ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
A Ti Ń Sin Jèhófà fún Nǹkan Bí Àádọ́rin Ọdún ní Cuba
ỌDÚN 1947 ni wọ́n bí mi, erékùṣù kan tó rẹwà ní Caribbean lórílẹ̀-èdè Cuba ni wọ́n bí mi sí. Ibẹ̀ wà níbi tí Òkun Caribbean tó gbóná fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ti pàdé Òkun Àtìláńtíìkì. Àbúrò obìnrin méjì ni mo ní, abúlé kan ní Esmeralda ni gbogbo wa sì ń gbé.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé abúlé kékeré là ń gbé, mo rántí pé nǹkan rọrùn gan-an nígbà yẹn. Ibi tá à ń gbé ò jìnnà síbi táwọn mọ̀lẹ́bí wa wà, títí kan àwọn òbí wa àgbà. Ohun tó wù wá là ń jẹ, ọkàn wa sì balẹ̀.
Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún márùn-ún, arákùnrin kan tó ń jẹ́ Walton Jones bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn òbí mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù gan-an, kódà ìrìn wákàtí mẹ́wàá ló máa ń rìn kó tó dé abúlé wa. Tí arákùnrin náà bá ti dé, ọ̀pọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wa ló máa ń kóra jọ sílé àwọn òbí mi àgbà, á sì fi ọ̀pọ̀ wákàtí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn òbí mi àtàwọn àbúrò bàbá mi, ìyẹn Pedro àti Ela fẹ́ràn ohun tí wọ́n ń kọ́ gan-an, kò sì pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n ṣèrìbọmi. Ela ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún báyìí, ó sì ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ ní Cuba.
Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lómìnira láti jọ́sìn Ọlọ́run bá a ṣe fẹ́ lórílẹ̀-èdè Cuba. Táwọn èèyàn bá ti rí àwọn tó ń wàásù láti ilé dé ilé, tí wọ́n sì gbé báàgì tí ìwé kún inú ẹ̀ dání, wọ́n á ti mọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. A máa ń rìn gan-an nígbà yẹn! Nígbà tí mo wà ní kékeré, ọ̀pọ̀ nǹkan amóríyá ló ṣẹlẹ̀ bá a ṣe ń sin Jèhófà láwọn ‘àkókò tí nǹkan rọrùn’ yẹn. Àmọ́, a ò mọ̀ pé ‘àkókò tí nǹkan ò ní rọrùn’ ṣì máa dé.—2 Tím. 4:2.
ÀKÓKÒ TÍ NǸKAN Ò RỌRÙN
Nǹkan bí ọmọ ọdún márùn-ún ṣì ni mí nígbà tí bàbá mi àti àbúrò wọn lọ sí àpéjọ kan lápá ibòmíì ní erékùṣù wa. Nígbà tí wọ́n ń rìnrìn àjò yẹn, wọ́n mu omi kan, ìyẹn sì mú kí wọ́n ní ibà táífọ́ọ̀dù. Mo rántí pé nígbà tí wọ́n dé, àìsàn yìí mú kí irun orí àbúrò bàbá mi bẹ̀rẹ̀ sí í re àmọ́ wọn ò kú. Ó dùn mí pé àìsàn náà ló pa bàbá mi. Ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32) péré ni wọ́n nígbà tí wọ́n kú.
Lẹ́yìn tí bàbá mi kú, màmá mi sọ pé ká lọ máa gbé lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n àwọn, bó ṣe di pé a kó lọ sọ́dọ̀ wọn lábúlé Lombillo nìyẹn. Ìyẹn mú ká jìnnà sáwọn òbí wa àgbà àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa míì tá a nífẹ̀ẹ́ gan-an. Síbẹ̀, a ò fi Jèhófà sílẹ̀.
Ní August 26, 1957, mo ṣèrìbọmi nínú kòtò omi kan nítòsí Lombillo. Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni mí nígbà tá à ń sọ yìí. Mi ò mọ̀ rárá pé kò ní tó ọdún méjì lẹ́yìn ìgbà yẹn tí nǹkan máa yí pa dà fáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Cuba. Lọ́dún 1959, àwọn tó fara mọ́ ìjọba Kọ́múníìsì dìtẹ̀ gbàjọba, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso.
Bó ṣe di pé a bára wa lábẹ́ ìjọba tó sọ iṣẹ́ ológun di dandan nìyẹn o. Wàhálà ńlá nìyẹn dá sílẹ̀ fáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí a kì í dá sọ́rọ̀ òṣèlú àti ogun. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, bó ṣe di pé a ò lómìnira láti sin Jèhófà bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ nìyẹn. Nígbà tó yá, ìjọba fòfin de iṣẹ́ wa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará ni wọ́n sì rán lọ sẹ́wọ̀n. Léraléra ni wọ́n lu àwọn kan nínú wọn, wọn ò sì fún wọn lóúnjẹ. Nígbà míì sí rèé, ẹ̀jẹ̀ máa ń wà nínú oúnjẹ tí wọ́n bá gbé wá, àwọn ará wa yìí ò sì ní lè jẹ ẹ́ torí pé ó ta ko òfin Ọlọ́run.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọrùn lásìkò yẹn, à ń kóra jọ, a sì ń sin Jèhófà. (Héb. 10:25) A tún ṣe àwọn àpéjọ nínú oko àti láwọn ibòmíì káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Mo rántí ìgbà kan tí arákùnrin kan fún wa láyè pé ká ṣe àpéjọ níbi tó ti ń sin àgùntàn. A ò ráyè tún ibẹ̀ ṣe, a ò sì ráyè kó àwọn àgùntàn náà jáde kí àpéjọ tó bẹ̀rẹ̀. Lọ́rọ̀ kan ṣá, bó ṣe di pé àwa àgùntàn Jèhófà àtàwọn àgùntàn arákùnrin náà jọ ṣèpàdé nìyẹn o!—Míkà 2:12.
Àwọn arákùnrin kan wà tí wọ́n rí sí i pé à ń rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà lásìkò yẹn, iṣẹ́ ńlá ni wọ́n ṣe, a sì mọyì wọn gan-an. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa sọ àsọyé àpéjọ àyíká, wọ́n á sì gbohùn ẹ̀ sílẹ̀ sórí kásẹ́ẹ̀tì, wọ́n á wá fi ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ará káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Nígbà míì, arákùnrin méjì péré lá sọ gbogbo àsọyé náà, wọ́n á sì gbohùn ẹ̀ sílẹ̀. Torí pé ibi tí ẹnikẹ́ni ò ti ní rí wọn làwọn arákùnrin yìí ti máa ń gba ohùn àsọyé yìí sílẹ̀, oríṣiríṣi ohùn la máa ń gbọ́ lábẹ́lẹ̀, irú bíi kí àkùkọ kọ. Tí kò bá sí iná mọ̀nàmọ́ná níbi tá a ti fẹ́ ṣe àpéjọ náà, a máa lo ẹ̀rọ kan tí wọ́n dè mọ́ ara kẹ̀kẹ́. Arákùnrin kan á máa yí táyà kẹ̀kẹ́ náà, ẹ̀rọ tó wà lára kẹ̀kẹ́ náà á sì máa múná jáde. Iná yìí la fi máa ń tan rédíò tá a fi ń gbọ́ àwọn àsọyé tí wọ́n gbà sílẹ̀ náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ipò tá a wà ò bára dé, tá ò sì ní ọ̀pọ̀ àwọn ìwé ètò Ọlọ́run bíi tàwọn ará wa tó wà láwọn ibòmíì, kò sígbà tá ò kì í rí oúnjẹ tẹ̀mí. Inú wa sì ń dùn bá a ṣe ń sin Jèhófà pẹ̀lú àwọn ará wa.—Neh. 8:10.
A ṢE AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ, A SÌ TÚN BÍMỌ
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìdínlógún (18), mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé nílùú Florida. Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, mo di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nílùú Camagüey. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé arábìnrin kan tó rẹwà tó ń jẹ́ Emilia, ìlú Santiago de Cuba ló ti wá. A bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra sọ́nà, a sì ṣègbéyàwó láàárín ọdún kan.
(Apá òsì) Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ fáwọn alàgbà ní Camagüey, Cuba lọ́dún 1966
(Apá ọ̀tún) Ọjọ́ ìgbéyàwó wa lọ́dún 1967
Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní ọ̀kan lára àwọn iléeṣẹ́ ìjọba tí wọ́n ti ń ṣe ṣúgà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èmi àti ìyàwó mi ò lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà mọ́, a pinnu láti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Mo ṣètò pé màá máa ṣiṣẹ́ láti aago mẹ́ta òru sí aago mọ́kànlá àárọ̀ níbiṣẹ́. Kì í ṣe pé ó wù mí kí n tètè máa jí, àmọ́ ìyẹn ló jẹ́ kí n máa ráyè lọ sóde ìwàásù déédéé, kí n sì máa lọ sí gbogbo ìpàdé pẹ̀lú ìyàwó mi.
Lọ́dún 1969, a bí Gustavo ọmọ wa àkọ́kọ́. Lákòókò yẹn, ètò Ọlọ́run ní ká máa ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ó wọ́pọ̀ kẹ́ ẹ ráwọn tó ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká tí wọ́n sì tún bímọ lórílẹ̀-èdè Cuba. Ọwọ́ wa dí gan-an nígbà yẹn, síbẹ̀ à ń láyọ̀. Èmi àtìyàwó mi mọyì àǹfààní tí ètò Ọlọ́run fún wa láti máa ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará. Lásìkò tá a ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká, a bí Obed ọmọ wa kejì. Nígbà tó yá, a bí Abner, ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, a bí Mahely ọmọbìnrin wa.
Tí mo bá rántí bí nǹkan ṣe rí láwọn ọdún tá a fi ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká, inú mi máa ń dùn gan-an láti rí bí Jèhófà ṣe bù kún àwọn èèyàn ẹ̀ lórílẹ̀-èdè Cuba. Bákan náà, ó tún ràn wá lọ́wọ́ ká lè kọ́ àwọn ọmọ wa, kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ látọkàn wa. Ní báyìí, ẹ jẹ́ kí n sọ bí nǹkan ṣe rí fún èmi àti Emilia nígbà tá à ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká.
MO ṢIṢẸ́ ALÁBÒÓJÚTÓ ÀYÍKÁ NÍGBÀ TÍ WỌ́N FÒFIN DE IṢẸ́ WA
Nǹkan le sí i láwọn ọdún 1960 àti 1970 torí bí ìjọba ṣe fòfin de iṣẹ́ wa, àwọn ará ò lè lọ sípàdé, wọn ò sì lè wàásù. Wọ́n ti àwọn Ilé Ìpàdé wa, wọ́n sì lé àwọn míṣọ́nnárì kúrò lórílẹ̀-èdè Cuba. Wọ́n mú ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin, wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní Havana.
Nígbà tá à ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká láwọn ọdún 1990
Lásìkò tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa, òpin ọ̀sẹ̀ nìkan la máa ń bẹ ìjọ wò. Torí náà, òpin ọ̀sẹ̀ méjì la fi ń bẹ ìjọ kọ̀ọ̀kan wò. A kì í di ẹrù tó pọ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé kẹ̀kẹ́ la máa ń gùn lọ, ìyẹn ni kì í jẹ́ káwọn ọlọ́pàá fura sí wa. Wọn kì í ṣèfilọ̀ nípàdé pé wọ́n fẹ́ gba ìbẹ̀wò, ṣe la kàn máa ń lọ bíi pé a fẹ́ lọ kí àwọn mọ̀lẹ́bí wa. Ìyẹn ló mú kí nǹkan rọrùn fún wa. Kódà, tá a bá wà pẹ̀lú àwọn ará, ara máa ń tù wá débi pé ṣe la máa ń rán ara wa létí pé ìbẹ̀wò la wá ṣe kì í ṣe pé a kàn wá kí wọn lásán. (Máàkù 10:29, 30) Síbẹ̀ a máa ń ṣọ́ra gan-an, torí pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọlọ́pàá máa ń tẹ̀ lé wa kiri, tí wọ́n sì ń fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò. Kódà wọ́n lè mú àwọn ará tó gbà wá sílé tí wọ́n bá mọ ìdí tá a fi wá sọ́dọ̀ wọn.—Róòmù 16:4.
Láwọn àkókò yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin la pàdé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará yìí ò lówó, wọ́n lawọ́ gan-an. Àwọn agbègbè kan wà tó jẹ́ pé ẹ̀fọn pọ̀ gan-an níbẹ̀, síbẹ̀ àwọn ará wa máa ń yọ̀ǹda nẹ́ẹ̀tì apẹ̀fọn kan ṣoṣo tí wọ́n ní, ká lè sùn dáadáa lóru. Àwọn míì máa ń gbà wá sílé, wọ́n sì máa ń ṣe wá lálejò bó tiẹ̀ jẹ́ pé oúnjẹ díẹ̀ ni wọ́n ní. Àwọn ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé oúnjẹ tá a bá gbé dání la jọ máa ń jẹ.
A ò lè kó gbogbo àwọn ọmọ wa dání tá a bá fẹ́ lọ bẹ ìjọ wò. Torí náà, ọmọ kan péré la máa ń gbé dání, màámi àti àbúrò mi sì máa ń bá wa bójú tó àwọn tó kù nílé. Ohun kan ni pé bá a ṣe máa ń gbé ọmọ dání yìí dáa gan-an, torí kì í jẹ́ kí àwọn ọlọ́pàá fura sí wa. Ìgbà kan wà táwọn ọlọ́pàá ń tú ẹrù wa, àmọ́ a ti kó àwọn ìwé wa sínú báàgì tá a kó ìtẹ́dìí ọmọ tó ti dọ̀tí sí, a sì mọ̀ pé wọn ò ní fẹ́ tú inú báàgì náà.
Obìnrin àtàtà nìyàwó mi, mo mọyì gbogbo nǹkan tó ṣe láti bójú tó àwọn ọmọ wa, tó sì tún ń tì mí lẹ́yìn ní gbogbo àkókò tá a fi ń ṣiṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run gbé fún wa. Ìyẹn ló jẹ́ kó rọrùn fún mi láti ṣiṣẹ́ tí mo fi ń gbọ́ bùkátà, kí n sì tún máa ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká. Ọgbọ́n wo ni mo dá sí i? Nígbà míì, mo máa ń ṣiṣẹ́ tó yẹ kí n fọjọ́ méjì ṣe láàárín ọjọ́ kan, kí n lè ráyè lọ bẹ ìjọ wò lópin ọ̀sẹ̀. Nígbà tó yá, wọ́n sọ mí di ọ̀gá iṣẹ́, èyí sì máa gba pé kí n máa fi gbogbo ọjọ́ méje tó wà nínú ọ̀sẹ̀ ṣiṣẹ́. Ohun tí mo wá ṣe ni pé, mo máa ń fún àwọn tó wà ní ẹ̀ka tí mò ń bójú tó ní iṣẹ́ tó pọ̀ dáadáa lópin ọ̀sẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n níṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe tí mi ò bá tiẹ̀ sí níbẹ̀. Màá wá fi àǹfààní yẹn lọ bẹ ìjọ wò. Mi ò rò pé àwọn ọ̀gá mi mọ̀ rárá pé mi ò kì í wá síbi iṣẹ́ láwọn òpin ọ̀sẹ̀.
MO ṢÌ Ń LÁYỌ̀ BÍ NǸKAN TIẸ̀ YÍ PA DÀ
Àpéjọ agbègbè tá a kọ́kọ́ ṣe lẹ́yìn tí wọ́n mú ìfòfindè náà kúrò lọ́dún 1994
Lọ́jọ́ kan lọ́dún 1994, àwọn arákùnrin tó ń bójú tó iṣẹ́ wa ni Cuba pe gbogbo àwa alábòójútó àyíká, tá a jẹ́ ọgọ́rin (80) sípàdé pàtàkì kan nílùú Havana. Ìdùnnú ṣubú láyọ̀ lọ́jọ́ náà pé gbogbo wa tún pa dà ríra lójúkojú lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún! Níbi ìpàdé náà, a kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn àyípadà tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ètò Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe ìfilọ̀ kan tó kà wá láyà. Àwọn arákùnrin náà sọ fún wa pé wọ́n fẹ́ kọ orúkọ gbogbo wa fáwọn aláṣẹ! A wò ó pé kí nìdí tí wọ́n fi fẹ́ ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀?
Wọ́n ṣàlàyé fún wa pé àwọn ti ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn aláṣẹ bóyá wọ́n á lè fún wa lómìnira ká lè máa jọ́sìn Jèhófà fàlàlà. Àwọn aláṣẹ náà wá ní kí ètò Ọlọ́run fún wọn ní orúkọ gbogbo àwa alábòójútó àyíká. Gbogbo wa fara mọ́ ọn, a sì fún wọn lórúkọ wa. Bó ṣe di pé, nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà fáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn.
Nígbà tó yá, ìjọba fún wa láǹfààní pé ká máa wàásù, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò tíì jẹ́ ká forúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Ẹ̀yìn náà la wá rí i pé àwọn aláṣẹ ti mọ orúkọ àwọn kan lára àwa alábòójútó àyíká, ṣe ni wọ́n kàn fẹ́ ká fúnra wa sọ ọ́ fún wọn.
Ní September 1994, ìjọba fún wa láyè pé ká ṣí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa pa dà. Bá a ṣe pa dà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tí wọ́n ti tì pa fóhun tó lé lógún (20) ọdún nìyẹn!
Lọ́dún 1996, wọ́n pe èmi àtìyàwó mi láti ẹ̀ka ọ́fíìsì pé ká wá máa sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Ó yà wá lẹ́nu gan-an, a wá sọ fáwọn tó pè wá pé a ṣì lọ́mọ méjì tó wà lọ́dọ̀ wa, àwa la sì ń bójú tó wọn. Àwọn arákùnrin náà sọ pé ọ̀rọ̀ wa yé wọn, àmọ́ àwọn ṣì fẹ́ ká wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Bá a ṣe gbà láti lọ nìyẹn, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í múra bí gbogbo wa ṣe máa kó lọ sílùú Havana tí ẹ̀ka ọ́fíìsì wà.
(Apá òsì) Emilia ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tí Wọ́n Ti Ń Ránṣọ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Cuba
(Apá ọ̀tún) À ń ya Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan sí mímọ́ lọ́dún 2012
Kí n sòótọ́, mi ò kọ́kọ́ gbádùn iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì. Ìdí sì ni pé ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká, mo sì gbádùn iṣẹ́ náà gan-an. Kò rọrùn fún mi bí mo ṣe wà lójú kan ní Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́, àwọn tá a jọ ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì títí kan ìyàwó mi ràn mí lọwọ́ kí n lè rí bí iṣẹ́ mi ṣe ń ṣe àwọn ará láǹfààní. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn iṣẹ́ ìsìn mi ní Bẹ́tẹ́lì, mo sì ń láyọ̀.
(Apá òsì) Ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Tọkọtaya lọ́dún 2013
(Apá ọ̀tún) Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Cuba lọ́dún 2013
Àwa àti ọmọbìnrin wa pẹ̀lú ọkọ ẹ̀ ní àpéjọ àyíká
Ní báyìí, èmi àtìyàwó mi ti dàgbà. Ayọ̀ wa máa ń kún tá a bá ronú nípa àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tá a mọ̀ tá a sì bá ṣiṣẹ́ láti àwọn ọdún yìí wá. Inú wa tún dùn pé àwọn ọmọ wa àtàwọn ọmọ ọmọ wa ń sin Jèhófà. Àpọ́sítélì Jòhánù tó ti dàgbà sọ pé: “Kò sí ohun tó ń mú inú mi dùn bíi kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń rìn nínú òtítọ́.” (3 Jòh. 4) Bọ́rọ̀ sì ṣe rí lára àwa náà nìyẹn.
Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọgbọ̀n (30) ọdún témi àti Emilia ti ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe bó tiẹ̀ jẹ́ pé àrùn jẹjẹrẹ àti ara tó ti ń dara àgbà ò jẹ́ kí nǹkan rọrùn fún wa. Òótọ́ ni pé onírúurú ìṣòro la ti ní bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ ìsìn Jèhófà láwọn ọdún yìí wá, àmọ́ inú wa dùn pé ó ti tó nǹkan bí àádọ́rin (70) ọdún báyìí tá a ti ń sin Jèhófà “Ọlọ́run aláyọ̀” ní erékùṣù Cuba.—1 Tím. 1:11; Sm. 97:1.