ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 April ojú ìwé 2-7
  • Jèhófà Ti Kọ́ Mi Láti Ìgbà Èwe Mi Wá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Ti Kọ́ Mi Láti Ìgbà Èwe Mi Wá
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • JÈHÓFÀ Ń DÁ MI LẸ́KỌ̀Ọ́ NÌṢÓ
  • MO GBÁDÙN IṢẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ
  • WỌ́N RÁN MI LỌ SÍ SẸ̀NẸ̀GÀ
  • A ṢIṢẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ NÍ NEW BRUNSWICK ÀTI QUEBEC
  • A RÁNTÍ ÀWỌN ARÁ WA TÍ WỌ́N ṢIṢẸ́ KÁRA
  • MO KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ÀWỌN ARÁKÙNRIN TÓ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́
  • A LỌ SÍ AMẸ́RÍKÀ
  • Mo Rí Ọ̀pọ̀ Ìbùkún Gbà Torí Mo Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Tó Fi Àpẹẹrẹ Tó Dáa Lélẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Tá A Bá Ń Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́, A Máa Jàǹfààní Ẹ̀ Títí Láé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Bí A Ṣe Ń Dá Àwọn Òjíṣẹ́ Ìjọba Náà Lẹ́kọ̀ọ́
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ìpinnu Tó Tọ́ Yọrí Sí Ìbùkún Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 April ojú ìwé 2-7
Arákùnrin David Splane ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fí ìsì ẹ̀.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Ti Kọ́ Mi Láti Ìgbà Èwe Mi Wá

BÍ DAVID SPLANE ṢE SỌ Ọ́

ARÁKÙNRIN kan fún mi ní ìwé pélébé kan. Ohun tó wà nínú ìwé náà ni, “David Splane, April 8, 1953: ‘Kíkéde Òpin Ayé.’” Bí mo ṣe ń wo ìwé yẹn tìyanu-tìyanu, mo bi arákùnrin náà pé “Kí leléyìí?” Wọ́n sọ pé, “Àsọyé tó o máa sọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run nìyẹn.”a Mo wá sọ fún arákùnrin náà pé, “Mi ò sọ pé mo fẹ́ sọ àsọyé nílé ẹ̀kọ́ yìí!”

Àmọ́ kí n tó máa bọ́rọ̀ lọ, ẹ jẹ́ kí n sọ ìtàn ìgbésí ayé mi fún yín. Ìgbà tí wọ́n ń ja Ogun Àgbáyé Kejì ni wọ́n bí mi nílùú Calgary, lórílẹ̀-èdè Kánádà. Ní nǹkan bí ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75) sẹ́yìn, ọ̀dọ́kùnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Donald Fraser wàásù dé ilé wa, màmá mi sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Òtítọ́ tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an, àmọ́ àìlera ò jẹ́ kí wọ́n lè máa lọ sípàdé déédéé. Síbẹ̀, wọ́n ṣèrìbọmi lọ́dún 1950. Kò ju ọdún méjì lẹ́yìn ìgbà yẹn ni wọ́n kú, ikú wọn dùn mi gan-an. Bàbá mi ò tíì máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn, àmọ́ wọ́n gbà kí àwọn ará bójú tó ètò ìsìnkú màámi.

Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn tá a sin màámi, arábìnrin àgbàlagbà kan pè mí wá sípàdé, Alice lorúkọ wọn, ẹni àmì òróró sì ni wọ́n. Wọ́n mọ̀ mí dáadáa torí wọ́n máa ń rí mi tí màámi bá mú mi wá sípàdé òpin ọ̀sẹ̀ nígbà tára wọn ṣì le. Mo bi bàbá mi bóyá mo lè lọ. Wọ́n gbà, wọ́n sì láwọn máa tẹ̀ lé mi lẹ́ẹ̀kan péré kí wọ́n lè fìyẹn dúpẹ́ lọ́wọ́ arákùnrin tó sọ àsọyé ìsìnkú màámi. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, a ṣe Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Bàbá mi gbádùn ìpàdé yẹn gan-an. Wọ́n ti fìgbà kan rí kẹ́kọ̀ọ́ nípa béèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ, torí náà ó wú wọn lórí bí wọ́n ṣe ń gbọ́ àwọn àsọyé tí wọ́n sọ nípàdé náà. Ìyẹn wá mú kí bàbá mi pinnu pé àwọn á máa lọ sípàdé yẹn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá sáwọn ìpàdé yòókù.

Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ẹni tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run máa ka orúkọ gbogbo àwọn arákùnrin tó ti forúkọ sílẹ̀, àwọn arákùnrin náà á sì dáhùn pé, “Mo wá.” Lálẹ́ ọjọ́ kan, mo sọ fún arákùnrin náà pé kí wọ́n pe orúkọ tèmi náà ní ìpàdé tó tẹ̀ lé e. Wọ́n gbóríyìn fún mi, wọn ò sì bi mí bóyá mo mọ ohun tíyẹn túmọ̀ sí.

Mi ò mọ̀ pé àwọn tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti sọ àsọyé ni wọ́n máa ń ka orúkọ wọn. Èmi kàn fẹ́ kí wọ́n ka orúkọ mi ni mo ṣe lọ bá arákùnrin náà. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, wọ́n pe orúkọ mi, tayọ̀tayọ̀ ni mo fi sọ pé, “Mo wá.” Lẹ́yìn ìpàdé, àwọn ará kí mi dáadáa, wọ́n sì gbóríyìn fún mi. Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n fún mi níwèé iṣẹ́ tí mo sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.

Ẹ̀rù bà mí gan-an. Torí nígbà yẹn, àsọyé oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́fà sí mẹ́jọ ni wọ́n máa ń fáwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́. Kò sí iṣẹ́ Bíbélì kíkà. Èmi àti bàbá mi jọ múra àsọyé náà, kódà tí mo bá ka iye ìgbà tá a fi dánra wò, á tó ogún (20). Lẹ́yìn iṣẹ́ yẹn, wọ́n fún mi nímọ̀ràn tó ṣe mí láǹfààní. Látàwọn ọdún yìí wá, Jèhófà ti dá mi lẹ́kọ̀ọ́ gan-an. Ó ti lo bàbá mi, àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin títí kan ètò ẹ̀ láti dá mi lẹ́kọ̀ọ́.

JÈHÓFÀ Ń DÁ MI LẸ́KỌ̀Ọ́ NÌṢÓ

Arábìnrin Alice tí mo sọ̀rọ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan kọ́ mi bí mo ṣe lè báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ tí mo bá fẹ́ wàásù. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ètò Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká ka ẹsẹ Bíbélì mẹ́ta fún ẹni tá à ń wàásù fún, lẹ́yìn náà ká fẹ́ni náà ní ìwé. Tó bá ti kàn mí láti wàásù, Arábìnrin Alice máa kọ́kọ́ bá ẹni yẹn sọ̀rọ̀, wọ́n á wá ní kí n ka ẹsẹ Bíbélì àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà, màá máa bá ìwàásù lọ, màá sì ka àwọn ẹsẹ Bíbélì méjì tó kù kí n tó fún ẹni náà níwèé. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, èmi náà kọ́ béèyàn ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tí mo bá fẹ́ wàásù. Bí ọdún 1954 ṣe ń parí lọ, bàbá mi ṣèrìbọmi, àwọn náà sì kọ́ mi bí màá ṣe máa wàásù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé òbí tó ń dá tọ́mọ ni wọ́n, wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti kọ́ mi kí n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Tó bá kan ìpàdé àti iṣẹ́ ìwàásù, wọn ò fi bá èèyàn ṣeré rárá. Mo ti mọ̀ pé tó bá di òpin ọ̀sẹ̀, ìpàdé àti iṣẹ́ ìwàásù la máa lọ.

Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo kọ́ lọ́dún méjìlá (12) tí mo lò nílé ìwé, àwọn nǹkan náà sì wúlò fún mi títí dòní. Bí àpẹẹrẹ, mo kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ìṣirò àti èdè Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn nǹkan tí mo kọ́ nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí mo gbà nípa bí wọ́n ṣe máa ń kọ ìtàn ti wúlò fún mi gan-an. Kódà, mò ń jàǹfààní ẹ̀ báyìí bí mo ṣe ń bá Ẹ̀ka Tó Ń Kọ̀wé ṣiṣẹ́.

Àwọn èèyàn sábà máa ń bi mí bóyá àtikékeré ni mo ti fẹ́ràn orin kíkọ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn òbí mi fẹ́ràn orin kíkọ gan-an. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méje, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ béèyàn ṣe ń tẹ dùrù, àmọ́ obìnrin tó ń kọ́ mi sọ pé mi ò lẹ́bùn orin kíkọ. Kódà, ó sọ fún bàbá mi pé kí wọ́n dá ẹ̀kọ́ náà dúró. Ohun tó sì fà á ti mi ò fi ṣe dáadáa ni pé orin kíkọ ò fi bẹ́ẹ̀ wù mí nígbà yẹn.

Oṣù mélòó kan lẹ́yìn ìgbà yẹn, bàbá mi gba ẹlòmíì táá máa kọ́ mi. Lọ́tẹ̀ yìí, dípò kí n kọ́ bí wọ́n ṣe ń tẹ dùrù nìkan, mo tún kọ́ bí wọ́n ṣe ń kọrin, ìyẹn sì jẹ́ kí n fakọyọ. Ohùn mi dùn gan-an nígbà yẹn, mo sì gbégbá orókè nínú àwọn ìdíje kan tí mo lọ. Ó wù mí kí n gboyè jáde nídìí orin kíkọ, torí pé ìyẹn á jẹ́ kí n lè máa kọ́ àwọn èèyàn lórin, màá sì lè rówó gbọ́ bùkátà mi tí mo bá di aṣáájú-ọ̀nà. Àmọ́ mo rí i pé kí n tó lè gboyè jáde, màá ní láti kàwé kí n sì kẹ́kọ̀ọ́ gan-an, ẹ̀kọ́ náà sì máa gbà mí lákòókò. Bí mo ṣe pa ẹ̀kọ́ yẹn tì nìyẹn tí mo sì gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé lọ́dún 1963.

MO GBÁDÙN IṢẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ

Lẹ́yìn tí mo lo ọdún kan lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ètò Ọlọ́run ní kí n lọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nílùú Kapuskasing, ìpínlẹ̀ Ontario. Gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ni Arákùnrin Daniel Skinner tá a jọ ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà níbẹ̀ fi jù mí lọ. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni arákùnrin yìí kọ́ mi nípa bá a ṣe ń ṣètò ìjọ. Kódà ọmọ ogún (20) ọdún péré ni mí nígbà tí wọ́n fọwọ́ sí i pé kí n wà nínú Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ìjọ, torí náà ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ kí n kọ́. Inú mi dùn gan-an pé lóde òní, ètò Ọlọ́run tún ti ń tẹnu mọ́ ọn pé ká máa dá àwọn ọ̀dọ́kùnrin lẹ́kọ̀ọ́. Táwọn ọ̀dọ́kùnrin náà bá sì fi ara wọn fún ẹ̀kọ́ náà, Jèhófà máa rí wọn lò dáadáa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀ bí wọ́n tiẹ̀ kéré lọ́jọ́ orí!

Nǹkan ò rọrùn nílùú Kapuskasing. Bí àpẹẹrẹ lásìkò òtútù, ojú ọjọ́ máa ń tutù gan-an. Síbẹ̀, èmi àti Dan sábà máa ń fẹsẹ̀ rìn lọ síbikíbi tá a bá fẹ́ lọ. Àmọ́, Jèhófà bù kún iṣẹ́ wa níbẹ̀. Lára àwọn ìbùkún tí mo rí ni pé ibẹ̀ ni mo ti pàdé arábìnrin kan tó ń jẹ́ Linda Cole, òun sì ni mo pa dà fẹ́.

Akéde tó nítara ni Linda, ó sì ń kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìwà ẹ̀ wuni gan-an torí pé ó lawọ́, ara ẹ̀ yọ̀ mọ́ọ̀yàn, ó sì lọ́yàyà. Màmá ẹ̀ tó ń jẹ́ Goldie náà ò kẹ̀rẹ̀ tó bá kan iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé bàbá wọn tó ń jẹ́ Allen ta kò wọ́n gan-an níbẹ̀rẹ̀, ìyá wọn máa ń mú Linda àtàwọn àbúrọ̀ ẹ̀ méjèèjì ìyẹn John àti Gordon wá sípàdé, ó sì tún máa ń mú wọn dání lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Goldie, Linda, John àti Gordon jọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó yá, bàbá wọn kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó sì sin Jèhófà tọkàntọkàn.

Lọ́dún 1965, ètò Ọlọ́run pè mí sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ olóṣù kan ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Kánádà kí n lè kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Nílé ẹ̀kọ́ náà, wọ́n sọ fún mi pé kí n kọ̀rọ̀ sí fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò rò ó rí pé mo lè di míṣọ́nnárì, kódà mi ò rò pé mo lẹ́bùn ẹ̀, síbẹ̀ mo kọ̀rọ̀ sí fọ́ọ̀mù náà. Bí wọ́n ṣe pè mí sí kíláàsì kejìlélógójì (42) ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì nìyẹn. Nílé ẹ̀kọ́ náà, àtìgbàdégbà làwọn olùkọ́ wa máa ń sọ ibi tí kálukú wa ti lè sunwọ̀n sí i. Ohun àkọ́kọ́ tí wọ́n sọ fún mi ni pé kí n sapá kí n lè mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ètò yìí nígbà tí mo ṣì wà nílé ẹ̀kọ́ náà. Ìmọ̀ràn yẹn ṣe mí láǹfààní torí pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún (21) ni mí nígbà yẹn.

Lára ohun tí wọ́n kọ́ wa ní Gílíádì ni bá a ṣe lè bá àwọn iléeṣẹ́ rédíò, tẹlifíṣọ̀n àtàwọn oníwèé ìròyìn ṣiṣẹ́. Mo gbádùn ẹ̀kọ́ náà dọ́ba. Mi ò mọ̀ pé ẹ̀kọ́ yìí ṣì máa wúlò fún mi lọ́jọ́ iwájú. Ẹ fọkàn balẹ̀, máa ṣàlàyé fún yín.

WỌ́N RÁN MI LỌ SÍ SẸ̀NẸ̀GÀ

Lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege, wọ́n rán èmi àti Michael Höhle lọ sórílẹ̀-èdè Sẹ̀nẹ̀gà ní Áfíríkà. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn la gbéra lọ síbi tí wọ́n rán wa lọ. Lákòókò yẹn, àwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè náà ò ju ọgọ́rùn-ún (100) lọ.

Lẹ́yìn tí mo lo oṣù mélòó kan lẹ́nu iṣẹ́, ètò Ọlọ́run ní kí n lọ máa ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì lọ́jọ́ kan lọ́sẹ̀. Gbogbo ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ò ju yàrá kan nínú ilé táwọn míṣọ́nnárì kan ń gbé. Síbẹ̀, Arákùnrin Emmanuel Paterakis tó jẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ka jẹ́ kí n mọ̀ pé bí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ò tiẹ̀ ju yàrá kan lọ, ibẹ̀ ni ojúkò ètò Ọlọ́run lórílẹ̀-èdè náà. Mo rántí ìgbà kan tí Arákùnrin Paterakis pinnu pé ká kọ lẹ́tà sí gbogbo míṣọ́nnárì tó wà lórílẹ̀-èdè náà ká lè fún wọn níṣìírí. Lákòókò yẹn, téèyàn bá fẹ́ ṣe ẹ̀dà lẹ́tà, ó máa ń wọ́n gan-an. Torí náà, ṣe la fi ẹ̀rọ typewriter tẹ lẹ́tà kọ̀ọ̀kan ká lè fi ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn míṣọ́nnárì náà. Kí n sòótọ́, iṣẹ́ yẹn ò rọrùn rárá torí pé a ò gbọ́dọ̀ ṣe àṣìṣe kankan bó ti wù kó kéré mọ!

Nígbà tá a parí iṣẹ́ lálẹ́ ọjọ́ yẹn, tí mo sì ń múra láti lọ sílé, Arákùnrin Paterakis fún mi ní àpò ìwé kan. Ó wá sọ fún mi pé, “David, ètò Ọlọ́run kọ lẹ́tà sí ẹ.” Nígbà tí mo ṣí àpò ìwé náà, mo rí i pé ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà tí mo tẹ̀ ló wà nínú ẹ̀! Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn kọ́ mi pé mo gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ètò Ọlọ́run, ì bàá jẹ́ inú yàrá kólóbó kan ni wọ́n ti ń ṣiṣẹ́.

Arákùnrin Splane àtàwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń rẹ́rìn-ín nígbà tí wọ́n ń ya fọ́tò.

Èmi àtàwọn míṣọ́nnárì míì lórílẹ̀-èdè Sẹ̀nẹ̀gà, lọ́dún 1967

Mo mú àwọn akéde tá a jọ wà nínú ìjọ lọ́rẹ̀ẹ́, mo sì máa ń ṣeré lọ sọ́dọ̀ wọn láwọn ìrọ̀lẹ́ Sátidé. Mo gbádùn àwọn àkókò yẹn gan-an! Kódà, a ṣì ń gbúròó ara wa títí dòní. Mo ṣì máa ń sọ èdè Faransé tí mo kọ́ níbẹ̀ tí n bá ṣèbẹ̀wò sáwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà kárí ayé.

Lọ́dún 1968, èmi àti Linda bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra sọ́nà. Ọ̀pọ̀ oṣù lẹ́yìn ìyẹn ni mo fi wáṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́ kémi àti Linda lè máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ ní Sẹ̀nẹ̀gà lẹ́yìn tá a bá ṣègbéyàwó. Àmọ́ mi ò ríṣẹ́ torí àwọn ọmọ ìlú ni ìjọba sọ pé kí wọ́n máa gbà síṣẹ́. Nígbà tó yá, mo pa dà sí Kánádà, a sì ṣègbéyàwó. Ètò Ọlọ́run wá ní ká lọ máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní agbègbè Edmundston, nílùú New Brunswick, ibẹ̀ ò sì jìnnà sílùú Quebec.

David àti Linda Splane dúró lójú ọ̀nà tí wọ́n fi òdòdó ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, wọ́n sì ń rẹ́rìn-ín músẹ́.

Ọjọ́ ìgbéyàwó wa lọ́dún 1969

A ṢIṢẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ NÍ NEW BRUNSWICK ÀTI QUEBEC

Kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan lágbègbè yẹn, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìdí ni pé àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ló ń darí bí nǹkan ṣe ń lọ nílùú yẹn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ilé tó wà níbẹ̀ ni wọ́n gbé àmì sí pé ‘A ò fẹ́ rí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan níbí.’ Nígbà yẹn, kò sí ìtọ́ni tó sọ pé ká má ṣe lọ sáwọn ilé tí wọ́n bá firú àmì bẹ́ẹ̀ sí. Torí náà, gbogbo ilé tó wà nílùú yẹn la wàásù dé, bóyá wọ́n fàmì sẹ́nu ọ̀nà tàbí wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé ìyẹn ti yí pa dà báyìí. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ làwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì máa ń fi sínú ìwé ìròyìn pé: “Ẹ jẹ́ ká wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ká sì lé wọn dànù.” Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rin péré ló wà ní gbogbo ìlú yẹn, ìyẹn Victor àti Velda Norberg pẹ̀lú èmi àti Linda. Torí náà, a mọ àwọn tí wọ́n ń bá wí!

Mi ò lè gbàgbé ìgbà àkọ́kọ́ tí alábòójútó àyíká bẹ̀ wá wò. Lẹ́yìn tó lo ọ̀sẹ̀ kan lọ́dọ̀ wa, ó sọ pé, “Ohun tó dáa jù tẹ́ ẹ lè ṣe níbí ni pé kẹ́ ẹ jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe èèyàn burúkú.” Látìgbà yẹn, ohun tá a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe nìyẹn, ó sì sèso rere! Díẹ̀díẹ̀, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nírẹ̀lẹ̀, a sì yàtọ̀ pátápátá sáwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tó jẹ́ agbéraga. Ní báyìí, ìjọ kékeré kan ti wà nílùú yẹn.

Lẹ́yìn tá a lo nǹkan bí ọdún kan níbẹ̀, ètò Ọlọ́run ní ká lọ ṣèrànwọ́ níjọ kan tó wà ní Quebec City. A gbádùn àwọn ará tó wà níjọ yẹn gan-an torí pé wọ́n kóòyàn mọ́ra. Àmọ́ oṣù mẹ́fà lẹ́yìn ìyẹn, ètò Ọlọ́run ní ká bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká.

Ọdún mẹ́rìnlá (14) la fi ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká ní agbègbè Quebec. A ò lè gbàgbé àsìkò yẹn! Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní Quebec, kódà tá a bá bẹ ìjọ wò, a sábà máa ń rí àwọn ìdílé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí gbogbo wọn ń kẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n sì ń múra láti ṣèrìbọmi!

A RÁNTÍ ÀWỌN ARÁ WA TÍ WỌ́N ṢIṢẸ́ KÁRA

A fẹ́ràn àwọn ará wa tó ń gbé lágbègbè tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé lórílẹ̀-èdè Kánádà gan-an. Ìdí ni pé wọn kì í figbá kan bọ̀kan nínú, wọ́n lọ́yàyà, inú wọn sì máa ń dùn. Àmọ́, kò rọrùn fún ọ̀pọ̀ wọn láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ìdílé wọn sì máa ń fojú wọn rí màbo. Àwọn ọ̀dọ́ kan wà táwọn òbí wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ fún pé, “Tó o bá fẹ́ ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o ò lè gbénú ilé yìí. Ọ̀kan lo máa fọwọ́ mú!” Ọ̀pọ̀ nínú wọn ò fi Jèhófà sílẹ̀ láìka àtakò yìí sí. Ó dá mi lójú pé inú Jèhófà máa dùn sí wọn gan-an!

Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, kò ní dáa kí n má sọ̀rọ̀ nípa àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tí wọ́n sìn nílùú Quebec nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ọ̀pọ̀ wọn ló jẹ́ pé àwọn apá ibòmíì lórílẹ̀-èdè Kánádà ni wọ́n ti wá. Wọ́n kọ́ èdè Faransé, wọ́n sì tún kọ́ àṣà ìbílẹ̀ àwọn èèyàn náà, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n ń ṣe nínú àṣà ìbílẹ̀ yìí ló jẹ́ pé inú ẹ̀sìn Kátólíìkì ló ti wá.

Ètò Ọlọ́run máa ń rán àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe pé kí wọ́n lọ sìn láwọn ibi tí kò ti sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan. Torí pé àwọn èèyàn ibẹ̀ ò fẹ́ràn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí mú kó nira gan-an fáwọn ará wa yìí láti rí ilé tí wọ́n á máa gbé. Èyí tó tiẹ̀ wá burú jù ni pé kò rọrùn rárá láti rí iṣẹ́ tí ò ní gba àkókò tí wọ́n á lè máa fi gbọ́ bùkátà ara wọn. Kódà, àwọn tọkọtaya bíi méjì sí mẹ́rin tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó jọ máa ń gba ilé kí wọ́n lè jọ máa pín owó ẹ̀ san. Ìdí sì ni pé owó ilé wọ́n gan-an. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà yìí nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ kára. Tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gbogbo ohun tó bá yẹ ni wọ́n máa ń ṣe láti ran ẹni náà lọ́wọ́. Ní báyìí táwọn ará ti pọ̀ ní Quebec, ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà yẹn ti lọ sáwọn ibòmíì tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i.

Nígbà tá a ṣì ń ṣe alábòójútó àyíká, a sábà máa ń bá àwọn ọ̀dọ́ tí ò tíì pé ogún ọdún ṣiṣẹ́ lóde ìwàásù láwọn àárọ̀ ọjọ́ Sátidé. Ìyẹn máa ń jẹ́ ká mọ àwọn ìṣòro tí wọ́n ní. Àwọn kan lára àwọn ọ̀dọ́ yẹn ti di míṣọ́nnárì nílẹ̀ òkèèrè báyìí, àwọn míì sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ míì nínú ètò Ọlọ́run.

Nígbà yẹn, tá a bá lọ bẹ àwọn ìjọ kan wò, wọn kì í lè fún wa ni owó tá a ná nígbà tá a bẹ̀ wọ́n wò. Torí náà láwọn ìgbà míì, owó máa ń tán lọ́wọ́ wa tí oṣù bá fi máa parí. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, Jèhófà la máa ń gbára lé pátápátá torí a mọ̀ pé òun nìkan ló mọ gbogbo bí nǹkan ṣe rí fún wa. Kì í dá wa dá ìṣòro wa. Ó sì máa ń ṣe ọ̀nà àbáyọ torí ó máa ń jẹ́ ká rí ọgbọ́n ẹ̀ dá tá a fi máa dé ìjọ míì.

MO KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ÀWỌN ARÁKÙNRIN TÓ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́

Nígbà tá a wà nílùú Quebec, a láǹfààní láti wàásù lórí rédíò, tẹlifíṣọ̀n àtàwọn ìwé ìròyìn. Inú mi sì dùn pé wọ́n ti kọ́ wa bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Èmi àti Arákùnrin Léonce Crépeault la jọ máa ń ṣiṣẹ́ yìí. Alábòójútó arìnrìn àjò làwọn náà, wọ́n sì mọ bá a ṣe ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ dáadáa. Tí wọ́n bá ń bá àwọn ọ̀gá ilé iṣẹ́ ìròyìn sọ̀rọ̀, wọn kì í ṣe bíi pé àwọn mọṣẹ́ náà dáadáa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n máa ń sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́ sà, oníwàásù lèmi àti ẹnì kejì mi. A ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ lórí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n. Àmọ́ wọ́n ní ká wá síbí ká lè sọ fáwọn èèyàn nípa àpéjọ ńlá táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ ṣe. Ẹ jọ̀ọ́, báwo lẹ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?” Bí wọ́n ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ yìí mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà láti ràn wá lọ́wọ́ nígbà yẹn lọ́hùn-ún.

Nígbà tó yá, ètò Ọlọ́run ní kí n bá Arákùnrin Glen How ṣiṣẹ́, ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò wa ni wọ́n, àwọn ló sì ń rí sí àwọn ọ̀rọ̀ tó gbẹgẹ́ táwọn oníròyìn fẹ́ gbé jáde nípa wa. Àwọn ohun tí mo kọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì àti nígbà témi àti Arákùnrin Léonce jọ ṣiṣẹ́ wúlò fún mi gan-an. Mo sì tún mọyì àǹfààní tí mo ní pé mo bá Arákùnrin How ṣiṣẹ́. Wọn kì í bẹ̀rù tí wọ́n bá ń gbèjà ètò Ọlọ́run nílé ẹjọ́. Àmọ́ ohun tó wú mi lórí jù ni pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú.

Lọ́dún 1985, ètò Ọlọ́run gbé wa lọ sí àyíká kan ní ìwọ̀ oòrùn Kánádà, apá ibẹ̀ ni Bàbá mi ń gbé, ìyẹn á sì jẹ́ ká lè bójú tó wọn. Ó dùn wá pé oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà ni wọ́n kú. Oríṣiríṣi àyíká la ti sìn lápá ìwọ̀ oòrùn Kánádà. Ó yà wá lẹ́nu gan-an nígbà tí ètò Ọlọ́run pè wá sí Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1989. Bó ṣe di pé a fi iṣẹ́ alábòójútó àyíká sílẹ̀ nìyẹn lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mọ́kàndínlógún (19) tá a ti gbádùn iṣẹ́ náà. Ní gbogbo ọdún tá a fi ṣiṣẹ́ yìí, a ò lè ka oríṣiríṣi ilé àwọn ará tá a dé sí àti oríṣiríṣi oúnjẹ aládùn tí wọ́n fi ṣe wá lálejò. A mọyì gbogbo àwọn ará tí wọ́n gbà wá sílé tí wọ́n sì fún wa ní oúnjẹ!

A LỌ SÍ AMẸ́RÍKÀ

Nígbà tá a dé Brooklyn, Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn ni mo ti ṣiṣẹ́. Mo mọyì àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí mo gbà níbẹ̀. Ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ pàtàkì tí mo kọ́ ni pé mi ò gbọ́dọ̀ ronú pé mo mọ bọ́rọ̀ kan ṣe jẹ́ láìmọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tó di ọdún 1998, wọ́n gbé mi lọ sí Ẹ̀ka Ìwé Kíkọ, ibẹ̀ ni mo wà títí di báyìí, mo ṣì ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé. Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi bá Arákùnrin John Barr ṣiṣẹ́, àwọn ni olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé nígbà yẹn. Mi ò jẹ́ gbàgbé àwọn nǹkan tí mo kọ́ lọ́dọ̀ wọn àti gbogbo àkókò alárinrin tá a jọ lò. Èèyàn dáadáa ni wọ́n, wọ́n sì fìwà jọ Jésù.

David àti Linda Splane jọ ya fọ́tò pẹ̀lú John àti Mildred Barr.

Èmi àti ìyàwó mi pẹ̀lú John àti Mildred Barr

Inú mi dùn pé mo láǹfààní láti bá àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìwé Kíkọ, àwọn ará yìí nírẹ̀lẹ̀ gan-an. Wọ́n máa ń gbàdúrà kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ èyíkéyìí. Wọ́n sì gbà pé àṣeyọrí yòówù kí wọ́n ṣe, kì í ṣe mímọ̀ọ́ṣe àwọn, ẹ̀mí Jèhófà ló ràn wọ́n lọ́wọ́.

Arákùnrin Splane ń darí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n jẹ́ ogún (20) nínú ẹgbẹ́ akọrin Watchtower, arábìnrin kan sì ń tẹ dùrù.

Èmi rèé níwájú ẹgbẹ́ akọrin Watchtower ní ìpàdé ọdọọdún 2009

Tayọ̀tayọ̀ ni Arákùnrin Splane ń fún arábìnrin kan ní Bíbélì.

Mò ń fún àwọn èèyàn ní Bíbélì ní àpéjọ àgbáyé ní Seoul, lórílẹ̀-èdè Kòríà lọ́dún 2014

Èmi àti ìyàwó mi mọyì àǹfààní tá a ní láti lọ bẹ àwọn ará wa wò láwọn orílẹ̀-èdè tó tó àádọ́fà (110). A rí i pé lóòótọ́ làwọn míṣọ́nnárì, Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka àtàwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún míì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. A tún rí i pé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin láwọn orílẹ̀-èdè tá a lọ yìí nítara gan-an, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi ìṣòro ni wọ́n ń bá yí, irú bí ogun, ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu àti inúnibíni. Ó dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an!

Látàwọn ọdún yìí wá, igi lẹ́yìn ọgbà ni ìyàwó mi jẹ́ fún mi bí mo ṣe ń ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run gbé fún mi. Ó fẹ́ràn àwọn èèyàn gan-an, ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Kò kẹ̀rẹ̀ tó bá kan kéèyàn bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wẹ́rẹ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó sì ti ran àwọn míì lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Ṣe ni Jèhófà fi ìyàwó mi ta mí lọ́rẹ! Bí ara ṣe ń di ara àgbà, a mọyì àwọn ọ̀dọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ rìnrìn àjò tàbí tá a fẹ́ ṣe àwọn nǹkan pàtàkì míì.—Máàkù 10:29, 30.

Tí mo bá ronú nípa àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ láti ọgọ́rin (80) ọdún sẹ́yìn, ṣe ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Èmi náà sọ bíi ti onísáàmù pé: “Ọlọ́run, o ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá, títí di báyìí, mò ń kéde àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.” (Sm. 71:17) Títí láé ni màá sì máa ṣe bẹ́ẹ̀!

a Ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ la ti ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn báyìí.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́