn yẹn sábà máa ń na àwọn ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n máa ń halẹ̀ mọ́ wọn kódà wọ́n máa ń pa wọ́n nígbà míì. Lóòótọ́, nǹkan ò rọrùn lọ́gbà ẹ̀wọ̀n àmọ́ mo máa ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti gba àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù níyànjú, kí n sì fàánù hàn sí wọn, bẹ́ẹ̀ sì rèé wọn kì í sábà rẹ́ni sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn.
Àwọn ọlọ́pàá KGB tún máa ń parọ́ fún wa, wọ́n sì máa ń fẹ́ ká lérò òdì. Mi ò mọ bí wọ́n ṣe máa ń gbọ́ nǹkan tí ìdílé mi ń sọ nínú ilé wa, wọ́n sì máa ń sọ fún mi nípa ẹ̀. Àmọ́ àwọn ọlọ́pàá yìí máa ń yí ohun tí wọ́n sọ pa dà, wọ́n sì máa ń jẹ́ kó dà bíi pé wọ́n ń jà àti pé wọn ò gbọ́ ara wọn yé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò gba àwọn ọlọ́pàá yẹn gbọ́, ìgbà tí mo kúrò lẹ́wọ̀n ni mo tó mọ ohun tí ìdílé mi ń sọ gangan, mo sì wá rí i pé irọ́ làwọn ọlọ́pàá yẹn ń pa mọ́ wọn.—Mátíù 10:16.
Ìgbà kan wà tí arábìnrin kan sọ pé kí ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tí wọ́n jọ ń gbé ládùúgbò mú Bíbélì kékeré kan tí wọ́n kọ lédè Rọ́ṣíà wá fún mi. Tó bá dalẹ́, mo máa ń kọ àwọn ẹsẹ kan látinú Ìwàásù orí Òkè sórí bébà kékeré kan, tí mo bá wá débi tá a ti ń ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ kejì, màá wá máa kà á léraléra nígbà tí kò sẹ́nì kankan níbẹ̀. Bí mo ṣe há Ìwàásù orí Òkè sórí nìyẹn lédè Rọ́ṣíà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe èdè abínibí mi. Nígbà tó yá, àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n rí Bíbélì náà, wọ́n sì gbà á lọ́wọ́ mi. Àmọ́ nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ lára nǹkan tí Jésù sọ ni mo ti há sórí, mi ò sì lè gbàgbé ẹ̀ mọ́.
Lidija ràn mí lọ́wọ́ gan-an, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ló máa ń kọ lẹ́tà sí mi. Àmọ́, ẹ̀ẹ̀mejì péré ni wọ́n máa ń gbà mí láyè láti kọ lẹ́tà sí i lóṣù. Síbẹ̀, ó sọ fún mi pé òun mọyì àwọn lẹ́tà tí mo máa ń kọ sóun gan-an, òun ò sì kóyán ẹ̀ kéré torí ó máa ń jẹ́ kóun mọ nǹkan pàtàkì mẹ́ta, ìyẹn ni pé mo ṣì wà láàyè, mo jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti pé mo ṣì nífẹ̀ẹ́ òun gan-an.
Jèhófà Máa Ń Gbọ́ Àdúrà Mi
Ìgbà kan wà táwọn ẹlẹ́wọ̀n kan sọ pé àwọn aláṣẹ gbọ́dọ̀ ṣe ohun táá mú kí nǹkan rọrùn díẹ̀ sí i níbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́. Àmọ́, kí wọ́n tó dá wọn lóhùn, wọ́n kọ̀, wọn ò lọ síbi iṣẹ́. Làwọn aláṣẹ bá fìyà jẹ wọ́n dáadáa torí ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọ́n hù. Àwọn aláṣẹ wá sọ fún èmi àtàwọn kan pé àwa la máa lọ rọ́pọ̀ àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn níbi iṣẹ́ wọn.
Tí mi ò bá gbà láti ṣe iṣẹ́ yìí, wọ́n máa fìyà jẹ mí gan-an. Tí mo bá sì gbà láti ṣe é, àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù máa gbà pé ọ̀dàlẹ̀ ni mí, ńṣe ni wọ́n á sì lù mí nílùkulù tàbí kí wọ́n gún mi pa. Ìdààmú ńlá bá mi, torí mo ti há sáàárín báyìí, mi ò sì mohun tí màá ṣe. (2 Kíróníkà 20:12) Torí náà, léraléra ni mò ń bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́.
Ṣàdédé ni ẹlẹ́wọ̀n kan níbi tí mo ti ń ṣiṣẹ́ gangan pe gbogbo wa jọ, ó sì ní ká lọ bá ọ̀gá wa. Èmi àti ẹ̀ kì í ṣọ̀rẹ́, a kàn jọ ń ṣiṣẹ́ ni. Àmọ́, ńṣe ló gbèjà mi, ó sì ní wọn ò gbọ́dọ̀ gbé mi kúrò níbi tí mo ti ń ṣiṣẹ́. Bórọ̀ yìí ṣe di wàhálà láàárín òun àti ọ̀gá wa nìyẹn. Nígbà tó yá, ńṣe ni ọ̀gá wa lé gbogbo wa kúrò ní ọ́fíìsì ẹ̀, ó sì sọ pé òun ti gbà pé kí wọ́n má gbé mi kúrò níbi tí mo ti ń ṣiṣẹ́. Bó ṣe sọ bẹ́ẹ̀ báyìí, ńṣe lara tù mí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, kìígbọ́-kìígbà ni ọ̀gá yìí! (2 Pétérù 2:9) Ní gbogbo ọdún tí mo lò lẹ́wọ̀n, mi ò tíì rí kí ẹlẹ́wọ̀n kan fi ìtara gbèjà ẹlẹ́wọ̀n míì bí èyí. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ kí n rí i pé kò sẹ́ni tí Jèhófà ò lè lò láti dáhùn àdúrà wa.
Jèhófà Ṣe Ọ̀nà Àbáyọ fún Lidija
Ẹ jẹ́ kí n sọ nǹkan tójú Lidija rí nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n. Ó ń wá iṣẹ́ tó lè máa fi gbọ́ bùkátà ara ẹ̀. Àmọ́, torí pé mo wà lẹ́wọ̀n, àwọn èèyàn ò fẹ́ gbà á síṣẹ́, torí wọ́n ń bẹ̀rù pé ńṣe làwọn ọlọ́pàá KGB á máa yọ àwọn lẹ́nu. Nígbà tó yá, ó rí iṣẹ́ kan táá máa fi wákàtí méjìlá (12) ṣe lójúmọ́. Àwọn ọmọ tí iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n (30) láá sì máa tọ́jú. Iṣẹ́ yìí ò rọrùn fún un rárá! Àmọ́ Jèhófà fún un lókun kó lè máa lọ lójoojúmọ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń wá láti àwọn ibi tó jìnnà káàkiri Lithuania láti wá tù ú nínú, wọ́n dúró tì í, wọ́n sì máa ń mú àwọn ìwé ètò Ọlọ́run lédè Rọ́ṣíà wá fún un. Àwọn ará ò fi í sílẹ̀ rárá.
Gbogbo Ìdílé Wa Ń Sin Jèhófà
Lẹ́yìn tí mo kúrò lẹ́wọ̀n, mo wà lára àwọn tó ń túmọ̀ àwọn ìwé wa sí èdè Lithuania lábẹ́lẹ̀. Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, ìjọba Soviet Union forí ṣọ́pọ́n, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì forúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba Lithuania. Nígbà tó yá, a ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè Lithuania. Wákàtí kan ààbọ̀ ni mo máa ń fi wa mọ́tò lọ síbẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, tayọ̀tayọ̀ ni mo sì fi ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọdún márùn-ún.
Ní August 1997, wọ́n pe èmi àti Lidija ìyàwó mi wá sí ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Lithuania, èyí tá à ń pè ní Bẹ́tẹ́lì. Inú wa dùn gan-an ni. A ní ọmọbìnrin méjì, Oksana ọmọ ọdún mésàn-án àti Svajūnė ọmọ ọdún márùn-ún. Ọjọ́ mẹ́ta ni wọ́n fún wa pé ká fi kó wá sí ilé kan tó wà nítòsí Bẹ́tẹ́lì, wọ́n sì ní ká forúkọ Oksana sílẹ̀ níléèwé tuntun táá máa lọ.
Oríṣiríṣi nǹkan la máa ń ṣe nígbà ìjọsìn ìdílé wa torí pé a fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́, a sì fẹ́ gbádùn ara wa. Àwa nìyẹn tá à ń ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́ Ahasuérúsì, Ẹ́sítà àti Módékáì
Báwo la ṣe bójú tó àwọn ọmọ wa, tá à ń ṣiṣẹ́ wa ní Bẹ́tẹ́lì, tá a sì ń ṣe àwọn nǹkan pàtàkì míì nígbà yẹn? Láàárọ̀ kùtù lójoojúmọ́, èmi ni mo máa ń kọ́kọ́ lọ sí Bẹ́tẹ́lì, Lidija á sì wá bá mi lẹ́yìn táwọn ọmọ bá ti lọ síléèwé. Lidija ti máa ń délé káwọn ọmọ tó dé láti iléèwé, èyí sì máa ń mú kí ara tù wọ́n nígbà tí wọ́n bá délé.
A wọ asọ ìbílẹ̀ Lithuania nígbà tí wọ́n mú ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Lithuania tóbi sí i, tí wọ́n sì yà á sí mímọ́ lọ́dún 2003
Ńṣe ni ìdílé wa máa ń fojú sọ́nà fún alaalẹ́ Friday. A máa ń dáná, a máa ń tún ilé ṣe, a máa ń ṣe ìjọsìn ìdílé, a sì jọ máa ń ṣeré. A máa ń lọ gbafẹ́ láwọn orí òkè, a máa ń lọ sí òkun, a sì máa ń lọ sáwọn Bẹ́tẹ́lì míì tó wà nílẹ̀ Yúróòpù. Èyí máa ń jẹ́ káwọn ọmọ wa túbọ̀ mọyì àwọn ìṣẹ̀dá Jèhófà, kí wọ́n sì tún mọ àwọn ará wa tó wà láwọn orílẹ̀-èdè míì. Ọmọ àmúyangàn làwọn ọmọbìnrin wa, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) làwọn méjèèjì nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ní báyìí, Oksana àti ọkọ ẹ̀ Jean-Benoit ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè Lithuania, Svajūnė àti ọkọ ẹ̀ Nicolas sì ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè Faransé.
Ohun tó túbọ̀ mú kí èmi àti Lidija di “ara kan” ni pé ìjọsìn Jèhófà la kà sí pàtàkì jù. (Éfésù 5:31; Oníwàásù 4:12) Wọ́n “há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, àmọ́ kò le débi tí a ò fi lè yíra.” Wọ́n ṣe inúnibíni sí wa fún ọ̀pọ̀ ọdún, àmọ́ Jèhófà ò fìgbà kan fi wá sílẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 4:8, 9) Léraléra ni Jèhófà ti ṣe ọ̀nà àbáyọ fún wa, ìṣòro yòówù kó tún yọjú lọ́jọ́ iwájú, ọkàn wa balẹ̀ pé ó tún máa ṣe ọ̀nà àbáyọ.
Èmi àti Lidija ìyàwó mi ọ̀wọ́n
a Kapsukas ni wọ́n ń pè é láti 1955 sí 1990.