ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 November ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbá Ẹranko Rírorò Méjì Wọ̀jà
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
  • Ohun Tí Ìwé Ìfihàn Sọ Pé Ó Máa Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Ọ̀tá Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Pípa Bábílónì Ńlá Run
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
  • Má Ṣe Bẹ̀rù Àwọn Ẹranko Abàmì Náà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 November ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí lohun tí Jèhófà máa fi sọ́kàn àwọn orílẹ̀-èdè lọ́jọ́ iwájú?

Nígbà tí Ìfihàn 17:16, 17 ń sọ nípa bí ìpọ́njú ńlá ṣe máa bẹ̀rẹ̀, ó sọ pé: “Ìwo mẹ́wàá tí o rí àti ẹranko náà, máa kórìíra aṣẹ́wó náà, wọ́n máa sọ ọ́ di ahoro, wọ́n á tú u sí ìhòòhò, wọ́n máa jẹ ẹran ara rẹ̀, wọ́n sì máa fi iná sun ún pátápátá. Torí Ọlọ́run ti fi sí ọkàn wọn láti ṣe ohun tí òun fẹ́, àní láti ṣe ohun kan ṣoṣo tí wọ́n ń rò láti fún ẹranko náà ní ìjọba wọn.” Tẹ́lẹ̀, nínú àwọn ìwé wa, a sọ pé ohun tí Jèhófà máa fi sọ́kàn àwọn orílẹ̀-èdè ni pé kí wọ́n pa ìsìn èké run.

Àmọ́ ní báyìí, a rí i pé ó yẹ ká ṣàtúnṣe òye tá a ní. Ohun tí Jèhófà máa fi sọ́kàn àwọn orílẹ̀-èdè ni pé kí wọ́n “fún ẹranko náà ní ìjọba wọn.” Ká lè mọ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe máa ṣẹ, ẹ jẹ́ ká dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

Àwọn wo ni àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ̀rọ̀ nípa wọn? Bíbélì tún pe “aṣẹ́wó” náà ní “Bábílónì Ńlá,” ó sì ṣàpẹẹrẹ àpapọ̀ ìsìn èké àgbáyé. “Ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” náà ṣàpẹẹrẹ àjọ táwọn èèyàn gbà pé ó máa mú àlàáfíà wá. Àjọ yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lọ́dún 1919, Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni wọ́n ń pè é tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí ó ti di Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé. (Ìfi. 17:3-5) “Ìwo mẹ́wàá” náà ṣàpẹẹrẹ gbogbo ìjọba tó jẹ́ alátìlẹyìn ẹranko náà.

Àjọṣe wo ló wà láàárín aṣẹ́wó àti ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà? Aṣẹ́wó yìí “jókòó lórí” ẹranko náà, ó ń ti ẹranko náà lẹ́yìn, ó sì ń gbìyànjú láti máa darí ẹ̀ síbi tó fẹ́.

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí aṣẹ́wó náà? Ẹranko náà àti ìwo mẹ́wàá tó ń tì í lẹ́yìn “máa kórìíra aṣẹ́wó náà.” Wọ́n á kórìíra ẹ̀ débi pé wọ́n á gba gbogbo ọrọ̀ ẹ̀, wọ́n á sì tú àṣírí gbogbo ìwà burúkú ẹ̀. Bákan náà, Jèhófà máa lò wọ́n láti ṣèdájọ́ aṣẹ́wó náà, ìyẹn ni pé wọ́n á pa á run pátápátá. (Ìfi. 17:1; 18:8) Ohun tí wọ́n máa ṣe yìí ló máa fòpin sí gbogbo ìsìn èké. Àmọ́ kíyẹn tó ṣẹlẹ̀, Jèhófà máa mú kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ohun kan tí kò ṣẹlẹ̀ rí látìgbà táwọn èèyàn ti ń ṣàkóso ara wọn.

Kí ni Jèhófà máa mú kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe? Jèhófà máa fi sí ọkàn ìwo mẹ́wàá náà láti ṣe “ohun tí òun fẹ́,” ìyẹn ni pé àwọn orílẹ̀-èdè máa fún ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó ṣàpẹẹrẹ Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé “ní agbára àti àṣẹ wọn.” (Ìfi. 17:13) Rò ó wò ná. Ṣé o rò pé àwọn ìjọba ayé kàn máa ṣàdédé pinnu láti fún ẹranko náà ní agbára àti àṣẹ wọn? Rárá o. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ló máa mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. (Òwe 21:1; fi wé Àìsáyà 44:28.) Ṣé díẹ̀díẹ̀ ni nǹkan yìí á máa ṣẹlẹ̀? Rárá o. Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé òjijì ló máa ṣẹlẹ̀. Ẹranko tó ti gba agbára àti àṣẹ yìí máa pa gbogbo ìsìn èké run bí Jèhófà ṣe sọ, wọn ò sì ní gbérí mọ́.

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́? Kò yẹ ká máa dara wa láàmú nípa ìròyìn tó ń fi hàn pé àwọn orílẹ̀-èdè ń ti Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé lẹ́yìn, wọ́n sì ń fún un lágbára díẹ̀díẹ̀. Ohun tá à ń retí ni pé: Lójijì, Jèhófà máa mú káwọn orílẹ̀-èdè fún ẹranko náà ní agbára àti àṣẹ wọn. Tíyẹn bá ṣẹlẹ̀, àá mọ̀ pé ìpọ́njú ńlá ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Àmọ́ ní báyìí, “ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò, kí a sì máa ronú bó ṣe tọ́” torí pé láìpẹ́ àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀ lójijì!—1 Tẹs. 5:6.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́