Tètè Yanjú Èdèkòyédè!
ṢÉ ARÁKÙNRIN tàbí arábìnrin kan ti ṣe ohun tó dùn ẹ́ débi tẹ́ ẹ fi ń bínú síra yín? Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì kó o gbé ìgbésẹ̀ ní kíákíá kó o sì ní èrò tó tọ́, ìyẹn máa jẹ́ kẹ́ ẹ lè yanjú ọ̀rọ̀ náà kẹ́ ẹ sì máa jẹ́ ọ̀rẹ́ nìṣó.a
Bí àpẹẹrẹ, tí egungun ẹnì kan bá kán, ó máa gba pé kó tètè lọ tọ́jú ẹ̀ kí egungun náà lè pa dà bọ̀ sípò, kí ìrora ẹ̀ sì lọ. Àmọ́ ìrora yẹn ò ní lọ tí ò bá tètè tọ́jú ara ẹ̀. Èyí tó wá burú jù ni pé egungun náà lè má pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, kó má sì lágbára mọ́.
Bá a ṣe máa ń tètè tọ́jú egungun tó kán, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká tètè wá nǹkan ṣe tí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀ láàárín àwa àti ẹnì kan nínú ìjọ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀dùn ọkàn tí èdèkòyédè náà fà kò ní lọ bọ̀rọ̀. Tẹ́ ò bá tètè yanjú ẹ̀, ẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí í di ara yín sínú, kí àjọṣe àárín yín sì bà jẹ́. Jésù sọ pé, ká “tètè yanjú ọ̀rọ̀.” (Mát. 5:25) Torí náà, á dáa kí ìwọ àti ọ̀rẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀, kẹ́ ẹ sì fi pẹ̀lẹ́tù yanjú ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́ ohun tá a sọ yìí lè má rọrùn. Kí nìdí? Ẹ jẹ́ ká wo ìdí méjì.
Àkọ́kọ́, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o pa ẹni yẹn tì, kó o má sì sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro náà torí pé inú ẹ̀ ń bí ẹ.b Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Yúódíà àti Síńtíkè nígbà tí wọn ò lè yanjú èdèkòyédè tó wáyé láàárín wọn. Ó jọ pé wàhálà náà pẹ́ kó tó yanjú torí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbọ́ nípa ẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé Róòmù ló wà. Pọ́ọ̀lù wá gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè yanjú ọ̀rọ̀ náà. (Fílí. 4:2) Ó dájú pé tí wọ́n bá nírẹ̀lẹ̀, tí wọ́n jọ sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro náà, tí wọ́n sì dárí ji ara wọn, wọn máa di ọ̀rẹ́ pa dà.
Ìkejì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ẹnì kejì ló jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ kó tọrọ àforíjì. Àmọ́ má gbàgbé pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni bẹ́ ẹ ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà, kì í ṣe bẹ́ ẹ ṣe máa wá ẹni tó jẹ̀bi. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá gbé ẹni tí egungun ẹ̀ kán wá sọ́dọ̀ dókítà, bó ṣe máa tọ́jú ẹni náà ló máa jẹ ẹ́ lógún, kì í ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ tí egungun náà fi kán. Torí náà, tíwọ àti ọ̀rẹ́ ẹ bá jọ ń sọ̀rọ̀, kì í ṣe ẹni tó jẹ̀bi ló yẹ kó jẹ ẹ́ lógún. Kàkà bẹ́ẹ̀, máa ronú nípa bí àárín yín ṣe gún régé tẹ́lẹ̀, kó o sì ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kẹ́ ẹ lè pa dà di ọ̀rẹ́.
Tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ti ṣe bí ọ̀rọ̀ láàárín ìwọ àti ẹnì kan, o ò ṣe wá bẹ́ ẹ ṣe máa yanjú ẹ̀ lónìí. Bíbélì sọ pé: “Má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá [ẹ] nínú ìbínú.” (Éfé. 4:26) Tó o bá ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti tètè yanjú ọ̀rọ̀ tó bá ṣẹlẹ̀, ṣe ni wàá mú kí “ìdè ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà” tó wà láàárín wa túbọ̀ lágbára.—Éfé. 4:1-3.
a Tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tí ò tó nǹkan ló fa èdèkòyédè láàárín àwọn Kristẹni méjì, á dáa kí wọ́n jọ yanjú ẹ̀ nítùbí-ìnùbí, kí wọ́n sì dárí ji ara wọn. (Mát. 5:23, 24) Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà le, wọ́n lè ní káwọn alàgbà bá wọn dá sí i. (Mát. 18:17) Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣe ohun tó wà ní Mátíù 18:15, 16 ni wọ́n tó lè gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀.