ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 December ojú ìwé 8-13
  • Ìwé Jóòbù Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Tá A Bá Fẹ́ Gba Àwọn Èèyàn Nímọ̀ràn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwé Jóòbù Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Tá A Bá Fẹ́ Gba Àwọn Èèyàn Nímọ̀ràn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • BÍ ÀWỌN Ọ̀RẸ́ JÓÒBÙ MẸ́TẸ̀Ẹ̀TA ṢE GBÀ Á NÍMỌ̀RÀN
  • BÍ ÉLÍHÙ ṢE GBA JÓÒBÙ NÍMỌ̀RÀN
  • TÚBỌ̀ MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ ÌWÉ JÓÒBÙ
  • Jèhófà Wò Ó Sàn
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Nípa Bí A Ṣe Lè Bójútó Ìṣòro
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Èrè Jobu—Orísun kan Fún Ìrètí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jóòbù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 December ojú ìwé 8-13

ÀPILẸ̀KỌ 49

ORIN 44 Àdúrà Ẹni Tó Ní Ẹ̀dùn Ọkàn

Ìwé Jóòbù Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Tá A Bá Fẹ́ Gba Àwọn Èèyàn Nímọ̀ràn

“Ní báyìí, Jóòbù, jọ̀ọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.”—JÓÒBÙ 33:1.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Ìwé Jóòbù máa jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe àtohun tó yẹ ká sọ tá a bá fẹ́ gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn.

1-2. Iṣẹ́ ńlá wo ló délẹ̀ fáwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àti Élíhù?

NÍGBÀ tí àjálù dé bá Jóòbù, ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní Ìlà Oòrùn ló gbọ́ torí pé òdú ni kì í ṣàìmọ̀ fólóko, ó gbajúmọ̀, ó sì lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Nígbà táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta, ìyẹn Élífásì, Bílídádì àti Sófárì gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, wọ́n rìnrìn àjò lọ sí Úsì kí wọ́n lè tù ú nínú. Àmọ́ ohun tí wọ́n bá nígbà tí wọ́n débẹ̀ yà wọ́n lẹ́nu gan-an.

2 Ẹ jẹ́ ká fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀. Gbogbo ohun tí Jóòbù ní pátá ló ti pa run. Gbogbo ẹran ọ̀sìn ẹ̀, màlúù ni o, àgùntàn ni o, ràkúnmí ni o àtàwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ló kú. Bákan náà, ilé wó pa àwọn ọmọ ẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá (10). Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n pa ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀. Àṣé ojú Jóòbù ò tíì rí nǹkan kan, àìsàn tún gbé e ṣánlẹ̀, eéwo sì bò ó látòkè délẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta rí i látọ̀ọ́kán tó jókòó sínú eérú, ìbànújẹ́ sì dorí ẹ̀ kodò. Kí ni wọ́n wá ṣe? Nígbà tí wọ́n rí bí ìrora Jóòbù ṣe pọ̀ tó, wọn ò sọ ohunkóhun fún odindi ọjọ́ méje gbáko. (Jóòbù 2:12, 13) Nígbà tó yá, ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Élíhù wá kí Jóòbù, ò sì jókòó sítòsí. Jóòbù tẹnu bọ̀rọ̀, ó fi ọjọ́ tí wọ́n bí i gégùn ún, kódà ó sọ pé ó sàn kóun kú. (Jóòbù 3:1-3, 11) Ẹ ò rí i pé Jóòbù nílò ìtùnú. Torí náà, ohun táwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ yìí bá sọ àti bí wọ́n bá ṣe sọ ọ́ máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jóòbù dénú tàbí pé ọ̀rọ̀ ẹ̀ jẹ wọ́n lógún.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Jèhófà ní kí Mósè ṣàkọsílẹ̀ ohun tí Élíhù àtàwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sọ àtohun tí wọ́n ṣe. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Élíhù sọ jẹ́ ká rí i pé Jèhófà ló gbẹnu ẹ̀ sọ̀rọ̀. Àmọ́ ní ti Élífásì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ẹ̀mí èṣù ló gbẹnu ẹ̀ sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó sọ. (Jóòbù 4:12-16; 33:24, 25) Abájọ tó fi jẹ́ pé nínú ìwé Jóòbù, a máa rí àwọn ìmọ̀ràn tó dáa gan-an, a sì tún máa rí àwọn míì tó burú jáì. Ọ̀kan lára ohun tó ṣe pàtàkì tá a lè kọ́ nínú ìwé Jóòbù ni bá a ṣe lè gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ ohun tá a kọ́ lára àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta nípa ohun tí kò yẹ ká sọ tàbí ṣe tá a bá fẹ́ gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a rí kọ́ lára Élíhù. Bá a ṣe ń jíròrò àwọn àpẹẹrẹ yìí, a máa sọ àǹfààní tí ìwé Jóòbù ì bá ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àǹfààní tó lè ṣe àwa náà lónìí.

BÍ ÀWỌN Ọ̀RẸ́ JÓÒBÙ MẸ́TẸ̀Ẹ̀TA ṢE GBÀ Á NÍMỌ̀RÀN

4. Kí làwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe tó dá kún ìṣòro ẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

4 Bíbélì sọ pé nígbà táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta gbọ́ àjálù tó ṣẹlẹ̀ sí i, wọ́n gbéra “kí wọ́n lè lọ bá Jóòbù kẹ́dùn, kí wọ́n sì tù ú nínú.” (Jóòbù 2:11) Àmọ́ kàkà kí wọ́n tu Jóòbù nínú, ṣe ni wọ́n tún dá kún ìṣòro ẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìdí mẹ́ta. Àkọ́kọ́, wọn ò fara balẹ̀ gbọ́ tẹnu Jóòbù kí wọ́n tó dá a lẹ́jọ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sọ pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ Jóòbù ló ń jẹ, ọ̀rọ̀ ò sì rí bẹ́ẹ̀.a (Jóòbù 4:7; 11:14) Ìkejì, àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé ló pọ̀ jù nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ sí Jóòbù, àwọn ọ̀rọ̀ náà buni kù, wọn ò sì tù ú nínú rárá. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ táwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sọ jọ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n, àmọ́ kò sòótọ́ kankan nínú ẹ̀. (Jóòbù 13:12) Ẹ̀ẹ̀méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Bílídádì sọ pé ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́ ni Jóòbù. (Jóòbù 8:2; 18:2) Sófárì tiẹ̀ fọgbọ́n pé Jóòbù ní “òpònú.” (Jóòbù 11:12) Ìkẹ́ta, òótọ́ ni pé wọ́n lè má jágbe mọ́ Jóòbù, àmọ́ ọ̀nà tí wọ́n gbà sọ̀rọ̀ fi hàn pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, wọn ò kà á sí, wọ́n sì tún dá a lẹ́bi. (Jóòbù 15:7-11) Ẹ ò rí i pé kì í ṣe bí wọ́n ṣe máa tù ú nínú ló jẹ wọ́n lógún, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n fẹ́ kó rí i pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ ló ń jẹ!

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù ń sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà sí i, àwọn méjì yòókù sì ń wò ó. Jóòbù jókòó sílẹ̀, eéwo bò ó látòkè délẹ̀, ó ń jẹ̀rora, ó sì ń gbọ́ ohun tí ọ̀rẹ̀ tó ń fún un nímọ̀ràn ń sọ.

Tó o bá ń fún ẹnì kan nímọ̀ràn, má ṣe sọ̀rọ̀ lọ́nà táá mú kẹ́ni náà rò pé òun ò já mọ́ nǹkan kan. Rántí pé bó o ṣe máa ran ẹni náà lọ́wọ́ ló ṣe pàtàkì jù (Wo ìpínrọ̀ 4)


5. Kí ni ọ̀rọ̀ táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sọ yọrí sí?

5 Kò yà wá lẹ́nu pé ọ̀rọ̀ táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sọ kò tù ú nínú, kódà Jóòbù sọ pé ṣe ni wọ́n fi ọ̀rọ̀ wọn fọ́ òun sí wẹ́wẹ́. (Jóòbù 19:2) Abájọ tó fi jẹ́ pé bí wọ́n ṣe ń sọ ọ́ ló ń fún wọn lésì. Ìyẹn ló mú kó ṣinú rò, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tí ò yẹ kó sọ. (Jóòbù 6:3, 26) Àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù ò ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú, wọn ò sì káàánú ẹ̀. Wọn ò mọ̀ pé ṣe ni wọ́n ń jẹ́ kí Sátánì lo àwọn láti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá Jóòbù. (Jóòbù 2:4, 6) Àǹfààní wo lohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ì bá ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àǹfààní wo ló sì lè ṣe àwa náà lónìí?

6. Ẹ̀kọ́ wo làwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì ì bá kọ́ nínú ohun tí ò dáa táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe?

6 Àǹfààní táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ì bá rí. Lẹ́yìn tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òfin, ó yan àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n àtàwọn àgbààgbà láti máa bójú tó àwọn èèyàn ẹ̀, kí wọ́n sì máa fi ìlànà ẹ̀ ṣèdájọ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. (Diu. 1:15-18; 27:1) Jèhófà fẹ́ káwọn ọkùnrin yìí máa fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn èèyàn dáadáa kí wọ́n tó gbà wọ́n nímọ̀ràn tàbí ṣèdájọ́. (2 Kíró. 19:6) Kò yẹ kí wọ́n kàn rò pé àwọn mọ bí gbogbo ọ̀rọ̀ kan ṣe jẹ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ó yẹ kí wọ́n máa béèrè ìbéèrè kí wọ́n lè mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà. (Diu. 19:18) Bákan náà, kò yẹ kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà sáwọn tó bá kó ẹjọ́ wá sọ́dọ̀ wọn. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní rọrùn fáwọn èèyàn láti sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn. (Ẹ́kís. 22:22-24) Ká sọ pé àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí Jèhófà yàn mọ ìtàn yìí ni, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni wọn ì bá kọ́.

7. Yàtọ̀ sáwọn àgbà ọkùnrin ní Ísírẹ́lì, àwọn wo ló tún lè gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn, báwo sì ni ìtàn Jóòbù ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? (Òwe 27:9)

7 Kì í ṣe àwọn àgbà ọkùnrin ní Ísírẹ́lì nìkan ló lè fáwọn èèyàn nímọ̀ràn. Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà ló lè gba ọ̀rẹ́ wọn nímọ̀ràn. Wọ́n lè gbà á nímọ̀ràn nípa bó ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà tàbí bó ṣe lè jáwọ́ nínú ìwà kan tó kù díẹ̀ káàtó. (Sm. 141:5) Ẹni tó bá gba ọ̀rẹ́ ẹ̀ nírú ìmọ̀ràn yìí máa fi hàn pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ lòun. (Ka Òwe 27:9.) Tó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kẹ́kọ̀ọ́ nínú àṣìṣe táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe nígbà tí wọ́n ń fún Jóòbù nímọ̀ràn, wọn ò bá mọ ohun tí kò yẹ kí wọ́n sọ àtohun tí kò yẹ kí wọ́n ṣe tí wọ́n bá ń fún àwọn èèyàn nímọ̀ràn.

8. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká máa rántí tá a bá fẹ́ fún àwọn èèyàn nímọ̀ràn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

8 Àǹfààní tó lè ṣe wá. Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń fẹ́ ran àwọn ará wa lọ́wọ́ tí wọ́n bá níṣòro. Àmọ́ tá a bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má lọ ṣe bí àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Torí náà, ó yẹ ká máa rántí àwọn nǹkan yìí. Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé a mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ kan ká tó gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn. Ìkejì, ká má fìwà jọ Élífásì, kàkà bẹ́ẹ̀ ká rí i dájú pé òtítọ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìmọ̀ràn wa dá lé dípò ohun tá a rò tàbí ìrírí wa. (Jóòbù 4:8; 5:3, 27) Ìkẹta, a ò gbọ́dọ̀ máa sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà tá a bá ń fáwọn èèyàn nímọ̀ràn. Ẹ má gbàgbé pé àwọn nǹkan kan wà tó jóòótọ́ nínú ohun tí Élífásì àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ sọ. Kódà nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àwọn ọ̀rọ̀ kan tó sọ. (Fi Jóòbù 5:13 wé 1 Kọ́ríńtì 3:19.) Síbẹ̀ irọ́ ló pọ̀ jù nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ nípa Jèhófà, wọ́n sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá Jóòbù, ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi sọ pé ohun tí wọ́n sọ kì í ṣòótọ́. (Jóòbù 42:7, 8) Torí náà, tá a bá fẹ́ fáwọn èèyàn nímọ̀ràn, a ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi máa dà bíi pé Jèhófà kì í gba tàwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ rò. A ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ronú pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wọn. Ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a lè kọ́ lára Élíhù.

Fọ́tò: Arákùnrin kan ń fún arákùnrin mí ì tínú ń bí nímọ̀ràn. 1. Arákùnrin náà ń fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí arákùnrin tínú ń bí náà ń sọ. Wọ́n jókòó síta, ohun mímu ẹlẹ́rìndòdò sì wà lórí tábìlì níwájú wọn. 2. Arákùnrin tó ń fún arákùnrin náà nímọ̀ràn ṣí Bíbélì. 3. Ó ń gba arákùnrin tínú ń bí náà nímọ̀ràn látinú Bíbélì, ó sì ń tẹ́tí sílẹ̀.

Tó o bá ń fún àwọn èèyàn nímọ̀ràn rí i dájú pé, (1) o mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà, (2) orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìmọ̀ràn ẹ dá lé àti (3) o sọ̀rọ̀ lọ́nà tó tuni lára (Wo ìpínrọ̀ 8)


BÍ ÉLÍHÙ ṢE GBA JÓÒBÙ NÍMỌ̀RÀN

9. Kí nìdí tí ara ò fi tu Jóòbù lẹ́yìn táwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ bá a sọ̀rọ̀ tán, báwo sì ni Jèhófà ṣe tù ú nínú?

9 Jóòbù àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta bára wọn fà á gan-an, kódà odindi orí méjìdínlọ́gbọ̀n (28) làwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ wà nínú Bíbélì, ọ̀pọ̀ nínú ẹ̀ ló sì jẹ́ pé ìbínú àti ìkanra ni wọ́n fi sọ ọ́. Abájọ tára ò fi tu Jóòbù rárá! Torí náà, ó nílò ẹni tó máa tù ú nínú, táá sì tọ́ ọ sọ́nà. Báwo ni Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́? Jèhófà lo Élíhù láti tọ́ ọ sọ́nà. Àmọ́ kí nìdí tí Élíhù ò fi tètè sọ̀rọ̀? Ó sọ pé, “Ọmọdé ni mí, àgbàlagbà sì ni ẹ̀yin. Ìdí nìyẹn tí mi ò fi sọ̀rọ̀ torí mo bọ̀wọ̀ fún yín.” (Jóòbù 32:6, 7) Élíhù tó jẹ́ ọ̀dọ́ mọ̀ pé àwọn àgbàlagbà máa ń gbọ́n ju àwọn ọmọdé, wọ́n sì nírìírí jù wọ́n lọ, ọ̀pọ̀ wa lónìí ló sì gbà bẹ́ẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn tó gbọ́ gbogbo atótónu Jóòbù àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀, ara ẹ̀ ò gbà á mọ́. Ó sọ pé: “Ọjọ́ orí nìkan kọ́ ló ń sọ èèyàn di ọlọ́gbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe àwọn àgbà nìkan ló mọ ohun tó tọ́.” (Jóòbù 32:9) Kí ni Élíhù wá sọ, báwo ló sì ṣe sọ ọ́?

10. Kí ni Élíhù ṣe kó tó fún Jóòbù nímọ̀ràn? (Jóòbù 33:6, 7)

10 Kí Élíhù tó fún Jóòbù nímọ̀ràn, ó kọ́kọ́ jẹ́ kí ara Jóòbù balẹ̀ torí ó mọ̀ pé ìyẹn lá jẹ́ kọ́rọ̀ òun wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Báwo ló ṣe ṣe é? Lákọ̀ọ́kọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Élíhù gbọ́ kọ́kọ́ bí i nínú bí Bíbélì ṣe sọ, ó ṣe sùúrù kó tó bá Jóòbù sọ̀rọ̀. (Jóòbù 32:2-5) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé kó fìbínú bá Jóòbù sọ̀rọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ tó fi Jóòbù lọ́kàn balẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fún Jóòbù pé: “Wò ó! Bákan náà ni èmi àti ìwọ rí níwájú Ọlọ́run tòótọ́.” (Ka Jóòbù 33:6, 7.) Lẹ́yìn náà, kó tó gba Jóòbù nímọ̀ràn, ó ṣàkópọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí Jóòbù sọ, ìyẹn sì fi hàn pé ó fara balẹ̀ gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ Jóòbù. (Jóòbù 32:11; 33:8-11) Ohun kan náà ló ṣe nígbà míì tó gba Jóòbù nímọ̀ràn.—Jóòbù 34:5, 6, 9; 35:1-4.

11. Àwọn nǹkan wo ni Élíhù ṣe nígbà tó ń fún Jóòbù nímọ̀ràn? (Jóòbù 33:1)

11 Nígbà tí Élíhù ń gba Jóòbù nímọ̀ràn, ọ̀nà tó gbà sọ̀rọ̀ fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ fún ọkùnrin olóòótọ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, ó dárúkọ Jóòbù nígbà tó ń bá a sọ̀rọ̀, ó sì ṣeé ṣe káwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́ta yòókù má ṣe bẹ́ẹ̀. (Ka Jóòbù 33:1.) Élíhù rántí bó ṣe ń wu òun láti sọ̀rọ̀ nígbà tí Jóòbù àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ ń jiyàn, ìyẹn ló jẹ́ kó fún Jóòbù láyè láti fèsì nígbà tó ń fún un nímọ̀ràn. (Jóòbù 32:4; 33:32) Élíhù tún jẹ́ kí Jóòbù mọ̀ pé, àwọn nǹkan tó ń sọ àtohun tó ń rò kù díẹ̀ káàtó, ó sì tún rán an létí pé Jèhófà lágbára, ó gbọ́n, ó nífẹ̀ẹ́ tí kì í yẹ̀, ó sì máa ń dájọ́ bó ṣe tọ́. (Jóòbù 36:18, 21-26; 37:23, 24) Bí Élíhù ṣe fún Jóòbù nímọ̀ràn mú kára tu Jóòbù, ó sì jẹ́ kó rọrùn fún un láti gba ìmọ̀ràn ti Jèhófà fún un nígbà tó yá. (Jóòbù 38:1-3) Ká sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ ohun tí Élíhù ṣe, báwo nìyẹn ì bá ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́, àǹfààní wo ló sì lè ṣe àwa náà lónìí?

12. Báwo ni Jèhófà ṣe lo àwọn wòlíì láti ran àwọn èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́, báwo sì ni àpẹẹrẹ Élíhù ṣe lè ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní?

12 Àǹfààní táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ì bá rí. Nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Jèhófà lo àwọn wòlíì láti tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, lásìkò àwọn onídàájọ́, Jèhófà lo Dèbórà tó jẹ́ wòlíì obìnrin. Bákan náà, àtikékeré ni Sámúẹ́lì ti ń jíṣẹ́ Jèhófà fáwọn èèyàn. (Oníd. 4:4-7; 5:7; 1 Sám. 3:19, 20) Yàtọ̀ síyẹn, lásìkò táwọn ọba ń jẹ ní Ísírẹ́lì, Jèhófà máa ń rán àwọn wòlíì sí àwọn èèyàn ẹ̀ kí wọ́n lè fún wọn lókun, kí wọ́n sì fún àwọn tó ti fi Jèhófà sílẹ̀ nímọ̀ràn kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ ẹ̀. (2 Sám. 12:1-4; Ìṣe 3:24) Bó ṣe wà nínú ìwé Jóòbù, àpẹẹrẹ Élíhù lè ran àwọn olóòótọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin lọ́wọ́ láti mọ ohun tó yẹ kí wọ́n sọ àti bí wọ́n ṣe máa sọ̀rọ̀ tí wọ́n bá ń gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn.

13. Báwo làwa Kristẹni ṣe lè fún àwọn ará wa níṣìírí?

13 Àǹfààní tó lè ṣe wá. Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà náà máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́, bó ṣe wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró ká lè fún àwọn ará wa lókun. (1 Kọ́r. 14:3) Ó ṣe pàtàkì káwọn alàgbà “máa sọ̀rọ̀ ìtùnú” fáwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, kódà wọ́n gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀ fáwọn tí ara ń kan àtàwọn tó ṣeé ṣe kó máa sọ “ọ̀rọ̀ ẹhànnà.”—1 Tẹs. 5:14; Jóòbù 6:3.

14-15. Sọ bí alàgbà kan ṣe lè fara wé Élíhù tó bá ń fún ẹnì kan nímọ̀ràn.

14 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí. Ká sọ pé alàgbà kan gbọ́ pé inú arábìnrin kan ò dùn. Òun àti arákùnrin míì wá lọ sọ́dọ̀ arábìnrin náà kí wọ́n lè fún un níṣìírí. Nígbà tí wọ́n jọ ń sọ̀rọ̀, arábìnrin náà sọ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun máa ń lọ sípàdé tóun sì máa ń wàásù, inú òun kì í dùn. Kí ló yẹ kí alàgbà náà ṣe?

15 Lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ kó gbìyànjú láti mọ ohun tó fà á gan-an tínú arábìnrin yẹn ò fi dùn. Kó lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ fi sùúrù tẹ́tí sí arábìnrin náà. Ó yẹ kó bi ara ẹ̀ pé, ‘ṣé kì í ṣe pé ó ń ronú pé Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ òun? Àbí “àníyàn ìgbésí ayé” ló ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá a?’ (Lúùkù 21:34) Ohun kejì tí alàgbà náà máa ṣe ni pé kó gbóríyìn fún un. Ó ṣe tán, ó ṣì ń wá sípàdé, ó sì ń lọ sóde ìwàásù láìka ẹ̀dùn ọkàn tó ní sí. Ìkẹta, tí alàgbà náà bá ti mọ ohun tó fà á tínú arábìnrin náà ò fi dùn, á wá lo Bíbélì láti jẹ́ kó dá a lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.—Gál. 2:20.

TÚBỌ̀ MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ ÌWÉ JÓÒBÙ

16. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ka ìwé Jóòbù?

16 Ẹ ò rí i pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè kọ́ nínú ìwé Jóòbù! Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ìwé Jóòbù jẹ́ ká mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ aráyé àti bá a ṣe lè fara dà á tá a bá ń jìyà. Bó sì ṣe wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti rí i pé tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Élíhù dípò àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, àá lè fáwọn èèyàn nímọ̀ràn tó dáa. Torí náà, a dáa ká ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tá a ti kọ́ nínú ìwé Jóòbù ká tó lọ fún ẹnì kan nímọ̀ràn. Tó bá jẹ́ pé ó ti ṣe díẹ̀ tó o ti ka ìwé Jóòbù, o ò ṣe pinnu láti tún un kà kó o lè ronú lórí àwọn ẹ̀kọ́ tó wà níbẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ kó o rí i pé bó ṣe wúlò nígbà yẹn, bẹ́ẹ̀ náà ló wúlò lónìí.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí làwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe tó yẹ ká yẹra fún tá a bá fẹ́ fún àwọn èèyàn nímọ̀ràn?

  • Kí la rí kọ́ nínú bí Élíhù ṣe gba Jóòbù nímọ̀ràn?

  • Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Jóòbù?

ORIN 125 “Aláyọ̀ Ni Àwọn Aláàánú!”

a Ó jọ pé ẹ̀mí burúkú kan ló mú kí Élífásì sọ pé kò sẹ́ni tó lè jẹ́ olódodo lójú Ọlọ́run àti pé a ò lè ṣe ohun táá múnú Ọlọ́run dùn. Èrò tí kò tọ́ yìí ló wà lọ́kàn Élífásì. Ìyẹn sì hàn nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀ nígbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó sọ̀rọ̀.—Jóòbù 4:17; 15:15, 16; 22:2.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́