AUGUST 17-23, 2026
ORIN 90 Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú
Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Àwọn Ará Wa
“Ẹ fi ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti àánú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀, ìwà tútù àti sùúrù wọ ara yín láṣọ.”—KÓL. 3:12.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Ohun tá a lè ṣe kí ohunkóhun má bàa da àárín àwa àtàwọn ará rú.
1. Ibo la ti lè rí àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́?
“KÒ RỌRÙN rárá ní àkókò yìí láti wà láìlọ́rẹ̀ẹ́. Jèhófà mọ̀ pé a nílò ọ̀rẹ́ gidi láyé wa.” Ṣé o rántí pé àwọn ọ̀rọ̀ yìí ló bẹ̀rẹ̀ ọ̀kan lára orin wa míì tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Ọ̀rẹ́ Tòótọ́”? Inú wa dùn pé a láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ láàárín àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà! (Sm. 119:63) Ọmọ ìyá ni gbogbo wa, ìfẹ́ ló so wá pọ̀, a sì ń jọ́sìn Jèhófà níṣọ̀kan.
2. Irú ọ̀rẹ́ wo ló yẹ ká jẹ́ sáwọn ará wa?
2 Kì í ṣe ọ̀rẹ́ òkèèrè la máa ń bá àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣe. Dípò bẹ́ẹ̀, a máa ń sún mọ́ wọn dáadáa, a sì máa ń nífẹ̀ẹ́ wọn dénú. Ìdílé kan ni gbogbo wa, a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù, ìfẹ́ yìí ló sì so wá pọ̀. (Jòh. 13:35) Àmọ́, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára ká tó lè di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ará wa. Láwọn ìgbà míì, àwọn ìṣòro kan máa ń yọjú tó lè mú kó nira láti sún mọ́ ara wa, ìdí sì ni pé aláìpé ni wá.
3. Kí ló lè mú kó ṣòro láti jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn ará wa?
3 Ká sòótọ́, ó máa ń rọrùn fún wa láti sún mọ́ àwọn kan ju àwọn míì lọ. Kí nìdí? Ó lè jẹ́ pé a jọ fẹ́ràn ohun kan náà tàbí kó jẹ́ pé ìwà wa jọra. Àmọ́ ó lè má rọrùn fún wa láti mú àwọn míì lọ́rẹ̀ẹ́ nínú ìjọ. Nígbà míì, a lè ní èdèkòyédè pẹ̀lú ẹnì kan, ìyẹn sì lè mú kó ṣòro láti sún mọ́ ẹni náà. Àwọn míì sì wà tó jẹ́ pé ìwà wa ò jọra, ó sì lè máa ṣe wá bíi pé kò sóhun tó lè pa wá pọ̀. Tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá sì ní ẹ̀dùn ọkàn tàbí tára ẹ̀ ò yá, ó lè má rọrùn láti sún mọ́ ọn bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, á máa sọ̀rọ̀ nípa bí àpẹẹrẹ Jésù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn ará nígbà táwọn nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ tó lè mú kó ṣòro láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwà tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn ará wa.
ÀWỌN ÌWÀ TÓ LÈ MÚ KÁ TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ ARA WA
4. Kí ló máa jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará wa?
4 Ó ṣe pàtàkì ká máa wo ibi táwọn ará wa dáa sí, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ra. Tá a bá ń wà pẹ̀lú wọn, a máa rí àwọn ìwà dáadáa tí wọ́n ní. Ó wu àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kó wà pẹ̀lú àwọn ará, ìdí nìyẹn tó fi kọ̀wé sáwọn ará ní Tẹsalóníkà pé: ‘A sa gbogbo ipá wa láti rí yín lójúkojú.’ (1 Tẹs. 2:17) Ọ̀pọ̀ àwọn ará gbà pé kò sóhun tó dà bíi kéèyàn máa bá ọ̀rẹ́ ẹ̀ sọ̀rọ̀ lójúkojú, torí ìyẹn máa jẹ́ kí àárín yín túbọ̀ gún régé. A máa ń láǹfààní láti bá àwọn ará wa sọ̀rọ̀ lójúkojú tá a bá lọ sóde ìwàásù, tá a wá sí ìpàdé tàbí àwọn àpéjọ wa. Àmọ́, ti pé à ń wà pẹ̀lú àwọn ará ò túmọ̀ sí pé a ò ní láwọn ìṣòro tó lè da àárín wa rú.
5. Táwọn ìṣòro tó lè da àárín wa rú bá yọjú, kí la lè ṣe? Ṣàpèjúwe. (Kólósè 3:12)
5 Táwọn ìṣòro tó lè da àárín wa rú bá yọjú, àwọn ìwà rere tí Bíbélì sọ máa ràn wá lọ́wọ́ láti borí ẹ̀. (Ka Kólósè 3:12.) Tá a bá nírẹ̀lẹ̀, tá à ń ṣe sùúrù, tá a jẹ́ onínúure, tá a sì ń ṣàánú àwọn èèyàn, ìyẹn á jẹ́ ká lè borí ìṣòro èyíkéyìí tó bá fẹ́ da àárín wa rú. Bí àpẹẹrẹ, bí ọ́ìlì ṣe máa ń mú kí ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ ṣiṣẹ́ dáadáa, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ìwà rere tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn máa ń jẹ́ kí nǹkan lọ dáadáa láàárín àwa àtàwọn ará. Ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan mẹ́ta tó lè mú kó ṣòro láti jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn ará. Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá sọ̀rọ̀ nípa bí Jésù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, onísùúrù, onínúure àti aláàánú, àá sì sọ báwa náà ṣe lè fìwà jọ ọ́ ká lè túbọ̀ jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́.
TÍ ÈDÈKÒYÉDÈ BÁ ṢẸLẸ̀
6. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ táwọn méjì bá ní èdèkòyédè?
6 Ìṣòro tó máa ń fà. Tí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn méjì, kálukú wọn lè ronú pé èrò tòun ló tọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn arákùnrin méjì lè ní èrò tó yàtọ̀ síra nípa bí wọ́n ṣe máa ṣètò iṣẹ́ ìwàásù ní àwùjọ wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà pé èrò tòun ló dáa jù. Ìgbéraga lè mú kí wọ́n máa rin kinkin mọ́ èrò wọn, kí wọ́n má sì gba èrò ẹnì kejì. Ṣé ẹ rí i pé tí wọn ò bá ṣọ́ra, ohun tí ò tó nǹkan lè di ńlá mọ́ wọn lọ́wọ́. Tí wọn ò bá tètè yanjú ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í di ara wọn sínú. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n lè má bára wọn sọ̀rọ̀ mọ́, kí wọ́n má sì jẹ́ ọ̀rẹ́ mọ́ torí ohun tí ò tó nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láàárín wọn.
7. Báwo ni Jésù ṣe kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé ìrẹ̀lẹ̀ ṣe pàtàkì tí wọ́n bá fẹ́ yanjú èdèkòyédè?
7 Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ bíi Jésù. Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé tí wọ́n bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè tètè máa yanjú èdèkòyédè tó bá ṣẹlẹ̀ láàárín wọn. Ó ṣe díẹ̀ táwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ ti ń bára wọn jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù láàárín wọn. Kí wọ́n lè borí ìwà tí ò dáa tó ti mọ́ wọn lára yìí, Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ gbà pé àwọn míì sàn jù wọ́n lọ. (Mát. 20:25-28) Jésù kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè nírẹ̀lẹ̀. Kódà ní alẹ́ tó máa lò kẹ́yìn pẹ̀lú wọn, ó ṣiṣẹ́ táwọn ìránṣẹ́ máa ń ṣe, ó fọ ẹsẹ̀ wọn kó lè “fi àpẹẹrẹ lélẹ̀” fún wọn. (Jòh. 13:3-5, 12-16) Ohun tí Jésù ṣe yìí máa jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe kí àárín wọn má bàa dà rú. Táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù bá gbà pé àwọn míì sàn ju àwọn lọ, á rọrùn fún wọn láti fara mọ́ ohun táwọn míì bá sọ tí èrò wọn bá tiẹ̀ yàtọ̀, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí àárín wọn dà rú.
8. Tó o bá nírẹ̀lẹ̀, báwo nìyẹn ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀? (Kólósè 3:13) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
8 Ohun tó o lè ṣe tí àjọṣe yín ò fi ní bà jẹ́. Ìrẹ̀lẹ̀ máa ń jẹ́ ká lè gbójú fo àwọn nǹkan kéékèèké táwọn míì bá ṣe, ká sì dárí jì wọ́n fàlàlà. (Ka Kólósè 3:13.) Tá a bá nírẹ̀lẹ̀, a ò ní bínú débi tá a fi máa ṣi ọ̀rọ̀ sọ tí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí àjọṣe wa bà jẹ́. (Sm. 4:4) Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti sọ̀rọ̀ síra yín, ẹ máa rántí pé kò sẹ́ni tí kì í ṣi ọ̀rọ̀ sọ. (Oníw. 7:21, 22) Bi ara ẹ pé, ‘Ṣé bí mo ṣe máa fi hàn pé èmi ni mo jàre ló ṣe pàtàkì jù ni, àbí bí àárín wa ò ṣe ní dà rú?’ Nígbà míì, o lè pinnu láti gbà fún ẹnì kejì kí àlàáfíà lè wà. Tó ò bá ronú nípa ọ̀rọ̀ yẹn mọ́, tó ò sì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ mọ́, kò ní pẹ́ tí wàá fi gbàgbé, ọkàn ẹ sì máa balẹ̀.
Tá a bá nírẹ̀lẹ̀, àá lè máa gbójú fo àwọn àṣìṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ táwọn ará wa ṣe, àá sì máa dárí jì wọ́n fàlàlà (Wo ìpínrọ̀ 8)a
9. Tó o bá nírẹ̀lẹ̀, báwo nìyẹn ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí èdèkòyédè náà ò bá yanjú bọ̀rọ̀? (Òwe 17:9)
9 Ìrẹ̀lẹ̀ tún máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí èdèkòyédè náà ò bá yanjú bọ̀rọ̀. Má ṣe máa jiyàn káwọn èèyàn ṣáà lè gbà pé èrò ẹ ló tọ̀nà. (Ka Òwe 17:9; 1 Kọ́r. 6:7) Ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì sí ẹ ni bí àárín ìwọ àtọ̀rẹ́ ẹ ò ṣe ní dà rú. Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ti yanjú èdèkòyédè tó wáyé láàárín wọn. Ohun tí wọ́n ṣe ni pé, wọ́n pe ẹni tọ́rọ̀ jọ ṣe bí ọ̀rọ̀ láàárín wọn, wọ́n sì yanjú ẹ̀ nítùbí-ìnùbí. (Sm. 34:14) Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, o lè lọ bá ẹni náà, kó o sì sọ fún un pé: ‘Ó pẹ́ tá a ti ń bá ọ̀rẹ́ wa bọ̀, kò yẹ ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí ò tó nǹkan dá wàhálà sílẹ̀ láàárín wa. Ó wù mí ká yanjú ọ̀rọ̀ yìí.’ Ó yẹ kó o ṣe tán láti gba ẹ̀bi ẹ lẹ́bi, gbà pé ohun tó ṣẹlẹ̀ dun ẹni náà, kó o sì tọrọ àforíjì. Tẹ́ni náà bá sì tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ẹ, dárí jì í kó o sì gbàgbé ọ̀rọ̀ náà. (Lúùkù 17:3, 4) Má gbàgbé pé bí àárín ìwọ àtọ̀rẹ́ ẹ ṣe máa pa dà gún régé lohun tó ṣe pàtàkì, kì í ṣe ẹni tó jẹ̀bi tàbí jàre.—Òwe 18:24.
TÍ ÌWÀ YÍN BÁ YÀTỌ̀
10. Kí ló lè mú kó ṣòro fún wa láti sún mọ́ àwọn kan nínú ìjọ?
10 Ìṣòro tó máa ń fà. Ó lè má rọrùn láti sún mọ́ àwọn ará wa kan torí pé ìwà wọn yàtọ̀ sí tiwa. Bí àpẹẹrẹ, ìwà àwọn kan lè rí bákan lára wa. Ará àwọn kan lè má yá mọ́ọ̀yàn, kí wọ́n sì rọra máa ṣe tiwọn. Ní tàwọn míì, wọ́n máa ń ṣàwàdà, wọ́n sì máa ń sọ̀rọ̀ gan-an. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ibi tí wọ́n ti tọ́ wọn dàgbà tàbí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn ló mú kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sì lè jẹ́ pé ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí ló yàtọ̀ sí tàwọn míì. A lè fẹ́ràn ká máa wà láàárín àwọn èèyàn ṣùgbọ́n káwọn máa tijú, ó sì lè jẹ́ pé àwa là ń tijú káwọn sì fẹ́ràn kí wọ́n máa wà láàárín àwọn èèyàn.
11. Kí ló mú kí Jésù lè jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn tí ìwà wọn yàtọ̀ sí tiẹ̀?
11 Máa ní sùúrù bíi Jésù. Onírúurú àwọn tí ìwà wọn yàtọ̀ sí tiẹ̀ ni Jésù mú lọ́rẹ̀ẹ́ nígbà tó wà láyé. Bí àpẹẹrẹ, ìgbéraga ló mú kí àpọ́sítélì Jémíìsì àti Jòhánù sọ fún Jésù pé kó fi àwọn sí ipò pàtàkì nínú Ìjọba ẹ̀. (Máàkù 10:35-37) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù ní ló mú kó fi ipò gíga tó wà lọ́run sílẹ̀ kó lè wá sáyé. (Fílí. 2:5-8) Ẹ ò rí i pé ìwà wọn yìí yàtọ̀ síra! Síbẹ̀, Jésù mú sùúrù fún Jémíìsì, Jòhánù àtàwọn míì.
12. Kí ló jẹ́ kí Jésù mú sùúrù fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀?
12 Jésù mọ̀ pé àwọn ọ̀rẹ́ òun kì í ṣe ẹni pípé, torí náà wọ́n lè ṣàṣìṣe. Ó mọ̀ pé ẹ̀mí ìdíje tó wà láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn òun ló mú kí Jémíìsì àti Jòhánù béèrè ohun tí wọ́n béèrè. (Máàkù 9:34) Jésù mọ ìṣòro wọn, ó ṣe tán, agbègbè tí wọ́n dàgbà sí lòun náà dàgbà sí. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn èèyàn máa ń gbé àwọn tó wà nípò ńlá gẹ̀gẹ̀, torí náà ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ wà nípò pàtàkì. Láìka ìwà yìí sí, Jésù mú sùúrù fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀ torí ó mọ̀ pé ó máa ṣe díẹ̀ kí wọ́n tó lè fi ìgbéraga àti wíwá ipò ńlá tó ti mọ́ wọn lára sílẹ̀.—Máàkù 10:42-45.
13. Tá a bá ní sùúrù, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká túbọ̀ jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wa? (Éfésù 4:2)
13 Ohun tó o lè ṣe tí àjọṣe yín ò fi ní bà jẹ́. Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kó o lè túbọ̀ máa mú sùúrù fáwọn èèyàn kódà tí ìwà wọn bá rí bákan lára ẹ. (Òwe 14:29) Kálukú wa ló ní ohun tá à ń ṣe tó mú ká yàtọ̀ sáwọn míì, àwọn nǹkan yìí kì í sì í ṣe àbùkù irú ẹni tá a jẹ́ ni. Torí náà, inú wa máa ń dùn táwọn èèyàn bá gbà wá bá a ṣe rí. (Ka Éfésù 4:2.) Ohun tó yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn, ká máa gba àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe rí. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ìsapá tó máa gba ẹni tó ń tijú láti sún mọ́ àwọn èèyàn, kó sì máa bá wọn sọ̀rọ̀. Lọ́wọ́ kejì, ó lè gba pé ká ṣe sùúrù tá a bá wà pẹ̀lú ẹnì kan tó máa ń ṣeré tó sì máa ń sọ̀rọ̀ gan-an. Òótọ́ kan ni pé a ò lè di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú gbogbo èèyàn, àmọ́ ká fi sọ́kàn pé ti pé ìwà wa yàtọ̀ síra ò túmọ̀ sí pé a ò lè mọwọ́ ara wa.
14. Tá a bá ní sùúrù, kí nìyẹn máa mú ká ṣe?
14 Tá a bá ní sùúrù, ibi táwọn ará wa dáa sí làá máa wò. Ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wa bí ìwà wa tiẹ̀ yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jémíìsì àti Jòhánù ń wá ipò ńlá fúnra wọn, ohun tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ Jésù jẹ́ ká rí i pé wọ́n gbà pé Ìjọba Ọlọ́run wà lóòótọ́. Jésù rí ọkàn wọn, ó sì mọyì bí wọ́n ṣe nígbàgbọ́. Tó bá jẹ́ pé ibi táwọn ọ̀rẹ́ wa dáa sí là ń wò, Jésù àti Jèhófà la fìwà jọ.
15. Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ sún mọ́ àwọn tí ìwà wọn yàtọ̀ sí tiwa?
15 Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká bẹ Jèhófà kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè túbọ̀ sún mọ́ àwọn tí ìwà wọn yàtọ̀ sí tiwa. Ronú nípa ohun tẹ́ni náà lè ṣe táá bí ẹ nínú, kó o wá gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe sùúrù. Máa rántí pé Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa mọ̀ pé gbogbo wa ò rí bákan náà. Torí náà, tó o bá ń gbàdúrà jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa ṣe sùúrù. Tó bá sì ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò lè ní sùúrù mọ́, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ kó o má bàa ṣìwà hù.—Lúùkù 11:13; Gál. 5:22, 23.
TÁWỌN ARÁ WA BÁ NÍṢÒRO
16. Kí làwọn ará wa lè máa ṣe tí wọ́n bá níṣòro?
16 Ìṣòro tó máa ń fà. Táwọn ará wa bá ní ẹ̀dùn ọkàn tàbí tí wọ́n ń ṣàìsàn, wọ́n lè sọ̀rọ̀ tàbí hùwà tó máa rí bákan lára wa. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè máa kanra, kí wọ́n má dá sí ẹnì kankan tàbí kí wọ́n ṣe ohun tá ò retí pé kí wọ́n ṣe. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n sọ̀rọ̀ tàbí hùwà tó lè bí wa nínú. (Jóòbù 6:2, 3) Torí pé a ò mọ ohun táwọn ará wa ń bá yí nígbà míì, ìyẹn lè mú kó máa ṣe wá bíi pé kò yẹ kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n ṣe tàbí sọ ohun tí wọ́n sọ.
17. Kí ní Jésù ṣe nígbà tó rí Báátíméù, kí la sì lè rí kọ́?
17 Jẹ́ onínúure àti aláàánú bíi Jésù. Jésù máa ń ṣàánú àwọn tó níṣòro, ó sì máa ń finúure hàn sí wọn bí ò tiẹ̀ mọ̀ wọ́n rí. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ohun tó ṣe nígbà tó fẹ́ la ojú Báátíméù. Nígbà tí Báátíméù gbọ́ pé Jésù ń kọjá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo kí Jésù lè rí òun. Lára àwọn tó wà níbẹ̀ sọ fún Báátíméù pé kó dákẹ́. Àmọ́ kò dá wọn lóhùn, ṣe ló tún gbóhùn sókè, torí ó fẹ́ kí Jésù wo òun sàn. Ó ṣeé ṣe kí ohun tó ṣe yìí rí bákan lára àwọn tó wà níbẹ̀, ó tiẹ̀ lè máa bí wọn nínú. Àmọ́, ‘àánú ọkùnrin náà ṣe Jésù,’ ìyẹn sì fi hàn pé ẹlẹ́yinjú àánú ni. (Mát. 20:34; Máàkù 10:46-52) Ó bá Báátíméù sọ̀rọ̀ lọ́nà tó tù ú lára, ó sì yìn ín torí ìgbàgbọ́ ẹ̀. Lẹ́yìn náà, Jésù la ojú ẹ̀ lọ́nà ìyanu.
18. Kí ló yẹ ká ṣe fáwọn ọ̀rẹ́ wa tó níṣòro? (1 Tẹsalóníkà 5:14)
18 Ohun tó o lè ṣe tí àjọṣe yín ò fi ní bà jẹ́. Jẹ́ aláàánú àti onínúure. Àwọn ìwà dáadáa yìí á jẹ́ kó o lè máa “sọ̀rọ̀ ìtùnú” fáwọn ará tó ń ṣàìsàn tàbí tó ní ẹ̀dùn ọkàn. (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:14.) Má gbàgbé pé àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń ran ara wọn lọ́wọ́ ní “ìgbà wàhálà.” (Òwe 17:17) Irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń bára wọn kẹ́dùn nígbà ìṣòro, wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ìtùnú, wọ́n máa ń dúró ti ara wọn, wọ́n sì máa ń ran ara wọn lọ́wọ́.
19. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi àánú àti inúure hàn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
19 Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi àánú àti inúure hàn sẹ́nì kan? Òótọ́ ni pé, táwọn ará wa bá ń ṣàìsàn a ò lè wò wọ́n sàn. Àmọ́ a lè bá wọn kẹ́dùn, ká sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kọ́rọ̀ wọn lè yé wa. (Mát. 7:12; 1 Pét. 3:8) Tí wọ́n bá ń sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn, á dáa ká tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa. Tá a bá rí i pé ó yẹ ká sọ̀rọ̀, ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa tù wọ́n lára. (Òwe 12:25) Má rò pé o ti mọ gbogbo bí nǹkan ṣe rí lára wọn. (Òwe 18:13) Ṣe sùúrù pẹ̀lú wọn, má sì jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun kan tó ò retí.—Éfé. 4:32.
Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń fi hàn pé aláàánú àti onínúure ni wọ́n tí wọ́n bá ń tu ara wọn nínú (Wo ìpínrọ̀ 19)
20. Irú ọ̀rẹ́ wo ló yẹ kó o jẹ́?
20 Gbogbo wa la mọyì ẹ̀ pé ọ̀rẹ́ àtàtà làwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Àmọ́ ó yẹ ká máa rántí pé aláìpé ni gbogbo wa, torí náà kò sí bá ò ṣe ní máa ṣẹ ara wa láwọn ìgbà míì. Àwọn nǹkan tí ò dáa tó ti ṣẹlẹ̀ sáwọn kan nínú wa ló mú kí wọ́n máa ṣe bí wọ́n ṣe ń ṣe. Síbẹ̀, a mọyì àwọn ará wa tí wọ́n nírẹ̀lẹ̀, tí wọ́n ní sùúrù, tí wọ́n láàánú, tí wọ́n sì jẹ́ onínúure torí pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni wọ́n. Ohun tó yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn ká lè fi hàn pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni wá.
ORIN 124 Jẹ́ Adúróṣinṣin
a ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arákùnrin àgbàlagbà kan àti arákùnrin kan tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ ní èrò tó yàtọ̀ síra nípa bí wọ́n á ṣe ṣètò ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Nígbà tó yá, àwọn méjèèjì jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ìwàásù.