JUNE 8-14, 2026
ORIN 8 Jèhófà Ni Ibi Ààbò Wa
Gbogbo Ìgbà Ni Jèhófà “Ọlọ́run Òtítọ́” Máa Ń Mú Ìlérí Ẹ̀ Ṣẹ
“O ti rà mí pa dà, Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́.”—SM. 31:5.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà máa mú gbogbo ìlérí ẹ̀ ṣẹ àti pé Ìjọba ẹ̀ máa fòpin sí irọ́ àti ẹ̀tàn tó kúnnú ayé Sátánì.
1. Kí ló jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ayé tí irọ́ kúnnú ẹ̀ là ń gbé? (Sáàmù 31:2-5)
INÚ ayé tí Sátánì ń darí là ń gbé. Ìdí nìyẹn tí irọ́, ẹ̀tàn àti ìwà ọ̀dàlẹ̀ fi wọ́pọ̀. Ó ṣòro láti rẹ́ni tó ṣeé fọkàn tán. Àwọn oníṣòwò máa ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ. Àwọn tó ń polówó ọjà máa ń ṣe àbùmọ́ èyí sì máa ń ṣi àwọn oníbàárà wọn lọ́nà. Àwọn kan sì ti rí i pé àwọn tó sún mọ́ wọn pàápàá ò ṣeé bá ṣe àdéhùn. Síbẹ̀, ọkàn wa balẹ̀ torí pé a lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà “Ọlọ́run òtítọ́”! (Ka Sáàmù 31:2-5.) Jèhófà kì í parọ́, gbogbo ohun tó bá sọ ló jóòótọ́. Torí náà, ó dá wa lójú pé gbogbo ohun tó bá sọ ló máa ṣe.
2. Kí la máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìdí tá a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run òtítọ́ ṣe máa fòpin sí ayé burúkú tí Sátánì ń darí yìí. Àá tún sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Jèhófà ń ṣe báyìí kí ìfẹ́ rẹ̀ lè ṣẹ. Àwọn nǹkan tá a máa kọ́ máa jẹ́ ká túbọ̀ nígboyà bá a ṣe ń sọ nípa Jèhófà fáwọn èèyàn.
KÍ NÌDÍ TÁ A FI LÈ GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN ÒTÍTỌ́?
3. Kí nìdí tá a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá?
3 A lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa. Jèhófà ló dá ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun alààyè tó wà. (Jẹ́n. 1:1; Sm. 36:9; Ìfi. 4:11) Bákan náà, ó fún wa láwọn nǹkan tó ń gbẹ́mìí wa ró, irú bí omi àti afẹ́fẹ́. Òun ló ń darí gbogbo ohun tó wà lọ́run àti láyé, á sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ títí láé. Torí náà, a lè gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá, ká sì jẹ́ kó máa darí wa torí pé òun ló dá wa, òun ló gbọ́n jù, agbára ẹ̀ ò sì láfiwé.
4. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?
4 A lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Jèhófà dá àwa èèyàn torí ó fẹ́ káwa náà wà láàyè ká sì gbádùn ayé wa. Ó sọ pé: “Jẹ́ ká dá èèyàn ní àwòrán wa, kí wọ́n jọ wá.” (Jẹ́n. 1:26) Ó fún wa lómìnira ká lè pinnu ohun tá a fẹ́. Ó dá ayé tó rẹwà ká lè máa gbé inú rẹ̀. (Sm. 115:16) Ó sì gbé iṣẹ́ aláyọ̀ kan fáwọn òbí wa àkọ́kọ́, ó ní kí wọ́n sọ ayé yìí di Párádísè. (Jẹ́n. 1:28; 2:15) Ó fi gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ àtàwọn ohun iyebíye tó wà láyé síkàáwọ́ wọn. Ká sòótọ́, gbogbo nǹkan yìí jẹ́ ká mọ̀ pé “ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ wà títí ayé.”—Sm. 103:17.
5. (a) Kí ni Jèhófà ṣe nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀? (b) Sọ díẹ̀ lára àwọn ìlérí Jèhófà tó ti ṣẹ. (Wo àpótí náà “Àwọn Àkọsílẹ̀ Tó Jẹ́ Ká Mọ̀ Pé Ìlérí Jèhófà Máa Ń Ṣẹ.”)
5 A lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà torí pé gbogbo ìgbà ló máa ń mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Jèhófà ‘ò kàn dá ayé yìí lásán, àmọ́ ó dá a ká lè máa gbé inú rẹ̀.’ (Àìsá. 45:18, 19) Nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, wọ́n gba ìdájọ́ ikú. Ó wá dà bíi pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún aráyé kò ní ṣeé ṣe mọ́. Àmọ́ kò sóhun tí Jèhófà sọ tí kò ní ṣẹ. (Àìsá. 46:10, 11) Ohun tó fẹ́ ni pé kí àwọn èèyàn olóòótọ́ kún ayé, ìyẹn ò sì yí pa dà. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ kí Ádámù àti Éfà bímọ kí wọ́n tó kú. Kì í ṣe ìyẹn nìkan, ó tún fún wa ní Jésù Ọmọ ẹ̀ kan ṣoṣo, kó lè ra àwa àtọmọdọ́mọ Ádámù pa dà, ká sì nírètí láti wà láàyè títí láé.—Jòh. 3:16.
ỌLỌ́RUN ÒTÍTỌ́ MÁA Ń MÚ ÌLÉRÍ Ẹ̀ ṢẸ
6. Kí ni Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ lẹ́yìn ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní Édẹ́nì?
6 Ẹni tó mú kí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run ni “ejò àtijọ́ náà, ẹni tí à ń pè ní Èṣù àti Sátánì.”a (Ìfi. 12:9; Jẹ́n. 3:4, 5; Jòh. 8:44) Torí ohun tí Èṣù ṣe yìí, Jèhófà sọ pé ó máa pa run lọ́jọ́ iwájú. (Jẹ́n. 3:15) Ṣùgbọ́n kíyẹn tó ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn lá máa ṣohun tí Sátánì fẹ́, wọ́n á sì máa hùwà bíi tiẹ̀. Àmọ́ ó dájú pé àwọn kan máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.
7. Àwọn wo ló ń ṣe ohun tí Sátánì fẹ́, kí ló sì máa gbẹ̀yìn wọn?
7 Àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ àtàwọn èèyàn aláìgbọràn wà lárá àwọn tó ń ṣe ohun tí Sátánì fẹ́. Torí pé wọ́n ṣàìgbọràn sí Jèhófà, tí wọn ò sì fẹ́ kí ìfẹ́ ẹ̀ ṣe, ìyẹn ló mú kí wọ́n sọ ara wọn di ọmọ Sátánì. Àmọ́ tó bá tó àkókò lójú Jèhófà, ó máa pa Sátánì àtàwọn alátìlẹyìn ẹ̀ run.—Dán. 2:44; Róòmù 16:20.
8. Kí ni Jésù ṣe lọ́dún 1914? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
8 Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa pa Sátánì àtàwọn tó ń tì í lẹ́yìn run? Lọ́dún 1914, Jésù bá Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ẹ̀ jagun, ó sì lé wọn jù sáyé. (Ìfi. 12:7-9) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀run ni wọ́n ti ja ogun náà, àwọn tó wà láyé mọ̀ ọ́n lára. Bíbélì sọ pé: “Ayé àti òkun gbé, torí pé Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ń bínú gidigidi, ó mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ló kù fún òun.” (Ìfi. 12:12) Àtọdún 1914 ni Èṣù ti dájú sọ ayé, ìdí nìyẹn tí nǹkan fi ń burú sí i láyè. Ẹ ò rí i pé ayé ti gbé lóòótọ́! Láìpẹ́, Jésù máa “parí ìṣẹ́gun rẹ̀,” ó máa ju Sátánì sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, á sì pa àwọn alátìlẹyìn ẹ̀ run. (Ìfi. 6:2) Jésù máa dá orúkọ Jèhófà láre. (Sm. 45:4-6) Gbogbo èèyàn á wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run òtítọ́.—Ìsík. 38:23.
World War I: U.S. National Archives photo; bomb: USAF photo; pandemic: blvdone/stock.adobe.com; riot: inhauscreative/E+ via Getty Images
Látọdún 1914, nǹkan ti túbọ̀ dojú rú láyé (Wo ìpínrọ̀ 8)
ỌLỌ́RUN ÒTÍTỌ́ Ń KÓ ÀWỌN TÓ NÍFẸ̀Ẹ́ ÒTÍTỌ́ JỌ
9. Àwọn wo ni Jèhófà ń kó jọ báyìí?
9 Ní báyìí, Jèhófà ń “kó ohun gbogbo jọ nínú Kristi . . . àwọn ohun tó wà ní ọ̀run àti àwọn ohun tó wà ní ayé.” (Éfé. 1:10) “Àwọn ohun tó wà ní ọ̀run” ni àwọn ẹni àmì òróró tí Jèhófà yàn láti bá Jésù ṣàkóso lọ́run. “Àwọn ohun tó wà ní ayé” làwọn tó máa gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé títí láé. Gbogbo àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà yìí ń já irọ́ Sátánì, wọ́n sì ń ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ káwọn náà lè wá mọ Ọlọ́run òtítọ́.
10. Kí ni Jèhófà ń ṣe kó lè já irọ́ tí ìsìn èké fi ń kọ́ àwọn èèyàn? (Ìfihàn 14:6, 7)
10 Jèhófà ń lo iṣẹ́ ìwàásù láti kó àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ jọ, iṣẹ́ ìwàásù tá a sì ń ṣe lákòókò wa yìí ló gbòòrò jù torí pé ó délé dóko. (Ka Ìfihàn 14:6, 7.) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa èèyàn ni Jèhófà ń lò láti sọ ìhìn rere, àwọn áńgẹ́lì náà ń darí wa lọ sọ́dọ̀ àwọn olóòótọ́ ọkàn tó fẹ́ di ọmọlẹ́yìn Kristi. Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń lo Bábílónì Ńlá, ìyẹn àpapọ̀ ìsìn èké àgbáyé láti parọ́ mọ́ Jèhófà, àmọ́ iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe yìí la fi ń já àwọn irọ́ náà. (Ìfi. 18:2, 4) Láìpẹ́, Jèhófà máa pa ìsìn èké run pátápátá, gbogbo àwọn tó bá sì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run òtítọ́ á máa yìn ín lógo.—Ìfi. 17:16.
11. Báwo la ṣe lè mọ àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́?
11 Onírúurú ibi tí àṣà ìbílẹ̀, ọrọ̀ ajé àti èdè wọn ti yàtọ̀ síra làwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ti wá. (Ìfi. 7:9, 10) Nígbà tí wọ́n gbọ́ “ìhìn rere náà,” wọ́n gbà pé àwọn ti rí òtítọ́, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n sì fi dara pọ̀ mọ́ àwa èèyàn Jèhófà. (Máàkù 13:10) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a ti wá túbọ̀ mọ àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́ àtàwọn tí ò ṣe bẹ́ẹ̀. Wòlíì Málákì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ẹ ó sì tún rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tó ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.” (Mál. 3:18) Torí náà, bí àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe ń hùwà tó dáa tá a sì ń wàásù ń fi hàn pé Ọlọ́run òtítọ́ là ń sìn.
12. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń mú kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ?
12 Bá a ṣe ń wàásù “ìhìn rere Ìjọba” náà, ṣe là ń pa àṣẹ Jésù mọ́, ìyẹn sì ń mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ. (Mát. 24:14; 28:18-20) Bákan náà, iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe ló ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé di ọmọlẹ́yìn Jésù, ó sì ń mú kí wọ́n láǹfààní láti jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run òtítọ́ títí láé. A mọyì àǹfààní ńlá tá a ní pé iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe ń mú kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ!
JẸ́ KÓ DÁ Ẹ LÓJÚ PÉ ÀWỌN ÌLÉRÍ JÈHÓFÀ MÁA ṢẸ
13. Àwọn wo ni Sátánì dìídì dájú sọ, kí sì nìdí?
13 Inú ń bí Sátánì burúkú burúkú torí “ó mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ló kù” kí ayé burúkú tó ń ṣàkóso pa run. (Ìfi. 12:12, 13) Ó dìídì dájú sọ àwọn ẹni àmì òróró ìyẹn àwọn tó ń ṣojú Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé tí wọ́n ń “pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí iṣẹ́ wọn sì jẹ́ láti jẹ́rìí Jésù.” (Ìfi. 12:17; 14:12) Bákan náà, ó máa ń fojú pọ́n àwọn tó ń tì wọ́n lẹ́yìn, tí wọ́n sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe.
14. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sátánì bá gbéjà ko àwa èèyàn Jèhófà? (Tún wo àwòrán.)
14 Lẹ́yìn tí Bábílónì Ńlá bá pa run, àwọn tí Sátánì ń darí máa gbéjà ko àwa ìránṣẹ́ Jèhófà. Ohun tí wọ́n ṣe yìí ló máa yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìfi. 16:13, 14, 16) Jésù àtàwọn ọmọ ogun ọ̀run máa gba àwa èèyàn Jèhófà sílẹ̀, wọ́n á sì pa gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù nínú ayé Sátánì run. (Ìfi. 16:13, 14, 16) Gbogbo àwọn èèyàn burúkú, àwọn òpùrọ́ àtàwọn tó ń gbèrò ibi máa pa run yán-án-yán-án. (Ìfi. 21:8) Á wá hàn sí gbogbo èèyàn pé Jèhófà ni Ọlọ́run òtítọ́.
Jésù àtàwọn ọmọ ogun ọ̀run ń gẹṣin lọ bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Ọlọ́run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì (Wo ìpínrọ̀ 14)
15. Kí ló mú kó dá wa lójú pé àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ? (Àìsáyà 65:16, 17) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
15 Ìgbésí ayé kóńkó jabele kálukú ló ń ṣe tiẹ̀ làwọn èèyàn ń gbé lónìí. Àmọ́ a dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó jẹ́ káwa èèyàn ẹ̀ wà níṣọ̀kan. Jèhófà ń kó gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ jọ lásìkò yìí. Kò sí àní-àní pé Jèhófà máa bù kún àwọn èèyàn ẹ̀, á sì fèrè síṣẹ́ wọn. (Ka Àìsáyà 65:16, 17.) Ó dá wa lójú pé àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ. Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú Róòmù 8:38, 39 fi wá lọ́kàn balẹ̀. Ó sọ pé: “Kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba tàbí àwọn ohun tó wà nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tó ń bọ̀ tàbí àwọn agbára tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ló máa lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.”
Gbogbo ìṣòro tá a ní báyìí ló máa dópin nínú ayé tuntun, a ò sì ní rántí wọn mọ́ (Wo ìpínrọ̀ 15)
16. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá?
16 Ó yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run òtítọ́, torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó ń jọ́sìn Jèhófà túbọ̀ ń pọ̀ sí i, torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn níbi gbogbo láyé ló ń wá sínú ètò Ọlọ́run. (Àìsá. 60:22; Sek. 8:23) Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ àti pé ó máa pa Sátánì run láìpẹ́ kí irọ́ àti ẹ̀tàn tó kúnnú ayé yìí lè dópin. Bíi ti Dáfídì, àwa náà gbàdúrà pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run, . . . òun nìkan ló ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu. Kí á yin orúkọ rẹ̀ ológo títí láé, kí ògo rẹ̀ sì kún gbogbo ayé.”—Sm. 72:18, 19.
ORIN 2 Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ
a Bíbélì ò sọ orúkọ tí áńgẹ́lì yìí ń jẹ́. Àmọ́ ó pè é ní “Èṣù” tó túmọ̀ sí Abanijẹ́ àti “Sátánì” tó túmọ̀ sí Alátakò.