GBÓLÓHÙN KAN LÁTINÚ BÍBÉLÌ
Máa Lo “Ẹ̀bùn Ẹ̀mí” Tó O Ní
Gbogbo wa la máa ń mọyì ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró táwọn ará máa ń sọ tá a bá wà lọ́dọ̀ wọn. Tá a bá fẹ́ kí àkókò tá a jọ wà pa pọ̀ yẹn ṣe wá láǹfààní, a gbọ́dọ̀ lò ó dáadáa. Bíbélì sọ pé tá a bá ń gbé àwọn ará ró kí ìgbàgbọ́ wọn lè lágbára, ńṣe là ń fún wọn ní “ẹ̀bùn ẹ̀mí.” (Róòmù 1:11, 12) Àwọn nǹkan wo la lè ṣe táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára?
Máa sọ̀rọ̀ tó máa gbé àwọn ará ró. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ń dáhùn nípàdé, ṣọ́ra kó má jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ara ẹ nìkan ni wàá máa sọ ṣáá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó o tún máa sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, Bíbélì àtàwọn ará. Torí náà, tó o bá wà lọ́dọ̀ àwọn ará, àwọn nǹkan tó máa gbé wọn ró, táá sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára ni kó o máa sọ.
Máa ṣe ohun táá fún àwọn ará níṣìírí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará kan lè rí i pé o ò fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sílẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé o láwọn ìṣòro tó ò ń bá yí. Ìpinnu tó o ṣe yìí lè fún wọn níṣìírí. Ìṣírí ló máa ń jẹ́ fáwọn ará wa kan tí wọ́n bá rí i pé ò ń wá sípàdé àárín ọ̀sẹ̀ déédéé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé o láwọn àìlera kan tàbí pé iṣẹ́ máa ń gba àkókò ẹ gan-an.
Torí náà bi ara ẹ pé, ṣé ohun tí mo máa ń sọ àtohun tí mò ń ṣe máa ń fún àwọn ará níṣìírí? Ṣé mo sì máa ń kíyè sí ohun táwọn ará ń sọ, tí wọ́n sì ń ṣe láti fún mi níṣìírí?