ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 June ojú ìwé 32
  • Àwọ̀n Tí Wọ́n Fi Ń Pẹja Láyé Ìgbà TÍ Wọ́n Ń Kọ Bíbélì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọ̀n Tí Wọ́n Fi Ń Pẹja Láyé Ìgbà TÍ Wọ́n Ń Kọ Bíbélì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣiṣiṣẹsin Gẹgẹ Bi Awọn Apẹja Eniyan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Mẹ́rin Di Apẹja Èèyàn
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • A Pe Awọn Ọmọ-ẹhin Mẹrin
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Lákòókò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì​—Apẹja
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 June ojú ìwé 32

ÀWỌN NǸKAN TÍ BÍBÉLÌ SỌ̀RỌ̀ NÍPA Ẹ̀

Àwọ̀n Tí Wọ́n Fi Ń Pẹja Láyé Ìgbà TÍ Wọ́n Ń Kọ Bíbélì

Apẹja ni àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù. (Máàkù 1:16-20) Àwọ̀n ìyẹn nẹ́ẹ̀tì ni wọ́n máa ń lò tí wọ́n bá lọ pẹja ní Òkun Gálílì.

Tí wọ́n bá fẹ́ ṣe nẹ́ẹ̀tì tí wọ́n fi ń pẹja, wọ́n máa ń hun oríṣiríṣi okùn pọ̀, wọ́n á sì jẹ́ kí àlàfo wà láàárín àwọn okùn náà. Bí ẹja tí wọ́n fẹ́ mú bá ṣe tóbi tó ni wọ́n á fi mọ bí àlàfo nẹ́ẹ̀tì náà á ṣe fẹ̀ tó. Wọ́n sábà máa ń so irin tàbí òkúta kéékèèké mọ́ eteetí àwọn nẹ́ẹ̀tì kékeré kó lè lọ sísàlẹ̀ omi. Wọ́n máa ń fi àwọn nǹkan tó wúwo díẹ̀ sísàlẹ̀ àwọn nẹ́ẹ̀tì ńlá, wọ́n á wá fi igi tàbí àwọn nǹkan míì tó lè léfòó sókè ẹ̀.

Owó kékeré kọ́ ni wọ́n fi ń ra nẹ́ẹ̀tì tí wọ́n fi ń pẹja. Àwọn òkúta tó wà nísàlẹ̀ odò lè ya á, ó tún lè ya tó bá kó ẹja tó pọ̀. (Lúùkù 5:6) Bíbélì sọ pé Jémíìsì àti Jòhánù “ń tún àwọ̀n wọn ṣe,” ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé abẹ́rẹ́ àti òwú ni wọ́n lò. (Mát. 4:21) Ohun táwọn apẹja sábà máa ń ṣe nìyẹn tí wọ́n bá pẹja tán. Lúùkù náà sọ pé àwọn apẹja kan ń “fọ àwọ̀n wọn” kí ìdọ̀tí ara ẹ̀ lè kúrò. (Lúùkù 5:2) Lẹ́yìn náà, àwọn apẹja máa sá nẹ́ẹ̀tì náà, kó má bàa dípẹtà.—Ìsík. 47:10.

Jésù ní kí àwọn kan tó máa ń fi àwọ̀n pẹja máa tẹ̀ lé òun, kóun lè sọ wọ́n di “apẹja èèyàn.”

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́