MAY 11-17, 2026
ORIN 7 Jèhófà Ni Agbára Wa
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run
“Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé.”—SM. 83:18.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Bá a ṣe lè jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, kí ọkàn wa sì balẹ̀ pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí àwọn ìṣòro tá a ní báyìí àtèyí tó ṣeé ṣe ká ní lọ́jọ́ iwájú.
1. Àdánù ńlá wo ló dé bá Jóòbù?
ỌKÙNRIN olóòótọ́ kan wà nígbà àtijọ́ tó ń jẹ́ Jóòbù. Àdánù ńlá dé bá a lójijì! Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun tó ní ló pòórá. Ọjọ́ kan náà ni gbogbo ọmọ ẹ̀ kú. Onílé ọlọ́nà wá di ẹdun arinlẹ̀. Kò tán síbẹ̀ o, àìsàn burúkú kan tún kọ lù ú, àwọn èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í fojú burúkú wò ó. Dípò káwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ tù ú nínú, ṣe ni wọ́n tún ń sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí i. Kódà nǹkan tojú sú ìyàwó ẹ̀ débi tó fi sọ fún un pé kó ‘sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, kó sì kú.’ (Jóòbù 2:9; 15:4, 5; 19:1-3) Àwọn ìṣòro yìí lè mú kí Jóòbù ronú pé Ọlọ́run ò rí tòun rò, kó sì máa ṣiyèméjì pé bóyá ni Jèhófà máa ń dáàbò bo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, tí wọ́n sì ń sìn ín.
2-3. Tá a bá níṣòro, èrò wo ló lè máa wá sí wa lọ́kàn, kí la sì máa kọ́ nínú ìwé Jóòbù?
2 Nígbà míì, àwa náà máa ń láwọn ìṣòro tó lè mú ká ronú pé Jèhófà ò rí tiwa rò. Ó ṣe tán, ‘àkókò tí nǹkan le gan-an, tó sì nira’ là ń gbé. (2 Tím. 3:1) Tíṣòro bá ń rọ́ lu ara wọn, nǹkan lè sú wa, kó sì máa ṣe wá bíi pé a ò lè fara dà á mọ́. Irú àwọn nǹkan báyìí ti mú káwọn kan ronú pé bóyá ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn.
3 Tó bá jẹ́ pé ìwọ náà máa ń nírú èrò yìí, má sọ̀rètí nù. Ní ti Jóòbù, ó rí i nígbà tó yá pé Jèhófà máa ń gba àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ sílẹ̀. Bíi ti Jóòbù, àwa náà lè kọ́ bá a ṣe lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí ọkàn wa sì balẹ̀ pé ó máa ràn wá lọ́wọ́. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, ẹ jẹ́ ká wo ẹ̀kọ́ pàtàkì méjì tá a lè rí kọ́ nínú ìwé Jóòbù. Àkọ́kọ́, Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Ìkejì, Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè lè darí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé kí ohun tó ní lọ́kàn lè ṣẹ, ó sì máa ń dáàbò bò wá kí ohunkóhun má bàa ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú ẹ̀ jẹ́, kí ohunkóhun má sì pa wá lára títí láé.
SÁTÁNÌ WÁ SÍPÀDÉ NÁÀ
4. Ta ló wọlé wá síbi ìpàdé tí Jèhófà àtàwọn áńgẹ́lì ṣe ní ọ̀run?
4 Lọ́jọ́ kan, “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́” dúró níwájú Jèhófà ní ọ̀run. Bíbélì sọ pé: “Sátánì náà sì wọlé sáàárín wọn.” (Jóòbù 1:6) Ibí ni Bíbélì ti kọ́kọ́ pe olórí ọ̀tá Jèhófà ní “Sátánì” tó túmọ̀ sí “Alátakò.” Lákòókò tá à ń sọ yìí, Jèhófà ti kọ Sátánì lọ́mọ torí pé ó ti di aláìṣòótọ́. Ó ti sọ ara ẹ̀ di ọ̀tá Jèhófà àti ọ̀tá ìdílé Jèhófà tó wà lọ́run àti láyé. Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 fi hàn pé Sátánì kì í ṣe ara ìdílé Jèhófà tó wà lọ́run mọ́. Torí náà, Sátánì ò sí lára àwọn tí Bíbélì pè ní “obìnrin” tó máa mú “ọmọ” náà jáde. Àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ tó wà lọ́run ni “obìnrin” tí Bíbélì sọ yìí.
5. Kí la kọ́ nínú àwọn nǹkan tí wọ́n sọ níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe lọ́run?
5 Jèhófà jẹ́ kí ohun tí wọ́n sọ nípàdé tí wọ́n ṣe lọ́run wà lákọsílẹ̀ nínú Bíbélì. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Sátánì sọ níbẹ̀ jẹ́ ká rí i pé ìkà àti abanijẹ́ ni, ó sì kórìíra àwọn tó ń sin Jèhófà. (Jóòbù 1:9; fi wé Ìfihàn 12:10.) Bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí wọ́n kọ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí sínú Bíbélì tún jẹ́ kó dá wa lójú pé kì í ṣi agbára ẹ̀ lò, ohun to tọ́ ló sì máa ń ṣe nígbà gbogbo. Bákan náà, ó tún jẹ́ ká rí i pé Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè ló máa ń pinnu ohun tẹ́nì kan lè ṣe àtohun tí kò lè ṣe.
JÈHÓFÀ SỌ OHUN TÍ SÁTÁNÌ Ò GBỌ́DỌ̀ ṢE
6. Kí ni Jèhófà ṣe tó jẹ́ ká mọ̀ pé òun ló pinnu ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe lọ́run? (Jóòbù 1:7, 8)
6 Ka Jóòbù 1:7, 8. Jèhófà ló darí ìpàdé náà, òun ló sì pinnu ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Ó bi Sátánì pé: “Ṣé o ti kíyè sí Jóòbù ìránṣẹ́ mi?” Ohun kan ni pé, Jèhófà mọ̀ dáadáa pé Sátánì ti dájú sọ Jóòbù tó jẹ́ olóòótọ́ kó lè fìyà jẹ ẹ́. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe lo agbára ńlá rẹ̀ láti ran Jóòbù lọ́wọ́.
7. Bó ṣe wà nínú Jóòbù 1:10, 11, kí ni Sátánì sọ pé ó ń mú ká sin Jèhófà?
7 Ka Jóòbù 1:10, 11. Jèhófà ni Olódùmarè, òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, gbogbo ìgbà ló sì máa ń lo agbára àti àṣẹ ẹ̀ lọ́nà tó tọ́. (Jer. 32:17; Dán. 4:35) Síbẹ̀, Sátánì fẹ̀sùn kan Jèhófà pé ó ń ṣi agbára ẹ̀ lò. Ohun tí Sátánì ń sọ ni pé ṣe ni Ọlọ́run fún Jóòbù àti gbogbo àwa èèyàn ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ká lè máa sìn ín. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún sọ pé torí ohun tá à ń rí gbà lọ́wọ́ Jèhófà la ṣe ń sìn ín. Kí ni Jèhófà wá ṣe?
8-9. Kí ni Jèhófà sọ fún Sátánì pé kò gbọ́dọ̀ ṣe, kí sì nìdí? (Jóòbù 1:12) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
8 Ka Jóòbù 1:12. Jèhófà fàyè gba Sátánì kó dán Jóòbù wò, àmọ́ ó sọ ohun tí kò gbọ́dọ̀ ṣe fún un. Ojú gbogbo àwọn tó wà níbi ìpàdé náà ni Jèhófà ti sọ ohun tí Sátánì ò gbọ́dọ̀ ṣe. Ọlọ́run sọ fún un kedere pé: “O ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan [Jóòbù] fúnra rẹ̀!” Kò sì sóhun tí Sátánì lè ṣe síyẹn, kò tó bẹ́ẹ̀ kó ṣe nǹkan tí Jèhófà ní kó má ṣe! Bọ́rọ̀ sì ṣe rí títí dòní náà nìyẹn. Jèhófà lo agbára àti àṣẹ ẹ̀ láti dáàbò bo Jóòbù, ó sì tún lò ó ká lè rí i pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, ohun tó tọ́ lòun sì máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà.
9 Ibi tí Sátánì fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀. Láìka gbogbo ohun tó ṣe sí, Jóòbù ṣì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (Jóòbù 1:22) Àmọ́, Sátánì tó jẹ́ Alátakò ò tíì dẹ̀yìn lẹ́yìn Jóòbù.
Jèhófà gba Sátánì láyè láti sọ tẹnu ẹ̀ níwájú àwọn áńgẹ́lì yòókù (Wo ìpínrọ̀ 8-9)
10. Kí nìdí tí Jèhófà fi fàyè gba Sátánì pé kó tún dán Jóòbù wò? (Jóòbù 2:2-6)
10 Ka Jóòbù 2:2-6. Lọ́tẹ̀ yìí, Sátánì tún fẹ́ ṣohun míì tó burú jáì kó lè rí i pé Jóòbù ò sin Jèhófà mọ́. Sátánì sọ pé tí Jóòbù bá rí àdánwò tó fẹ́ gbẹ̀mí ẹ̀, ó máa bú Ọlọ́run. Kọ́rọ̀ náà lè yanjú, Jèhófà gba Sátánì láyè kó fi àìsàn kọ lu Jóòbù. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà tún sọ ohun tí Sátánì ò gbọ́dọ̀ ṣe, ó ní: “O ò gbọ́dọ̀ gba ẹ̀mí rẹ̀!” Kò sì sóhun tí Sátánì lè ṣe síyẹn, kò gbọ́dọ̀ ṣe kọjá ohun tí Jèhófà sọ. A tún rí i nínú ọ̀rọ̀ yìí pé Jèhófà ni Ẹni Gíga Jù Lọ torí pé ó sọ ohun tí Sátánì ò gbọ́dọ̀ ṣe ní gbogbo ìgbà tó ń dán Jóòbù wò, Sátánì ò sì lè yẹ Jèhófà lọ́wọ́ wò.
JÈHÓFÀ FÒPIN SÍ ÌYÀ TÓ Ń JẸ JÓÒBÙ
11. Lẹ́yìn tí Jèhófà fòpin sí àwọn àdánwò Jóòbù, báwo ló ṣe san án lẹ́san? (Jóòbù 42:10-13)
11 Ka Jóòbù 42:10-13. Ó ti wá hàn báyìí pé Jóòbù ti pinnu pé òun ò ní fi Jèhófà sílẹ̀, Jèhófà sì gba Jóòbù lọ́wọ́ Sátánì. Jèhófà fòpin sí gbogbo ìyà tí Jóòbù ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ti jẹ. A tún rí i pé Sátánì tó jẹ́ Alátakò ò ní agbára kankan láti dá Jèhófà dúró pé kó má ṣe ohun tó fẹ́. Jèhófà ò gba Sátánì láyè mọ́ láti máa fojú pọ́n Jóòbù ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ nìṣó.
12. Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó bá gbà pé Jèhófà lágbára láti dáàbò bò wọ́n.
12 Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, Jèhófà ti lo agbára ẹ̀ láti dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ nígbà ìjọba Násì lọ́dún 1945, àwọn sójà fipá mú àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé kí wọ́n fẹsẹ̀ rin ọ̀nà tó jìn gan-an tó sì léwu kí wọ́n lè lọ pa wọ́n. Àmọ́ gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ọgbọ̀n (230) tó wà lára wọn ló la ìṣẹ̀lẹ̀ náà já. Àwọn ará wa yìí kọ ọ̀rọ̀ sínú ìwé kan kí wọ́n lè fi ṣàlàyé ohun tójú wọn rí. Wọ́n ní: “Àkókò tí nǹkan le koko bí ojú ẹja ti kọjá, ṣe làwọn tó sì là á já dà bí ẹni tí wọ́n gbé jáde nínú iná, tí òórùn iná kò sì sí lára wọn. . . . Kàkà bẹ́ẹ̀, koko lara wọn le, Jèhófà fún wọn lágbára.” Wọ́n tún sọ pé: “Ohun kan ṣoṣo là ń béèrè . . . ohun náà sì ni pé [lẹ́yìn] tá a ti kúrò nínú ihò kìnnìún, ká láǹfààní láti máa sin Jèhófà . . . títí láé. Èrè tó dáa jù tá a lè rí gbà nìyẹn.”—Fi wé Dáníẹ́lì 3:27; 6:22.
13. Bó o tiẹ̀ níṣòro tó ò ń bá yí, kí ló yẹ kó dá ẹ lójú? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
13 Àwọn ìgbà kan lè wà nígbèésí ayé wa tó máa ṣe wá bíi pé wọ́n jù wá sínú ihò kìnnìún. (1 Pét. 5:8-10) Nígbà míì gbogbo nǹkan lè tojú sú wa, ká sì máa wò ó pé bóyá la máa bọ́ nínú ìṣòro tó ń bá wa fínra. Láwọn ìgbà tó bá ń ṣe wá bẹ́ẹ̀, ó dáa ká máa rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù. Ká jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa lo agbára ẹ̀ láti fòpin sí ìyà tó ń jẹ wá nísinsìnyí tàbí nínú ayé tuntun. Kò sì ní jẹ́ kí àkókò tó ti yàn láti pa ayé burúkú yìí run kọjá ìṣẹ́jú kan!
Jèhófà máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ olóòótọ́ (Wo ìpínrọ̀ 13)
JÈHÓFÀ FẸ́RÀN ÀWỌN TÓ Ń FÒÓTỌ́ ỌKÀN SÌN ÍN
14-15. Kí ni Jèhófà máa ṣe fáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́, kí sì nìdí? (Jóòbù 14:15) (Tún wo àwòrán.)
14 Ka Jóòbù 14:15. Jèhófà Baba wa ọ̀run kì í fi àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ sílẹ̀. Wọ́n ṣeyebíye gan-an lójú ẹ̀ débi pé tí wọ́n bá tiẹ̀ kú, ó máa jí wọn dìde. Tó bá sì jí wọn dìde, á sọ ìbànújẹ́ wọn dayọ̀.—Àìsá. 65:17.
15 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ayé Sátánì ni Jóòbù ṣì wà lákòókò yẹn, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà bù kún un. Lákọ̀ọ́kọ́, Jèhófà wo Jóòbù sàn, ó sì fún un láwọn nǹkan tó ju èyí tó pàdánù nígbà tí Sátánì dán an wò. Ìtọ́wò lásán làwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún Jóòbù, tá a bá fi wé èyí tó máa gbádùn nínú ayé tuntun. Àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe yìí jẹ́ ká rí i pé ó fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ láyọ̀, kí wọ́n sì gbádùn ayé wọn. Kódà, ó máa fún gbogbo àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ láǹfààní láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Ìfi. 21:3, 4) Ó ń wu Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run láti ṣe àwọn nǹkan yìí. Tá a bá ń ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà fẹ́ ṣe yìí, ó máa jẹ́ kára tù wá tá a bá ń fara da ìṣòro.
Jèhófà bù kún Jóòbù àti ìyàwó ẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n borí àdánwò Sátánì (Wo ìpínrọ̀ 14-15)
16. Kí nìdí tó tún fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run?
16 Jóòbù pẹ́ láyé gan-an, nígbà tó sì yá ó kú. Àmọ́ Jèhófà lágbára láti jí i dìde torí pé òun ni Olódùmarè àti Ẹni Gíga Ju Lọ̀. (Diu. 32:39) Torí náà, kò sẹ́ni tó lè dá Jèhófà dúró kó má jí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ dìde. Ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ lákòókò tó yàn.—Róòmù 8:38, 39.
GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ PÁTÁPÁTÁ
17. Kí ló jẹ́ ká gbà pé Sátánì ò ṣàṣeyọrí láti pa àwa èèyàn Jèhófà run?
17 Ìtàn Jóòbù jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ò jẹ́ kí Sátánì ṣàṣeyọrí láti pa àwa èèyàn ẹ̀ run! Lónìí, àwa tí iye wa ju mílíọ̀nù mẹ́sàn-án (9,000,000) ló ń sin Jèhófà tọkàntọkàn, ìyẹn sì jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run lágbára gan-an. Kódà, àìmọye ìgbà làwọn ọ̀tá ti ṣe oríṣiríṣi nǹkan láti gbógun tì wá, àmọ́ wọn ò ṣàṣeyọrí. (Àìsá. 54:17) Àwọn orílẹ̀-èdè tó lágbára gan-an àtàwọn olórí ẹ̀sìn ti gbógun ti àwa èèyàn Jèhófà torí wọ́n rò pé a ò ní olùgbèjà, àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá wọn já sí. Bákan náà, kò sóhun tó lè dá wa dúró bá a ṣe ń sọ òótọ́ nípa Jèhófà tá a sì ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òpùrọ́ àti apààyàn ni Sátánì. Kódà tá a bá tiẹ̀ kú, Jèhófà máa jí wa dìde tá a bá ṣáà ti jẹ́ olóòótọ́.—Hós. 13:14.
18. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?
18 Tá a bá ronú jinlẹ̀ nípa ìtàn Jóòbù, ọkàn wa máa balẹ̀ pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà máa dúró tì wá. Nígbà ìpọ́njú ńlá, Sátánì àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ máa rò pé kò sẹ́ni tó máa gbèjà wa, àti pé wẹ́rẹ́ báyìí làwọn máa pa wá run. Àmọ́ bó ṣe rí nínú ọ̀rọ̀ Jóòbù, Jèhófà máa dá sí ọ̀rọ̀ náà, kò sì ní jẹ́ kí Sátánì pa àwa èèyàn ẹ̀ run. Láìpẹ́, Jèhófà máa fòpin sí gbogbo wàhálà àti ìdààmú tí Sátánì ti fà fún aráyé. Jésù máa ju Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ẹ̀ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún. (Lúùkù 8:31; Ìfi. 20:1-3) Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Sátánì àti gbogbo àwọn tó ń tì í lẹ́yìn máa pa run pátápátá. (Ìfi. 20:10) Jésù máa fọ́ orí Sátánì bí Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀. A ò sì ní gbúròó ẹ̀ mọ́ títí láé!—Jẹ́n. 3:15; Róòmù 16:20.
19. Àwọn ìbùkún wo làwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá máa gbádùn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
19 Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ń fayọ̀ retí ìgbà tí ayé tuntun máa dé tá a sì máa gbádùn ìlera pípé àti ayọ̀ tòótọ́. Àkókò yẹn máa dùn gan-an, kódà ìròyìn ẹ̀ ò lè tó àfojúbà. Jèhófà ṣèlérí pé: “Wò ó! Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.” (Ìfi. 21:5) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ò ní lè fojú pọ́n ẹnikẹ́ni mọ́, wọn ò sì ní lè mú káwọn èèyàn hùwà ìkà. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tírú ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ láyé yìí! Kò sí àní-àní pé ara máa tù wá gan-an. Àníyàn ayé ò tún ní gba oorun lójú wa mọ́. Bákan náà, àwọn tó bá la Amágẹ́dọ́nì já níbi gbogbo kárí ayé máa gba ìwòsàn lọ́nà ìyanu. Kò tán síbẹ̀ o, àjíǹde àwọn èèyàn wa tó ti kú tá a ti ń retí á wá bẹ̀rẹ̀. Ó dájú pé ayé á dùn, àá sì gbádùn ayé wa bí Jèhófà Baba wa ọ̀run ṣe fẹ́.
Jèhófà máa bù kún àwọn olóòótọ́ tó ti fara da ọ̀pọ̀ ìṣòro (Wo ìpínrọ̀ 19)
20. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?
20 A mọ̀ pé onírúurú ìṣòro la ṣì máa ní báwọn ọjọ́ ìkẹyìn ṣe ń lọ sópin, síbẹ̀ ẹ jẹ́ ká nígboyà, ká pinnu pé a máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run pátápátá, àá sì máa ṣègbọràn sí i. Ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Baba wa ọ̀run àti pé òpùrọ́ ni Sátánì. Kò sí àní-àní pé ó wu Jèhófà gan-an láti san àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ lẹ́san. Torí náà, tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà Ọba Aláṣẹ, ó dájú pé a máa gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún tó ṣèlérí lọ́jọ́ iwájú.
ORIN 153 Jẹ́ Kí N Ní Ìgboyà