Ẹ Máa “Pa Ìṣọ̀kan Ẹ̀mí Mọ́”
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù pé ‘kí wọ́n máa fara dà á fún ara wọn nínú ìfẹ́, kí wọ́n máa sapá lójú méjèèjì láti pa ìṣọ̀kan ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà.’—Éfé. 4:2, 3.
Ẹsẹ yìí pe “ìṣọ̀kan” tó wà láàárín wa ní “ìṣọ̀kan ẹ̀mí.” Ó túmọ̀ sí pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń jẹ́ ká wà níṣọ̀kan. Àmọ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, ó gba pé ká ṣiṣẹ́ kára ká lè máa wà níṣọ̀kan. Ọwọ́ gbogbo wa nìyẹn sì wà. Torí náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára ká lè “pa ìṣọ̀kan ẹ̀mí mọ́.”
Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí, ká sọ pé ẹnì kan fún ẹ ní mọ́tò tuntun kan. Ta lá máa tọ́jú mọ́tò náà? Ó dájú pé ìwọ fúnra ẹ ni. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé mọ́tò náà bà jẹ́ torí pé o ò tọ́jú ẹ̀ dáadáa, ṣé ẹni tó fún ẹ ní mọ́tò náà ni wàá dá lẹ́bi? Rárá o!
Lọ́nà kan náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ló jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín wa, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ sapá kí èṣù má bàa yà wá, ká sì máa ṣera wa lọ́kan. Tí àárín àwa àti arákùnrin tàbí arábìnrin kan ò bá gún, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé mò ń sapá ká lè yanjú ọ̀rọ̀ náà, ká sì wà níṣọ̀kan?’
“MÁA SAPÁ LÓJÚ MÉJÈÈJÌ” KÁ LÈ WÀ NÍṢỌ̀KAN
Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, àwọn ìgbà míì wà tó máa gba pé ká sapá gan-an ká lè wà níṣọ̀kan. Ìyẹn sì lè má rọrùn pàápàá tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ṣe ohun tó dùn wá. Ṣé ó dìgbà tá a bá lọ bá ẹni náà ká sì sọ ohun tó ṣe, ká tó lè fi hàn pé a fẹ́ kí ìṣọ̀kan wà? Kò pọn dandan. Bi ara ẹ pé, ‘Tí mo bá lọ bá ẹni náà, ṣé ó máa jẹ́ kọ́rọ̀ náà yanjú àbí ṣe ló máa dá kún un?’ Nígbà míì, ohun tó máa dáa jù ni pé ká gbójú fo ọ̀rọ̀ náà tàbí ká tiẹ̀ dárí ji ẹni náà.—Òwe 19:11; Máàkù 11:25.
Bi ara ẹ pé, ‘Tí mo bá lọ bá ẹni náà, ṣé ó máa jẹ́ kọ́rọ̀ náà yanjú àbí ṣe ló máa dá kún un?’
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ká máa ‘fara dà á fún ara wa nínú ìfẹ́.’ (Éfé. 4:2) Ìwé ìwádìí kan sọ pé a tún lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí sí, “ká gba àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe rí.” Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé, aláìpé bíi tiwa làwọn ará wa, wọ́n sì lè ṣàṣìṣe. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ṣe ni gbogbo wa ń sapá ká lè gbé “ìwà tuntun wọ̀.” (Éfé. 4:23, 24) Àmọ́, kò sí ẹnì kankan nínú wa tó lè ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó pé. (Róòmù 3:23) Tá a bá gbà bẹ́ẹ̀, á rọrùn fún wa láti fara dà á fún ara wa, àá máa dárí ji ara wa, àá sì lè máa “pa ìṣọ̀kan ẹ̀mí mọ́.”
Tá a bá ń dárí ji ara wa, tá a sì gbé ohun tẹ́ni náà ṣe kúrò lọ́kàn, “ìdè ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà” tó wà láàárín wa á túbọ̀ lágbára. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ìdè ìrẹ́pọ̀” nínú Éfésù 4:3 ni wọ́n lò fún “àwọn iṣan” ní Kólósè 2:19. Àwọn iṣan máa ń lágbára débi pé wọ́n máa ń so àwọn eegun pa pọ̀. Lọ́nà kan náà, tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, tá a sì ń sapá láti wà lálàáfíà pẹ̀lú wọn, a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun da àárín wa rú tí wọ́n bá tiẹ̀ ṣe ohun tó dùn wá.
Torí náà, tí arákùnrin tàbí arábìnrin wa bá ṣe ohun tó dùn wá tàbí tó múnú bí wa, ó yẹ ká gbìyànjú láti mọ ohun tó fà á tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ dípò ká máa ronú ṣáá nípa ohun tí ò dáa tẹ́ni náà ṣe. (Kól. 3:12) Torí aláìpé ni gbogbo wa, ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti ṣe ohun tó dun ẹnì kan rí. Tá a bá ń rántí kókó yìí, àá lè máa “pa ìṣọ̀kan ẹ̀mí mọ́.”