ÌBÉÈRÈ LÁTI ỌWỌ́ ÀWỌN ÒǸKÀWÉ
Májẹ̀mú méjì wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí nínú Gálátíà 4:24?
Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa àjọṣe tó wà láàárín Ábúráhámù, Sérà àti Hágárì, ó sọ pé: “A lè fi àwọn nǹkan yìí ṣe àkàwé; àwọn obìnrin yìí dúró fún májẹ̀mú méjì.” (Gál. 4:22-24) Ohun tá a sọ tẹ́lẹ̀ ni pé májẹ̀mú méjì yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú Òfin àti májẹ̀mú tuntun. Àmọ́, nígbà tá a tún gbé ẹsẹ Bíbélì yìí yẹ̀ wò, a wá rí i pé ó yẹ ká ṣàlàyé ẹ̀ lọ́nà míì. Ó jọ pé májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, kì í ṣe májẹ̀mú tuntun. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀.a
Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan Òkè Sínáì nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Hágárì tó jẹ́ ìránṣẹ́bìnrin. (Gál. 4:25) Hágárì túmọ̀ sí májẹ̀mú Òfin tí Ọlọ́run fún Mósè ní Òkè Sínáì lọ́dún 1513 Ṣ.S.K. (Ẹ́kís. 19:5, 6) Kò sí èèyàn aláìpé kankan tó lè pa gbogbo Òfin yẹn mọ́ délẹ̀délẹ̀, torí náà májẹ̀mú yìí á jẹ́ káwọn Júù máa rántí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ làwọn. Májẹ̀mú yìí á tún jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá Mèsáyà mọ̀, ìyẹn ẹnì kan ṣoṣo tó lè ṣe ohun tí Òfin náà sọ délẹ̀délẹ̀. Torí pé ẹni pípé ni Mèsáyà, tó sì fi ẹ̀mí ẹ̀ rúbọ, ìyẹn ló jẹ́ káwa èèyàn aláìpé bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Gál. 3:19, 24, 25) Lẹ́yìn tí Jésù fẹ̀mí ẹ̀ rúbọ tó sì mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ, Òfin náà ò wúlò mọ́.—Róòmù 10:4.
Pọ́ọ̀lù fi ìyàtọ̀ sáàárín Hágárì àti Sérà ìyẹn “obìnrin tó lómìnira” tó sì bímọ “nípasẹ̀ ìlérí.” (Gál. 4:23) Ìlérí náà ni májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá. (Gál. 3:29; 4:28, 30) Jẹ́nẹ́sísì 22:18 sọ̀rọ̀ nípa májẹ̀mú yìí, ó ní: “Gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé yóò gba ìbùkún fún ara wọn nípasẹ̀ ọmọ rẹ [ìyẹn Ábúráhámù] torí pé o fetí sí ohùn mi.”
Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá yìí jẹ́ ká mọ púpọ̀ sí i nípa ìlérí tí Jèhófà ṣe ní ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́n. 3:15) Májẹ̀mú yìí jẹ́ ká mọ̀ pé àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ni “ọmọ” tí Ọlọ́run ṣèlérí yẹn máa jẹ́. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé Jésù Kristi gangan ni “ọmọ” inú àsọtẹ́lẹ̀ náà. Àmọ́ àwọn tó “jẹ́ ti Kristi,” ìyẹn àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n jẹ́ ajogún, tí wọ́n sì máa bá Jésù jọba lọ́run wà lára ọmọ ìṣàpẹẹrẹ náà. (Gál. 3:16, 29; Ìfi. 14:1-3) Nígbà tí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù bá ṣẹ, ọ̀pọ̀ ohun rere làwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú Jésù tí wọ́n sì ṣègbọràn sí i máa gbádùn.
Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi ṣe “àkàwé” yìí? Ó jẹ́ ká rí i pé táwọn Júù ìgbà yẹn bá ń rin kinkin mọ́ Òfin, ṣe làwọn náà máa di ẹrú bíi Hágárì. Àmọ́, tí wọ́n bá gba “ọmọ” Ábúráhámù ìyẹn Jésù Kristi gbọ́, wọ́n máa wà lómìnira bíi Sérà. Wọ́n máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú pátápátá. (Jòh. 8:32-34) Àmọ́, tí wọn ò bá gba Jésù gbọ́, májẹ̀mú Òfin yẹn ò ní ṣe wọ́n láǹfààní. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìdí pàtàkì tí Ọlọ́run fi fún wọn ní májẹ̀mú Òfin ni pé kó ṣamọ̀nà wọn sí Kristi.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn ará Gálátíà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí ni kì í ṣe Júù, tí wọn ò sì fìgbà kan rí wà lábẹ́ Òfin. Àmọ́, àwọn Júù kan sọ pé àwọn tí kì í ṣe Júù gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tí Òfin sọ, tó fi mọ́ èyí tó sọ̀rọ̀ nípa ìdádọ̀dọ́. Pọ́ọ̀lù wá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìwà òmùgọ̀ ló máa jẹ́ táwọn tó ti gba Kristi gbọ́ tí wọ́n sì ti wà ní “òmìnira” bá tún wá ń sọ ara wọn di “ẹrú” Òfin.—Gál. 5:1, 10-14.
a Èyí jẹ́ àtúnṣe sí àlàyé tá a ṣe nínú Ilé Ìṣọ́, March 15, 2006, ojú ìwé 10-12.