ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 December ojú ìwé 2-7
  • Ìwé Jóòbù Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Tá A Bá Ń Jìyà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwé Jóòbù Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Tá A Bá Ń Jìyà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ỌLỌ́RUN FÀYÈ GBA ÌYÀ TÓ JẸ JÓÒBÙ
  • BÍ ÌWÉ JÓÒBÙ ṢE LÈ JẸ́ KÁ FARA DA ÌṢÒRO
  • BÓ O ṢE LÈ FI ÌWÉ JÓÒBÙ RAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́
  • Jóòbù Gbé Orúkọ Jèhófà Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • “Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jóòbù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • “Mi Ò Ní Fi Ìwà Títọ́ Mi Sílẹ̀!”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 December ojú ìwé 2-7

ÀPILẸ̀KỌ 48

ORIN 129 A Ó Máa Fara Dà Á Nìṣó

Ìwé Jóòbù Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Tá A Bá Ń Jìyà

“Ó dájú pé, Ọlọ́run kì í hùwà burúkú.”—JÓÒBÙ 34:12.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Jóòbù nípa ìdí tí Jèhófà fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn àti bá a ṣe lè fara dà á tá a bá níṣòro.

1-2. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ka ìwé Jóòbù?

ṢÉ O ti ka ìwé Jóòbù lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ (3,500) ọdún sẹ́yìn ni wọ́n kọ ìwé yìí, ọ̀pọ̀ gbà pé ó wà lára àwọn ìwé tó dáa jù lọ. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì tiẹ̀ sọ pé “ọ̀jọ̀gbọ́n” lẹ́ni tó kọ ìwé Jóòbù torí pé ó rọrùn kà, ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ dùn, ó sì yé àwọn èèyàn. Mósè ló kọ ìwé tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí, àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run ló sọ ohun tó kọ sílẹ̀.—2 Tím. 3:16.

2 Ìwé Jóòbù wà lára àwọn ìwé tó ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an nínú Bíbélì. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó jẹ́ ká rí bí ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì, ìyẹn bí orúkọ Jèhófà ṣe máa di mímọ́ ṣe kan àwa èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì. Bákan náà, ó jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ tó dáa tí Jèhófà ní, irú bí ìfẹ́, ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo àti agbára. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31) ni ọ̀rọ̀ náà “Olódùmarè” fara hàn nínú ìwé Jóòbù, ìyẹn sì ju iye ìgbà tó fara hàn nínú gbogbo ìwé tó kù nínú Bíbélì. Kò tán síbẹ̀ o, ìwé Jóòbù tún dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó ṣe pàtàkì táwọn èèyàn ti ń wá ìdáhùn wọn tipẹ́, irú bíi: Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn?

3. Sọ díẹ̀ lára àǹfààní tá a máa rí tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Jóòbù.

3 Téèyàn bá wà lórí òkè kan tó ga, ó máa rí àwọn nǹkan tó wà láyìíká ẹ̀ dáadáa ju ẹni tó wà nísàlẹ̀ lọ. Lọ́nà kan náà, ìwé Jóòbù ló jẹ́ ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìdí tí ìyà fi ń jẹ àwa èèyàn àti ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀rọ̀ náà. Ẹ jẹ́ ká wo bí ìwé Jóòbù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á tá a bá ń jìyà. A máa sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò bá rí tó bá jẹ́ pé wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù, a sì máa mọ àǹfààní tó máa ṣe àwa náà lónìí. Yàtọ̀ síyẹn, a máa rí bá a ṣe lè fi ìtàn Jóòbù ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.

ỌLỌ́RUN FÀYÈ GBA ÌYÀ TÓ JẸ JÓÒBÙ

4. Kí ni Jóòbù ṣe tó mú kó yàtọ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní Íjíbítì?

4 Lásìkò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jìyà lóko ẹrú Íjíbítì, ilẹ̀ Úsì ni Jóòbù ń gbé. Ó sì ṣeé ṣe kí ilẹ̀ náà wà ní apá ìlà oòrùn Ilẹ̀ Ìlérí àti apá àríwá Arébíà. Jóòbù ò dà bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn òrìṣà ní Íjíbítì, Jèhófà ló ń sìn tọkàntọkàn ní tiẹ̀. (Jóṣ. 24:14; Ìsík. 20:8) Jèhófà sọ nípa Jóòbù pé: “Kò sí ẹni tó dà bíi rẹ̀ ní ayé.”a (Jóòbù 1:8) Jóòbù lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó sì gbayì láwùjọ. Kódà, kò sẹ́ni tó lọ́lá tó o nínú gbogbo àwọn ará Ìlà Oòrùn. (Jóòbù 1:3) Ó dájú pé inú Sátánì ò lè dùn rárá bó ṣe rí i pé ọkùnrin tó lówó tó sì lọ́lá yìí ń sin Jèhófà tọkàntọkàn!

5. Kí nìdí tí Jèhófà fi fàyè gba Sátánì kó fìyà jẹ Jóòbù? (Jóòbù 1:20-22; 2:9, 10)

5 Sátánì sọ pé tí ọwọ́ ìyà bá tẹ Jóòbù, kò ní sin Jèhófà mọ́. (Jóòbù 1:7-11; 2:2-5) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Jóòbù, kò sì fẹ́ kó jìyà, Jèhófà fàyè gba Sátánì kó fìyà jẹ Jóòbù ká lè mọ̀ bóyá òótọ́ ni Sátánì ń sọ tàbí irọ́ ló ń pa. (Jóòbù 1:12-19; 2:6-8) Ni Sátánì bá pa gbogbo ẹran ọ̀sìn Jóòbù àtàwọn ọmọ ẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá (10). Ó wá fi eéwo tó ń roni lára kọ lu Jóòbù láti àtàrí dé àtẹ́lẹsẹ̀. Láìka gbogbo ohun tí Sátánì ṣe yìí sí, Jóòbù ò fi Jèhófà sílẹ̀. (Ka Jóòbù 1:20-22; 2:9, 10.) Nígbà tó yá, Jèhófà wo Jóòbù sàn, ó mú kó lọ́rọ̀, ó sì mú kó gbayì láwùjọ. Bákan náà, ó fi ọmọ mẹ́wàá míì dá a lọ́lá, ó sì fi ogóje (140) ọdún kún ọdún tó lò láyé débi pé ó rí àwọn ọmọ ẹ̀ àtàwọn ọmọ ọmọ ẹ̀, dé ìran kẹrin. (Jóòbù 42:10-13, 16) Àǹfààní wo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù yìí ì bá ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Àǹfààní wo ló sì lè ṣe àwa náà lónìí?

6. Àǹfààní wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò bá rí tó bá jẹ́ pé wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

6 Àǹfààní táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò bá rí. Nǹkan ò rọrùn rárá fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n wà ní Íjíbítì. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún ni Jóṣúà àti Kélẹ́bù fi ṣẹrú nílẹ̀ Íjíbítì. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lo ogójì (40) ọdún nínú aginjù torí pé àwọn kan lára wọn dẹ́ṣẹ̀. Tó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù àti bí Jèhófà ṣe san án lérè, ó dájú pé ó máa ran àwọn àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó máa jẹ́ kí wọ́n mọ ẹni tó fa ìyà tó ń jẹ aráyé. Yàtọ̀ síyẹn, wọn ò bá mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn àti bí inú ẹ̀ ṣe máa ń dùn tá a bá jẹ́ olóòótọ́.

Nígbà tí ọmọ Ísírẹ́lì kan ń mọ bíríkì ní Íjíbítì, ó ń ronú torí kò mọ ìdí tó fi ń jìyà. Nítòsí ẹ̀, àwọn ará Íjíbítì ń na àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan tó ń ṣiṣẹ́ kára.

Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ṣẹrú nílẹ̀ Íjíbítì, ó ṣeé ṣe kí wọ́n pa dà mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù, ìyẹn sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ (Wo ìpínrọ̀ 6)


7-8. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la kọ́ nínú ìwé Jóòbù tó lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ń jìyà? Sọ àpẹẹrẹ kan.

7 Àǹfààní tá a máa rí. Ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run mọ́ torí wọn ò mọ ìdí tí nǹkan burúkú fi máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn rere. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hazelb tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Rùwáńdà. Nígbà tó wà ní kékeré, ó nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Àmọ́, nǹkan yí pa dà fún un. Àwọn òbí ẹ̀ kọra wọn sílẹ̀, torí náà ọkùnrin míì tí ìyá ẹ̀ fẹ́ ló tọ́ ọ dàgbà, ọkùnrin náà sì fìyà jẹ ẹ́ gan-an. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ọkùnrin kan tún fipá bá a lòpọ̀. Hazel wá lọ sílé ìsìn tó ń dara pọ̀ mọ́, àmọ́ dípò kí wọ́n tù ú nínú, wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tó yá, Hazel kọ lẹ́tà sí Ọlọ́run. Ohun tó sọ nínú lẹ́tà náà ni pé: “Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo gbàdúrà sí ẹ, mo sì máa ń gbìyànjú láti ṣe ohun tó o fẹ́, àmọ́ ibi lo fi san án fún mi. Ní báyìí, mi ò ní sìn ẹ́ mọ́, ohun tó bá sì wù mí ni màá máa ṣe.” Ó máa ń dùn wá gan-an tá a bá rí àwọn tó nírú èrò tí Hazel ní yìí, torí àwọn èèyàn ti mú kí wọ́n rò pé Ọlọ́run ló ń fìyà jẹ wọ́n.

8 Àmọ́, àwa ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Jóòbù pé Sátánì ló ń fa ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn, kì í ṣe Ọlọ́run. Bákan náà, a ti kẹ́kọ̀ọ́ pé tẹ́nì kan bá ń jìyà, kò yẹ ká máa rò pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ ló ń jẹ. Bíbélì ti jẹ́ ká mọ̀ pé “ìgbà àti èèṣì” lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni nígbàkigbà. (Oníw. 9:11; Jóòbù 4:1, 8) A tún ti kẹ́kọ̀ọ́ pé tá a bá fara da ìṣòro tá ò sì fi Jèhófà sílẹ̀, ńṣe là ń jẹ́ kí Jèhófà fún Sátánì lésì. Ìyẹn sì ń jẹ́ ká lè máa sọ orúkọ ẹ̀ di mímọ́. (Jóòbù 2:3; Òwe 27:11) A mọyì àwọn nǹkan tá a ti kọ́ yìí torí wọ́n jẹ́ ká mọ ìdí tá a fi ń jìyà. Nígbà tó yá, Hazel kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó wá mọ̀ pé Ọlọ́run kọ́ ló fa àwọn nǹkan tójú ẹ̀ ti rí. Ó sọ pé: “Mo pa dà gbàdúrà sí Ọlọ́run, mo sì sọ gbogbo bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi fún un. Mo sọ fún Jèhófà pé nígbà tí mo sọ pé mi ò ní sìn ín mọ́, kò wù mí kí n ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, mi ò mọ̀ pé òun kọ́ ló fa ìyà tó ń jẹ mí nígbà yẹn. Ní báyìí, mo ti wá rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi, torí náà inú mi ń dùn, ọkàn mi sì balẹ̀.” Inú wa dùn pé Jèhófà jẹ́ ká mọ ìdí táwa èèyàn fi ń jìyà. Ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá níṣòro.

BÍ ÌWÉ JÓÒBÙ ṢE LÈ JẸ́ KÁ FARA DA ÌṢÒRO

9. Sọ ohun tójú Jóòbù rí, kí ló sì ṣe? (Jémíìsì 5:11)

9 Ẹ fojú inú wo baba ńlá ìyà tó jẹ Jóòbù. Eéwo bò ó látòkè délẹ̀, ó dá jókòó sínú eérú, ó sì ń jẹ̀rora tó lékenkà. Gbogbo àwọ̀ ẹ̀ ló ti ṣì, ó sì ti rù keegun. Kò lókun mọ́ rárá, ó ń fi àfọ́kù ìkòkò họ ara ẹ̀, ó sì ń sọ bí ìrora tó ní ṣe pọ̀ tó. Láìka gbogbo ohun tójú Jóòbù rí yìí, ó fara dà á, kò sì fi Jèhófà sílẹ̀. (Ka Jémíìsì 5:11.) Kí ló jẹ́ kí Jóòbù lè fara dà á?

10. Àwọn nǹkan wo ni Jóòbù sọ nígbà tó ń sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀? Ṣàlàyé.

10 Jóòbù sọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ fún Jèhófà. (Jóòbù 10:1, 2; 16:20) Bí àpẹẹrẹ ní orí 3, àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ fi hàn pé ó ní ẹ̀dùn ọkàn, ìbànújẹ́ sì dorí ẹ̀ kodò torí àwọn àjálù tó ṣẹlẹ̀ sí i. Lọ́kàn ẹ̀, ó gbà pé Jèhófà ló fa àwọn ìṣòro tó ní. Lẹ́yìn náà, léraléra làwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù sọ fún un pé Ọlọ́run ló ń fìyà ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ jẹ ẹ́. Àmọ́ Jóòbù gbèjà ara ẹ̀, ó sì ń sọ pé Jèhófà gan-an mọ̀ pé olóòótọ́ lòun. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jóòbù sọ fi hàn pé láwọn ìgbà kan, ó gbà pé òun jẹ́ olóòótọ́ ju Ọlọ́run lọ. (Jóòbù 10:1-3; 32:1, 2; 35:1, 2) Àmọ́ ká sòótọ́, àwọn ìgbà kan wà tí Jóòbù gbà pé òun sọ “ọ̀rọ̀ ẹhànnà” nígbà tóun ń gbèjà ara òun. (Jóòbù 6:3, 26) Ní orí 31, Jóòbù fẹ́ kí Ọlọ́run fúnra ẹ̀ wá sọ pé òun ò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun. (Jóòbù 31:35) Àmọ́ kò yẹ kí Jóòbù sọ pé kí Jèhófà wá ṣàlàyé ìdí tóun fi ń jìyà.

11. Báwo ni Jèhófà ṣe dá Jóòbù lóhùn?

11 Ká sòótọ́, ọ̀nà tí Jóòbù gbà sọ̀rọ̀ fi hàn pé ó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ó sì dá a lójú pé Jèhófà máa dá sọ́rọ̀ òun, á sì ṣe ohun tó tọ́. Nígbà tí Jèhófà dá a lóhùn látinú ìjì, kò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ ìdí tí Jóòbù fi ń jìyà. Bákan náà, kò fìyà jẹ Jóòbù torí àwọn nǹkan tó sọ àti bó ṣe ń dá ara ẹ̀ láre. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni Jèhófà bá Jóòbù sọ̀rọ̀ bíi bàbá sọ́mọ. Ohun tí Jèhófà ṣe yìí sì ran Jóòbù lọ́wọ́. Ìyẹn jẹ́ kí Jóòbù gbà pé ìwọ̀nba ni nǹkan tóun mọ̀ nípa Jèhófà, ó sì ronú pìwà dà. (Jóòbù 31:6; 40:4, 5; 42:1-6) Tó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù, àǹfààní wo ni ì bá ṣe wọ́n? Àǹfààní wo ló sì lè ṣe wá lónìí?

12. Àǹfààní wo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù ì bá ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

12 Àǹfààní táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò bá rí. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ì bá kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mósè. Nígbà tí Mósè ń darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn èèyàn náà jẹ́ kíṣẹ́ náà nira fún un. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ìyẹn sì kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a. Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ti níṣòro, ṣe ni wọ́n máa ń kùn sí Jèhófà, àmọ́ ní ti Mósè, ṣe ló máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́. (Ẹ́kís. 16:6-8; Nọ́ń. 11:10-14; 14:1-4, 11; 16:41, 49; 17:5) Mósè tún nílò ìfaradà nígbà tí Jèhófà bá a wí. Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàgọ́ sí Kádéṣì, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n ti lo ogójì (40) ọdún nínú aginjù nígbà yẹn. Àsìkò yẹn ni Mósè “fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ láìronú,” kò sì fògo fún Jèhófà. (Sm. 106:32, 33) Torí ohun tí Mósè ṣe yìí, Jèhófà ò jẹ́ kó wọ Ilẹ̀ Ìlérí. (Diu. 32:50-52) Ó dájú pé ìbáwí yìí máa dun Mósè gan-an, àmọ́ torí pé ó nírẹ̀lẹ̀, ó gba ìbáwí náà. Tó bá jẹ́ pé àtọmọdọ́mọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù ni, wọn ò bá fara da àwọn ìṣòro tí wọ́n ní. Táwọn tó jẹ́ olóòótọ́ lára wọn bá ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù, ìyẹn ì bá jẹ́ kí wọ́n mọ ọ̀nà tó dáa jù láti sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn fún Jèhófà, wọn ò sì ní máa sọ pé òdodo àwọn ju ti Jèhófà lọ. Wọ́n á tún rí i pé ó yẹ káwọn nírẹ̀lẹ̀ tí Jèhófà bá bá àwọn wí.

13. Báwo ni ìwé Jóòbù ṣe lè jẹ́ ká fara da ìṣòro wa? (Hébérù 10:36)

13 Àǹfààní tá a máa rí. Ó yẹ káwa Kristẹni náà ní ìfaradà. (Ka Hébérù 10:36.) Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lára wa ń ṣàìsàn tó le, àwọn míì sì ní ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára. Ìṣòro ìdílé làwọn kan ń bá yí, àwọn míì sì ń ṣọ̀fọ̀ èèyàn wọn tó ti kú tàbí kó jẹ́ pé àwọn ìṣòro míì tó le ni wọ́n ń bá yí. Nígbà míì sì rèé, ìwà táwọn èèyàn hù tàbí ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ lè mú kó ṣòro fún wa láti fara da àwọn ìṣòro yẹn. (Òwe 12:18) Àmọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù jẹ́ ká rí i pé a lè sọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa fún Jèhófà, kó sì dá wa lójú pé á gbọ́ àdúrà wa. (1 Jòh. 5:14) Kò ní bínú sí wa tá a bá ń sọ ohun tó ń ṣe wá, kódà nígbà míì tá a bá sọ “ọ̀rọ̀ ẹhànnà” bíi ti Jóòbù. Kàkà bẹ́ẹ̀, á fún wa lókun, á sì fún wa lọ́gbọ́n ká lè fara da ìṣòro náà. (2 Kíró. 16:9; Jém. 1:5) Àmọ́ tó bá gba pé kó bá wa wí bíi ti Jóòbù, ó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Tá a bá ka ohun kan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó bá wa wí, tí ètò Ọlọ́run tàbí àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn bá bá wa wí, ìwé Jóòbù lè jẹ́ ká fara dà á. (Héb. 12:5-7) Torí náà bíi ti Jóòbù, àwa náà máa jàǹfààní tá a bá nírẹ̀lẹ̀, tá a sì gba ìbáwí tí wọ́n fún wa. (2 Kọ́r. 13:11) Ẹ ò rí i pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè kọ́ nínú ìwé Jóòbù! Ẹ jẹ́ ká wá wo bá a ṣe lè fi ohun tó wà nínú ìwé Jóòbù ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.

BÓ O ṢE LÈ FI ÌWÉ JÓÒBÙ RAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́

14. Tẹ́nì kan bá béèrè ìdí tá a fi ń jìyà, kí lo máa sọ?

14 Ó ṣeé ṣe kó o ti pàdé ẹnì kan rí nígbà tó ò ń wàásù tẹ́ni náà sì bi ẹ́ pé, ‘Kí nìdí tá a fi ń jìyà?’ Báwo lo ṣe dáhùn ìbéèrè yẹn? Ó ṣeé ṣe kó o ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ pé ó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì. Bóyá o kọ́kọ́ ṣàlàyé pé Sátánì tó jẹ́ ẹni ibi parọ́ fún Ádámù àti Éfà, ìyẹn sì mú kí wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. (Jẹ́n. 3:1-6) O tún wá sọ fún un pé àìgbọràn Ádámù àti Éfà ló fà á tá a fi ń jìyà, tá a sì ń kú. (Róòmù 5:12) Nígbà tó ò ń parí ọ̀rọ̀ ẹ, ó ṣeé ṣe kó o ṣàlàyé pé Ọlọ́run fẹ́ kí àkókò tó pọ̀ kọjá kó lè hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa, ìyẹn á sì jẹ́ káwọn èèyàn lè gbọ́ ìhìn rere náà pé lọ́jọ́ iwájú Ọlọ́run máa mú ìyà tó ń jẹ aráyé kúrò, àwa èèyàn á sì di pípé. (Ìfi. 21:3, 4) Àlàyé yìí dáa gan-an, ó sì ti jẹ́ kọ́pọ̀ èèyàn mọ ìdí tá a fi ń jìyà.

15. Tẹ́nì kan bá béèrè ìdí tá a fi ń jìyà, báwo la ṣe lè fi ìwé Jóòbù dáhùn ìbéèrè yẹn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Ẹ jẹ́ ká tún wo ọ̀nà míì tá a lè gbà dáhùn ìbéèrè yẹn. A lè lo ohun tó wà nínú ìwé Jóòbù. O lè kọ́kọ́ gbóríyìn fún ẹni náà pé ìbéèrè pàtàkì ló béèrè yẹn. Kó o wá sọ fún un pé Jóòbù tó jẹ́ olóòótọ́ náà béèrè ìdí tóun fi ń jìyà. Ó tiẹ̀ rò pé Ọlọ́run ló fa ìyà tó ń jẹ òun. (Jóòbù 7:17-21) Ó lè ya ẹni náà lẹ́nu pé ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń béèrè ìbéèrè yìí. Lẹ́yìn náà, o lè fọgbọ́n ṣàlàyé fún un pé Èṣù ló fìyà jẹ Jóòbù, kì í ṣe Ọlọ́run. Èṣù sọ pé torí ohun tá à ń rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run la ṣe ń sìn ín, pé tọ́wọ́ ìyà bá bà wá, a ò ní sin Ọlọ́run mọ́. Ìdí nìyẹn tó ṣe fìyà jẹ Jóòbù. Kó o wá jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ pé Ọlọ́run kọ́ ló fìyà jẹ ẹ́, ṣe ló kàn fàyè gbà á torí ó mọ̀ pé àwọn ìránṣẹ́ òun máa jẹ́ olóòótọ́ bó ti wù kí ìyà náà pọ̀ tó, wọ́n á sì fi hàn pé irọ́ gbuu ni Sátánì ń pa. Tó o bá fẹ́ parí ọ̀rọ̀ ẹ, o lè sọ fún ẹni náà pé nígbà tó yá Ọlọ́run bù kún Jóòbù torí pé ó jẹ́ olóòótọ́. Torí náà, tá a bá jẹ́ kó dá àwọn èèyàn lójú pé Ọlọ́run kọ́ ló fa ìyà tó ń jẹ aráyé, ìyẹn á tù wọ́n nínú.

Fọ́tò: 1. Obìnrin kan tí ẹ̀dùn ọkàn bá mú fọ́tò kan dání, ó rí fọ́tò náà nílẹ̀ lẹ́yìn tí iná ńlá kan jó àwọn nǹkan ní agbègbè wọn. 2. Nígbà tó yá, obìnrin náà dúró níbi tá a pàtẹ iwé wa sí nítòsí ibi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn tí àjálù bá, arábìnrin kan sì ń ka ẹsẹ Bíbélì kan fún un.

Báwo lo ṣe lè lo ìwé Jóòbù láti mú kó dá àwọn èèyàn lójú pé “Ọlọ́run kì í hùwà burúkú”? (Wo ìpínrọ̀ 15)


16. Sọ ìrírí kan tó jẹ́ ká rí i pé ìwé Jóòbù lè ran ẹni tó ń jìyà lọ́wọ́.

16 Ẹ jẹ́ ká wo bí ìwé Jóòbù ṣe ran Mario lọ́wọ́. Lọ́jọ́ kan lọ́dún 2021, arábìnrin kan ń wàásù lórí fóònù. Mario ni arábìnrin náà kọ́kọ́ pè, ó sì ka ẹsẹ Bíbélì kan fún un tó jẹ́ kó mọ̀ pé Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà wa, ó sì ti ṣèlérí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Nígbà tí arábìnrin náà béèrè ohun tó rò, Mario sọ fún un pé ńṣe lòun fẹ́ pa ara òun. Kódà, lẹ́tà ìdágbére lòun ń kọ lọ́wọ́ tí arábìnrin náà fi pe òun. Ó sọ pé, “Òótọ́ ni pé mo gba Ọlọ́run gbọ́, àmọ́ mi ò gbà pé ó rí tèmi rò.” Nígbà míì tí arábìnrin náà pe Mario lórí fóònù, wọ́n sọ̀rọ̀ nípa bí Jóòbù ṣe jìyà. Mario wá pinnu pé òun máa ka ìwé Jóòbù látòkè délẹ̀. Arábìnrin náà wá fi ìlujá Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ránṣẹ́ sí i. Lẹ́yìn náà, ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó lè mọ̀ sí i nípa Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ yìí.

17. Kí nìdí tó o fi mọyì bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí ìwé Jóòbù wà nínú Bíbélì? (Jóòbù 34:12)

17 Kò sí àní-àní pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára láti tún ayé àwa èèyàn ṣe, kó sì tu àwọn tó ń jìyà nínú. (Héb. 4:12) Inú wa mà dùn o pé Jèhófà jẹ́ kí wọ́n kọ ìtàn Jóòbù sínú Bíbélì! (Jóòbù 19:23, 24) Ìwé Jóòbù fi dá wa lójú pé “Ọlọ́run kì í hùwà burúkú.” (Ka Jóòbù 34:12.) Ó tún jẹ́ ká mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ wá àti bá a ṣe lè fara dà á. Yàtọ̀ síyẹn, ó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè tu àwọn tó ń jìyà nínú. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí ìwé Jóòbù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ fún àwọn èèyàn nímọ̀ràn tó dáa.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Àǹfààní wo là ń rí torí pé a mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó jẹ Jóòbù?

  • Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù ṣe lè jẹ́ ká fara da ìṣòro?

  • Báwo la ṣe lè fi ìwé Jóòbù ran àwọn èèyàn lọ́wọ́?

ORIN 156 Mo Ní Ìgbàgbọ́

a Ẹ̀rí fi hàn pé lẹ́yìn tí Jósẹ́fù kú (lọ́dún 1657 Ṣ.S.K.) sígbà tí Jèhófà fi Mósè ṣe aṣáájú Ísírẹ́lì (ní nǹkan bí 1514 Ṣ.S.K.) ni Jóòbù gbé láyé. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àkókò yẹn ni Sátánì fẹ̀sùn kan Jóòbù níwájú Jèhófà, tó sì dán Jóòbù wò.

b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́