AUGUST 24-30, 2026
ORIN 65 Ẹ Tẹ̀ Síwájú!
Àwùjọ Iṣẹ́ Ìwàásù Máa Ń Ṣe Wá Láǹfààní
“Màá fi gbogbo ọkàn mi yin Jèhófà nínú àwùjọ àwọn adúróṣinṣin.”—SM. 111:1.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Bá a ṣe lè jàǹfààní nínú àwùjọ iṣẹ́ ìwàásù.
1-2. Báwo ni ètò àwùjọ iṣẹ́ ìwàásù ṣe rí lára àwọn ará wa?
ṢÉ O rántí ọjọ́ tó o di akéde Ìjọba Ọlọ́run? Ó dájú pé inú ẹ dùn gan-an, ìdí sì ni pé o ti láǹfààní láti di ọ̀kan lára àwùjọ àwọn èèyàn tó ń yin orúkọ Jèhófà. (Sm. 148:1, 2, 12, 13) Lọ́jọ́ náà, ó tún ṣeé ṣe kí wọ́n pín ẹ sí àwùjọ kékeré kan tí ìwọ̀nba àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin wà nínú ìjọ. Àwùjọ iṣẹ́ ìwàásù ni wọ́n máa ń pè é. Àwùjọ iṣẹ́ ìwàásù máa ń jẹ́ kó rọrùn láti ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa, ìyẹn láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà ní “gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.”—Mát. 24:14.
2 Báwo ni ètò àwùjọ iṣẹ́ ìwàásù ṣe rí lára ẹ? Arábìnrin Wendya sọ pé: “Ètò tí wọ́n ṣe ká lè wà ní àwùjọ kọ̀ọ̀kan ti jẹ́ kí n ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, mo ti wá mọ onírúurú ọ̀nà tí mo lè gbà wàásù kí n sì kọ́ni. Bákan náà, ó jẹ́ kí n láwọn nǹkan tí mo lè máa ṣe táá jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ó sì ti jẹ́ kí n láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́.” Arákùnrin Rich sọ pé: “Mo mọyì àǹfààní tí mo ní láti jẹ́ alábòójútó àwùjọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará nínú ìjọ lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ títí tẹ́ni náà á fi ṣèrìbọmi, alábòójútó àwùjọ tẹ́ni náà wà lá máa ràn án lọ́wọ́ kó lè máa tẹ̀ síwájú sí i.” Arábìnrin Dinah sọ pé: “Mo mọyì bí ètò Ọlọ́run ṣe sọ pé ká máa wà ní àwùjọ àwùjọ! Ṣe làwọn tá a jọ wà láwùjọ dà bí ọmọ ìyá.”
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa kọ́kọ́ jíròrò iṣẹ́ tí alábòójútó àwùjọ àti olùrànlọ́wọ́ ẹ̀ máa ń ṣe. Àá tún jíròrò bí wọ́n ṣe máa ń ran àwọn tó wà láwùjọ wọn lọ́wọ́. Bákan náà, àá sọ̀rọ̀ nípa bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè ran àwọn tó wà láwùjọ wa lọ́wọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, àá wá sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní tí gbogbo wa máa rí tá a bá kọ́wọ́ ti ètò yìí.
IṢẸ́ ALÁBÒÓJÚTÓ ÀWÙJỌ ÀTI OLÙRÀNLỌ́WỌ́ Ẹ̀
4. (a) Kí ni iṣẹ́ alábòójútó àwùjọ? (b) Kí làwọn nǹkan tí alábòójútó àwùjọ lè ṣe kó lè máa bójú tó àwọn tó wà láwùjọ ẹ̀? (Wo àpótí náà “Ohun Táwọn Alábòójútó Àwùjọ Lè Ṣe.”)
4 Ìgbìmọ̀ alàgbà ló máa ń yan alàgbà kanb láti jẹ́ alábòójútó àwùjọ, iṣẹ́ ẹ̀ ni pé kó ran àwọn tó wà láwùjọ ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Báwo ló ṣe ń ṣe é? Àkọ́kọ́, ó máa ń rí i pé ọ̀rọ̀ gbogbo àwọn tó wà láwùjọ ẹ̀ jẹ ẹ́ lógún. (Òwe 27:23) Torí ó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, tó sì wà lójúfò, ó máa ń kàn sí gbogbo àwọn tó wà láwùjọ ẹ̀ déédéé. Ohun míì tó máa ń ṣe ni pé ó máa ń gba àwọn ará níyànjú kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ó máa ń tù wọ́n nínú, ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. (Òwe 12:25; Àìsá. 32:2; Jém. 2:15-17) Ìkejì, ó máa ń ran gbogbo àwọn tó wà láwùjọ ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa wàásù déédéé. Òun náà kì í gbẹ̀yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, pàápàá láwọn òpin ọ̀sẹ̀. Ó tún máa ń bá ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà láwùjọ ẹ̀ ṣiṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kó lè dá wọn lẹ́kọ̀ọ́, kó sì fún wọn níṣìírí. Láwọn ìgbà míì, tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò lè wá sóde ìwàásù, ó máa ń rí i dájú pé olùrànlọ́wọ́ òun tàbí akéde kan tó kúnjú ìwọ̀n wà níbẹ̀, kó lè bójú tó àwùjọ náà. Ìkẹ́ta, ó máa ń ran àwọn arákùnrin tó wà ní àwùjọ ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè kúnjú ìwọ̀n fún àwọn iṣẹ́ pàtàkì míì nínú ìjọ. (1 Tím. 3:1) Ó máa ń gbóríyìn fáwọn tó wà láwùjọ ẹ̀ látọkàn wá, ó máa ń gbà wọ́n nímọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́, ó sì máa ń dá àwọn arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà. Tórí pé iṣẹ́ alábòójútó àwùjọ ṣe pàtàkì gan-an, àwọn alàgbà tó kúnjú ìwọ̀n dáadáa ni ìgbìmọ̀ alàgbà máa ń yàn láti ṣe iṣẹ́ yìí.
5. Àwọn ìṣòro wo làwọn alábòójútó àwùjọ máa ń ní?
5 Iṣẹ́ ńlá làwọn alábòójútó àwùjọ máa ń ṣe kí wọ́n lè bójú tó àwọn tó wà láwùjọ wọn, iṣẹ́ yìí ò sì rọrùn rárá. Alábòójútó àwùjọ ni Jörg tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Jámánì, bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà, òun náà láwọn iṣẹ́ míì tó ń bójú tó nínú ìjọ. Ó sọ pé: “Kò rọrùn kéèyàn láwọn ojúṣe tó pọ̀ láìjẹ́ kí ọ̀kan pa òmíì lára. Ìyẹn kì í jẹ́ kí n lè pe gbogbo àwọn tó wà láwùjọ mi bí mo ṣe pinnu pé màá máa ṣe.” Ẹni àádọ́rin (70) ọdún ni alàgbà kan tó ń jẹ́ Abel, orílẹ̀-èdè Uganda ló sì ń gbé, ó sọ pé: “Àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá a ní níjọ wa ò tó nǹkan rárá. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé àwọn akéde tó wà láwùjọ kọ̀ọ̀kan pọ̀ gan-an. Ó wù mí kí n máa ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ akéde kọ̀ọ̀kan tó wà láwùjọ mi déédéé, àmọ́ kò rọrùn fún mi rárá.” Arákùnrin Obed tóun náà jẹ́ alàgbà lórílẹ̀-èdè Suriname sọ pé: “Ó máa ń wù mí kí n dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ ó máa ń gba àkókò gan-an ó sì máa ń tánni lókun. Ibi tó wá le sí ni pé, ohun tá à ń kọ́ ẹni náà lè má tètè yé e. Torí náà, tíṣẹ́ bá pọ̀ lọ́rùn èèyàn, ìdálẹ́kọ̀ọ́ wà lára ohun téèyàn máa ń kọ́kọ́ pa tì.” Kí làwọn alàgbà lè ṣe tí wọ́n bá nírú ìṣòro yìí àbí àwọn ìṣòro míì?
6. Táwọn tó wà láwùjọ ò bá pọ̀ jù, báwo nìyẹn ṣe máa mú kí iṣẹ́ àwọn alábòójútó àwùjọ rọrùn?
6 Tó bá ṣeé ṣe, kò yẹ káwọn akéde tó wà láwùjọ kọ̀ọ̀kan pọ̀ jù, kó lè rọrùn fáwọn alábòójútó àwùjọ láti mọ àwọn tó wà láwùjọ wọn dáadáa, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Táwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ ò bá pọ̀ ńkọ́? Dípò tí wọ́n á fi jẹ́ káwọn akéde pọ̀ jù láwùjọ kọ̀ọ̀kan débi tí alábòójútó àwùjọ ò fi ní lè bójú tó wọn bó ṣe yẹ, ìgbìmọ̀ alàgbà lè ṣètò pé kí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan máa bójú tó àwùjọ kan fúngbà díẹ̀. Táwọn tó wà láwùjọ ò bá pọ̀, á rọrùn fáwọn alábòójútó àwùjọ láti ṣe ojúṣe wọn tó ṣe pàtàkì jù, ìyẹn ni pé kí wọ́n bójú tó àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn.
7. Táwọn alàgbà ò bá pọ̀ nínú ìjọ kan, kí làwọn alábòójútó àwùjọ lè ṣe kí gbogbo àwọn tó wà láwùjọ wọn lè rí àbójútó tó yẹ? (1 Pétérù 5:2) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
7 Tó bá jẹ́ pé alábòójútó àwùjọ ni ẹ́, táwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ yín ò sì pọ̀, rí i pé ò ń dá olùrànlọ́wọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ kó lè máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó o ṣe ń bójú tó agbo Ọlọ́run. (Ka 1 Pétérù 5:2.) Máa yan iṣẹ́ fún olùrànlọ́wọ́ ẹ. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ó lè sọ pé kó kó àwọn ará jáde lóde ìwàásù. Ẹ lè jọ fọ̀rọ̀ àwọn tó wà láwùjọ yín sádùúrà, kẹ́ ẹ sì sọ bẹ́ ẹ ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Máa mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn ará tó o bá fẹ́ lọ ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, kó o sì sọ ohun tẹ́ ẹ máa ṣe kẹ́ ẹ tó lọ. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá sì kúrò níbẹ̀, o lè sọ àwọn ibi tó ti ṣe dáadáa àtàwọn ibi tó ti lè sunwọ̀n sí i. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, olùrànlọ́wọ́ ẹ náà lè kúnjú ìwọ̀n láti di alábòójútó àwùjọ. (2 Tím. 2:2) O tún lè ní kí àwọn ará míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn bá ẹ dá àwọn tó wà láwùjọ yín lẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, o lè ní kí àwọn aṣáájú-ọ̀nà àtàwọn akéde tó já fáfá bá àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde àtàwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ nírìírí ṣiṣẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn akéde tó já fáfá lè ran àwọn akéde míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ mọ bí wọ́n ṣe lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀, bí wọ́n ṣe lè ṣèpadàbẹ̀wò àti bí wọ́n ṣe lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun mẹ́ta tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe kí nǹkan lè máa lọ bó ṣe yẹ ní àwùjọ iṣẹ́ ìwàásù wa.
Alábòójútó àwùjọ kan lè dá ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó wà láwùjọ ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́, bí àpẹẹrẹ, ó lè ní kó darí ìpàdé iṣẹ́ ìwàásù (Wo ìpínrọ̀ 7)
OHUN TÓ O LÈ ṢE KÍ NǸKAN LÈ MÁA LỌ BÓ ṢE YẸ NÍ ÀWÙJỌ YÍN
8. Kí la lè ṣe kí nǹkan lè máa lọ bó ṣe yẹ ní àwùjọ wa? (Róòmù 1:12)
8 Máa bá àwọn tó wà láwùjọ ẹ jáde. Tó o bá ń bá àwọn tó wà láwùjọ ẹ jáde òde ìwàásù, ẹ̀ẹ́ lè máa “fún ara [yín] ní ìṣírí.” (Ka Róòmù 1:12.) Tẹ́ ẹ bá jọ ń wàásù pa pọ̀ ìyẹn á jẹ́ kọ́kàn yín balẹ̀, pàápàá láwọn agbègbè kan tó dà bíi pé ó léwu, á sì jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ nígboyà láti bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀. Tí iṣẹ́ tó ò ń ṣe ò bá jẹ́ kó o ráyè bá àwọn tó wà láwùjọ ẹ jáde, ṣé o lè bá ọ̀gá ẹ sọ̀rọ̀ bóyá ó lè yí ọjọ́ iṣẹ́ ẹ pa dà? Ó ṣeé ṣe kó gbà. (Neh. 2:4-6) Tó bá jẹ́ pé àìlera tàbí ọjọ́ ogbó ò jẹ́ kó o lè lọ síbi tí àwùjọ yín ti ń pà dé, á dáa kó o sọ fún alábòójútó àwùjọ yín. Ó lè ṣètò pé kó o dara pọ̀ lórí Zoom, kó o sì máa fi lẹ́tà tàbí fóònù wàásù. Ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti lọ sóde ìwàásù déédéé bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́ ni ẹ́ tí ìlera ẹ sì dáa? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o ò ṣe pinnu pé wàá máa bá ẹnì kan ṣiṣẹ́ láwùjọ ẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀? Ó lè gba pé kó o ṣe àwọn àyípadà kan, kó o sì máa fọgbọ́n lo àkókò ẹ. (Róòmù 12:11; Kól. 4:5) Àyípadà yòówù kó o ṣe, gbà pé ó máa ṣe ìwọ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ wà láwùjọ láǹfààní. Bẹ Jèhófà kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, ó máa jẹ́ ‘kó wù ẹ́ láti gbé ìgbésẹ̀, á sì fún ẹ ní agbára’ tó o nílò.—Fílí. 2:13.
9. Kí la lè ṣe kí ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan lè túbọ̀ wà láwùjọ wa? (Róòmù 12:13)
9 Máa gba àwọn èèyàn lálejò. Tẹ́ ẹ bá ń gba ara yín lálejò, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan á túbọ̀ wà láàárín ẹ̀yin tẹ́ ẹ jọ wà láwùjọ. (Ka Róòmù 12:13.) Bí àpẹẹrẹ, ṣé a lè jẹ́ kí àwọn tó wà láwùjọ wa máa pà dé nílé wa fún ìpàdé iṣẹ́ ìwàásù? Láwọn ìjọ kan, ètò ti wà pé tí àlejò bá wá sọ àsọyé, kí àwùjọ kan gbà á lálejò, tí àlejò míì bá sì tún wá, àwùjọ míì á tún ṣe bẹ́ẹ̀. Bóyá àlejò náà lè wá síbi ìkórajọ náà tàbí kò lè ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn tó wà láwùjọ náà lè kóra jọ, kí wọ́n jọ jẹun kí wọ́n sì fún ara wọn níṣìírí. Arábìnrin Sarah tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe sọ pé: “Tí mo bá fẹ́ gba àwọn èèyàn lálejò, ṣe ni mo máa ń kọ́kàn sókè. Torí náà, ohun tí mo bá lè ṣe ni mo máa ń ṣe. Dípò kí n máa ṣe kùrùkẹrẹ nídìí oúnjẹ, bí màá ṣe túbọ̀ mọ àwọn àlejò mi ni mo máa ń gbájú mọ́.” Tá a bá ń gbara wa lálejò, tá a sì ń ṣe bí ọmọ ìyà, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, àá sì mọwọ́ ara wa.—Neh. 8:10; Ìṣe 20:35.
10. Kí la lè ṣe tá a bá fẹ́ túbọ̀ já fáfá láwọn ọ̀nà kan tá à ń gbà wàásù? (Òwe 1:5; 27:17) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
10 Sọ fáwọn míì pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tá a bá já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tá a sì mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa, á máa wù wá láti jáde lọ wàásù, á sì tún máa wù wá láti bá àwọn tó wà láwùjọ wa ṣiṣẹ́. Ṣé apá kan wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tó ti wù ẹ́ kó o ṣe dáadáa sí i? O ò ṣe ní kẹ́nì kan ràn ẹ́ lọ́wọ́, bóyá aṣáájú-ọ̀nà tàbí akéde kan tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa láwùjọ ẹ? (Ka Òwe 1:5; 27:17.) Sọ apá ibi tó ti wù ẹ́ kó o ṣe dáadáa sí i fún alábòójútó àwùjọ ẹ. Ó dájú pé ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. O tún lè ní káwọn míì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ohun tí Arábìnrin Heather tó máa ń tijú ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Kì í rọrùn fún mi láti ṣe ìpadàbẹ̀wò, mo wá ní kí aṣáájú-ọ̀nà kan ràn mí lọ́wọ́. Ó máa ń ní sùúrù, ó sì mára tù mí, ó tún máa ń ṣètò pé ká jọ ṣiṣẹ́ lóde ìwàásù látìgbàdégbà. Ó ràn mí lọ́wọ́ gan-an torí pé nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ìpadàbẹ̀wò mi kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú mi dùn pé mo ní kí aṣáájú-ọ̀nà yìí ràn mí lọ́wọ́, ní báyìí mo ti ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù.” Ẹ ò rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan la lè ṣe kí nǹkan lè máa lọ bó ṣe yẹ ní àwùjọ wa.
Torí pé àwọn tó wà láwùjọ kọ̀ọ̀kan kì í pọ̀, ìyẹn máa ń jẹ́ ká lè mọra wa dáadáa, ká sì jọ máa wàásù (Wo ìpínrọ̀ 10)
ÀǸFÀÀNÍ TÁ À Ń RÍ NÍ ÀWÙJỌ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ WA
11-12. Báwo ni àwùjọ iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? Sọ àpẹẹrẹ kan.
11 Ó ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Bí wọ́n ṣe ṣètò àwùjọ iṣẹ́ ìwàásù lè mú kí gbogbo wa túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, àtìgbàdégbà ni alábòójútó àwùjọ máa ń ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìyẹn àwọn opó, àwọn ọmọ aláìlóbìí àtàwọn àgbàlagbà kó lè fún wọn níṣìírí. (1 Tẹs. 2:8; Jém. 1:27) Bá a tún ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ máa ń jẹ́ ká túbọ̀ já fáfá nínú onírúurú ọ̀nà tá à ń gbà wàásù tá a sì ń kọ́ni. Àwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi tí wọ́n sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere tún máa ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó máa jẹ́ kí wọ́n kúnjú ìwọ̀n láti ṣe àwọn iṣẹ́ pàtàkì míì nínú ìjọ.—1 Tím. 3:10.
12 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa báwọn tó wà ní àwùjọ Wendy tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣe ràn án lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Torí pé bàbá mi ò fẹ́ ká sin Jèhófà, kì í rọrùn fún màámi láti bá àwùjọ wọn jáde òde ìwàásù láwọn òpin ọ̀sẹ̀. Àmọ́, wọ́n gbà kémi máa lọ, torí náà mo máa ń bá àwùjọ wa jáde. Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ti dàgbà fà mí mọ́ra, wọ́n sì kọ́ mi kí n lè túbọ̀ já fáfá lóde ìwàásù àti nínú ìjọ. Mo ṣì máa ń rántí àwọn ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí alábòójútó àwùjọ wa fún mi látinú Bíbélì, títí di báyìí làwọn ìmọ̀ràn náà ṣì ń ṣe mí láǹfààní.”
13. Àǹfààní míì wo la máa ń rí láwùjọ iṣẹ́ ìwàásù wa? (Tún wo àwòrán.)
13 Ó ń jẹ́ ká láwọn ọ̀rẹ́ tó ń dúró tini. Bá a ṣe ń báwọn tó wà láwùjọ wa ṣiṣẹ́ lóde ìwàásù ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ra. (Fílí. 1:27) Torí pé àwọn tó wà láwùjọ kọ̀ọ̀kan kì í pọ̀, ó máa ń rọrùn fáwọn tó ń tijú láti túra ká, kí wọ́n sì láwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. (2 Kọ́r. 6:13) Àwọn ọ̀rẹ́ yìí máa ń dúró tì wá tá a bá ń ṣàìsàn, tá a lẹ́dùn ọkàn tàbí téèyàn wa kan kú. (1 Tẹs. 5:14) Kò sí àní-àní pé a máa nílò àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ yìí gan-an lọ́jọ́ iwájú. (Mát. 24:21) Ti pé a láwọn ọ̀rẹ́ ò túmọ̀ sí pé àwọn ìṣòro wa máa lọ, àmọ́ torí pé àwọn ọ̀rẹ́ yìí nífẹ̀ẹ́ wa tí wọ́n sì máa ń ràn wá lọ́wọ́, ìyẹn máa ń jẹ́ kó rọrùn fún wa láti fara da àwọn ìṣòro náà.—Òwe 17:17.
Àwọn arábìnrin méjì tí wọ́n jọ wà láwùjọ kan náà jọ ń wàásù (Wo ìpínrọ̀ 13)
14. Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, báwo làwọn tó wà láwùjọ wa ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́?
14 Ó máa ń jẹ́ ká rí ìrànlọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Táwọn nǹkan tí ò bára dé bá ṣẹlẹ̀ sí wa, irú bí àjàkálẹ̀ àrùn, inúnibíni, àìsàn òjijì, ìṣòro ìṣúnná owó, tó fi mọ́ àwọn àjálù míì, àwọn tó wà láwùjọ wa máa ń ràn wá lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ níjọ kọ̀ọ̀kan, Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn àtàwọn alábòójútó àwùjọ máa ń ṣètò bí wọ́n á ṣe ran àwọn tó nírú ìṣòro yìí lọ́wọ́. Àwọn alábòójútó àwùjọ ló máa ń ṣètò bí wọ́n á ṣe kàn sí ìdílé kọ̀ọ̀kan tó wà láwùjọ wọn, kí wọ́n lè mọ ohun tí wọ́n nílò, irú bí oúnjẹ, oògùn, omi, ilé, aṣọ àtàwọn nǹkan míì. A mà dúpẹ́ o pé à ń rí ìrànlọ́wọ́ tá a nílò láwọn àwùjọ wa!
15. Kí ló mú kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé Jèhófà wà níṣọ̀kan?
15 Bá a ṣe mọ̀, àwọn tó wà nínú ìdílé Jèhófà pọ̀ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì ló wà lọ́run. Àwa èèyàn ẹ̀ tó wà láyé sì ju mílíọ̀nù mẹ́sàn-án, ojoojúmọ́ la sì ń pọ̀ sí i. (Sek. 8:23; Ìfi. 5:11) Gbogbo àwọn tó ń sin Jèhófà lọ́run àti láyé ló ń ṣiṣẹ́ pọ̀ níṣọ̀kan bí wọ́n ṣe ń kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Ìfi. 14:6, 7) A mà dúpẹ́ o, pé bí wọ́n ṣe ṣètò àwùjọ iṣẹ́ ìwàásù ń jẹ́ ká lè máa fi gbogbo ọkàn wa yin Jèhófà. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè máa kọ́wọ́ ti ètò yìí.—Sm. 111:1.
ORIN 61 Ẹ Tẹ̀ Síwájú, Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
b Tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, wọ́n lè yan ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó kúnjú ìwọ̀n láti máa ṣe iṣẹ́ yìí títí alàgbà míì fi máa gba iṣẹ́ náà. Torí pé arákùnrin náà kì í ṣe alàgbà, ìránṣẹ́ àwùjọ ni wọ́n á máa pè é. Àwọn alàgbà á máa tọ́ ọ sọ́nà nípa bá ṣe máa bójú tó àwọn tó wà láwùjọ náà.