ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfs àpilẹ̀kọ 24
  • Jèhófà Jẹ́ Ká Ṣe Ìpinnu Tó Dáa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Jẹ́ Ká Ṣe Ìpinnu Tó Dáa
  • Ìtàn Ìgbésí Ayé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mo Láwọn Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Míì
  • A Ṣe Ìpinnu Kan Tí Ò Rọrùn
  • A Ṣe Àwọn Ìpinnu Tí Ò Rọrùn Nígbà Tí Ogun Ń Lọ Lọ́wọ́
  • Mo Fara Da Àìsàn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tá A Fi Ń Ṣe Ìrànwọ́
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ọlọrun Kò Gbagbe “Ifẹ ti Ẹyin Fihàn si Orukọ Rẹ̀”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Wíwàásù ‘ní Àsìkò Tí Ó Rọgbọ àti ní Àsìkò Tí Ó Kún fún Ìdààmú’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Baba Kú àmọ́, Baba Kù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ìtàn Ìgbésí Ayé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
lfs àpilẹ̀kọ 24
Peter àti Lenka Hamadej.

PETER HAMADEJ | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Jẹ́ Ká Ṣe Ìpinnu Tó Dáa

Ọdún 1952 ni wọ́n bí mi ní ìlú kan tó ń jẹ́ Karlovy Varya ní apá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń pè ní Czechoslovakia tẹ́lẹ̀ nítòsí ibodè orílẹ̀-èdè Jámánì. Torí pé ọmọ orílẹ̀-èdè Jámánì ni wá, àwọn ọmọ ilé ìwé wa máa ń fìtínà èmi àti ẹ̀gbọ́n mi tó ń jẹ́ Milan. Torí náà, nígbà tó di ọdún 1966, ìdílé wa kó lọ sí Frankfurt lórílẹ̀-èdè Jámánì.

Àwòrán ilẹ̀ Yúróòpù tó jẹ́ ká rí àwọn ibi tí Arákùnrin Peter Hamadej gbé àti ibi tí wọ́n ti sìn.

Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí mi nígbà tí mo wà lọ́mọdé, àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n mú wọn kúrò nínú ìjọ, mi ò sì tíì dàgbà púpọ̀ nígbà yẹn. Torí náà, mi ò ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.

Nígbà tó yá, àwọn òbí mi pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Bákan náà, Milan kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó sì pinnu pé òun máa ṣèrìbọmi ní àpéjọ agbègbè tá a ṣe nílùú Hannover. Èmi náà wá pinnu pé màá ṣèrìbọmi lọ́jọ́ yẹn! Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ni mí nígbà yẹn. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, mo bẹ àwọn òbí mi pé kí wọ́n jẹ́ kí n lọ gbé nílùú Berlin kí n lè kọ́ iṣẹ́ ọnà níbẹ̀.

Nígbà tí mò ń kọ́ iṣẹ́ ọnà, mo sábà máa ń ronú nípa ìbéèrè méjì kan tó máa ń dà mí láàmú. Àkọ́kọ́, ṣé Ẹlẹ́dàá kan wà? Ìkejì ni pé ṣé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá lóòótọ́? Nínú àwọn nǹkan tá à ń yà, mo rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan la máa ń ṣe ká tó parí iṣẹ́ kan kí gbogbo ẹ̀ sì di odindi, àmọ́ àwọn nǹkan yẹn ò já mọ́ nǹkan kan rárá tá a bá fi wé àwọn nǹkan tá a wò láti fi ya àwọn nǹkan yẹn. Mo wá rí i pé àwòrán kan ò lè wà láìjẹ́ pé ẹnì kan ló yà á, torí náà àwọn nǹkan tá à ń wò láti fi ya àwòrán ò kàn lè wà láìjẹ́ pé ẹnì kan ló dá wọn!

Mo rí ìdáhùn ìbéèrè kejì nígbà tí mo ṣèwádìí nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti bó ṣe ṣẹ, mo wá fi wé ohun táwọn òpìtàn sọ, mo sì rí i pé bó ṣe rí nìyẹn. Díẹ̀díẹ̀, ó dá mi lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì lóòótọ́.—1 Tẹsalóníkà 2:13.

Arákùnrin Peter mú ọ̀kan lára àwọn àwòrán tó yà dání, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń rìn pẹ̀lú àwọn àgùntàn wọn ló wà nínú àwòrán náà.

Ọ̀kan lára àwọn àwòrán tí mo yà lọ́dún 1980

Yàtọ̀ sáwọn ìwádìí tí mo ṣe, mo máa ń bá alàgbà kan tó mú mi bí ọmọ sọ̀rọ̀ dáadáa. Mo túbọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, mo wá fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ dípò iṣẹ́ ọnà tí mò ń kọ́. Ní 1972, mo ṣe ọ̀kan lára ìpinnu tó dáa jù láyé mi nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nílùú Berlin. Mo sì ronú pé oṣù mẹ́ta péré ni màá fi ṣe é.

Mo Láwọn Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Míì

Kò rọrùn rárá láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní Berlin. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún (100) ọdún tí wọ́n ti ń wàásù ìhìn rere nílùú yìí, síbẹ̀, àwọn díẹ̀ ló wá sin Jèhófà. Ṣe ló dà bí àlá lójú mi nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní báyìí, ó dá mi lójú pé kò síbi tí mi ò ti lè wàásù lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà, mo sì ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà mi lọ.

Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì bi mí pé ṣé màá fẹ́ kọ́ èdè Serbo-Croatianb kí n lè máa wàásù fáwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè Yugoslavia tó ń ṣiṣẹ́ ní Jámánì. Tayọ̀tayọ̀ ni mo gba iṣẹ́ náà, wọ́n sì rán mi lọ́ sílùú Frankfurt. Ibẹ̀ ni èmi pẹ̀lú Hans àti Sonja Smode tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ti kọ́ èdè Serbo-Croatian. Lẹ́yìn tí mo lo oṣù mẹ́ta pẹ̀lú wọn, ètò Ọlọ́run ní kí n máa lọ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nílùú Stuttgart. Láti ọdún 1973 sí 1975, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ètò Ọlọ́run gbé mi láti ibì kan lọ sí ibòmíì, ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ márùn-ún la sì jọ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.

Nígbà tó yá, ètò Ọlọ́run ní kí n lọ máa dara pọ̀ mọ́ àwùjọ kan tó ń sọ èdè Serbo-Croatian nílùú Karlsruhe. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé ẹni tá a jọ máa ṣiṣẹ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé mi. Aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tó nítara ni, Lenka lorúkọ ẹ̀. Kò pẹ́ tí mo fi yọ́fẹ̀ẹ́, a sì ṣègbéyàwó. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ní 1978, ètò Ọlọ́run ní ká lọ máa ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká láwọn àwùjọ àti ìjọ tó ń sọ èdè Yugoslavia.

Peter àti Lenka.

Èmi àti Lenka

A Ṣe Ìpinnu Kan Tí Ò Rọrùn

Ní ọdún mẹ́wàá tó tẹ̀ lé e, à ń bẹ àwọn àwùjọ àti ìjọ tó wà káàkiri ilẹ̀ Yúróòpù wò. Àmọ́ nígbà tó yá, bó tiẹ̀ jẹ́ pé à ń gbádùn iṣẹ́ náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ̀ wá. Tí ara Lenka ò bá fi bẹ́ẹ̀ gbé e mọ́, ṣe ló túbọ̀ máa ń tiraka láti ṣe púpọ̀ sí i. Àmọ́, kì í ṣe ohun tó yẹ ká máa ṣe nìyẹn. A wá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà.

Peter àti Lenka ń kẹ́rù sínú mọ́tò wọn.

Nígbà tá a wà lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó àyíká

Ìgbà tá a lọ sọ́dọ̀ dọ́kítà kan ni Jèhófà gbọ́ àdúrà wa. Ó jẹ́ ká rí i pé a gbọ́dọ̀ mọ ibi tí agbára wa mọ àti pé kì í ṣe gbogbo nǹkan tó wù wá láti ṣe la máa lè ṣe. (Míkà 6:8) A wá rí i pé ó máa dáa ká kúrò lẹ́nu iṣẹ́ aláàbójútó àyíká, àmọ́ ìpinnu yẹn ò rọrùn rárá. A sọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa fáwọn alábòójútó kan ní Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́ ó yà wá lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n sọ pé ká lọ dara pọ̀ mọ́ àwọn atúmọ̀ èdè Serbo-Croatian ní Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè Austria. Ètò tí wọ́n ṣe yìí jẹ́ kí ara Lenka balẹ̀, ara ẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í yá díẹ̀díẹ̀. Jèhófà lo àwọn agbani-nímọ̀ràn láti ràn wá lọ́wọ́, ìyẹn ló sì jẹ́ ká ṣe ìpinnu tó dáa.—Òwe 15:22.

A Ṣe Àwọn Ìpinnu Tí Ò Rọrùn Nígbà Tí Ogun Ń Lọ Lọ́wọ́

Lẹ́yìn tá a ṣiṣẹ́ sìn ní Vienna fún ọdún méjì, ètò Ọlọ́run ní kí èmi àti Lenka máa lọ ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà nílùú Zagreb, lórílẹ̀-èdè Croatia. Ẹ̀ka ọ́fíìsì yẹn ló ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù wa níbi tí wọ́n ń pè ní Yugoslavia tẹ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wá láti Yugoslavia ló máa ń gbé pọ̀ níṣọ̀kan bó tiẹ̀ jẹ́ pé àṣà ìbílẹ̀ àti ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ síra, àmọ́ nǹkan yí pa dà nígbà tí ogun abẹ́lé bẹ̀rẹ̀ ní 1991. Oṣù díẹ̀ kí ogun náà tó bẹ̀rẹ̀ ni Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-èdè wa ti bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ fún àpéjọ àgbáyé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà káàkiri orílẹ̀-èdè Yugoslavia ló sì máa wá síbẹ̀.

Lenka ń ṣiṣẹ́ atúmọ̀ èdè ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nílùú Zagreb, lórílẹ̀-èdè Croatia

A gbàdúrà, a jíròrò bí gbogbo ètò náà ṣe máa lọ, a sì pinnu pé àá máa bá ètò tá à ń ṣe lọ, a ò ní dá a dúró. A tún kàn sáwọn aláṣẹ kí wọ́n lè rí i dájú pé nǹkan kan ò ṣe àwọn àlejò tó ń bọ̀ láti àwọn orílẹ̀-èdè míì. Inú wa dùn gan-an nígbà tí márùn-ún lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí wá sí ìpàdé náà! Àwọn ará gbádùn àpéjọ agbègbè yẹn dọ́ba torí ohun tí wọ́n nílò gan-an nìyẹn.

Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tí ogun náà bẹ̀rẹ̀, Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-èdè gbọ́ pé àwọn ará wa tó wà ní Sarajevo àtàwọn apá ibòmíì lórílẹ̀-èdè Bosnia ò ní oúnjẹ, igi ìdáná àti oògùn mọ́. Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Serbia ti dí gbogbo ọ̀nà tó wọ ìlú wọn, wọn ò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gbé nǹkan kan dé ọ̀dọ̀ wọn. Ṣe la bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà taratara pé kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà. Kí la máa wá ṣe báyìí?

Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Austria ṣètò pé ká ṣèrànwọ́ fún wọn láìka ewu tó wà níbẹ̀ sí. Ní October 26, 1993, àwọn mọ́tò akẹ́rù ńlá kó ẹrù tó tó tọ́ọ̀nù mẹ́rìndínlógún (16) láti Vienna lọ sí Bosnia fáwọn ará wa.c

Peter àtàwọn arákùnrin kan jọ dúró.

Ìgbà tá a fẹ́ kó oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì lọ fáwọn ará wa ní Sarajevo

Bá a ṣe ń kọjá láwọn ibi tí ogun ti gbóná, ìgbà yẹn gangan la wá rí i pé “ọwọ́ Jèhófà kò kúrú jù láti gbani là.” (Àìsáyà 59:1) Kò sí bá a ṣe lè gbàgbé ìrìn àjò tó léwu tá a rìn láti Zenica sí Sarajevo. Nígbà tó ku nǹkan bíi kìlómítà ogójì (40) péré ká dé ìlú Sarajevo, a ní láti lọ gba inú igbó, ìyẹn sì mú ká tún rin ìrìn ogóje (140) kìlómítà.

Nígbà tá a sún mọ́ ìlú tí wọ́n ń gbógun jà yẹn, mo ní kí wọ́n jẹ́ kí n bá ọ̀gágun tó wà níbẹ̀ sọ̀rọ̀. Ó ní kò dá òun lójú pé a lè gbé àwọn ẹrù náà débẹ̀. Àmọ́ nígbà tó gbọ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, ó bi mí pé ṣé mo mọ arákùnrin kan tó ń jẹ́ Hajrudin. Mo ní mo mọ̀ ọ́ dáadáa àti pé ọ̀rẹ́ wa ni. Ọ̀gágun náà wá sọ pé: “Ọ̀rẹ́ tèmi náà ni. Ilé ìwé kan náà la jọ lọ. Àtìgbà tó sì ti di Ajẹ́rìí ni mo ti túbọ̀ bọ̀wọ̀ fún un.”

Lẹ́yìn tó béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa ohun tá a gbà gbọ́, ọ̀gágun yìí gbà pé ká gba inú ọ̀nà abẹ́lẹ̀ kan tí ẹnikẹ́ni ọ̀ mọ̀ kọjá, ká lè gbé oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì lọ fáwọn ará wa ní Sarajevo. Kódà, òrú ọjọ́ méjì ló fi dá ẹrù àwọn ológun dúró káwọn ọmọ ogun ẹ̀ lè bá wa kó ẹrù wa gba ọ̀nà abẹ́lẹ̀ yẹn. Ẹrù tó tó nǹkan bíi kìlógíráàmù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) ni ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan gbé fún òru ọjọ́ méjì kí wọ́n tó kó ẹrù náà tán. Kò sí bá a ṣe máa dá gbé ẹrù náà tí kì bá ṣe Jèhófà tó ràn wá lọ́wọ́!

Peter pẹ̀lú Halim Curi ní ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tí wọ́n gbà gbé oúnjẹ lọ fáwọn ará ní Sarajevo.

Lọ́dún díẹ̀ lẹ́yìn ogun tí wọ́n jà ní Bosnia, èmi àti alàgbà kan tó ń jẹ́ Halim Curi láti Sarajevo jọ ṣèbẹ̀wò sọ́nà abẹ́lẹ̀ yẹn

Nígbà tí wọ́n kó ẹrù náà dé òdìkejì, àwọn ọmọ ogun náà gbé ẹrù náà lọ síbi tí ò séwu fáwọn ará wa, wọ́n sì pín in fáwọn ará àtàwọn aládùúgbò wọn. Inú àwọn kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà dùn débi pé ṣe ni wọ́n kúnlẹ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀, wọ́n sì jọ ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà.—2 Kọ́ríńtì 9:13.

Torí pé a kì í dá sọ́rọ̀ òṣèlú, ọ̀pọ̀ ibi táwọn ọmọ ogun máa ń dúró sí la máa ń gbà kọjá láìséwu. Àmọ́ tá ò bá ní dá sí tọ̀tún tòsì lóòótọ́, ó kọjá ka kàn fi báàjì sáyà pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá. A gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára ká má bàa dá sí i nínú ọkàn àti èrò wa. Torí náà, a pinnu pé ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan làá máa tẹ́tí sí ìròyìn ká má bàa gbè sápá kan, ká má sì kórìíra ẹnikẹ́ni.

Àtọdún 1990 ni mo ti ń sìn nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lórílẹ̀-èdè Croatia lẹ́yìn náà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Czech-Slovak. Kí ni mo kọ́ nínú àwọn iṣẹ́ tí mo ṣe nínú ètò Ọlọ́run tí mo bá fẹ́ ṣèpinnu? Ohun tí mo kọ́ ni pé kò sẹ́ni tí Jèhófà ò lè lò láti yanjú ìṣòro títí kan àwọn ọ̀gágun! Mo tún kọ́ pé kò yẹ kí n máa ro ara mi jù torí pé mo ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan nínú ètò Ọlọ́run, Jèhófà ló yẹ kí n gbára lé, kí n sì máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tí ètò ẹ̀ bá fún wa.

Mo Fara Da Àìsàn

Nígbà tí mo ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ dókítà kan lọ́dún 2023, wọ́n sọ fún mi pé mo lárùn jẹjẹrẹ kan tó léwu. Torí pé mi ò tíì ṣàìsàn kankan tó lágbára rí, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà wá torí pé a ò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀. Léraléra lèmi àti Lenka bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣèpinnu tó dáa, ká sì ṣe ohun tó bá àdúrà wa mu. A ṣèwádìí, a sì lọ sọ́dọ̀ dókítà lóríṣiríṣi. Tá a bá ti pinnu irú ìtọ́jú tí mo máa gbà, ọkàn wa máa ń balẹ̀.

A tún pinnu pé a ò ní jẹ́ kí àníyàn àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú kó ìdààmú bá wa. (Mátíù 6:34) Àá ń rí ìdí tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà! Ìgbà kan wà tá a fẹ́ lọ gba ìtọ́jú ní orílẹ̀-èdè Jámánì, a kọ lẹ́tà sí ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú Bratislava, lórílẹ̀-èdè Slovakia, a sì ṣàlàyé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa fún wọn. Ọ̀pọ̀ wọn ló fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí wa, wọ́n gbàdúrà fún wa, wọ́n sì jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wa. Jèhófà lè lo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láti fún wa lókun, kó sì jẹ́ ká ní àlàáfíà “tó kọjá gbogbo òye.”—Fílípì 4:7.

Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tó mọ ìgbà tóun máa ṣàìsàn tó le gan-an tàbí tóun máa kú. (Oníwàásù 9:11; Jémíìsì 4:14) Torí náà, mo dúpẹ́ mo tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kí n ṣèpinnu láti kékeré pé màá fi gbogbo okun mi sìn ín. Kò sóhun tó dáa tó ohun tí mo fayé mi ṣe yìí!d

a Wọ́n tún máa ń pe ìlú Karlovy Vary ní Karlsbad lédè Jámánì.

b Serbo-Croatian ni èdè àjọgbà tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè Yugoslavia tẹ́lẹ̀.

c Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa iṣẹ́ tí wọ́n ṣe yìí, wo àpilẹ̀kọ náà “Ṣíṣèrànwọ́ fún Àwọn Ìdílé Onígbàgbọ́ Wa ní Bosnia,” nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 1994, ojú ìwé 23-27.

d Arákùnrin Hamadej kú ní January 28, 2025, nígbà tá à ń ṣètò àpilẹ̀kọ yìí lọ́wọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́