AUGUST 31–SEPTEMBER 6, 2026
ORIN 89 Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O sì Gba Ìbùkún
Máa Fetí Sílẹ̀ Dáadáa Nípàdé
“Ẹ kíyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.”—LÚÙKÙ 8:18.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa jíròrò ìdí tó fi yẹ ká máa fetí sílẹ̀ dáadáa nípàdé àti láwọn àpéjọ wa, àá tún sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀.
1-2. (a) Kí ni Jèhófà ń pèsè fáwọn èèyàn ẹ̀ lónìí? (Sáàmù 23:1, 2, 5) (b) Kí la máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
Ọ̀PỌ̀ nǹkan ni Jèhófà ń pèsè fún wa lónìí tó ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Àwa náà gbà pẹ̀lú ohun tí Dáfídì sọ pé: “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní.”—Ka Sáàmù 23:1, 2, 5.
2 Àwọn ìpàdé wa jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà pèsè àwọn nǹkan táá jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ la sábà máa ń kọ́ láwọn ìpàdé wa. Síbẹ̀, kò yẹ ká fojú kéré àwọn ẹ̀kọ́ yìí torí pé bá a tiẹ̀ “fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú òtítọ́,” àwọn ìránnilétí yìí ṣì wúlò fún wa. (2 Pét. 1:12) Àmọ́, ó lè má rọrùn fún ẹ láti pọkàn pọ̀ tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ là ń kọ́. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. A máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ ká máa fetí sílẹ̀ dáadáa nípàdé. Yàtọ̀ síyẹn, àá sọ̀rọ̀ nípa báwọn tó ń sọ àsọyé ṣe lè mú kó rọrùn fáwọn ará láti pọkàn pọ̀. Àá tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tá a lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ máa fetí sílẹ̀ dáadáa nípàdé. Àmọ́, tá a bá wà nípàdé, ta ló ń bá wa sọ̀rọ̀ gan-an? Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ dáhùn ìbéèrè yìí.
MÁA RÁNTÍ PÉ JÈHÓFÀ LÓ Ń BÁ WA SỌ̀RỌ̀
3. Kí ni Jèhófà máa ń lò tó bá fẹ́ báwa sọ̀rọ̀, kí làwọn èèyàn ẹ̀ máa ń ṣe tó fi hàn pé wọ́n ń lo Bíbélì dáadáa?
3 Tí Jèhófà bá fẹ́ báwa sọ̀rọ̀, ó máa ń lo Bíbélì. (2 Tím. 3:16, 17) Jésù náà mọ̀ bẹ́ẹ̀. Kódà ó mọ bí wọ́n ṣe ń lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, ìgbà kan tiẹ̀ wà táwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ sọ pé: “Báwo ni ọkùnrin yìí ṣe mọ Ìwé Mímọ́ tó báyìí láìjẹ́ pé ó lọ sáwọn ilé ẹ̀kọ́?” (Jòh. 7:15) Inú àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà dùn gan-an nígbà tí wọ́n gbọ́ bí Jésù ṣe ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, Àpólò àtàwọn Kristẹni ìgbà àtijọ́ máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ tí wọ́n bá ń wàásù fáwọn èèyàn. (Ìṣe 17:2, 3; 18:24, 28) Àwa èèyàn Jèhófà mọ̀ pé Bíbélì ni àwọn ìwé wa, ètò oṣooṣù, àwọn àsọyé àtàwọn fídíò wa máa ń dá lé. Tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá wá sípàdé fúngbà àkọ́kọ́, tí wọ́n sì rí bá a ṣe ń ṣàlàyé Bíbélì, ẹnu máa ń yà wọ́n gan-an. Inú Bíbélì làwọn tó níṣẹ́ nípàdé ti máa ń mú ọ̀rọ̀ wọn, kì í ṣe pé wọ́n kàn máa ń ka Bíbélì nìkan, wọ́n tún máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ bí wọ́n ṣe lè fi í sílò.—Lúùkù 24:32.
4. Tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “gbọ́” àti “fetí sílẹ̀,” kí lohun tó ń sọ?
4 Lọ́pọ̀ ìgbà, tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “gbọ́” àti “fetí sílẹ̀,” ohun tó ń sọ ni pé ká ṣe ohun tẹ́nì náà bá sọ. Torí náà, tí Jèhófà bá ń lo Bíbélì láti báwa sọ̀rọ̀ láwọn ìpàdé wa, ìyẹn á jẹ́ ká mọ ohun tó fẹ́ ká ṣe. Tá a bá sì ti mọ ohun tó fẹ́, á rọrùn fún wa láti ṣègbọràn sí i. Ó dá wa lójú pé inú Jèhófà máa dùn sí wa tá a bá fetí sí i, tá a sì ṣe ohun tó fẹ́.—Òwe 27:11.
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA FETÍ SÍLẸ̀ DÁADÁA NÍPÀDÉ?
5. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí nìyẹn máa jẹ́ ká ṣe? (Jòhánù 4:23, 24; 1 Jòhánù 5:3)
5 A máa ń fetí sílẹ̀ nípàdé torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Mát. 22:37) Bá a bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ìfẹ́ yìí lá sì mú kó máa wù wá láti fetí sí i, òun ló ń jẹ́ ká ṣègbọràn sí i, ká sì máa jọ́sìn ẹ̀ bó ṣe fẹ́.—Ka Jòhánù 4:23, 24; 1 Jòhánù 5:3.
6. Kí là ń kọ́ láwọn ìpàdé wa tó ń jẹ́ ká lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́?
6 A máa ń fetí sílẹ̀ nípàdé torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. (Mát. 22:39) Láwọn ìpàdé wa, Jèhófà máa ń kọ́ wa bá a ṣe lè ran àwọn ará wa lọ́wọ́ títí kan àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn ti jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Nípàdé àárín ọ̀sẹ̀, a máa ń kọ́ bá a ṣe lè fi àwọn àbá tó wà nínú ìwé yìí sílò. Ṣé ó ṣòro fún ẹ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́ tó o bá ń wàásù? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, máa pọkàn pọ̀ dáadáa táwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ bá ń ṣiṣẹ́ ní apá “Tẹra Mọ́ Iṣẹ́ Ìwàásù” nípàdé àárín ọ̀sẹ̀.
7. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fetí sí Jèhófà?
7 A máa ń fetí sílẹ̀ nípàdé torí pé a fẹ́ gbádùn ayé wa títí láé. Bí Jèhófà ṣe sọ fáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ ìgbà àtijọ́, táwa náà bá fẹ́ wà láàyè títí láé, àfi ká ṣègbọràn sí i. (Diu. 32:44-47) Tá a bá ń fetí sílẹ̀ nípàdé, àá gbọ́ àwọn nǹkan tó máa fún wa níṣìírí táá sì jẹ́ ká lè máa fara da ìṣòro wa bá a ṣe ń retí ayé tuntun. (Róòmù 8:25) Torí pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí, ó ṣe pàtàkì ká túbọ̀ máa fetí sí Jèhófà, ìyẹn á jẹ́ ká lè wà lójúfò.—Mát. 24:42-44; Ìfi. 1:3.
OHUN TÁ A LÈ ṢE KÁWỌN MÍÌ LÈ MÁA FETÍ SÍLẸ̀ NÍPÀDÉ
8. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn arákùnrin tó ń ṣiṣẹ́ lórí pèpéle máa ṣiṣẹ́ kára kí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà kọ́ni lè máa sunwọ̀n sí i?
8 Àwọn arákùnrin tó ń ṣiṣẹ́ lórí pèpéle pàápàá àwọn tó ń sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára kí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà kọ́ni lè máa sunwọ̀n sí i. Tí arákùnrin kan bá múra àsọyé ẹ̀ dáadáa tó sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀ dá lórí Bíbélì, ìyẹn lè jẹ́ káwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ pinnu láti wá sin Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, ó lè mú káwọn ará túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Torí náà, má ṣe fojú kéré iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún ẹ lórí pèpéle, máa rántí pé iṣẹ́ náà lè ṣe àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ láǹfààní kí wọ́n sì ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Tó o bá láǹfààní láti máa kọ́ni lórí pèpéle, ronú nípa bó o ṣe lè fi àwọn kókó tá a fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ báyìí sílò. Òótọ́ ni pé àwọn tó ń sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn la dìídì darí ọ̀rọ̀ náà sí, gbogbo àwọn tó bá ń ṣiṣẹ́ lórí pèpéle ló lè fi àwọn ìlànà inú ẹ̀ sílò.—2 Tím. 4:2; Títù 1:9.
9. Kí nìdí tí kò fi yẹ kí àsọyé ẹ lọ́jú pọ̀?
9 Jẹ́ kí kókó inú àsọyé ẹ ṣe kedere. Tó o bá ń sọ àsọyé, ó dájú pé wàá fẹ́ kí àsọyé ẹ rọrùn, káwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ lè máa fọkàn bá ẹ lọ. Tí ọ̀rọ̀ ẹ bá lójú pọ̀, ó lè dà rú mọ́ àwùjọ lójú. Báwo lo ṣe lè gbé àsọyé ẹ kalẹ̀ kó lè yé àwọn èèyàn dáadáa? Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó o lè ṣe rèé: (1) Àtìbẹ̀rẹ̀ ni kó o ti sọ àwọn kókó tó wà nínú àsọyé náà. (2) Ṣàlàyé àwọn kókó náà lọ́kọ̀ọ̀kan, ó máa dáa kó o dánu dúró díẹ̀ tó o bá parí kókó kan, kó o sì jẹ́ kí àwùjọ mọ kókó tó kàn kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé ẹ̀. (3) Ní ṣókí, ṣe àkópọ̀ àwọn kókó náà ní ìparí ọ̀rọ̀ ẹ.
10. Kí nìdí tó fi yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ ohun tó o fẹ́ kọ́ àwọn èèyàn?
10 Nífẹ̀ẹ́ ohun tó o fẹ́ kọ́ àwọn èèyàn. Tí ìwọ fúnra ẹ bá nífẹ̀ẹ́ ohun tó o fẹ́ kọ́ àwọn míì, wàá lè fi ìtara sọ ọ́. (Òwe 2:4, 5; Ìṣe 4:20) Kí lo lè ṣe kó o lè nífẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ ẹ? Ronú jinlẹ̀ lórí àwọn kókó àti ẹsẹ Bíbélì tó wà nínú ìwé àsọyé ẹ, ìyẹn á jẹ́ kó túbọ̀ wọ̀ ẹ́ lọ́kàn. Arákùnrin kan tó ti lé lẹ́ni àádọ́rin (70) ọdún, tó sì ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé òun ṣì máa ń rántí àsọyé kan tóun gbọ́ nígbà tóun wà lọ́dọ̀ọ́. Ó ní: “Mi ò lè gbàgbé bí alásọyé yẹn ṣe gbà wá níyànjú pé ká máa ronú jinlẹ̀ dáadáa tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó fi ìdánilójú sọ̀rọ̀, ó sì ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tó yéni yékéyéké. Àsọyé yẹn yí ìgbésí ayé mi pa dà pátápátá. Ó jẹ́ kí n fọwọ́ pàtàkì mú bí mo ṣe ń ka Bíbélì, ìyẹn sì mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.”
11. Kí làwọn tó ń sọ àsọyé lè kọ́ nínú ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì ní 1 Tímótì 4:13-16?
11 Ronú nípa ohun tó máa ṣe àwùjọ láǹfààní, kó o sì sọ bí wọ́n ṣe lè fi ohun tí wọ́n gbọ́ sílò. Dípò kó o kàn mẹ́nu kan àwọn kókó inú àsọyé náà lóréfèé, á dáa kó o lo Bíbélì láti fún àwùjọ ní ìṣírí àti ìmọ̀ràn tó ṣe pàtó. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún Tímótì láwọn ìmọ̀ràn tó ṣe pàtó nípa ohun tó lè ṣe kó lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà bó ṣe ń ṣiṣẹ́ kára ní Éfésù. (Ka 1 Tímótì 4:13-16.) Ronú nípa ohun tó máa ṣe àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ láǹfààní, kó o sì ṣàlàyé àwọn nǹkan pàtó tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè fi ohun tí wọ́n ń gbọ́ sílò láyé wọn.
12. Kí nìdí tó fi yẹ kó o sọ̀rọ̀ látọkàn wá tó o bá ń sọ àsọyé?
12 Tó o bá ń múra àsọyé ẹ sílẹ̀, máa sọ̀rọ̀ síta, ìyẹn á jẹ́ kó o lè sọ̀rọ̀ látọkàn wá. Káwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ lè máa fọkàn bá ẹ lọ, kí ọ̀rọ̀ ẹ sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn, á dáa kó o sọ̀rọ̀ látọkàn wá dípò kó o máa ka ọ̀rọ̀ ẹ jáde nínú ìwé. Ìwé Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni sọ pé: “Sọ̀rọ̀ bó o ṣe máa ń sọ̀rọ̀ gangan, sọ̀rọ̀ látọkàn wá, jẹ́ kó hàn pé o nífẹ̀ẹ́ ohun tó ò ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ àtàwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀.” Torí náà, tó o bá ń sọ̀rọ̀ látọkàn wá, àwùjọ máa gbádùn ọ̀rọ̀ ẹ dáadáa, á lárinrin, á sì mú kí wọ́n fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò.
13. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ní kí ẹnì kan tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ gbà ẹ́ nímọ̀ràn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
13 Ní kí ẹnì kan tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa gbà ẹ́ nímọ̀ràn. Bí àpẹẹrẹ, kó o tó sọ àsọyé ẹ, o lè fún arákùnrin kan tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ ní ìwé tó o fi múra àsọyé ẹ kó lè sọ àwọn ibi tó o ti lè sunwọ̀n sí i. Lẹ́yìn náà, fi àwọn àbá tó bá fún ẹ sílò tó o bá ń sọ àsọyé náà. Yàtọ̀ síyẹn, sọ fún un pé kó tẹ́tí sí àsọyé náà kó lè fún ẹ nímọ̀ràn táá jẹ́ kó o túbọ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa. (Òwe 1:5) Ohun kan ni pé ìpàkọ́ onípàkọ́ la máa ń rí, ẹlòmíì ló máa ń rí tẹni. Ìyẹn fi hàn pé, a lè má rí àwọn ibi tá a kù sí, ìdí nìyẹn tá a fi nílò ẹnì kan tó lè ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, ohun tó yẹ kó jẹ wá lógún ni bá a ṣe máa mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa ká lè ran àwọn tó ń gbọ́rọ̀ wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.a
Sọ fún ẹnì kan tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kíwọ náà lè mọ̀ọ̀yàn kọ́ (Wo ìpínrọ̀ 13)
OHUN TÓ O LÈ ṢE KÓ O LÈ MÁA FETÍ SÍLẸ̀ DÁADÁA NÍPÀDÉ
14. Kí nìdí tó fi yẹ ká nírú èrò tí ẹni tó kọ Sáàmù 119 ní? (Sáàmù 119:24, 111, 167)
14 Àá túbọ̀ máa fetí sílẹ̀ nípàdé tá a bá mọyì àwọn ìránnilétí Jèhófà. Kò sí àní-àní pé a nílò àwọn ìránnilétí Jèhófà ká lè fara dà àwọn ìṣòro tó wọ́pọ̀ ní ‘àkókò tí nǹkan le gan-an, tó sì nira’ yìí. (2 Tím. 3:1) Kódà tó bá ń ṣe wá bíi pé àìmọye ìgbà la ti gbọ́ ohun tá à ń kọ́ nípàdé, á dáa ká nírú èrò tí ẹni tó kọ Sáàmù 119 ní nípa àwọn ìránnilétí Jèhófà.—Ka Sáàmù 119:24, 111, 167.
15. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọyì àwọn nǹkan tá à ń kọ́ nípàdé?
15 Ó yẹ ká máa rántí pé ẹ̀bùn tó ṣeyebíye tí Jèhófà fún wa làwọn ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ láwọn ìpàdé wa. A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí Jèhófà pèsè mánà fún wọn nínú aginjù. (Ẹ́kís. 16:15, 31) Kò sí àní-àní pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọyì mánà yìí nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ rí i. Ó ṣe tán, Jèhófà ló pèsè ẹ̀ lọ́nà ìyanu, ó tún dùn lẹ́nu, ó sì gbẹ́mìí wọn ró. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, mánà yìí sú àwọn kan lára wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn. (Nọ́ń. 21:5) Kí nìyẹn kọ́ wa? A gbọ́dọ̀ kíyè sára, ká má ṣe máa wo àwọn nǹkan tá à ń kọ́ nípàdé bí àsọtúnsọ lásán. Kàkà bẹ́ẹ̀, ká máa rántí pé àtọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn nǹkan tá à ń kọ́ yìí ti wá. Ó tún yẹ ká fi sọ́kàn pé ètò Ọlọ́run máa ń fara balẹ̀ ronú nípa ohun tá a máa kọ́ nípàdé. Ká má sì gbàgbé pé ohun tá à ń kọ́ ló ń jẹ́ ká máa ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́, táá jẹ́ ká lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Òwe 3:13, 16-18; Jòh. 17:3.
16. Kí ló ran àwọn kan tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́ lọ́wọ́ láti máa fetí sílẹ̀ dáadáa nípàdé? (Tún wo àpótí náà “Ohun Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Máa Fetí Sílẹ̀ Dáadáa Nípàdé.”)
16 Àá túbọ̀ máa fetí sílẹ̀ dáadáa nípàdé tá a bá ń fi àwọn nǹkan tá a fẹ́ sọ yìí sílò. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí àwọn kan tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́ sọ pé ó ran àwọn lọ́wọ́ láti máa fetí sílẹ̀ dáadáa nípàdé. Arábìnrin Ashley tó ti sin Jèhófà fún ohun tó lé ní ọgbọ̀n (30) ọdún sọ pé: “Kò sí àbùjá lọ́rùn ọ̀pẹ, tá a bá múra ìpàdé sílẹ̀, á jẹ́ ká máa fetí sílẹ̀ dáadáa. Tí mi ò bá múra sílẹ̀, mi ò ní lè dáhùn, mi ò sì ní lè pọkàn pọ̀.” Arákùnrin József tó ti sin Jèhófà fún ọdún méjìléláàádọ́ta (52) sọ pé: “Mo gbádùn kí n máa gbọ́ àlàyé táwọn míì ṣe lórí àwọn nǹkan tí mo ti gbọ́ tẹ́lẹ̀. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí n kọ́ àwọn nǹkan tuntun tí mi ò mọ̀ tẹ́lẹ̀.” Ó tún sọ pé: “Tí arákùnrin kan ò bá tiẹ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa, ohun tó ń sọ ni mo máa ń fọkàn sí, kì í ṣe bó ṣe ń sọ̀rọ̀.”
17. Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe kó o lè máa fetí sílẹ̀ dáadáa nípàdé? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
17 Ẹ jẹ́ ká tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan míì tó o lè ṣe kó o lè máa fetí sílẹ̀ dáadáa nípàdé. (1) Tó o bá fẹ́ jẹun kó o tó wá sípàdé, ìwọ̀nba díẹ̀ ni kó o jẹ kó o má bàa máa tòògbé. (2) Máa tètè dé, kó o sì wábi jókòó kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀. (3) Yí fóònù ẹ wálẹ̀ kó má bàa máa dún nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́, ìyẹn á jẹ́ kọ́kàn ẹ pa pọ̀. (4) Máa ronú ohun tó ṣeé ṣe káwọn tó fẹ́ bójú tó iṣẹ́ lórí pèpéle sọ. (5) Máa wojú ẹni tó ń sọ̀rọ̀ lórí pèpéle. (6) Ṣàkọsílẹ̀ àwọn kókó pàtàkì tàbí kó o yàwòrán ẹ̀ sórí ìwé. (7) Máa ronú lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n kà àti bó ṣe tan mọ́ ohun tí wọ́n ń sọ. (8) Bi ara ẹ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè fi ohun tí wọ́n ń sọ yìí ran ẹnì kan lọ́wọ́ nínú ìjọ tàbí lóde ìwàásù?’ (9) Tó o bá wà ní àpéjọ àyíká tàbí agbègbè, ronú nípa àkòrí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, àwọn àsọyé tí wọ́n máa sọ àtàwọn ẹsẹ Bíbélì tí àsọyé kọ̀ọ̀kan dá lé. (10) Jókòó jẹ́ẹ́, kó o sì máa gbọ́ ohùn orin tàbí fídíò orin tá a máa ń gbọ́ kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀, ìyẹn á lè jẹ́ kó o wà ní sẹpẹ́ láti gbádùn ìpàdé náà.
Máa fetí sáwọn ìránnilétí Jèhófà, má ṣe jẹ́ kí fóònù pín ọkàn ẹ níyà (Wo ìpínrọ̀ 17)
MÁA FETÍ SÍ JÈHÓFÀ NÌṢÓ
18. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fetí sílẹ̀ dáadáa nípàdé?
18 Tá a bá ń fetí sílẹ̀ dáadáa nípàdé, Jèhófà á máa darí wa nìṣó “ní ipa ọ̀nà òdodo.” (Sm. 23:3; 31:3) A nílò àwọn ìmọ̀ràn tá à ń gbà nípàdé ká má bàa sú lọ bí ọkọ̀ ojú omi tí ìjì gbé lọ. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa “kíyè sí bí [a] ṣe ń fetí sílẹ̀,” ká sì máa fi ohun tá à ń gbọ́ láwọn ìpàdé wa sílò. (Lúùkù 8:18) Àwọn tó bá ń fetí sí Jèhófà máa láyọ̀ nísinsìnyí, wọ́n sì máa gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú.—Sm. 119:2, 14.
ORIN 87 Ẹ Wá Gba Ìtura
a Tó o bá fẹ́ mọ àwọn nǹkan míì tó o lè ṣe kó o lè mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa, ka ìwé Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni àti ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.