ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 July ojú ìwé 26-30
  • Mo Jẹ́ Kí Jèhófà Kọ́ Mi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Jẹ́ Kí Jèhófà Kọ́ Mi
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀTIKÉKERÉ LÓ TI WÙ MI KÍ N MỌ ỌLỌ́RUN
  • MO FI YUNIFÁSÍTÌ SÍLẸ̀, MO SÌ BẸ̀RẸ̀ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ
  • MO KỌ́ ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ PÀTÀKÌ NÍ BẸ́TẸ́LÌ TÓ WÀ NÍ BROOKLYN
  • “Ó YẸ KÓ O KỌ́ ÈDÈ JAPANESE!”
  • A LỌ SÍ Ẹ̀KA Ọ́FÍÌSÌ JAPAN, A SÌ TÚN DI AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ ÀKÀNṢE
  • MO TI PINNU PÉ MÀÁ JẸ́ KÍ JÈHÓFÀ TÚBỌ̀ MÁA KỌ́ MI
  • Èyí Ha Lè Jẹ́ Iṣẹ́ Tó Dára Jù Lọ fún Ọ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ǹjẹ́ O Lè Yọ̀ǹda Ara Rẹ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Gbogbo Èèyàn La Pè!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ibi Tí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún Gbé Mi Dé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 July ojú ìwé 26-30
Ken Kiuchi.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Jẹ́ Kí Jèhófà Kọ́ Mi

BÍ KEN KIUCHI ṢE SỌ Ọ́

MI Ò lè gbàgbé ọjọ́ tí mo kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tó ń di ìwé pọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn, New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Bí mo ṣe débẹ̀ báyìí, tí mo rí báwọn maṣíìnì tó wà níbẹ̀ ṣe ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n sì ń pariwo, ṣe lọkàn mi kó sókè. Àwọn eruku tó ń jáde nínú ìwé tí wọ́n ń gé bo gbogbo ibẹ̀, òórùn ọ́ìlì tí wọ́n ń lò sì gba ibẹ̀ kan.

Àmọ́ ohun kan wà tó wú mi lórí gan-an, ìyẹn sì làwọn èèyàn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Ọ̀dọ́ làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí, iṣẹ́ kan náà ni wọ́n sì ń ṣe lójoojúmọ́. Àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ rí wọn, débi tí wọ́n á fi rí iṣẹ́ ńlá tí wọ́n ń ṣe. Síbẹ̀, inú wọn ń dùn, wọ́n sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Ohun tí mo kọ́ lára wọn ni pé ó yẹ kí n nírẹ̀lẹ̀ bí mo ṣe ń sin Jèhófà.

Láti àwọn ọdún yìí wá, Jèhófà ti kọ́ mi kí n lè túbọ̀ wúlò fún un. Àmọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ bí mo ṣe ń wá òtítọ́ fún yín nígbà tí mo ṣì ń ṣe ẹ̀sìn Búdà.

ÀTIKÉKERÉ LÓ TI WÙ MI KÍ N MỌ ỌLỌ́RUN

Ìlú Chicago, Illinois, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n bí mi sí, ibẹ̀ ni mo sì dàgbà sí. Èmi làkọ́bí nínú àwa ọmọ mẹ́rin. Orílẹ̀-èdè Japan làwọn òbí mi ń gbé kí wọ́n tó kó lọ sílùú Chicago lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, torí wọ́n gbà pé nǹkan máa rọ̀ṣọ̀mù níbẹ̀. Wọ́n fẹ́ káwa ọmọ wọn lọ sílé ìwé tó dáa, ká sì di èèyàn pàtàkì nígbèésí ayé.

Ẹ̀sìn Búdà làwọn òbí mi ń ṣe, wọn ò sì fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré rárá. Kódà, tẹ́ńpìlì Búdà wà nílé tí wọ́n ti tọ́ màmá mi dàgbà. Kò tán síbẹ̀ o, àlùfáà Búdà ni bàbá ìyá mi àtàwọn àbúrò ìyá mi méjì. Torí náà, nígbà tí mo wà ní kékeré, a ò fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré nílé wa. Ohun tí mo máa ń kọ́kọ́ ṣe tí mo bá dé láti ilé ìwé ni pé, màá lọ sun tùràrí nídìí ère Búdà, màá sì gbé ìrẹsì àti omi síbẹ̀. Tó bá wá di ọjọ́ Sunday, àá lọ sí tẹ́ńpìlì Búdà, àá lọ kọrin fún ère tó wà níbẹ̀. Ère yìí tóbi ju èyí tá a ní sílé, wúrà ni wọ́n sì fi bò ó látòkè délẹ̀.

Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún méje, mo rántí pé tí mo bá ń wo ère Búdà tó wà nílé wa, mo máa ń bi ara mi pé, ‘Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí mi tí mo bá kú?’ Ohun tí wọ́n fi kọ́ mi nínú ẹ̀sìn Búdà ni pé, téèyàn bá kú, ẹni náà á lọ máa gbé níbi táwọn ẹni ẹ̀mí ń gbé. Mo wá rò ó pé lọ́jọ́ kan èmi náà máa kú, ó sì ṣeé ṣe kí n lọ máa gbé níbi táwọn ẹni ẹ̀mí wà. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, mi ò ní lè gbádùn ayé mi bíi tàwọn èèyàn yòókù mọ́. Ìyẹn kórònú bá mi gan-an! Kí n tó mọ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi.

Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15), àwọn nǹkan tá à ń ṣe nínú ẹ̀sìn Búdà ò nítumọ̀ kankan sí mi mọ́. Ó máa ń ṣe mí bíi pé nǹkan kan wà tó sọ nù láyé mi. (Mát. 5:3) Nínú mi lọ́hùn-ún, mo gbà pé ó yẹ kí Ọlọ́run alágbára kan wà níbì kan. Ó wù mí kí n mọ̀ ọ́n. Mo wá ń wò ó pé ó ṣeé ṣe kí n rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè mi nínú Bíbélì. Ni mo bá ra àlòkù Bíbélì King James Version kan níbi àjọyọ̀ Búdà. Mi ò mọ̀ pé mo lè rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rà níbẹ̀.

Ken Kiuchi àti Wilson Bashou tó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Èmi àti Wilson Bashou, tó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́

Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17), arákùnrin kan tó ń jẹ́ Wilson Bashou pà dé mi lójú ọ̀nà nígbà tí mò ń mú ajá mi rìn káàkiri. Ó béèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ṣé o mọ ohun tí Ọlọ́run sọ pé òun máa ṣe lọ́jọ́ iwájú?” Ìbéèrè yẹn mú káwa méjèèjì sọ̀rọ̀ gan-an látinú Bíbélì. Ó ka Ìfihàn 17:1, ó sì bi mí pé, “Kí ni ‘omi púpọ̀’ tí aṣẹ́wó náà jókòó lé túmọ̀ sí?” Kò yé mi rárá. Ó wá fi ẹsẹ kẹẹ̀ẹ́dógún (15) hàn mí tó sọ pé àwọn èèyàn ni omi púpọ̀ náà túmọ̀ sí. Ó wú mi lórí gan-an nígbà tí mo mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ka gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì, ìyẹn ló sì máa ń jẹ́ kí àwọn ibi tó ṣòro lóye nínú ẹ̀ tètè yé wọn. Kí Wilson tó máa lọ, ó fún mi ní ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye. Ohun tí mo kà nínú ìwé kékeré aláwọ̀ búlúù yìí ló yí ìgbésí ayé mi pa dà pátápátá.

Ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn náà, mo lọ sípàdé fúngbà àkọ́kọ́. Mi ò lè gbàgbé báwọn ará ṣe gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀ lọ́jọ́ náà. Àtìgbà yẹn ni mo sì ti ń lọ sípàdé. Nígbà tó yá, Wilson bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mò ń gbádùn ohun tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì débi pé nígbà míì, nǹkan bíi wákàtí mẹ́jọ la fi máa ń kẹ́kọ̀ọ́. Inú àwọn òbí mi ò dùn rárá pé mò ń kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì gbìyànjú gan-an láti dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró. Àmọ́ bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń dá mi lójú pé mo ti rí òtítọ́. Torí náà, mo ṣèrìbọmi lọ́dún 1983.

MO FI YUNIFÁSÍTÌ SÍLẸ̀, MO SÌ BẸ̀RẸ̀ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ

Lásìkò tí mo ṣèrìbọmi, yunifásítì kan tó lórúkọ ni mo wà, mo sì ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ìṣègùn. Àwọn òbí mi ṣiṣẹ́ kára gan-an kí wọ́n lè rí i pé mo lọ sí yunifásítì. Ohun tí mo fẹ́ ṣe tẹ́lẹ̀ ni pé kí n parí ẹ̀kọ́ mi ní yunifásítì, àmọ́ ohun tó wù mí jù ni pé kí n fayé mi sin Jèhófà, kí n sì ṣiṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.

Bàbá mi ti kìlọ̀ fún mi tẹ́lẹ̀ pé, tí mo bá fi yunifásítì sílẹ̀ pẹ́rẹ́n, àwọn máa lé mi kúrò nílé. Ọ̀rọ̀ náà tojú sú mi, inú mi ò sì dùn rárá. Ìdí ni pé mo nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí mi gan-an, mi ò sì fẹ́ ṣe ohun tó máa dùn wọ́n. Torí náà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń bọ́ síta gbangba nínú ọgbà ilé ìwé wa lálẹ́, tí màá sì máa gbàdúrà pé, “Jèhófà, jọ̀ọ́ ràn mí lọ́wọ́ kí n lè ṣèpinnu tó tọ́.” Nígbà tí mo wá pinnu pé mo máa fi yunifásítì sílẹ̀, bàbá mi lé mi kúrò nílé. Mo pe Wilson mo sì ṣàlàyé gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un, ó ní kí n wá máa gbé lọ́dọ̀ òun. Ni mo bá di gbogbo ẹrù mi sínú báàgì kan, mo wọ mọ́tò, mo sì kó lọ sílé ẹ̀. Mo rántí pé ṣe lara tù mí pẹ̀sẹ̀, torí mo mọ̀ pé ìpinnu tó tọ́ ni mo ṣe.

Ṣe ló ń ṣe mí bíi pé wọ́n tú mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n! Mo wá lómìnira láti ṣe ohun tó wù mí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ni mo bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ́dún 1984.

Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà kọ́ mi láwọn ọdún tí mo fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Bí àpẹẹrẹ, mo kọ́ béèyàn ṣe ń láforítì. Mo rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan, kò yẹ kí n lọ sóde ìwàásù, torí kò sẹ́ni tí màá bá ṣiṣẹ́ lọ́sàn-án ọjọ́ náà. Àmọ́, mo gbìyànjú láti lọ. Lẹ́yìn tí mo ti ṣiṣẹ́ fún wákàtí mélòó kan, mo pinnu pé màá dé ilé kan sí i, lẹ́yìn náà màá ṣíwọ́. Èmi nìkan ni mo dá ṣiṣẹ́, ó ti rẹ̀ mí gan-an, ó sì jọ pé òjò fẹ́ rọ̀. Mo wá ronú pé, ‘Àbí kí n ṣíwọ́ ni?’ Àmọ́ mi ò ṣe bẹ́ẹ̀, bí mo ṣe dé àjà kẹta ní ilé tí mo ti pinnu láti wàásù kẹ́yìn, mo rí ọkùnrin kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Phillipines. Mo sọ lọ́kàn mi pé, ‘Kò dájú pé ẹni yìí lè gbọ́rọ̀ mi.’ Àṣé mò ń tan ara mi ni. Ọkùnrin náà gbà kí n wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tó yá.

MO KỌ́ ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ PÀTÀKÌ NÍ BẸ́TẸ́LÌ TÓ WÀ NÍ BROOKLYN

Lẹ́yìn tí mo gbé lọ́dọ̀ Wilson fún ọdún méjì, wọ́n pè mí sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn lọ́dún 1985. Bí mo ṣe sọ ṣáájú, ẹ̀ka tí wọ́n ti ń dìwé pọ̀ ni wọ́n ní kí n ti máa ṣiṣẹ́. Lọ́jọ́ kan, mo ṣàṣìṣe ńlá kan nígbà tí mò ń lo maṣíìnì tí wọ́n fi ń tẹ ọ̀rọ̀ sára èèpo ẹ̀yìn ìwé, ọ̀pọ̀ ìwé náà ló sì bà jẹ́. Àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ rọ̀ mí pé kí n lọ̀ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún arákùnrin tó ń bójú tó iṣẹ́ wa. Mo ṣàlàyé gbogbo bọ́rọ̀ náà ṣe jẹ́ fún un, àmọ́ ohun kan wà tó yẹ kí n ṣe tí mi ò ṣe. Arákùnrin náà wa rọra fohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ sọ fún mi pé, “Ó dáa kéèyàn máa tọrọ àforíjì.” Lójú ẹsẹ̀, mo kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan pé tí mo bá ṣàṣìṣe ó yẹ kí n gba ẹ̀bi mi lẹ́bi kí n sì sọ pé, “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ má bínú.”

Ken mú àwọn ìwé tí wọ́n fi ń ṣe èèpo ẹ̀yìn ìwé dání ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn.

Mò ń fi bá a ṣe ń tẹ ìwé han àwọn èèyàn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn

Ohun kan wà tí mo kọ́ lára àwọn àgbàlagbà tí wọ́n ti ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tipẹ́, ohun náà sì ni pé kí n ṣe tán láti ṣiṣẹ́ sin àwọn míì. Ìyẹn jẹ́ kí n rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́sàn-án ọjọ́ kan, tábìlì tí Arákùnrin Milton Henschel tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti fẹ́ jẹun lèmi náà wà. Lọ́jọ́ náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló kún inú yàrá ìjẹun, àwọn tó ń pín oúnjẹ náà ń ṣiṣẹ́ kára, kí oúnjẹ náà lè dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn, ó sì hàn lójú wọn pé iṣẹ́ náà kà wọ́n láyà torí wọn ò mọ̀ pé èrò máa pọ̀ tóyẹn. Àwa tá a jẹ́ ọ̀dọ́ lórí tábìlì náà bẹ̀rẹ̀ sí í kùn pé àwọn tó ń pín oúnjẹ náà ò yára. Arákùnrin Henschel ò tiẹ̀ sọ nǹkan kan rárá, ṣe ni wọ́n kàn dìde tí wọ́n sì lọ ran àwọn tó ń pín oúnjẹ náà lọ́wọ́. Wọ́n bá wọn pín omi, búrẹ́dì àti bọ́tà. Mi ò lè gbàgbé ohun tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ yẹn. Ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ní rán mi létí bí Jésù náà ṣe fọ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì ẹ̀.—Jòh. 13:3-5.

“Ó YẸ KÓ O KỌ́ ÈDÈ JAPANESE!”

Èmi àti Michiko Oda àti ọkọ wọn

Lọ́dún 1987 mo lọ sí Japan, inú mi sì dùn láti rí báwọn ará tó wà níbẹ̀ ṣe nírẹ̀lẹ̀, tí wọ́n sì ń fìtara wàásù. Ó wù mí láti ràn wọ́n lọ́wọ́, àmọ́ mi ò gbọ́ èdè Japanese. Arábìnrin kan ní Bẹ́tẹ́lì tó ń jẹ́ Michiko Oda wò mí, wọ́n sì sọ fún mi pé, “Ó yẹ kó o kọ́ èdè Japanese!” Ohun tí mo sì ṣe nìyẹn. Mi ò mọ̀ pé ìmọ̀ràn tí wọ́n fún mi yẹn máa ṣe mí láǹfààní jálẹ̀ ìgbésí ayé mi.

Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fún mi nímọ̀ràn yẹn, mo lọ sí ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Japanese nílùú New York. Èdè tí mo kọ́ yìí jẹ́ kí n lè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Lọ́dún 1989, mo lọ sí àpéjọ agbègbè tí wọ́n ṣe lédè Japanese ní Los Angeles, ìpínlẹ̀ California. Ìgbà àkọ́kọ́ tí mo sì máa lọ sí àpéjọ tí wọ́n ṣe lédè Japanese nìyẹn. Ní àpéjọ yẹn, mo rí Arábìnrin Miwako Onami tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ó sì wà lára àwọn tó ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́. Bí mo ṣe rí arábìnrin náà, ọkàn mi fà sí i.

Èmi àti Miwako ṣègbéyàwó lọ́dún 1992, ètò Ọlọ́run sì ní ká máa báṣẹ́ lọ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn. Miwako láròjinlẹ̀, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó sì máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Mo kẹ́kọ̀ọ́ gan-an lára ìyàwó mi, ìyẹn sì ti jẹ́ kí n túbọ̀ máa ṣe àwọn èèyàn jẹ́jẹ́. Jèhófà ló fi ìyàwó mi kẹ́ mi, torí pé gbogbo ìgbà ló máa ń múnú mi dùn, tó sì máa ń mára tù mí.

Ken àti Miwako Kiuchi lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn.

Ọjọ́ ìgbéyàwó wa

A LỌ SÍ Ẹ̀KA Ọ́FÍÌSÌ JAPAN, A SÌ TÚN DI AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ ÀKÀNṢE

Orílẹ̀-èdè Japan làwọn òbí ìyàwó mi wà. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn tó le gan-an. A sọ fún ètò Ọlọ́run bóyá wọ́n lè rán wa lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Japan, torí ìyẹn á jẹ́ ká lè wà nítòsí wọn, ká sì ríbi bójú tó wọn. Wọ́n fọwọ́ sí i, nígbà tó sì di ọdún 1999, a kó lọ sí Japan.

Ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Japan gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀, kò sì pẹ́ tára wa fi mọlé. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo kọ́ lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ní Japan. Wọ́n lawọ́ gan-an, wọ́n sì máa ń ṣàlejò. Wọn kì í fiṣẹ́ ṣeré, wọ́n sì máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kíṣẹ́ lè yá. Ìdí ni pé nínú àṣà ìbílẹ̀ wọn, wọ́n gbà pé táwọn èèyàn bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, iṣẹ́ máa ń yá ju kẹ́nì kan máa dá ṣe é, ó ṣe tán àgbájọ ọwọ́ la fi ń sọ̀yà. Àpẹẹrẹ àtàtà ni wọ́n jẹ́ fún mi, mo sì ti rí i pé ó yẹ kí n nírẹ̀lẹ̀ tí mo bá ń bá àwọn míì ṣiṣẹ́, kí n má sì fojú kéré ìwọ̀nba ohun tí mò ń ṣe kí ìfẹ́ Jèhófà lè ṣẹ.

Torí pé àṣà ìbílẹ̀ àwọn ará Japan yàtọ̀ sí tibi tí mo dàgbà sí, nígbà míì tí wọ́n bá bójú tó àwọn ọ̀rọ̀ kan, kì í rọrùn fún mi láti lóye ìdí tí wọ́n fi bójú tó o lọ́nà yẹn. Nígbà to yá, mo rí i pé ó yẹ kí n túbọ̀ máa ní sùúrù, kí n má sì máa bínú tí ìpinnu tí wọ́n ṣe bá rí bákan lára mi. Yàtọ̀ síyẹn, mo kẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan pé tá a bá tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà fún wa nípasẹ̀ ètò ẹ̀, á máa rọ́wọ́ ẹ̀ nínú ìpinnu èyíkéyìí táwọn tó ń ṣàbójútó wa bá ṣe. Ó ṣe tán, Jèhófà ló ń mú kí gbogbo nǹkan lọ bó ṣe yẹ.

Tí mo bá ń ronú nípa àwọn nǹkan tí mo kọ́ ní Bẹ́tẹ́lì, mo máa ń rántí wòlíì Mósè. Jèhófà ran Mósè lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ níwà tútù ní gbogbo ogójì (40) ọdún tó fi ṣe olùṣọ́ àgùntàn. Èmi náà kàwé bíi ti Mósè. Ìwé tí mo sì kà yìí mú kí n máa gbéra ga, kí n sì máa wò ó pé mi ò nílò ìrànlọ́wọ́ ẹnikẹ́ni kí n tó ṣàṣeyọrí. Àmọ́ ní Bẹ́tẹ́lì ohun tí mo kọ́ ni pé, ó yẹ kí n nírẹ̀lẹ̀ kí n sì máa gbára lé Jèhófà. Jèhófà fi sùúrù dá Mósè lẹ́kọ̀ọ́, ohun kan náà ló sì ń ṣe fún èmi náà látàwọn ọdún yìí wá.

Ken wà ní ọ́fí ìsì ẹ̀.

Mò ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Japan

Nǹkan bí ọdún mẹ́rìnlélógún (24) la fi tọ́jú àwọn òbí ìyàwó mi kí wọ́n tó kú. Ní gbogbo ìgbà yẹn, bá a ṣe ń pe tibí là ń pe tọ̀hún, àwọn ìgbà kan wà tọ́kàn wa ò balẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà la sì gbé wọn lọ sílé ìwòsàn. Ìlera ìyá ìyàwó mi ń burú sí i débi pé nígbà tó yá, wọn ò lè rìn mọ́. Kò rọrùn fún wọn láti lọ sípàdé tàbí kí wọ́n tiẹ̀ lọ wàásù. Nígbà tó ku díẹ̀ kí wọ́n kú, kẹ̀kẹ́ arọ ni wọ́n máa ń lò. Láìka gbogbo àwọn ìṣòro yìí sí, wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn, ayọ̀ wọn sì máa ń kún nígbàkigbà tí wọ́n bá láǹfààní láti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Bí nǹkan ò tiẹ̀ rọrùn fún wọn, wọ́n ń láyọ̀, wọ́n sì mọyì ìwọ̀nba nǹkan tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àpẹẹrẹ àtàtà ni wọ́n jẹ́ fún mi.

Ken àti Miwako níbi ti wọ́n ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.

Èmi àti ìyàwó mi ń wàásù ní Okinawa

Lọ́dún 2024, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó yí ìgbésí ayé wa pa dà. Lẹ́yìn nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọdún tá a ti wà ní Bẹ́tẹ́lì, ètò Ọlọ́run ní ká lọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní Erékùṣù Okinawa. Ibẹ̀ la wà títí di báyìí, a sì máa ń wàásù fáwọn tó ń gbé ní ibùdó àwọn ológun nítòsí wa. Àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a ti gbà ní Bẹ́tẹ́lì ràn wá lọ́wọ́ gan-an nígbà tá a lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tuntun yìí. A máa ń fi ètò sí gbogbo ohun tá a bá fẹ́ ṣe. Bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, tá ò sì jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn wa níyà ń jẹ́ ká lè máa lo àkókò wa dáadáa. Jèhófà bù kún iṣẹ́ wa, ó sì jẹ́ ká láwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó dà bí ọmọ ìyá. Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa lójoojúmọ́ ń jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ojoojúmọ́ lèmi àtìyàwó mi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún wa níṣẹ́ tuntun yìí.

MO TI PINNU PÉ MÀÁ JẸ́ KÍ JÈHÓFÀ TÚBỌ̀ MÁA KỌ́ MI

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn mọ̀lẹ́bí mi ò ta kò mí mọ́, wọn ò tíì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Síbẹ̀, Jésù ṣèlérí pé àwọn tó bá fi ìdílé wọn sílẹ̀, kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn òun máa gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100) àwọn ará tó máa dà bí ọmọ ìyá. (Máàkù 10:29, 30) Bọ́rọ̀ sì ṣe rí fún mi gẹ́lẹ́ nìyẹn. Mi ò lè ka iye àwọn ìdílé tí wọ́n ti fìfẹ́ hàn sí mi, tí wọ́n sì ti tọ́jú mi láti àwọn ọdún yìí wá.

Ìwé Òtítọ́ tí Wilson fún mi nígbà yẹn lọ́hùn-ún ṣì wà lọ́wọ́ mi títí dòní. Ìwé aláwọ̀ búlúù yìí máa ń rán mi létí bí Jèhófà ṣe ràn mí lọ́wọ́ kí n lè mọ òun. (1 Kíró. 28:9) Mo ti pinnu pé màá jẹ́ kí Jèhófà túbọ̀ máa kọ́ mi, màá sì máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ òtítọ́ táá jẹ́ kí wọ́n rí ìyè àìnípẹ̀kun.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́