AUGUST 10-16, 2026
ORIN 122 Ẹ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin
Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Olóòótọ́ Lójú Àdánwò
“Olúwa, ọ̀dọ̀ ta la máa lọ? Ìwọ lo ní àwọn ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”—JÒH. 6:68.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láìka àdánwò yòówù kó dé bá wa sí.
1-2. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn ní Kápánáúmù?
NÍGBÀ tí Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn ní Kápánáúmù, ó sọ ohun kan tó ya àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ lẹ́nu, kódà àwọn kan nínú wọn sọ pé: “Ọ̀rọ̀ yìí ń dẹ́rù bani; kò ṣeé gbọ́ sétí!” (Jòh. 6:60) Kí ni Jésù sọ gan-an? Ó ní: “Láìjẹ́ pé ẹ jẹ ẹran ara Ọmọ èèyàn, tí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ ò ní ìyè kankan nínú ara yín.” Ó tún sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ń jẹ ẹran ara mi, tó sì ń mu ẹ̀jẹ̀ mi máa ní ìyè àìnípẹ̀kun, màá sì jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.”—Jòh. 6:53, 54.
2 Ohun tí Jésù sọ yìí bí àwọn kan nínú, wọ́n sì pa dà lẹ́yìn ẹ̀. Kí nìdí tí wọ́n fi pa dà lẹ́yìn ẹ̀, ṣé torí pé wọn ò nígbàgbọ́ nínú ẹ̀ ni? Ṣáájú àkókò yìí, Jésù ṣe ohun kan tó wú àwọn èèyàn náà lórí gan-an, títí kan àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, wọ́n tiẹ̀ sọ pé: “Ó dájú pé Wòlíì tí wọ́n ní ó máa wá sí ayé nìyí.” (Jòh. 6:14) Ìyẹn fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú Jésù. Àmọ́ nígbà tí ohun kan ṣẹlẹ̀ tó dán ìgbàgbọ́ wọn wò, wọ́n fi Jésù sílẹ̀.
3. Kí ni àwọn àpọ́sítélì ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́rọ̀ Jésù, kí sì nìdí? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
3 Ohun táwọn àpọ́sítélì ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́rọ̀ Jésù yàtọ̀ sí tàwọn tó kù. Nígbà tí Jésù béèrè pé ṣáwọn náà ò ní lọ ni, Pétérù dáhùn pé: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta la máa lọ? Ìwọ lo ní àwọn ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun. A ti gbà gbọ́, a sì ti mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.” (Jòh. 6:68, 69) Ṣẹ́ ẹ kíyè sí i pé nígbà tí Jésù ní wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ ẹran ara òun, kí wọ́n sì mu ẹ̀jẹ̀ òun, Pétérù ò sọ pé ohun tí Jésù sọ yìí yé òun àtàwọn àpọ́sítélì yòókù dáadáa. Bóyá ohun tí Jésù sọ lákòókò yẹn yé wọn àbí kò yé wọn, wọ́n pinnu pé àwọn ò ní fi Jésù sílẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó dá wọn lójú pé Jésù ni “Kristi ti Ọlọ́run.”—Lúùkù 9:20, 35.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ló pa dà lẹ́yìn Jésù, Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì tó kù dúró tì í (Wo ìpínrọ̀ 3)
4. Àwọn nǹkan wo ló lè dán ìgbàgbọ́ wa wò?
4 Oríṣiríṣi àwọn nǹkan tó lè dán ìgbàgbọ́ wa wò ló lè ṣẹlẹ̀ sí wa. Bí àpẹẹrẹ, tí ètò Ọlọ́run bá ṣe àyípadà sí òye tá a ní nípa ẹsẹ Bíbélì kan, tàbí tí wọ́n yí bá a ṣe ń wàásù pa dà, báwo ló ṣe máa ń rí lára wa? Tí Jèhófà bá fàyè gbà á kí àjálù kan ṣẹlẹ̀ sí wa, tá ò sì mọ ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀, báwo ló ṣe máa ń rí lára wa? Ohun míì tó tún lè dán ìgbàgbọ́ wa wò ni tí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan tá a jọ ń sin Jèhófà bá ṣe ohun tó dùn wá gan-an, tàbí tẹ́nì kan tá a bọ̀wọ̀ fún bá ṣohun tí ò dáa sí wa.
5. Sọ àpèjúwe kan táá jẹ́ ká rí ìdí tí ìgbàgbọ́ wa fi gbọ́dọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀. (Kólósè 1:23)
5 Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe kan táá jẹ́ ká rí ìdí tí ìgbàgbọ́ wa fi gbọ́dọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀. Ká sọ pé wọ́n kọ́ ilé kan sí agbègbè tí ìmìtìtì ilẹ̀ ti máa ń ṣẹlẹ̀, kí ni ò ní jẹ́ kílé náà wó? Àfi káwọn tó kọ́ ọ rí i dájú pé ìpìlẹ̀ ilé náà dúró digbí. Lọ́nà kan náà, tá ò bá fẹ́ kí ohunkóhun paná ìgbàgbọ́ wa, títí kan àwọn ohun tá a sọ ní ìpínrọ̀ tó ṣáájú, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa fẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ tó dájú. Tá a bá sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí ìpìlẹ̀ náà lè máa lágbára sí i, àá fẹsẹ̀ múlẹ̀, àá sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láìka ìṣòro yòówù kó dé bá wa sí.—1 Kọ́r. 15:58; ka Kólósè 1:23.
6. Kí ni ò jẹ́ káwọn àpọ́sítélì fi Jésù sílẹ̀?
6 Kí ni ò jẹ́ káwọn àpọ́sítélì pa Jésù tì nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi í sílẹ̀? Ìdí ni pé ó dá àwọn àpọ́sítélì náà lójú pé Jèhófà nìkan ló yẹ káwọn máa sìn torí pé Òun ló dá ohun gbogbo. Wọ́n tún mọ̀ pé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run, àti pé àwọn máa ní ìyè àìnípẹ̀kun táwọn bá ń ṣègbọràn sí Jésù. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n mọ̀ pé Jèhófà wà lẹ́yìn Jésù gbágbáágbá. Ní báyìí, dípò tá a fi máa sọ̀rọ̀ lórí oríṣiríṣi nǹkan tó lè dán ìgbàgbọ́ wa wò, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan mẹ́ta tó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa dúró digbí láìka àdánwò tó lè dé bá wa sí. Àwọn nǹkan náà ni: (1) Jèhófà ló dá ohun gbogbo. (2) Jèhófà ló fẹ̀mí ẹ̀ darí àwọn tó kọ Bíbélì. (3) Jèhófà ń ti àwọn èèyàn ẹ̀ lẹ́yìn lónìí. Táwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí bá dá wa lójú délẹ̀délẹ̀, a máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láìka ohunkóhun tó lè dán ìgbàgbọ́ wa wò sí.
JÈHÓFÀ NI ẸLẸ́DÀÁ
7. Kí ni Ìfihàn 4:11 rán wa létí, kí ló sì lè ṣẹlẹ̀ tá a bá kojú àwọn nǹkan tó lè dán ìgbàgbọ́ wa wò?
7 Ka Ìfihàn 4:11. Ẹsẹ Bíbélì yìí rán wa létí pé Jèhófà ló dá ohun gbogbo. Ìyẹn sì fi hàn pé òun nìkan ló yẹ ká máa sìn. Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ nípa agbára ẹ̀ tí ò láfiwé, á jẹ́ kó dá wa lójú pé ó lè gbà wá sílẹ̀ nínú gbogbo ìṣòro wa. Àmọ́, Sátánì ti fi irọ́ àti ẹ̀tàn kún inú ayé yìí káwọn èèyàn lè máa rò pé kò sí Ọlọ́run. Bi àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan lè sọ pé àgbáálá ayé wa yìí kàn ṣàdédé wà ni. Torí náà, tí kò bá dá wa lójú délẹ̀délẹ̀ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá àti pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì bóyá Ọlọ́run wà lóòótọ́, àti pé bóyá ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá kojú àwọn nǹkan tó lè dán ìgbàgbọ́ wa wò.—Héb. 11:6.
8-9. Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá ń ṣiyèméjì pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
8 Tó o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá, á dáa kó o tètè wá nǹkan ṣe sí i. Fara balẹ̀ ṣèwádìí nínú àwọn ìwé wa kó o lè rí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà ló dá ohun gbogbo. O lè rí àwọn ẹ̀rí táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára nínú ìwé Was Life Created? àti The Origin of Life—Five Questions Worth Asking. O tún lè rí irú àwọn ẹ̀rí yìí nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?” lórí ìkànnì jw.org. Ọ̀dọ́bìnrin kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó ń jẹ́ Jessica sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo ka ìwé Origin of Life, ó túbọ̀ dá mi lójú pé ẹnì kan tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti olóye ló dá ayé yìí. Mo mọ̀ bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀, àmọ́ lẹ́yìn tí mo ka ìwé yìí, ó túbọ̀ yé mi dáadáa, ẹnikẹ́ni ò sì lè ṣì mí lọ́nà.” Bákan náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti jàǹfààní nígbà tí wọ́n ka ìwé Is There a Creator Who Cares About You? Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti ka ìwé yẹn rí, tó o bá ti kà á tẹ́lẹ̀, á dáa kó o tún un kà.
9 Nígbà tó o bá tún fẹ́ dá kẹ́kọ̀ọ́, á dáa kó o gbé àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà yẹ̀ wò. Àwọn nǹkan tó o bá kọ́ máa jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà wà lóòótọ́, wàá sì túbọ̀ mọ irú ẹni tó jẹ́. (Róòmù 1:20) Bákan náà, wàá lè fi ohun tó o kọ́ ran àwọn míì lọ́wọ́ tó ṣeé ṣe kí wọ́n máa ṣiyèméjì bóyá Ọlọ́run wà àbí kò sí. Kókó ibẹ̀ ni pé: Jèhófà ti fún wa ní ẹ̀rí tó pọ̀ gan-an tó jẹ́ ká gbà pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa.
Nebula: IAC/RGO/David Malin Images; fish and car: Mercedes-Benz USA; plane: Kristen Bartlett/University of Florida
Ó ṣeé ṣe kó o ti ka ìwé Was Life Created? Tó o bá ti kà á tẹ́lẹ̀, á dáa kó o tún un kà (Wo ìpínrọ̀ 8)
JÈHÓFÀ LÓ FẸ̀MÍ Ẹ̀ DARÍ ÀWỌN TÓ KỌ BÍBÉLÌ
10. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣe pàtàkì tó sí wa? (2 Tímótì 3:16, 17)
10 Ka 2 Tímótì 3:16, 17. Ohun tí Jèhófà fẹ́ káwa èèyàn mọ̀ ló wà nínú Bíbélì. Ó dáhùn àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé, ó tún jẹ́ ká mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe fáwa èèyàn àti bá a ṣe lè ṣe ohun tó fẹ́. A gbà pé Jèhófà ló ni Bíbélì, ìyẹn ló sì mú kí Bíbélì jẹ́ ìwé tó ṣe pàtàkì jù láyé wa. Torí náà, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ohun tá a bá kà níbẹ̀ yé wa dáadáa, a sì fi sílò.
11. Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run ló fẹ̀mí ẹ̀ darí àwọn tó kọ Bíbélì?
11 Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà ló fẹ̀mí ẹ̀ darí àwọn tó kọ Bíbélì? Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló wà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ ló wà nínú Bíbélì, kì í ṣe ìtàn àròsọ. (Lúùkù 3:1, 2) Bákan náà, ohun tó sọ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá péye. (Jóòbù 26:7) Yàtọ̀ síyẹn, láìka gbogbo bí Sátánì ṣe gbógun láti pa Bíbélì run, òun ni ìwé tí wọ́n pín kiri jù lọ láyé. Nǹkan bí ogójì (40) ọkùnrin ló kọ Bíbélì, ó sì tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (1,600) ọdún tí wọ́n fi kọ ọ́, síbẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ò ta kora. Àwọn ìmọ̀ràn inú ẹ̀ sì ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lọ́wọ́ nígbèésí ayé wọn. (Òwe 13:20; 15:21; Mát. 7:12) Bákan náà, ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì ló ti ṣẹ, ìyẹn sì jẹ́ ẹ̀rí míì tó jẹ́ ká gbà pé Bíbélì ṣe é gbára lé. (Jóṣ. 23:14) Kò sí àní˗àní pé Ọlọ́run ló fẹ̀mí ẹ̀ darí àwọn tó kọ Bíbélì!
12. Kí ló yẹ ká ṣe tí kò bá dá wa lójú pé Ọlọ́run ló fẹ̀mí ẹ̀ darí àwọn tó kọ Bíbélì?
12 Kí ló yẹ ká ṣe tí kò bá dá wa lójú pé Ọlọ́run ló fẹ̀mí ẹ̀ darí àwọn tó kọ Bíbélì? A gbọ́dọ̀ fọ̀rọ̀ náà sádùúrà, ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́, ká sì tún ṣèwádìí. Ẹ gbọ́ ohun tí Arákùnrin Jordan tó jẹ́ ọ̀dọ́ táwọn òbí ẹ̀ sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ, ó ní: “Kì í ṣe gbogbo nǹkan táwọn èèyàn bá sọ fún mi ni mo máa ń gbà gbọ́. Mo máa ń yẹ̀ ẹ́ wò dáadáa kí n tó gbà á gbọ́. Kí n sòótọ́, mo ṣì máa ń ṣiyèméjì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, mó máa ń rí i dájú pé mo ṣèwádìí nínú àwọn ìwé wa kí n lè rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè mi, kí n má sì ṣiyèméjì mọ́.” Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kó lè túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà ló fẹ̀mí ẹ̀ darí àwọn tó kọ Bíbélì, ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀.—1 Kọ́r. 3:12, 13.
JÈHÓFÀ Ń TI ÀWỌN ÈÈYÀN Ẹ̀ LẸ́YÌN LÓNÌÍ
13. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì nípa ètò tí Ọlọ́run ń lò lónìí?
13 Tí kò bá dá wa lójú pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà là ń ṣe ìsìn tòótọ́ tí Ọlọ́run fọwọ́ sí, a gbọ́dọ̀ tètè wá nǹkan ṣe sí i. Kí la lè ṣe? A lè bi ara wa láwọn ìbéèrè bí: ‘Àwọn wo ló ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì? Àwọn wo ló gbà pé gbogbo ohun tí Bíbélì bá sọ ni wọ́n máa tẹ̀ lé?’ (2 Tím. 4:3, 4) ‘Àwọn wo ló ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ lónìí?’—Mát. 7:20, 21.
14. Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń lo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti mú àsọtẹ́lẹ̀ Mátíù 24:14 ṣẹ?
14 A mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo èèyàn gbọ́ ìhìn rere kó tó pa ayé burúkú yìí run. A lè wá bi ara wa pé, ‘Àwọn wo ló ń wàásù ìhìn rere yìí lónìí?’ (Mát. 24:14) Ìdáhùn ẹ̀ ṣe kedere. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Jèhófà ń lò láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà lónìí. À ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní ilẹ̀ tó lé ní igba ó lé ogójì (240). Ó sì ti lé ní ọgọ́rùn-ún (100) ọdún báyìí tá a ti ń ṣiṣẹ́ náà lábẹ́ àkóso Jésù ọba wa. Iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni yìí làwa èèyàn Jèhófà gbájú mọ́, torí òun la kà sí pàtàkì jù.—Mát. 28:19, 20.
15. Báwo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣe ipa tiwa láti sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ lónìí? (Mátíù 6:9; Àìsáyà 43:10)
15 Ka Mátíù 6:9 àti Àìsáyà 43:10. Orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gangan, ìyẹn Jèhófà, làwọn èèyàn fi mọ̀ wá, inú wa sì máa ń dùn táwọn èèyàn bá ń pè wá ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ orúkọ Ọlọ́run, àwa mọ̀ ọ́n, a sì ti dá a pa dà sáwọn ibi tó yẹ kó wà nínú Bíbélì. Kódà, ó lé ní ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ìgbà tí orúkọ yìí fara hàn nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
16. Kí ló mú ká gbà pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ohun tó wà ní Jòhánù 13:34, 35? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Ka Jòhánù 13:34, 35. Nínú ayé lónìí, àwọn èèyàn kẹ̀yìn síra wọn, wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Àmọ́ tàwa èèyàn Jèhófà yàtọ̀ pátápátá, a nífẹ̀ẹ́ ara wa, a sì wà níṣọ̀kan. Ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la ti wá, àṣà wa àti bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà sì yàtọ̀ síra, síbẹ̀ àlàáfíà wà láàárín wa, a sì nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú. Ó ṣeé ṣe kó o ti lọ sí ìjọ míì rí nígbà tó o rìnrìn àjò. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá ti rí i pé àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n sì wà níṣọ̀kan. Ìyẹn fi hàn pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Jèhófà ń lò lónìí láti mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Tá a bá ń rántí pé Jèhófà wà lẹ́yìn wa, á jẹ́ ká lè jólóòótọ́ tíṣòro bá dé.
Ìkórìíra ló kúnnú ayé yìí, àmọ́ àwa èèyàn Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ara wa, a sì wà níṣọ̀kan (Wo ìpínrọ̀ 16)a
MÁ FI JÈHÓFÀ SÍLẸ̀ LÁÉ
17-18. Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ sí wa, kí la sì lè fi ìdánilójú sọ?
17 Àkókò tí nǹkan le gan-an tó sì nira là ń gbé yìí, torí náà nǹkan ò rọrùn fún gbogbo wa. (2 Tím. 3:1, 13) A tún lè láwọn ìṣòro míì tá à ń bá yí. Ètò Ọlọ́run sì lè ṣe àwọn ìpinnu kan tó lè má yé wa dáadáa. Yàtọ̀ síyẹn, arákùnrin tàbí arábìnrin kan lè ṣì wá lóye àbí kó ṣe ohun to dùn wá gan-an. Ibi tọ́rọ̀ wá ṣe sí ni pé, a lè má mọ ohun tó fà á táwọn nǹkan kan fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa, a sì lè má tètè rí ojútùú síṣòro wa.
18 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan yìí lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa, a lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà tá a bá gbà pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, ọ̀rọ̀ ẹ̀ ló wà nínú Bíbélì, àti pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń tì lẹ́yìn. Bí Pétérù ṣe sọ fún Jésù, àwa náà lè sọ fún Jèhófà pé: “Ọ̀dọ̀ ta la máa lọ? Ìwọ lo ní àwọn ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”
ORIN 123 Máa Ṣègbọràn sí Ètò Ọlọ́run
a Àlàyé Àwòrán: Ìyá kan àti ọmọ ẹ̀ wà nínú bọ́ọ̀sì, inú wọn dùn bí wọ́n ṣe ń wo àwọn ará tó wà lóde ìwàásù.