ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 November ojú ìwé 30
  • Àpilẹ̀kọ Tó Ń Tu Àwọn Obìnrin Tí Wọ́n Hùwà Ìkà sí Nínú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpilẹ̀kọ Tó Ń Tu Àwọn Obìnrin Tí Wọ́n Hùwà Ìkà sí Nínú
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀rọ̀ Ààbò Àwọn Obìnrin—Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Máa Lo Ìkànnì jw.org Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ—“Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • “Awọn Obinrin Ti Wọn Nṣiṣẹ Kára Ninu Oluwa”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 November ojú ìwé 30
Arábìnrin kan ń fún obìnrin kan ní ìwé “Ọ̀rọ̀ Ààbò Àwọn Obìnrin—Ohun Tí Bíbélì Sọ”

Àpilẹ̀kọ Tó Ń Tu Àwọn Obìnrin Tí Wọ́n Hùwà Ìkà sí Nínú

“Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé tó jẹ́ obìnrin ni wọ́n ti hùwà ìkà sí kárí ayé. Ṣé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, wàá rí i pé ọ̀rọ̀ ẹ jẹ Ọlọ́run lógún àti pé ó máa wá nǹkan ṣe sí ìwà ìkà tí wọ́n ń hù sáwọn obìnrin.”

Ọ̀rọ̀ yìí ló bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ náà, “Ọ̀rọ̀ Ààbò Àwọn Obìnrin—Ohun Tí Bíbélì Sọ” tó wà lórí ìkànnì jw.org. Nísàlẹ̀ àpilẹ̀kọ náà, ìlujá kan wà níbẹ̀ téèyàn ti lè wa ẹ̀dà ti orí ìwé jáde. Lẹ́yìn náà, a lè tẹ̀ ẹ́, ká sì ká a sí ojú ìwé mẹ́rin. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Stacy lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Mo tẹ ìwé yìí jáde, èmi àti arábìnrin kan sì lọ pín in fáwọn tó wà níbi tí wọ́n ti ń bójú tó àwọn obìnrin tí wọ́n hùwà ìkà sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa.”

Ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ béèrè lọ́wọ́ Stacy pé, ‘Ṣé ẹ lè bá wa kó ìwé yìí sí i wá?’ Torí náà, wọ́n kó ogójì (40) ìwé yìí àti ọgbọ̀n (30) káàdì ìkànnì jw.org lọ fún wọn. Nígbà tí wọ́n pa dà lọ, ẹni tó jẹ́ ọ̀gá wọn níbẹ̀ sọ pé ó máa wu òun kí wọ́n máa kọ́ àwọn obìnrin náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Stacy àtàwọn arábìnrin méjì tún lọ sí ibòmíì tí wọ́n ti ń bójú tó àwọn obìnrin tí wọ́n hùwà ìkà sí. Wọ́n gba márùn-ún lára ìwé náà, wọ́n sì sọ pé kí wọ́n kó sí i wá tí wọ́n bá ń bọ̀ nígbà míì. Ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ sọ pé: “Ìwé yìí máa ran àwọn obìnrin tó wà níbí lọ́wọ́. Ohun tá a nílò gan-an rèé.” Nígbà míì tí wọ́n lọ síbẹ̀, díẹ̀ lára àwọn tó wà níbẹ̀ kóra jọ, kí wọ́n lè rí bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe tán, méjì nínú wọn sọ pé ó máa wu àwọn láti wá sí ìpàdé tá a máa ṣe lópin ọ̀sẹ̀ yẹn.

Stacy sọ pé: “Inú wa dùn láti rí i pé àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ìwé yìí, wọ́n sì gbà á gan-an. Bá a ṣe tẹ ìwé yìí jáde jẹ́ kó rọrùn láti sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn obìnrin tí wọ́n ti hùwà ìkà sí. Orí wa wú nígbà tá a rí i pé ohun tó wà nínú ìwé náà wọ̀ wọ́n lọ́kàn. A mọ̀ pé Jèhófà máa bù kún wa bá a ṣe ń sapá láti kéde ìhìn rere fáwọn obìnrin tí wọ́n ti fojú wọn rí màbo.”

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́