ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 136
  • Máa Wáyè Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Wáyè Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọlọ́run
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Jésù sọ
  • “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.”—Mátíù 5:3.
    “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.”—Mátíù 5:3.
  • Bí A Ṣe Lè Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • O Lè Ní Àjọṣe Tó Dáa Pẹ̀lú Ọlọ́run
    Jí!—2010
  • O Lè Ní Ayọ̀ Tòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 136
Àwòrán àwọn ọ̀dọ́ láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láyé tó ń ka Bíbélì, wọ́n ń ṣètò àkókó tí wọ́n máa dá kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì ń gbàdúrà.

KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA JÉSÙ

Máa Wáyè Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọlọ́run

Ayé ẹ máa dáa sí i tó o bá ń wáyè láti túbọ̀ mọ Ọlọ́run. Ìyẹn ló máa fi hàn pé o fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Jésù ní ká ṣe tá a bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run.

Ohun tí Jésù sọ

“Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.”—Mátíù 5:3.

  • Gbogbo wa la fẹ́ mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bíi: Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá wa? Kí nìdí tí ìyà fi pọ̀ gan-an láyé? Kí ló ń ṣelẹ̀ sáwọn tó ti kú? Tá a bá mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí, a máa láyọ̀.

“Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè, àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu Jèhófàa jáde ni èèyàn fi ń wà láàyè.”—Mátíù 4:4.

  • Bí oúnjẹ ṣe máa ń jẹ́ kéèyàn wà láàyè, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe ohun táá jẹ́ ká sún mọ́ Ọlọ́run. Jésù sọ pé gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa wojú Ọlọ́run fún ìtọ́sọ́nà.

“Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.”—Jòhánù 17:17.

  • Jésù jẹ́ ká mọ nǹkan tí Ọlọ́run ń lò láti tọ́ wa sọ́nà, ìyẹn ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀.

A rọ̀ ẹ́ pé kó o ṣe ohun tó máa jẹ́ kó o láyọ̀ títí láé. Bó o ṣe lè ṣe é ni pé kó o máa wáyè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, kó o sì máa ṣe ohun tó máa jẹ́ kó o sún mọ́ ọn. Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ rèé:

  • Ka Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́.

  • Ní kí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Ta Ni Jèhófà?”

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́